ÀPILẸ̀KỌ 45
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
Ohun Tó O Lè Ṣe Kínú Ẹ Lè Máa Dùn Tó O Bá Ń Tọ́jú Èèyàn Ẹ
“Àwọn tó ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ayọ̀ kórè.”—SM. 126:5.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn tó ń tọ́jú arúgbó tàbí àwọn tára wọn ò yá máa ń ní. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa láyọ̀.
1-2. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń tọ́jú arúgbó tàbí tára wọn ò yá? (Òwe 19:17) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
ARÁKÙNRIN Jin-yeol tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòríà sọ pé: “Ó ti lé lọ́dún méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí èmi àti ìyàwó mi ti ṣègbéyàwó. Ó ti ju ọdún márùn-ún báyìí tó ti ń ṣàìsàn, èmi ni mo sì ń tọ́jú ẹ̀. Àìsàn Parkinson tó máa ń jẹ́ kí ọwọ́ àtẹsẹ̀ gbọ̀n ló ń ṣe é, àìsàn náà sì máa ń jẹ́ kó ṣòro fún un láti kúrò lójú kan. Mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi gan-an, mo sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tọ́jú ẹ̀. Tó bá dalẹ́, orí bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n ṣe fáwọn aláìsàn ló máa ń sùn sí nílé wa. Mo máa ń sùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀, àá sì di ọwọ́ ara wa mú tá a bá fẹ́ sùn.”
2 Ṣé ìwọ lò ń tọ́jú àwọn òbí ẹ, ọkọ tàbí aya ẹ, ọmọ ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an bó o ṣe ń ran ẹni náà lọ́wọ́ torí pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Bó o sì ṣe ń tọ́jú ẹni náà tún fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Tím. 5:4, 8; Jém. 1:27) Àmọ́, o lè láwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó má hàn sáwọn èèyàn. Kódà nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó mọ ohun tó ò ń bá yí. Tó o bá wà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, ó ṣeé ṣe kí ìṣòro náà má hàn lójú ẹ, àmọ́ tó bá kùwọ nìkan, ọ̀rọ̀ náà lè tojú sú ẹ, kó sì gba omijé lójú ẹ. (Sm. 6:6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè má mọ ìṣòro tó ò ń bá yì, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ̀ ọ́n. (Fi wé Ẹ́kísódù 3:7.) Jèhófà ń rí omijé ẹ, ó sì mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe bó o ṣe ń tọ́jú ẹni náà. (Sm. 56:8; 126:5) Ó ń kíyè sí bó o ṣe ń ran èèyàn ẹ lọ́wọ́, bóyá arúgbó lẹ́ni náà tàbí ẹni tára ẹ̀ ò yá. Jèhófà gbà pé òun lo ṣe é fún, òun á sì san án pa dà fún ẹ.—Ka Òwe 19:17.
Ṣé ìwọ lò ń tọ́jú èèyàn ẹ kan tó ti darúgbó tàbí tó ń ṣàìsàn? (Wo ìpínrọ̀ 2)
3. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kí Ábúráhámù àti Sérà ní nígbà tí wọ́n ń tọ́jú Térà?
3 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n tọ́jú àwọn arúgbó àtàwọn tára wọn ò yá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Ábúráhámù àti Sérà. Nígbà tí wọ́n kúrò nílùú Úrì, Térà bàbá wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó, ó tẹ̀ lé wọn lọ. Wọ́n rìnrìn àjò nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgọ́ta (960) kìlómítà lọ sí Háránì. (Jẹ́n. 11:31, 32) Ó dájú pé Ábúráhámù àti Sérà nífẹ̀ẹ́ Térà, àmọ́ ẹ wo bó ṣe máa nira fáwọn méjèèjì láti bójú tó bàbá tó ti darúgbó yìí bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ràkúnmí tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni Térà gùn, ó sì dájú pé kò ní rọrùn fún un torí ara ti dara àgbà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣeé ṣe kó rẹ Ábúráhámù àti Sérà tẹnutẹnu bí wọ́n ṣe ń tọ́jú Térà nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò náà. Èyí ó wù ó jẹ́, Jèhófà fún wọn lókun tí wọ́n nílò nígbà ìrìn àjò náà. Torí náà, bí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù àti Sérà lókun láti tọ́jú Térà, ó dájú pé ó máa fún ìwọ náà lókun láti tọ́jú èèyàn ẹ tó ti darúgbó tàbí tára ẹ̀ ò yá.—Sm. 55:22.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Tó o bá ń láyọ̀, wàá lè fara dà á bó o ṣe ń tọ́jú èèyàn ẹ tó ti darúgbó tàbí tára ẹ̀ ò yá. (Òwe 15:13) Má gbàgbé pé o lè láyọ̀ tí nǹkan ò bá tiẹ̀ rọrùn fún ẹ. (Jém. 1:2, 3) Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè máa láyọ̀? Ọ̀kan lára ohun tó o lè ṣe ni pé kó o bẹ Jèhófà kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kínú ẹ lè máa dùn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe tó o bá ń tọ́jú èèyàn ẹ tó ti darúgbó tàbí tára ẹ̀ ò yá. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa báwọn ará ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ káwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn máa láyọ̀ àtàwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún wọn láti láyọ̀.
ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÁWỌN TÓ Ń TỌ́JÚ ÈÈYÀN WỌN MÁ LÁYỌ̀ MỌ́
5. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn ò bá láyọ̀ mọ́?
5 Táwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn ò bá láyọ̀ mọ́, ìyẹn lè mú kíṣẹ́ náà sú wọn. (Òwe 24:10) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n lè má fìfẹ́ hàn sẹ́ni náà mọ́, kí wọ́n má sì tọ́jú ẹ̀ dáadáa mọ́. Àmọ́, àwọn nǹkan wo ló lè mú káwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn má láyọ̀ mọ́?
6. Kí nìdí tó fi máa ń rẹ àwọn kan tẹnutẹnu bí wọ́n ṣe ń tọ́jú èèyàn wọn?
6 Ó máa ń rẹ àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn tẹnutẹnu. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Leah sọ pé: “Kì í rọrùn rárá láti tọ́jú arúgbó tàbí ẹni tára ẹ̀ ò yá. Tílẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá fi máa ṣú, á ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Nígbà míì, á ti rẹ̀ mí débi pé mi ò ní lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù.” Ní tàwọn míì, wọn kì í ráyè sùn dáadáa tàbí kí wọ́n sinmi tó bó ṣe yẹ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Inés sọ pé: “Mi ò kì í ráyè sùn dáadáa torí pé wákàtí méjì-méjì ni mo máa ń jí lóru kí n lè tọ́jú ìyá ọkọ mi. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé ọ̀pọ̀ ọdún lèmi àti ọkọ mi ò fi ráyè ṣeré jáde ká lè sinmi.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn kan tó ń tọ́jú èèyàn wọn kì í ráyè fáwọn nǹkan míì, irú bíi kí wọ́n lọ kí àwọn ọ̀rẹ́ wọn tàbí kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ìdí sì ni pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń dúró ti ẹni tí wọ́n ń tọ́jú. Gbogbo nǹkan yìí lè kó ìrònú bá wọn, kínú wọn má sì dùn torí pé wọn ò lè ṣe àwọn nǹkan tó wù wọ́n.
7. Kí ló lè mú káwọn kan tó ń tọ́jú èèyàn wọn máa dára wọn lẹ́bi tàbí kí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn?
7 Àwọn kan tó ń tọ́jú èèyàn wọn máa ń dára wọn lẹ́bi, wọ́n sì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn. Arábìnrin kan tó ń jẹ Jessica sọ pé: “Ó wù mí gan-an kí n tọ́jú bàbá mi dáadáa, àmọ́ nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò tọ́jú wọn bó ṣe yẹ. Tí mi ò bá sí lọ́dọ̀ wọn torí pé mo fẹ́ bójú tó ara mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé ohun tí mo ṣe yẹn ò dáa.” Inú àwọn kan tó ń tọ́jú èèyàn wọn kì í dùn torí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n sì máa ń dára wọn lẹ́bi. Ní táwọn kan, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò tọ́jú ẹni náà bó ṣe yẹ. Ohun tó sì ń mú káwọn ẹlòmíì dára wọn lẹ́bi ni pé nígbà tí nǹkan tojú sú wọn, wọ́n ti fìbínú sọ̀rọ̀ tí ò dáa sẹ́ni tí wọ́n ń tọ́jú. (Jém. 3:2) Àwọn míì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n bá rí i pé ẹni tí wọ́n ń tọ́jú ò lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, tí ìlera ẹni náà sì ń burú sí i. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó bà mí nínú jẹ́ jù ni bí mo ṣe rí i pé àìsàn tó ń ṣe ọ̀rẹ́ mi tí mo fẹ́ràn gan-an ń burú sí i lójoojúmọ́.”
8. Báwo ló ṣe rí lára ẹni tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ kan nígbà tẹ́ni náà dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.
8 Ó máa ń ṣe àwọn kan tó ń tọ́jú èèyàn wọn bíi pé ẹni náà ò mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń rò bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni tí wọ́n ń tọ́jú náà kì í sábà dúpẹ́ tàbí yìn wọ́n torí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe. Torí náà, tẹ́ni tí wọ́n ń tọ́jú bá ń gbóríyìn fáwọn tó ń tọ́jú ẹ̀, inú wọn máa dùn. Wọ́n ṣáà máa ń sọ pé yinniyinni kẹ́ni lè ṣèmíì. (1 Tẹs. 5:18) Arábìnrin Melissa sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń bú sẹ́kún tí gbogbo nǹkan bá ti tojú sú mi. Àmọ́ táwọn tí mò ń tọ́jú bá sọ fún mi pé ‘O ṣé o, o kú ìtọ́jú mi,’ ṣe lara máa ń tù mí, inú mi sì máa ń dùn! Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí máa ń jẹ́ kára mi yá gágá lọ́jọ́ kejì, ó sì ń jẹ́ kí n lè máa tọ́jú wọn nìṣó.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ahmadu sọ bó ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tẹ́ni tó ń tọ́jú gbóríyìn fún un. Àìsàn wárápá ń ṣe ọmọ àbúrò ìyàwó ẹ̀ kan tó ń gbé lọ́dọ̀ wọn, òun àti ìyàwó ẹ̀ ló sì ń tọ́jú ọmọ náà. Ó ní: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà ò mọ gbogbo nǹkan tá à ń ṣe ká lè tọ́jú ẹ̀, inú wa máa ń dùn gan-an tó bá dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, tá a sì ka ọ̀rọ̀ tó kọ sínú ìwé fún wa pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ yín gan-an.’”
ÀWỌN NǸKAN TÓ O LÈ ṢE KÓ O LÈ MÁA LÁYỌ̀
9. Báwo làwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn ṣe lè mọ̀wọ̀n ara wọn?
9 Mọ̀wọ̀n ara ẹ. (Òwe 11:2) Kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń ráyè ṣohun tó wù wá, ó sì níbi tágbára wa mọ. Torí náà, ó yẹ kó o mọ ohun tágbára ẹ gbé àtohun tágbára ẹ ò gbé, kó o sì mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn bá fẹ́ lo máa lè ṣe. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé o mọ̀wọ̀n ara ẹ. Táwọn èèyàn bá fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Jay sọ pé: “Tá ò bá ṣe ju ohun tágbára wa gbé, ìyẹn á jẹ́ ká máa láyọ̀.”
10. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn máa lo ìfòyemọ̀? (Òwe 19:11)
10 Máa lo ìfòyemọ̀. (Ka Òwe 19:11.) Tó o bá mọ ohun tó mú kẹ́nì kan ṣe ohun tó bí ẹ nínú, ìyẹn á jẹ́ kó o ṣe sùúrù, kó o má sì gbaná jẹ. Ẹni tó ní ìfòyemọ̀ máa ń ronú jinlẹ̀ kó lè mọ ìdí tẹ́nì kan fi hùwà kan sóun. Ó tún yẹ ká rántí pé tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn kan tó le gan-an, ẹni náà lè hùwà tí ò dáa sí wa torí ìnira tí àìsàn náà fà. (Oníw. 7:7) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì tó máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tẹ́lẹ̀, tó sì máa ń ronú jinlẹ̀ lè ṣàdédé máa jiyàn tàbí kó máa bínú sáwọn èèyàn. Ó tún lè máa ṣàríwísí tàbí kó máa kanra. Torí náà, tó o bá ń ran ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó le lọ́wọ́, á dáa kó o ṣèwádìí nípa àìsàn tó ń ṣe é. Tó o bá mọ bí àìsàn náà ṣe le tó, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ̀ pé àìsàn tó ń ṣe é ló jẹ́ kó hùwà yẹn, kì í ṣe pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Òwe 14:29.
11. Àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì wo ló yẹ káwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn máa ṣe lójoojúmọ́? (Sáàmù 132:4, 5)
11 Máa wáyè ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Nígbà míì, ó lè gba pé kó o wáyè láti ṣe “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù tó o máa ṣe ni pé kó o jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ohun tí Ọba Dáfídì ṣe nìyẹn, ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú láyé ẹ̀. (Ka Sáàmù 132:4, 5.) Bíi Dáfídì, rí i dájú pé ò ń wáyè ka Bíbélì, o sì ń gbàdúrà lójoojúmọ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Elisha sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà, mo máa ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí mo kà nínú Sáàmù, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n láyọ̀. Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ jù ni àdúrà tí mò ń gbà sí Jèhófà, jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni mo sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.”
12. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ń tójú èèyàn wọn máa wáyè tọ́jú ara wọn?
12 Máa wáyè tọ́jú ara ẹ kó o lè nílera tó dáa. Àwọn tọ́wọ́ wọn máa ń dí kì í sábà jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore torí pé wọn kì í ráyè lọ ra oúnjẹ lọ́jà kí wọ́n lè fúnra wọn sè é, ìṣòro yìí sì kan àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn. Tó o bá fẹ́ ní ìlera tó dáa kí ọpọlọ ẹ sì jí pépé, ó yẹ kó o máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì máa ṣeré ìmárale. Torí náà láwọn ìgbà tó o bá ráyè, rí i pé o jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì ṣeré ìmárale. (Éfé. 5:15, 16) Bákan náà, rí i pé ò ń sùn dáadáa. (Oníw. 4:6) Ìwádìí kan fi hàn pé téèyàn bá ń sùn dáadáa, ó máa ń jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ìwé kan tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìlera tún sọ pé, téèyàn bá ń sùn dáadáa, kò ní jẹ́ kó máa ṣàníyàn jù, á sì jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀ nígbà ìṣòro. Ó tún yẹ kó o máa wáyè ṣeré jáde lọ gbafẹ́. (Oníw. 8:15) Arábìnrin kan tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ kó lè máa láyọ̀, ó sọ pé: “Tójú ọjọ́ bá dáa, mo máa ń jáde lọ síta kí n lè lọ gbatẹ́gùn. Bákan náà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù, mo máa ń rí i pé èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan máa ń jáde lọ gbafẹ́.”
13. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa rẹ́rìn-ín? (Òwe 17:22)
13 Máa túra ká, kó o sì máa ṣàwàdà. (Ka Òwe 17:22; Oníw. 3:1, 4) Tó o bá ń rẹ́rìn-ín, á jẹ́ kó o túbọ̀ nílera tó dáa. Tó bá jẹ́ pé ò ń tọ́jú arúgbó tàbí ẹni tára ẹ̀ ò yá, gbogbo nǹkan lè má lọ bó o ṣe rò. Àmọ́ tínú ẹ bá ń dùn tó o sì ń báwọn èèyàn ṣàwàdà tí nǹkan ò bá tiẹ̀ rọrùn, á jẹ́ kó o lè máa fara dà á. Yàtọ̀ síyẹn, tíwọ àtẹni tó ò ń tọ́jú bá jọ ń ṣe ohun táá pa yín lẹ́rìn-ín, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín.
14. Tó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán, àǹfààní wo lo máa rí?
14 Sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè máa láyọ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan kan ṣì lè máa kó ẹ lọ́kàn sókè. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, o lè sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán, tó o sì mọ̀ pé kò ní dá ẹ lẹ́bi. (Òwe 17:17) Ó dájú pé tẹ́ni náà bá fara balẹ̀ gbọ́ ẹ, tó sì sọ̀rọ̀ tó fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn máa jẹ́ kó o láyọ̀.—Òwe 12:25.
15. Tẹ́ ẹ bá ń ronú nípa ayé tuntun tí ò ní pẹ́ dé, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀?
15 Ẹ jọ máa ronú nípa ohun tẹ́ ẹ máa ṣe nínú Párádísè. Máa rántí pé bó o ṣe ń tọ́jú èèyàn ẹ ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, torí pé kì í ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe nìyẹn nígbà tó dá wa. (2 Kọ́r. 4:16-18) Mọ̀ dájú pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé níbi tá a ti máa ní “ìyè tòótọ́.” (1 Tím. 6:19) Tíwọ àtẹni tó ò ń tọ́jú bá ń sọ àwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ máa ṣe nínú ayé tuntun, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ máa láyọ̀. (Àìsá. 33:24; 65:21) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé: “Mo sábà máa ń sọ fún àwọn tí mò ń tọ́jú pé, láìpẹ́ nínú ayé tuntun àá jọ máa fi maṣíìnì ránṣọ, àá jọ sáré, àá sì jọ gun kẹ̀kẹ́. Bákan náà, àá jọ ṣe búrẹ́dì, àá sì se oúnjẹ aládùn fáwọn èèyàn wa tó bá jíǹde. Torí náà, èmi àtàwọn tí mò ń tọ́jú máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”
BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN TÓ Ń TỌ́JÚ ÈÈYÀN WỌN LỌ́WỌ́
16. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn lọ́wọ́ nínú ìjọ wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Máa ran àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn lọ́wọ́. Àwa tá a wà nínú ìjọ lè ran ẹni tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ tá abá dúró ti ẹni tó ń tọ́jú. Tá abá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí ẹni náà lè sinmi kó sì ráyè ṣe àwọn nǹkan míì tó bá fẹ́ ṣe. (Gál. 6:2) Àwọn ará kan nínú ìjọ máa ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa ran ẹni náà lọ́wọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Arábìnrin Natalya tó ń tọ́jú ọkọ ẹ̀ tí ò lè rìn sọ pé: “Arákùnrin kan níjọ wa máa ń wá dúró ti ọkọ mi, ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì lọ́sẹ̀. Wọ́n á jọ wàásù, wọ́n á jọ sọ̀rọ̀, wọ́n á sì jọ wo fíìmù. Inú ọkọ mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí arákùnrin yìí bá wà lọ́dọ̀ ẹ̀ ó sì mọyì ẹ̀. Èmi náà mọyì ẹ̀ torí ó máa ń jẹ́ kí n ráyè ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe, irú bíi kí n nasẹ̀ jáde.” Ohun míì tá a tún lè ṣe ni pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a lè lọ sùn sílé wọn ká lè bá wọn tọ́jú ẹni náà, kí ẹni tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ lè ráyè sùn dáadáa.
Báwo lo ṣe lè ran àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn lọ́wọ́ nínú ìjọ ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 16)a
17. Báwo la ṣe lè ran ẹni tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè gbádùn ìpàdé?
17 Máa ran ẹni tó ń tọ́jú èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè gbádùn ìpàdé. Ẹni tó ń tọ́jú arúgbó tàbí ẹni tára ẹ̀ ò yá lè má ráyè gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé, ní àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè torí bó ṣe ń bójú tó ẹni náà. Torí náà, àwọn ará ìjọ lè wá jókòó ti ẹni tí wọ́n ń tọ́jú náà jálẹ̀ ìpàdé tàbí fáwọn àkókò kan. Tó bá jẹ́ pé ẹni tí wọ́n ń tọ́jú náà ò lè kúrò nílé, o lè lọ sílé ẹ̀ kẹ́ ẹ lè jọ ṣèpàdé látorí fóònù, kẹ́ni tó ń tọ́jú ẹ̀ lè wá sípàdé lójúkojú.
18. Àwọn nǹkan wo la tún lè ṣe fáwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn?
18 Máa gbóríyìn fáwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn, kó o sì máa gbàdúrà fún wọn. Látìgbàdégbà, ó yẹ káwọn alàgbà máa bẹ àwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn wò. (Òwe 27:23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa la níṣòro tá à ń bá yí, ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn tó ń tọ́jú èèyàn wọn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. A tún lè bẹ Jèhófà pé kó fún wọn lókun, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa láyọ̀.—2 Kọ́r. 1:11.
19. Àwọn nǹkan wo ló máa ṣelẹ̀ láìpẹ́?
19 Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ń pa àwọn èèyàn lẹ́kún kúrò. Àìsàn àti ikú máa dohun ìgbàgbé. (Ìfi. 21:3, 4) Bákan náà, “ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín.” (Àìsá. 35:5, 6) Tó bá dìgbà yẹn, a ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní ṣe wàhálà mọ́ láti tọ́jú àwọn arúgbó àtàwọn tára wọn ò yá. Kódà Bíbélì sọ pé, “àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí” mọ́. (Àìsá. 65:17) Àmọ́ ní báyìí tá a ṣì ń retí ìgbà táwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní fi wá sílẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lókun. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká “lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.”—Kól. 1:11.
ORIN 155 Orísun Ayọ̀ Wa
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin méjì lọ dúró ti arábìnrin àgbàlagbà kan, kí ẹni tó ń tọ́jú ẹ̀ lè ráyè ṣeré jáde.