ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 November ojú ìwé 2-7
  • Bí Àwọn Tó Ti Darúgbó Ṣe Lè Máa Láyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Tó Ti Darúgbó Ṣe Lè Máa Láyọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÍNÚ ÀWỌN ARÚGBÓ MÁ DÙN
  • ÀWỌN NǸKAN TÓ MÁA JẸ́ KÁWỌN ARÚGBÓ LÁYỌ̀
  • BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ARÚGBÓ LỌ́WỌ́
  • Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Kí La Kọ́ Nínú Ohun Táwọn Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Kí Wọ́n Tó Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 November ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ 44

ORIN 138 Ẹwà Orí Ewú

Bí Àwọn Tó Ti Darúgbó Ṣe Lè Máa Láyọ̀

“Nígbà arúgbó wọn, wọ́n á máa lókun.”—SM. 92:14.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ìdí tó fi yẹ káwọn arúgbó máa láyọ̀ àtohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa láyọ̀.

1-2. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti darúgbó? (Sáàmù 92:12-14; tún wo àwòrán.)

LÁWỌN ibì kan, àwọn èèyàn gbà pé táwọn bá darúgbó, ó ma jẹ́ káwọn túbọ̀ gbayì. Àmọ́ láwọn ibòmíì kì í wu àwọn èèyàn kí wọ́n darúgbó. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o rántí ìgbà tó o kọ́kọ́ rí irun funfun lórí ẹ? O lè máa wò ó pé kó o sáré fà á tu káwọn èèyàn tó rí i. Àmọ́ nígbà tó yá, o wá rí i pé bó o ṣe ń fa àwọn irun funfun náà tu, bẹ́ẹ̀ làwọn míì ń yọ. Ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí jẹ́ ká rí i pé kò sọ́gbọ́n tá a lè dá sí i ká má darúgbó.

2 Àmọ́ ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti ń darúgbó? (Òwe 16:31) Ó fi àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ yìí wé igi tó ń gbilẹ̀. (Ka Sáàmù 92:12-14.) Kí nìdí tó fi lo àpèjúwe yìí? Àwọn igi tó ti pẹ́ láyé sábà máa ń ní ewé tó pọ̀, wọ́n sì máa ń yọ òdòdó tó lóòórùn dídùn. Bí àpẹẹrẹ, igi kan wà lórílẹ̀-èdè Japan tó ń jẹ́ flowering cherry, ó sì máa ń pẹ́ láyé gan-an. Àwọn kan lára àwọn igi yìí ti lò ju ẹgbẹ̀rún-ún (1,000) ọdún lọ, wọ́n sì rẹwà gan-an. Bíi tàwọn igi yìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti darúgbó náà rẹwà gan-an lójú ẹ̀. Ẹni tí wọ́n jẹ́ ni Jèhófà ń wò, kì í ṣe irun orí wọn tó ti funfun. Jèhófà mọyì bí àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti darúgbó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, tí wọ́n ní ìfaradà àti bí wọ́n ṣe ń fi òótọ́ sìn ín fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Tọkọtaya kan tó ti darúgbó jókòó síta, àwọn igi cherry tó rẹwà gan-an sì wà láyìíká ibẹ̀.

Bí igi ńlá kan ṣe ń dàgbà, á túbọ̀ máa rẹwà, bẹ́ẹ̀ làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti darúgbó ṣe rẹwà, tí wọ́n sì ṣeyebíye lójú Jèhófà àtàwọn ará (Wo ìpínrọ̀ 2)


3. Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn àgbàlagbà láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan?

3 Téèyàn bá ti darúgbó, ìyẹn ò sọ pé onítọ̀hún ò ṣeyebíye mọ́ lójú Jèhófà.a Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà lo àwọn àgbàlagbà láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, Sérà ti dàgbà gan-an nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé ó máa di ìyá orílẹ̀-èdè ńlá, Mèsáyà sì máa wà lára àtọmọdọ́mọ ẹ̀. (Jẹ́n. 17:15-19) Mósè ti dàgbà gan-an nígbà tí Jèhófà yàn-án láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní oko ẹrú Íjíbítì. (Ẹ́kís. 7:6, 7) Àpọ́sítélì Jòhánù náà sì ti darúgbó nígbà tí Jèhófà lò ó láti kọ ìwé márùn-ún nínú Bíbélì.

4. Kí ni Òwe 15:15 sọ pé ó máa ran àwọn arúgbó lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ọjọ́ ogbó? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Onírúurú ìṣòro làwọn tó ti darúgbó máa ń ní. Arábìnrin àgbàlagbà kan sọ ọ́ lọ́nà àwàdà pé, “Ẹni tó bá fẹ́ darúgbó gbọ́dọ̀ nígboyà torí pé ohun táwọn arúgbó ń bá yí kì í rọrùn.” Àmọ́ táwọn arúgbó bá ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀,b wọ́n á lè fara da àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó. (Ka Òwe 15:15.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan táwọn arúgbó lè ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ máa láyọ̀. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan táwọn ará lè ṣe láti ran àwọn tó ti darúgbó tó wà níjọ wọn lọ́wọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè mú kó ṣòro fáwọn arúgbó láti máa láyọ̀ tọ́jọ́ ogbó bá dé.

Tọkọtaya tá a rí nínú àwòrán tó ṣáájú dira wọn lọ́wọ́ mú, wọ́n dúró sábẹ́ igi cherry, wọ́n sì ń rẹ́rìn ín.

Táwọn tó ti darúgbó bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kínú wọn dùn, wọ́n á lè fara da ìṣòro ọjọ́ ogbó (Wo ìpínrọ̀ 4)


ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÍNÚ ÀWỌN ARÚGBÓ MÁ DÙN

5. Kí ló lè mú kínú àwọn kan tó ti darúgbó má dùn?

5 Tó o bá jẹ́ arúgbó, kí ló lè mú kínú ẹ má dùn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé o ò lè ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa dà di ọ̀dọ́ tí ara ẹ̀ jí pépé. (Oníw. 7:10) Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ruby sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi tí mo bá fẹ́ wọṣọ torí pé gbogbo ara ló máa ń ro mí. Ọ̀rọ̀ náà le débi pé mi ò lè dá gbé ẹsẹ̀ sókè tí mo bá fẹ́ wọ ìbọ̀sẹ̀. Ọwọ́ mi máa ń kú torí pé mo ní àìsàn aromọléegun, ìyẹn máa ń jẹ́ kó nira fún mi láti ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe, títí kan àwọn iṣẹ́ tí ò tó nǹkan.” Arákùnrin Harold tó ti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì rí sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé èmi náà ni mo wá dà báyìí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sú mi. Ara mi le gan-an nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Eré ìdárayá kan tí wọ́n ń pè ní baseball ni mo fẹ́ràn láti máa ṣe nígbà yẹn. Tá a bá ti ń ṣeré ìdárayá náà, àwọn tá a jọ wà ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan náà máa ń sọ pé, ‘Ẹ ju bọ́ọ̀lù sí Harold torí ó máa jù ú wọlé.’ Àmọ́ ní báyìí tára ti dara àgbà, tí wọ́n bá tiẹ̀ gbé bọ́ọ̀lù fún mi, mi ò rò pé màá lè jù ú.”

6. (a) Nǹkan míì wo ló lè mú kínú àwọn tó ti darúgbó má dùn? (b) Kí ló máa jẹ́ káwọn tó ti darúgbó mọ̀ bóyá kí wọ́n ṣì máa wakọ̀ tàbí kí wọ́n má wakọ̀ mọ́? (Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ó Yẹ Kí N Ṣì Máa Wakọ̀?” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí)

6 Nǹkan míì tó lè mú kínú àwọn tó ti darúgbó má dùn ni pé wọn ò lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe fúnra wọn tẹ́lẹ̀ mọ́. Ó lè gba pé kí ẹnì kan máa wá ràn wọ́n lọ́wọ́ nílé láti ṣe àwọn iṣẹ́ kan tàbí kí wọ́n lọ máa gbé lọ́dọ̀ ọmọ wọn. Inú wọn sì lè má dùn torí pé ara wọn ò jí pépé mọ́, wọn ò ríran dáadáa mọ́ débi pé wọn ò lè jáde nílé fúnra wọn mọ́, wọn ò sì lè wakọ̀ mọ́. Ká sòótọ́, àwọn nǹkan yìí lè má jẹ́ kínú wọn dùn! Àmọ́ máa rántí pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà àtàwọn ará, bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè dá bójú tó ara ẹ mọ́, tó ò ń dá gbé, tó ò sì lè wakọ̀ mọ́. Jẹ́ kó tún dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú ẹ̀ ni ẹni tá a jẹ́, bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àtàwọn ará, tá a sì mọyì gbogbo ohun tí òun àtàwọn ará ń ṣe fún wa.—1 Sám. 16:7.

7. Kí ló máa ran àwọn arúgbó tí wọ́n rò pé àwọn lè kú kí òpin tó dé lọ́wọ́?

7 Ohun míì tó lè mú kínú àwọn arúgbó má dùn ni pé, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa rò pé àwọn lè kú kí òpin tó dé. Tó o bá nírú èrò yìí, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Máa rántí pé ó nídìí tí Jèhófà ṣe ní sùúrù, tí ò fi pa ayé burúkú yìí run báyìí. (Àìsá. 30:18) Kí nìdí tí Jèhófà ṣe ní sùúrù. Ìdí ni pé sùúrù tí Jèhófà ní ló ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn wá mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì wá jọ́sìn ẹ̀. (2 Pét. 3:9) Torí náà, tínú ẹ ò bá dùn torí ò ń rò pé o lè kú kí òpin tó dé, máa ronú nípa iye àwọn èèyàn tó ṣì máa wá mọ Jèhófà kí ayé burúkú yìí tó pa run torí pé ó ní sùúrù. Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn kan nínú ìdílé ẹ wà lára wọn.

8. Táwọn arúgbó bá ń ṣàìsàn tàbí jẹ̀rora, kí ni wọ́n máa ń ṣe?

8 Bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, tára wa ò bá yá, ó ṣeé ṣe ká sọ ohun tí ò yẹ ká sọ tàbí ṣe ohun tí ò yẹ ká ṣe. (Oníw. 7:7; Jém. 3:2) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jóòbù olóòótọ́ ń jìyà, Bíbélì sọ pé ó ń sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” (Jóòbù 6:1-3) Bákan náà, àwọn tó ti darúgbó lè máa ṣàìsàn tó lè mú kí wọ́n sọ ohun tí wọn ò fẹ́ sọ tàbí ṣe ohun tí wọn ò fẹ́ ṣe. Ká sòótọ́, tá a bá tiẹ̀ ti darúgbó tàbí tá à ń ṣàìsàn, ìyẹn ò sọ pé ká máa sọ tàbí ṣe ohun tí ò yẹ, kò sì yẹ ká máa sọ pé gbogbo ohun tá a bá fẹ́ ni kí wọ́n máa ṣe fún wa. Tá a bá sì rí i pé a ti sọ ohun tí ò dáa sẹ́nì kan, ṣe ló yẹ ká tètè tọrọ àforíjì.—Mát. 5:23, 24.

ÀWỌN NǸKAN TÓ MÁA JẸ́ KÁWỌN ARÚGBÓ LÁYỌ̀

Ẹ̀ka igi cherry rèé; àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀ jẹ́ ká rí i pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lè máa láyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti darúgbó. Àwọn nǹkan tá a rí nínú àwòrán yẹn la jíròrò ní ìpínrọ̀ 9-13.

Àwọn nǹkan wo lá jẹ́ kẹ́ ẹ máa láyọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ọjọ́ ogbó ń bá yín fínra? (Wo ìpínrọ̀ 9-13)


9. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ti darúgbó jẹ́ káwọn ẹlòmíì ràn wọ́n lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Jẹ́ káwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Gál. 6:2) Táwọn èèyàn bá fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi kó o sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣèyọnu. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Gretl sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń nira fún mi láti sọ pé káwọn ẹlòmíì ràn mí lọ́wọ́ torí pé mi ò fẹ́ yọ wọ́n lẹ́nu, mi ò sì fẹ́ dá kún ìṣòro wọn. Ó pẹ́ gan-an kí n tó yí èrò tí mo ní yẹn pa dà, kí n sì gbà pé ó yẹ káwọn ẹlòmíì ràn mí lọ́wọ́.” Torí náà, tó o bá jẹ́ káwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá rí i pé wọ́n máa ní ayọ̀ tí Bíbélì sọ pé àwọn tó bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan máa ń ní. (Ìṣe 20:35) Inú ìwọ náà máa dùn torí o mọ̀ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, ọ̀rọ̀ ẹ sì jẹ wọ́n lógún.

Arábìnrin ọ̀dọ́ kan di ọwọ́ arábìnrin kan tó ti darúgbó mú nígbà tí wọ́n lọ ra nǹkan lọ́jà.

(Wo ìpínrọ̀ 9)


10. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ti darúgbó máa dúpẹ́ tí wọ́n bá ṣe wọ́n lóore? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Máa dúpẹ́ oore. (Kól. 3:15; 1 Tẹs. 5:18) Táwọn èèyàn bá ṣe wá lóore, a máa ń mọyì ẹ̀, àmọ́ nígbà míì a lè gbàgbé láti dúpẹ́. Ṣùgbọ́n tá a bá rọra rẹ́rìn ín músẹ́, tá a sì sọ pé ẹ ṣeun inú ẹni náà máa dùn, á sì mọ̀ pé a mọyì ohun tóun ṣe fún wa. Arábìnrin Leah tó ń tọ́jú àwọn tó ti darúgbó ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tí mò ń tọ́jú máa ń kọ̀rọ̀ sínú ìwé kékeré kan láti dúpẹ́ lọ́wọ́ mi. Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé náà kì í gùn, àmọ́ wọ́n máa ń múnú mi dùn. Ó máa ń wù mí láti ka àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sí mi yẹn, ó máa ń jẹ́ kí n láyọ̀ torí ó jẹ́ kí n rí i pé wọ́n mọyì ohun tí mò ń ṣe fún wọn.”

Arábìnrin àgbàlagbà kan ń kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì kó lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnì kan.

(Wo ìpínrọ̀ 10)


11. Báwo làwọn tó ti darúgbó ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Sapá láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Táwọn tó ti darúgbó bá ń lo àkókò àti okun wọn láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí wọ́n máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wọn. Òwe kan sọ pé bí ọmọdé bá láṣọ bí àgbà kò lè ní àkísà bí àgbà. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìrírí táwọn àgbàlagbà ní máa ń ju tàwọn ọ̀dọ́ lọ. Torí náà, ó yẹ kẹ́ ẹ sapá láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láwọn nǹkan tẹ́ ẹ mọ̀. Ẹ bi wọ́n láwọn ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì fara balẹ̀ gbọ́ wọn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní, wọ́n sì máa láyọ̀. Kò sí àní-àní pé tẹ́ ẹ bá mú àwọn ọ̀dọ́ lọ́rẹ̀ẹ́, tẹ́ ẹ̀ ń fún wọn níṣìírí, tẹ́ ẹ sì ń gbà wọ́n níyànjú, ẹ máa túbọ̀ láyọ̀.—Sm. 71:18.

Arákùnrin àgbàlagbà kan ń fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń sọ fún un

(Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Kí ni Àìsáyà 46:4 sọ pé Jèhófà máa ṣe fáwọn tó ti darúgbó? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Bẹ Jèhófà kó fún ẹ lókun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o lè má lókun, inú ẹ sì lè má dùn, ní ti Jèhófà “kì í rẹ̀ ẹ́, okun rẹ̀ kì í sì í tán.” (Àìsá. 40:28) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo okun ẹ̀ tí kì í tán láti ràn wá lọ́wọ́? Ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti darúgbó lókun. (Àìsá. 40:29-31) Kódà, ó ṣèlérí pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Àìsáyà 46:4.) Awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ sì ni Jèhófà. (Jóṣ. 23:14; Àìsá. 55:10, 11) Torí náà, táwọn tó ti darúgbó bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, inú wọn á sì máa dùn.

Arákùnrin àgbàlagbà kan ń gbàdúrà.

(Wo ìpínrọ̀ 12)


13. Kí ni 2 Kọ́ríńtì 4:16-18 sọ pé ó yẹ ká máa rántí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Má gbàgbé pé o máa pa dà di ọ̀dọ́, wàá sì lókun. Tá a bá ń rántí pé kò sóhun tó níbẹ̀rẹ̀ tí kì í lópin, ìyẹn á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí. Bíbélì sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ọjọ́ ogbó àti àìsàn máa tó dópin. (Jóòbù 33:25; Àìsá. 33:24) Torí náà, tẹ́ ẹ bá ń rántí pé lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ ẹ máa pa dà di ọ̀dọ́, ara yín sì máa jí pépé, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ máa láyọ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:16-18.) Àmọ́, kí làwọn ẹlòmíì lè ṣe láti ran àwọn tó ti darúgbó lọ́wọ́?

Arábìnrin àgbàlagbà kan jókòó sórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláìlera, ó ń ka Bíbélì. Ó ń fojú inú wò ó pé òun wà nínú Párádísè, òun ti di ọ̀dọ́, òun ò sì jókòó sórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláìlera mọ́.

(Wo ìpínrọ̀ 13)


BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ARÚGBÓ LỌ́WỌ́

14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká lọ kí àwọn arúgbó nílé, ká sì máa pè wọ́n lórí fóònù?

14 Máa lọ kí àwọn arúgbó nílé, kó o sì máa pè wọ́n lórí fóònù déédéé. (Héb. 13:16) Ó máa ń ṣe àwọn arúgbó bíi pé àwọn dá wà, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kínú wọn dùn. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Camille tí ò lè jáde nílé sọ pé: “Inú ilé ni mo máa ń wà láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dà bí kìnnìún kan tó ti dàgbà tí wọ́n fi sínú àhámọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí nǹkan sú mi.” Tá a bá lọ ń kí àwọn arúgbó nílé, ńṣe là ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì mọyì wọn. Ó ṣeé ṣe ká rántí ìgbà kan tá a sọ pé a fẹ́ lọ kí ẹnì kan tó ti darúgbó tó wà níjọ wa, àmọ́ tá ò lè lọ. Ohun tó sì máa ń fà á ni pé gbogbo wa lọ́wọ́ wa máa ń dí. Torí náà, kí lá jẹ́ ká lè “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù,” bíi ká lọ kí àwọn tó ti darúgbó nílé? (Fílí. 1:10) Lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká kọ̀rọ̀ sínú kàlẹ́ńdà wa kó lè rán wa létí pé a fẹ́ fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù àwọn arúgbó tó wà níjọ wa tàbí ká pè wọ́n lórí fóònù. O tún lè ṣètò pé wàá lọ kí wọn nílé, má sì gbàgbé láti lọ.

15. Kí làwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tó ti darúgbó lè jọ ṣe?

15 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé tó o bá lọ kí àwọn arúgbó nílé, o lè má mọ ohun tí wàá bá wọn sọ tàbí ohun tẹ́ ẹ lè jọ ṣe. Àmọ́, má jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Tó o bá débẹ̀, ṣe ohun tó máa jẹ́ kẹ́yin méjèèjì túbọ̀ mọwọ́ ara yín. (Òwe 17:17) Máa bá àwọn tó ti darúgbó sọ̀rọ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. O lè ní kí wọ́n sọ ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n fẹ́ràn jù fún ẹ tàbí kó o ní kí wọ́n sọ àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ tó máa ń jẹ́ kínú wọn dùn. O tún lè ní kẹ́ ẹ jọ wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Yàtọ̀ síyẹn, o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè bá wọn ṣe fóònù wọn kó lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, tàbí kó o bá wọn wa àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ tó dé kẹ́yìn sórí fóònù wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Carol sọ pé: “Tẹ́yin ọ̀dọ́ bá fẹ́ ṣe nǹkan tẹ́ ẹ fẹ́ràn, ẹ lè sọ pé kẹ́yin àtàwọn arúgbó jọ ṣe é pa pọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti darúgbó, mo ṣì mayé jẹ. Mo fẹ́ràn kémi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ máa jáde lọ ra oríṣiríṣi nǹkan, ká lọ jẹun nílé oúnjẹ tàbí ká jọ ṣeré lọ sí ọgbà ìgbafẹ́.” Bákan náà, Arábìnrin Maira sọ pé: “Ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) ló fi jù mí lọ. Àmọ́ mi ò kì í rántí ìyẹn rárá torí a jọ máa ń ṣàwàdà, a sì jọ máa ń wo fíìmù pa pọ̀. Tá a bá sì níṣòro, a máa ń gba ara wa nímọ̀ràn.”

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé àwọn tó ti darúgbó tí wọ́n bá fẹ́ lọ rí dókítà?

16 Máa tẹ̀ lé wọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ rí dókítà. Táwọn tó ti darúgbó bá fẹ́ lọ rí dókítà, o lè gbé wọn lọ. Tẹ́ ẹ bá sì débẹ̀, rí i pé o ṣaájò wọn kí dókítà lè tètè rí wọn, kí wọ́n sì tọ́jú wọn dáadáa. (Àìsá. 1:17) O tún lè bá wọn kọ ohun tí dókítà bá sọ sílẹ̀, kí wọ́n má bàa gbàgbé. Arábìnrin kan tó ti darúgbó tó ń jẹ́ Ruth sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá dá lọ sílé ìwòsàn, àwọn dókítà kì í fara balẹ̀ gbọ́ mi, wọn kì í sì í gba ohun tí mo sọ gbọ́. Nígbà míì, àwọn dókítà lè sọ fún mi pé, ‘Màmá, nǹkan kan ò ṣe yín, ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń ṣarán.’ Àmọ́ tẹ́nì kan bá tẹ̀ lé mi lọ, àwọn dókítà máa ń bọ̀wọ̀ fún mi, wọ́n sì máa ń tọ́jú mi dáadáa. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé mi tí mo bá fẹ́ lọ rí dókítà.”

17. Sọ onírúurú ọ̀nà tí ìwọ àtàwọn tó ti darúgbó lè jọ wàásù?

17 Ẹ jọ máa wàásù. Àwọn kan tó ti darúgbó lè má lókun mọ́ láti máa wàásù ilé-dé-ilé. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè sọ fún arábìnrin kan tó ti darúgbó pé kẹ́ ẹ jọ lọ wàásù níbi ìpàtẹ ìwé? O tiẹ̀ lè gbé ìjókòó dání tó máa jókòó sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpàtẹ ìwé náà. Ṣé o lè sọ fún arákùnrin kan tó ti darúgbó pé kẹ́ ẹ jọ lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà ẹ lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nílé arákùnrin náà? Àwọn alàgbà lè ṣètò pé káwọn ará lọ ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù nílé arákùnrin kan tó ti darúgbó, ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn fún un láti lọ wàásù. Tá a bá ṣe àwọn nǹkan yìí, inú Jèhófà máa dùn sí wa torí pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 3:27; Róòmù 12:10.

18. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

18 A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ti darúgbó gan-an, ó sì mọyì wọn. Àwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì mọyì wọn. A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn tó ti darúgbó máa ń ní, àmọ́ Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa láyọ̀. (Sm. 37:25) A tún mọ̀ pé inú yín ń dùn bẹ́ ẹ ṣe mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, ẹ máa pa dà di ọ̀dọ́, ara yín sì máa jí pépé. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìwọ lò ń tọ́jú ẹni tó ti darúgbó nínú ìdílé ẹ, tó ò ń tọ́jú ọmọ ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ tára ẹ̀ ò yá ńkọ́? Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá jẹ́ kó o máa láyọ̀? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àwọn nǹkan wo ló lè mú káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti darúgbó má láyọ̀ mọ́?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn arúgbó máa ṣe kí wọ́n lè máa láyọ̀?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti ran àwọn arúgbó tó wà níjọ wa lọ́wọ́?

ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi

a Lọ sí jw.org tàbí JW Library®, wàá rí fídíò tí àkòrí ẹ̀ sọ pé Ẹ̀yin Àgbàlagbà—Ẹ Ní Iṣẹ́ Ribiribi Láti Ṣe.

b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ayọ̀ wà lára ànímọ́ tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:22) Tá a bá sún mọ́ Jèhófà, tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́, a máa ní ayọ̀ tòótọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́