ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 July ojú ìwé 14-19
  • Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MỌ JÈHÓFÀ?
  • KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ TÚBỌ̀ MỌ JÈHÓFÀ?
  • KÍ LA LÈ ṢE KÁ LÈ TÚBỌ̀ MỌ JÈHÓFÀ?
  • TÍTÍ LÁÉ LÀÁ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA JÈHÓFÀ
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • “Ẹ Fúnra Yín Yan Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ Máa Sìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 July ojú ìwé 14-19

SEPTEMBER 21-27, 2026

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà

“Mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn . . . sìn ín.”—1 KÍRÓ. 28:9.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àá rí ohun tó túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà, ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ̀ ọ́n àtohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n.

1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ronú nípa ọgbọ́n, ìmọ̀ àtàwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe?

ṢÉ O ti fìgbà kan rí ronú nípa bí ìmọ̀ Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó àti bí ọgbọ́n ẹ̀ ṣe pọ̀ tó, títí kan àwọn nǹkan àgbàyanu tó ti ṣe? Kò sí àní-àní pé tá a bá ronú nípa Ẹlẹ́dàá wa, ó máa ń mórí wa wú gan-an. Ó lè ṣe àwa náà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o! Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó, tí àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì kọjá àwárí!”—Róòmù 11:33, 34.

2. Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé a lè mọ Jèhófà?

2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ gbogbo nǹkan nípa Jèhófà, a ṣì lè mọ irú ẹni tó jẹ́ déwọ̀n àyè kan. Ọba Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ pé: “Mọ Ọlọ́run bàbá rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn àti inú dídùn sìn ín . . . Tí o bá wá a, á jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíró. 28:9) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń bá àwọn Kristẹni àtijọ́ sọ̀rọ̀, ó sọ fún wọn pé, a “ní òye ká lè mọ ẹni tòótọ́ náà.” (1 Jòh. 5:20) Bákan náà, Jésù sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ní ìmọ̀ Jèhófà, òun ṣe tán láti ‘ṣí i payá fún un.’—Mát. 11:27.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ ti mọ̀ nípa Jèhófà. Síbẹ̀, ó ṣì ń wù wá láti mọ Jèhófà sí i. (Jòh. 17:3.) Bí àpẹẹrẹ, a lè ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá múnú ẹ̀ dùn, àti bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé e. Síbẹ̀, a ṣì lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn nǹkan yìí. Àwọn ìbéèrè mẹ́ta kan wà tó yẹ kí gbogbo wa ronú lé láìka bó ṣe pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà. Àwọn ìbéèrè náà ni: Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà? Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ Jèhófà? Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè náà.

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MỌ JÈHÓFÀ?

4. Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà?

4 Tá a bá ronú lórí ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn Júù tó máa pa dà láti ìgbèkùn Bábílónì, á jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Màá fún wọn ní ọkàn tí á jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà.” (Jer. 24:7) Ká sòótọ́, áwọn Júù tó pa dà láti ìgbèkùn Bábílónì yìí ti mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn, kí ìfẹ́ yìí sì hàn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà nínú kéèyàn mọ̀ nípa Ọlọ́run àti kéèyàn mọ Ọlọ́run dáadáa. Ṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìyàtọ̀ tó wà nínú kẹ́nì kan kà nípa ìfẹ́ àti kéèyàn yófẹ̀ẹ́.” Torí náà, ká kàn mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run àti pé ó wà nìkan kò tó. Ó tún yẹ ká mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an àtàwọn ànímọ́ ẹ̀.

5. Kí la kọ́ lára Ọba Jòsáyà tó bá di pé ká mọ Jèhófà?

5 Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, àá máa mọ àwọn nǹkan táá múnú ẹ̀ dùn àtàwọn nǹkan tínú ẹ̀ ò dùn sí. Kí ohun tá à ń sọ lè yé wa dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ọba Jòsáyà. Bíbélì sọ pé: “Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀.” (2 Kíró. 34:3) Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jòsáyà kọ́ nígbà tó ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Ó gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tó kà. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mí sí wòlíì Jeremáyà láti sọ nípa Jòsáyà pé, “ó dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó ṣe òdodo” àti pé ó gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ àtàwọn aláìní. Jèhófà wá fi kún un pé: “Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó fi hàn pé ẹnì kan mọ̀ mí nìyẹn?”—Jer. 22:15, 16.

6. Bí Sáàmù 9:10 ṣe sọ, tá a bá ń sapá láti mọ Jèhófà sí i, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe?

6 Ka Sáàmù 9:10. Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìyẹn. Nígbà tí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, tó sì ń retí ìgbà tí wọ́n máa pa òun, ó sọ pé: “Ojú ò tì mí. Torí mo mọ Ẹni tí mo gbà gbọ́.” (2 Tím. 1:12) Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ti kọ́, tó sì ti rí nígbèésí ayé ẹ̀ ló mú kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé: “Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé gbogbo ohun tóun ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó sì máa jí òun dìde.”

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ TÚBỌ̀ MỌ JÈHÓFÀ?

7. Tó bá ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa?

7 Nígbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó máa ń wù wá gan-an láti mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè má fi bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá ń ka Bíbélì láyè ara wa tàbí nínú ìjọ, ohun tó sábà máa ń gbà wá lọ́kàn ni bá a ṣe lè fi ohun tá à ń kọ́ sílò láyé wa àti bá a ṣe lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Kò sì sóhun tó burú níbẹ̀ torí Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Tím. 3:16, 17) Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì sọ nípa Jèhófà. (Sm. 25:8-10) Torí náà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò yẹ kó jẹ́ pé bí ohun tá à ń kọ́ ṣe lè ṣe àwa tàbí àwọn míì láǹfààní nìkan làá máa rò débi tá ò fi ní ronú nípa ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ‘Kí ni ohun tí mò ń kà yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?’a

8. Tá a bá túbọ̀ mọ Jèhófà, báwo ni àárín àwa àti ẹ̀ ṣe máa rí? (Sáàmù 73:24-28)

8 Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọ̀rẹ́ wa àtàtà yìí. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá parí Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ tàbí tó o wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW tàbí tó o lọ sí àpéjọ kan, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tá a ṣe yẹn ti jẹ́ ká túbọ̀ mọ Jèhófà sí i. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká yìn ín lógo, ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti onísáàmù tó ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó òun, ìyẹn sì mú kó sọ pé: “Ọlọ́run ni àpáta ọkàn mi àti ìpín mi títí láé.” (Ka Sáàmù 73:24-28.) Bá a bá ṣe ń sapá láti túbọ̀ mọ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ọ̀rẹ́ gidi ló jẹ́ sí wa, àá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

9. Tá a bá ń “kíyè sí” Jèhófà, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe? Ṣàpèjúwe.

9 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa “kíyè sí” Jèhófà. (Òwe 3:5, 6) Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nípa ẹ̀ àti bí ohun tá a bá ṣe ṣe máa rí lára ẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá ṣèpinnu tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ti ṣègbéyàwó máa ń gbé fọ́tò ọkọ tàbí ìyàwó wọn sórí fóònù tàbí sórí tábìlì tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n máa ronú nípa ẹnì kejì wọn látìgbàdégbà, kí wọ́n ṣe ohun táá múnú ẹ̀ dùn, kí wọ́n sì yẹra fún ohunkóhun tó máa bà á lọ́kàn jẹ́. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ronú nípa Jèhófà látìgbàdégbà, á rọrùn fún wa láti ṣe àwọn ìpinnu táá múnú ẹ̀ dùn.—Sm. 19:13, 14.

10. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe?

10 Torí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán ẹ̀, ìyẹn jẹ́ ká lè fìwà jọ ọ́. (Jẹ́n. 1:26) Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún wa láti fìwà jọ ọ́. Jésù dẹ́bi fáwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí pé kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni wọ́n ń ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń rin kinkin mọ́ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kéékèèké tó wà nínú Òfin, wọn “ò ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.” (Mát. 23:23) Kò yẹ ká dà bí àwọn aṣáájú ìsìn yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa ronú nípa ohun táwọn òfin àti ìlànà inú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ fìwà jọ ọ́.—1 Jòh. 4:8, 11.

KÍ LA LÈ ṢE KÁ LÈ TÚBỌ̀ MỌ JÈHÓFÀ?

11. Báwo lo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

11 Ta ló kọ́ ẹ nípa Jèhófà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ló kọ́ ẹ kó o lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ àwọn ìtàn inú Bíbélì fún ẹ tàbí kí wọ́n jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó dá. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ́ ẹ nípa Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ìwé ètò Ọlọ́run, irú bí ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ni wọ́n fi kọ́ ẹ. Ẹni tó kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ lè jẹ́ kó o mọ bí àwọn ìtàn inú Bíbélì àtàwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe jẹ́ ká túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà.b (Neh. 8:8; Ìṣe 14:17) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ Jèhófà.

12-13. Kí la lè kọ́ lára Jèhófà tá a bá ń ka Bíbélì? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Jeremáyà 39:15-18) (Tún wo àwòrán .)

12 Lákọ̀ọ́kọ́, a máa túbọ̀ mọ Jèhófà tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. Nígbà míì, Bíbélì máa ń dìídì mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ Jèhófà. (Ẹ́kís. 34:6, 7) Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ohun táwọn èèyàn ṣe ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Torí náà, tó o bá ń ka ìtàn àwọn èèyàn yìí, á dáa kó o ronú nípa ohun tó kọ́ ẹ nípa Jèhófà.

13 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ká sọ pé ò ń ka Jeremáyà 38:6-13, ọ̀pọ̀ nǹkan lo máa kọ́ lára Ebedi-mélékì ará Etiópíà tó gba wòlíì Jeremáyà sílẹ̀. Ó dájú pé wàá tètè rí bó o ṣe lè fara wé Ebedi-mélékì nínú àwọn ẹsẹ yẹn. Bí àpẹẹrẹ ó nígboyà, ó sì ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jeremáyà. Àmọ́, ṣé o lè rí ohunkóhun kọ́ lára Jèhófà nínú ìtàn yìí? (Ka Jeremáyà 39:15-18.) Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn ẹsẹ yìí ló jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń mọyì ohun táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá ṣe? Èwo ló jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe ojúsàájú àti pé ọ̀rọ̀ gbogbo èèyàn jẹ ẹ́ lógún? Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tá a sọ yìí, kí lohun míì tí ìtàn yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? Nígbàkigbà tó o bá ń ka Bíbélì, máa kíyè sí ohun tí ìtàn náà kọ́ ẹ nípa Jèhófà, lẹ́yìn náà dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé o mọyì àwọn ànímọ́ tó ní.

Ebedi-mélékì àtàwọn ọkùnrin mí ì ń fi okùn fa Jeremáyà síta nínú kòtò omi. Àwọn ọkùnrin mí ì tó dira ogun dúró sítòsì, wọ́n sì wà lójúfò.

Ebedi-mélékì fìgboyà gba Jeremáyà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n jù ú sínú kòtò omi (Wo ìpínrọ̀ 12-13)


14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?

14 Ìkejì, a máa túbọ̀ mọ Jèhófà tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tó dá. (Sm. 145:9, 10) Ká kàn máa kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá nìkan ò tó. Ìdí ni pé ohun táwọn kan ń fi gbogbo ayé wọn ṣe nìyẹn, síbẹ̀ wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rí àwọn ànímọ́ ẹ̀ nínú àwọn nǹkan tó dá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jèhófà pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.” (Róòmù 1:20) Ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé ‘tẹ́nì kan bá láròjinlẹ̀, á rí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run.’ Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ká sì máa kíyè sí ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa.

15. Kí ni Patrick ṣe kó lè túbọ̀ mọ Jèhófà, kí lo sì lè kọ́ lára ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ìgboro lọ̀pọ̀ wa ń gbé, kò sì rọrùn láti rí oríṣiríṣi ẹranko, ewéko àtàwọn nǹkan míì tí Jèhófà dá. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ẹ ṣẹ rí nìyẹn, ṣé o mọ̀ pé o ṣì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Patrick. Ìlú Brazzaville tó wà lorílẹ̀-èdè Republic of the Congo ló ń gbé, ìlú náà sì tóbi gan-an. Ó sọ pé: “Mo máa ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá tí mo bá wo ìta látojú wíńdò ilé mi. Mo sábà máa ń rí àwọn kòkòrò àtàwọn ẹyẹ kéékèèké tí wọ́n ń wá oúnjẹ àti ibi tí wọ́n máa gbé. Ìgbà kan wà tí mo rí báwọn ẹyẹ kan ṣe ń kọ́ ilé wọn. Wọ́n lo àwọn nǹkan tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn láti ṣe ilé tó mọ níwọ̀n tí wọ́n lè pa ọmọ sí tí wọ́n bá yé.” Àmọ́ Patrick ò fi mọ síbẹ̀ o, ó ronú nípa ohun tóun lè kọ́ lára Jèhófà tó dá àwọn ẹyẹ náà. Ó sọ pé: “Mo rí i pé Jèhófà máa ń bójú tó àwọn nǹkan tó dá, ó sì máa ń pèsè fún wọn tó bá tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n kéré lójú wa. Torí náà ọkàn mi balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ mi jẹ Jèhófà lógún, ó sì dá mi lójú pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tí mo nílò.”

Arábìnrin kan tó ń gbé nígboro ń bomi rin àwọn òdòdó tó wà nílé ẹ̀, ó sì ń wo ẹyẹ tó fẹ́ bà lé òdòdó náà.

Wàá túbọ̀ mọ Jèhófà tó o bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó dá (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Kí ló jẹ́ kí Màríà ìyá Jésù túbọ̀ mọ Jèhófà, kí la sì lè kọ́ lára ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ìkẹta, ohun míì tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ Jèhófà ni pé ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe fún wa. Ohun tí Màríà ìyá Jésù ṣe nìyẹn. Ó ti mọ Jèhófà dáadáa, ó sì “ti rí ojúure [ẹ̀].” (Lúùkù 1:30) Àmọ́ Jèhófà gbéṣẹ́ ńlá kan fún un pé òun ló máa jẹ́ ìyá Jésù Ọmọ òun, iṣẹ́ náà ò sì rọrùn rárá. Jèhófà lo áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ẹ̀ láti fi í lọ́kàn balẹ̀. Nígbà tó yá, ó ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fóun, àtohun tíyẹn kọ́ òun nípa ẹ̀. Ó wá rí i pé alágbára ni Jèhófà, ó máa ń ṣàánú, kì í ṣojúsàájú, ó sì máa ń kíyè sí àwọn táwọn èèyàn ò kà sí. (Lúùkù 1:46-55) Bíi ti Màríà tó mọyì bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́, ó yẹ káwa náà máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe ń “ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó tọ́.” (Héb. 4:16) Nígbàkigbà tí Jèhófà bá ràn ẹ́ lọ́wọ́, bi ara ẹ pé: ‘Kí lohun tí Jèhófà ṣe fún mi yìí kọ́ mi nípa ẹ̀? Èwo nínú àwọn ànímọ́ ẹ̀ ló fi hàn nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí?’

Fọ́tò: Arákùnrin kan ń ronú nípa ìgbà kan tí Jèhófà ràn án lọ́wọ́. 1. Ó ń gbàdúrà nípa iṣẹ́ tó ní nípàdé. 2. Ó ṣiṣẹ́ náà, àwọn ará sì gbádùn ẹ̀.

Wàá túbọ̀ mọ Jèhófà tó o bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe fún ẹ (Wo ìpínrọ̀ 16)c


TÍTÍ LÁÉ LÀÁ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA JÈHÓFÀ

17-18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé títí láé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

17 Ọ̀pọ̀ nǹkan la máa kọ́ nípa Jèhófà nínú ayé tuntun. Nígbà yẹn, Jèhófà máa fún wa ní àkájọ ìwé tuntun táá jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó fẹ́ ká ṣe. (Ìfi. 20:12) Yàtọ̀ síyẹn, a máa fara balẹ̀ kíyè sáwọn nǹkan tí Jèhófà dá. (Àìsá. 11:6-9) Tó bá dìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu tá ò rí rí á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ ká túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde, ojoojúmọ́ làá sì máa di pípé.

18 Títí láé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ká má gbàgbé pé Jèhófà ti wà tipẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan tá ò mọ̀ ló sì mọ̀. Torí náà, “òye rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n.” (Sm. 90:2; 147:5) A “ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníw. 3:11) Torí náà, bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Baba wa ọ̀run.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ Jèhófà?

  • Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ Jèhófà?

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

a Wo ìbéèrè 20 ní apá “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tó wà lọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

b Ka ẹ̀kọ́ 07 kókó 5-7 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN : Arákùnrin kan tó máa ń ṣàníyàn ronú nípa bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ nígbà tó ṣiṣẹ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́