SEPTEMBER 14-20, 2026
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
Jẹ́ Káwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà Tù Ẹ́ Nínú
“Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: . . . ‘Bí ìyá ṣe ń tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni màá máa tù yín nínú.’”—ÀÌSÁ. 66:12, 13.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó wà nínú ìwé Àìsáyà, ó máa tù wá nínú tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn.
1-2. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn?
FOJÚ inú wo ọmọdé kan tínú ẹ̀ ò dùn, tó sì ń sunkún gan-an. Ó lè jẹ́ torí pé wọ́n ń kó lọ síbòmíì, tíyẹn sì máa mú kó fàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sílẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé àṣìṣe kan tó ṣe ni ò jẹ́ kínú ẹ̀ dùn. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, kí lo rò pé abiyamọ tòótọ́ máa ṣe? Ṣe ló máa fa ọmọ náà mọ́ra, á fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ń pa á lẹ́kún, á sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.
2 Nínú Bíbélì, Jèhófà fi ara ẹ̀ wé abiyamọ tòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀, tó sì ń tù ú nínú. Ó sọ pé: “Bí ìyá ṣe ń tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni màá máa tù yín nínú.” (Àìsá. 66:13) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ju ìfẹ́ táwọn òbí máa ń ní sí ọmọ wọn. (Àìsá. 49:15) Jèhófà máa ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa lókun tá a bá ní ìṣòro tàbí ẹ̀dùn ọkàn.—Róòmù 15:4.
3. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú ìwé Àìsáyà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà sọ tó lè tù wá nínú. (Àìsá. 40:1) Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí Àìsáyà láti kọ ìwé yìí kó lè fi àwọn èèyàn ẹ̀ tó ń gbé ní Júdà lọ́kàn balẹ̀ lásìkò tí nǹkan ò rọrùn fún wọn. ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ làwa náà ń gbé lónìí, torí náà a nílò ìtùnú. (2 Tím. 3:1) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹsẹ mélòó kan nínú ìwé Àìsáyà tó lè tù wá nínú, kó sì fún wa lókun. Àwọn ẹsẹ yìí máa ràn wá lọ́wọ́ (1) tí nǹkan bá yí pa dà fún wa lójijì, (2) tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi ṣáá, tàbí (3) tí èèyàn wa bá kú.
TÍ NǸKAN BÁ YÍ PA DÀ FÚN WA LÓJIJÌ
4. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tí nǹkan bá yí pa dà fún wa lójijì?
4 Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà nígbèésí ayé wa. (Oníw. 9:11; 1 Kọ́r. 7:31) A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn láìròtẹ́lẹ̀, ọrọ̀ ajé lè ṣàdédé dẹnu kọlẹ̀, ọ̀rọ̀ òṣèlú lè dá rògbòdìyàn sílẹ̀, tàbí kíṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run yí pa dà. Irú àwọn nǹkan yìí lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè, kí gbogbo nǹkan sì tojú sú wa. A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Ibo ni mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀?’ Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Joseph tí wọ́n ní kó lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn tó ti lo ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ní Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ ò kọ́kọ́ yé mi. Mi ò mọ ibi tí mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ torí ó ti pẹ́ tí mo ti wà ní Bẹ́tẹ́lì. Ṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi.” Kí ni Jèhófà sọ nínú ìwé Àìsáyà tó lè tù wá nínú tí nǹkan bá yí pa dà fún wa lójijì?
5. Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 42:16, kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ka Àìsáyà 42:16. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa mú àwọn tó fọ́jú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ gba ọ̀nà tó ṣàjèjì sí wọn, òun á sì sọ òkùnkùn tó wà níwájú wọn di ìmọ́lẹ̀. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, a máa rí àwọn ọ̀rọ̀ bí “afọ́jú,” “ọ̀nà tó ṣàjèjì,” “òkùnkùn,” àti “ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣàpẹẹrẹ bí nǹkan ṣe máa ń rí nígbà tí ìgbésí ayé wa bá yí pa dà lójijì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé à ń rìn nínú igbó kan tó ṣókùnkùn, a ò sì rí ọ̀ọ́kán rárá. Síbẹ̀, Jèhófà fi dá wa lójú pé, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, òun máa tọ́ wa sọ́nà, òun ò sì ní pa wá tì. Ṣe ló máa di ọwọ́ wa mú, kó lè mú wa gba ibi tó ṣókùnkùn yẹn. Á tan ìmọ́lẹ̀ sójú ọ̀nà wa, á sì sọ ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ àti ètò ẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ ohun tá a máa ṣe. (Sm. 119:105; Àìsá. 30:21) Ó tún máa ń lo àwọn ará láti ràn wá lọ́wọ́, kí wọ́n sì pèsè ohun tá a nílò. Torí náà, tí ìyípadà tá ò retí bá dé, tá ò sì mọ ohun tá a máa ṣe, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ torí ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa.—Àìsá. 41:10; 1 Pét. 5:6, 7.
Kódà tí nǹkan bá yí pa dà fún ẹ lójijì, Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé (Wo ìpínrọ̀ 5)b
6. Tí nǹkan bá yí pa dà fún wa lójijì, kí ló yẹ kó dá wa lójú?
6 Arákùnrin Joseph tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bóun àti ìyàwó ẹ̀ ṣe rọ́wọ́ Jèhófà láyé wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ pé: “Jèhófà ò fi wa sílẹ̀, ó ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan yí pa dà fún wa. Ó fi àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kẹ́ wa. Jèhófà pèsè àwọn nǹkan tá a nílò, ó sì jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ lákòókò tí nǹkan ò rọrùn fún wa yẹn. Títí di báyìí ló sì ń ṣe bẹ́ẹ̀.” Tí nǹkan bá yí pa dà fún ìwọ náà lójijì, tó sì dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fún ẹ lókun, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsá. 54:10; 58:11) Arákùnrin Joseph tún sọ pé: “Mo fẹ́ràn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn orin wa míì tó sọ pé, ‘Ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́la. Mo mọ̀ pé ṣe ni wàá dúró tì mí.’a Torí náà tí nǹkan ò bá rí bá a ṣe rò, ó dájú pé Jèhófà máa dúró tì wá.”
TÍ ỌKÀN WA BÁ Ń DÁ WA LẸ́BI ṢÁÁ
7. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì?
7 Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tá a sì jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà, wọ́n máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a máa ń kíyè sára ká má bàa tún dá irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́. (Òwe 28:13; Jém. 5:14-16; 1 Jòh. 1:9) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ọkàn wa ṣì lè máa dá wa lẹ́bi ṣáá. Ó lè máa ṣe wá bíi pé, ‘Ṣé Jèhófà lè dárí jì mí ṣá pẹ̀lú ohun tí mo ṣe yìí?’ (2 Kọ́r. 2:7) Kò sóhun tó burú tí irú èrò yìí bá ń wá sí wa lọ́kàn, torí pé kì í rọrùn láti gbọ́kàn kúrò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tèèyàn dá, ó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò ká tó gbàgbé. Ọba Dáfídì sọ pé: “Kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ara mi ti kú tipiri, àárẹ̀ sì ti bá mi gidigidi.” (Sm. 38:3, 8) Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tiẹ̀ náà ṣe rí nìyẹn, ìwé Àìsáyà lè tù ẹ́ nínú.
8-9. Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 1:18, báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá?
8 Ka Àìsáyà 1:18. Jèhófà lo àpèjúwe kan ká lè mọ̀ pé tóun bá ti dárí jì wá, òun ò ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Ó sọ pé táwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bá tiẹ̀ “rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,” òun máa mú kó “funfun bíi yìnyín.” Àwọ̀ rírẹ̀dòdò máa ń pọ́n gan-an torí náà tí àbààwọ́n ẹ̀ bá ta sára aṣọ funfun, ó máa ń ṣòro láti fọ̀ ọ́ kúrò. Síbẹ̀ Jèhófà fi dá wa lójú pé tóun bá dárí jì wá, òun á sọ ẹ̀ṣẹ̀ wa tó dà bí aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò di funfun, ìyẹn ni pé kò ní rántí ẹ̀ mọ́ títí láé.
9 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Ọba Dáfídì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣàgbèrè tó sì tún pààyàn, nígbà tó ronú pìwà dà Jèhófà dárí jì í, kódà nígbà tó yá ó pè é ní ọkùnrin olóòótọ́. (2 Sám. 11:3, 4, 14, 15; 12:13; 1 Ọba 9:4, 5) Àwọn nǹkan rere tí Dáfídì ṣe ni Jèhófà rántí, kì í ṣe àṣìṣe ẹ̀. Lọ́nà kan náà, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ó máa ń dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ sìn ín. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo la tún lè rí nínú ìwé Àìsáyà?
10. Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú Àìsáyà 38:17?
10 Ka Àìsáyà 38:17 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. Gbólóhùn náà “o ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ” tún lè túmọ̀ sí o ti “mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò níwájú rẹ.” Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ohun tí Jèhófà máa ń ṣe sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó bá ronú pìwà dà. Ó sọ pé ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà jù ú sẹ́yìn ẹ̀ níbi tí ò ti ní rí i mọ́ tàbí rántí ẹ̀ mọ́. Nígbà tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ yìí ó sọ pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí ò wáyé rí.” Torí náà, tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń rí wa bíi pé a ò dẹ́ṣẹ̀ rí, kò ní fìyà jẹ wá torí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Ìdí ni pé Jèhófà ti gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ náà pátápátá. Ó ṣèlérí pé: “Mi ò ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.” (Àìsá. 43:25) Ìyẹn mà tuni nínú o! Tí Jèhófà tó jẹ́ Onídàájọ́ Tó Ga Jù Lọ bá sọ pé òun ò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí wa lọ́rùn mọ́, ṣé ó wá yẹ káwa ṣì máa dára wa lẹ́bi torí ẹ̀ṣẹ̀ náà?
Má ṣe jẹ́ kí àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn ba ayọ̀ ẹ jẹ́
11. Láìka àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, kí lohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Nígbàkigbà tí ọkàn wa bá tún dá wa lẹ́bi, ó yẹ ká rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Jèhófà sọ. Ká má gbàgbé pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́ rárá. Jèhófà kì í pa wá tì nítorí àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, kì í sì í di èèyàn sínú bíi tàwa èèyàn aláìpé. (Àìsá. 57:16) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe irú ẹni tá a jẹ́ tẹ́lẹ̀ ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà, àmọ́ irú ẹni tá a jẹ́ báyìí àti irú ẹni tá à ń sapá láti jẹ́ lọ́jọ́ iwájú. (Àìsá. 55:7) Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń dárí jini là ń sìn! Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn ba ayọ̀ wa jẹ́ tàbí kó mú ká pàdánù àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú.
Jèhófà kì í fojú àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn wò wá (Wo ìpínrọ̀ 11)c
TÍ ÈÈYÀN WA BÁ KÚ
12. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa téèyàn wa bá kú?
12 Téèyàn wa bá kú, ẹ̀dùn ọkàn tá a máa ń ní máa ń lágbára gan-an, kì í sì í lọ bọ̀rọ̀. Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé kò yẹ kí Jèhófà jẹ́ kẹ́ni náà kú. Arákùnrin Michael táwọn òbí ẹ̀ kú nínú jàǹbá iná sọ pé: “Ọkàn mi gbọgbẹ́ gan-an, mo sì bínú sí Jèhófà pé ó jẹ́ kí wọ́n kú. Mo mọ̀ pé òun kọ́ ló fa ikú wọn, àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ kó ṣẹlẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí nígbà téèyàn ẹ kú. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú? Kí ló sì ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa?
13. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe ní Àìsáyà 25:8?
13 Ka Àìsáyà 25:8. Jèhófà ṣèlérí pé òun “máa gbé ikú mì títí láé.” Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí ò bá sí ikú mọ́! O ò ní máa ṣọ̀fọ̀ àwọn èèyàn ẹ tó kú mọ́. (Àìsá. 35:10) O ò sì ní máa lẹ́dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá rí sàréè àwọn èèyàn ẹ̀ tó ti kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ àtàwọn èèyàn ẹ máa wà láàyè títí láé, ara yín á sì le. Ìlérí yìí kì í ṣe àsọdùn rárá, ó dájú pé ó máa ṣẹ torí pé Jèhófà Ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe é ló ṣèlérí náà.—Ìfi. 21:4, 5.
14. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá ronú nípa àjíǹde? (Àìsáyà 26:19) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ka Àìsáyà 26:19. Kì í ṣe pé Jèhófà máa fòpin sí ikú nìkan ni, àmọ́ ó tún máa jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn wa tó ti kú, ó sọ pé: “Àwọn òkú mi máa jíǹde.” Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà gbà pé èèyàn òun làwọn èèyàn wa tó ti kú. Jèhófà ò gbàgbé wọn, tí àkókò bá sì tó lójú ẹ̀, á jí wọn dìde. Bí ìrì òwúrọ̀ ṣe máa ń jẹ́ kí ewéko tó ti gbẹ sọjí, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà tó fún wa lẹ́mìí ṣe máa jí gbogbo àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Ó dájú pé ìdùnnú á ṣubú layọ̀ nígbà táwọn èèyàn wa tó ti kú bá jíǹde!—Fi wé Máàkù 5:42.
Ó dá wa lójú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde (Wo ìpínrọ̀ 14)
15. Báwo ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa àjíǹde ṣe máa ń jẹ́ kára tù wá téèyàn wa bá kú?
15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa àjíǹde kì í mú kí ìbànújẹ́ ọkàn wa pòórá, ó máa ń tù wá nínú torí a mọ̀ pé Jèhófà ò gbàgbé àwọn èèyàn wa tó ti kú. Ìrètí yìí tu Michael tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan nínú. Ó sọ pé: “Àìsáyà 26:19 jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí mi gan-an. Kò gbàgbé wọn, ṣe ló tọ́jú wọn pa mọ́ sínú agbára ìrántí ẹ̀, tó bá sì tó àkókò lójú ẹ̀, ó máa jí wọn dìde. Ìrètí yìí máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń fún mi lókun.” Á dáa káwa náà máa ronú nípa ìgbà tá a máa rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kára tù wá.
16. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló ti tù ẹ́ nínú nígbà tó o níṣòro?
16 A ti jíròrò àwọn ẹsẹ díẹ̀ nínú ìwé Àìsáyà tó lè tù wá nínú nígbà tí nǹkan bá yí pa dà fún wa lójijì, tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi ṣáá, àti nígbà tí èèyàn wa bá kú. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wá nínú, ó sì ń mára tù wá! (Sm. 94:19) Ṣé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wà tó máa ń tù ẹ́ nínú tó o bá níṣòro? Tó bá ṣeé ṣe, há a sórí tàbí kó o kọ ọ́ sínú ìwé kan kó o sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ibi tí wà á tí máa rí i déédéé. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa sọ tù ẹ́ nínú.
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
a Àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn wà nínú ọ̀kan lára àwọn orin wa míì tí àkòrí ẹ̀ jẹ́, “Jèhófà Wà Lẹ́yìn Mi.”
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí tọkọtaya kan kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn ará gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n dé síjọ wọn.
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan gbàgbé àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, inú ẹ̀ sì ń dùn nígbà tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà.