ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 April ojú ìwé 32
  • Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àpèjúwe Inú Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àpèjúwe Inú Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 April ojú ìwé 32

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Bá A Ṣe Lè Lóye Àwọn Àpèjúwe Inú Bíbélì

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpèjúwe ló wà nínú Bíbélì. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì kì í lóye àwọn àpèjúwe yìí. (Mát. 13:13) Kí ló máa jẹ́ kó o lóye àwọn àpèjúwe tó wà nínú Bíbélì? Àwọn àbá yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́:

  • Mọ ohun tí àpèjúwe náà dá lé àti àfiwé tí wọ́n lò. Lọ́pọ̀ ìgbà, àpèjúwe kan máa ń ní ohun tó dá lé àti àfiwé tí wọ́n fi gbé kókó ọ̀rọ̀ náà yọ. Bí àpẹẹrẹ, Ìfihàn 3:3 fi ìpadàbọ̀ Jésù wé ìgbà tí olè ń bọ̀. Ìpadàbọ̀ Jésù ni àpèjúwe náà dá lé, àfiwé tó sì lò ní bí olè ṣe máa ń wá.

  • Ronú nípa bí ohun tí àpèjúwe náà dá lé ṣe jọra pẹ̀lú àfiwé tí wọ́n lò. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ohun tó mú kí méjèèjì jọra.

  • Ṣèwádìí kó o lè rí ohun tí àpèjúwe náà túmọ̀ sí gan-an. Nígbà míì, ìjọra tó wà láàárín ohun tí àpèjúwe kan dá lé àti àfiwé tí wọ́n lò lè mú kéèyàn ṣi àpèjúwe náà lóye. Nínú àpẹẹrẹ tá a sọ lẹ́ẹ̀kan, kì í ṣe pé Jésù fẹ́ wá jalè ló ṣe ń bọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí àpèjúwe yẹn túmọ̀ sí ni pé, bó ṣe jẹ́ pé èèyàn kì í mọ ìgbà tí olè ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ náà la ò mọ ìgbà tí Jésù ń bọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́