ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 April ojú ìwé 26-31
  • Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àárín Yín Túbọ̀ Gún Régé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àárín Yín Túbọ̀ Gún Régé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÓ O ṢE LÈ YAN ẸNI TÓ O MÁA FẸ́
  • Ẹ MÁA WAYÈ WÀ PA PỌ̀ KẸ́ Ẹ LÈ TÚBỌ̀ MỌWỌ́ ARA YÍN
  • Ẹ MÁ FI ARA YÍN SÍLẸ̀ TÍṢÒRO BÁ DÉ
  • Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ẹni Tó O Máa Fẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 April ojú ìwé 26-31

JUNE 29–JULY 5, 2026

ORIN 131 ‘Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀’

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àárín Yín Túbọ̀ Gún Régé

“Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”—ÒWE 18:24.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Tí tọkọtaya bá fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn dùn bí oyin kí wọ́n sì bára wọn kalẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

1. Kí nìdí táwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ fi jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà?

Ẹ̀BÙN látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ jẹ́. (Jém. 1:17) Ìdí ni pé irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwa náà. Wọ́n máa ń bá wa yọ̀, wọ́n sì máa ń tù wá nínú tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n máa gbà wá nímọ̀ràn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Wọ́n tún máa ń dúró tì wá nígbà ìṣòro, a sì lè fọkàn tán wọn. Kò sí àní-àní pé irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ “máa ń mú ọkàn [wa] yọ̀”!—Òwe 27:9.

2. Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya máa ṣe ohun táá jẹ́ kí àárín wọn túbọ̀ gún régé? (Mátíù 19:6)

2 Ó ṣe pàtàkì káwọn tọkọtaya jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún ara wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣera wọn lọ́kan kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé. Tí wọn ò bá ṣe ohun táá jẹ́ kí àárín wọn túbọ̀ gún régé, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé wọ́n dá wà, kí ara máa kan wọ́n, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa bínú lódìlódì. Àmọ́ tí wọ́n bá ń wáyè fún ara wọn, wọ́n á túbọ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa, àárín wọn á sì gún régé. (Ka Mátíù 19:6.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ohun táwọn tọkọtaya lè ṣe kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó lè ṣe kí wọ́n lè rí ẹnì kejì tó máa bá wọn kalẹ́.

BÓ O ṢE LÈ YAN ẸNI TÓ O MÁA FẸ́

3-4. Kí ló máa jẹ́ kẹ́nì kan rí ẹni tí wọ́n á jọ bára wọn kalẹ́? (Òwe 18:22)

3 Ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé, á dáa ká rò ó síwá sẹ́yìn, ká sì tún ro ibi tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà já sí. Ìdí ni pé àwọn ìpinnu pàtàkì yìí lè ṣe wá láǹfààní jálẹ̀ ayé wa tàbí kó ṣàkóbá fún wa. Torí náà, ó yẹ ká rò ó dáadáa ká tó ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀.

4 Lára àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tá a lè ṣe nígbèésí ayé ni yíyan ẹni tá a máa fẹ́. Torí pé Jèhófà ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀, á dáa ká jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́. Ó fẹ́ káwọn ọkùnrin rí aya rere fẹ́, ó sì fẹ́ káwọn obìnrin náà rí ọkọ gidi fẹ́. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Jèhófà ló mọ irú ẹni tó yẹ wá. (Ka Òwe 18:22; Àìsá. 48:17, 18) Àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti rí ẹni tí wọ́n á jọ bára wọn kalẹ́.

5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kó o fẹ́ ẹni tó ti ṣèrìbọmi?

5 Tá a bá ti ṣèrìbọmi, a ti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nìyẹn. (Sm. 25:14) Torí náà, tó o bá ń wá ẹni tó o máa fẹ́, á dáa kó o yan ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:39) Ìyẹn á fi hàn pé o mọyì ìlànà Jèhófà, á sì jẹ́ kó o rí i pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọkọ tàbí aya tó o fẹ́. (Òwe 19:14) Yàtọ̀ síyẹn, o ò ní kó sí wàhálà táwọn tó fi “àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́” máa ń ní. (2 Kọ́r. 6:14) Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé o ò tíì rí ẹni tó wù ẹ́ láàárín àwọn ará, kò ní bọ́gbọ́n mu kó o ronú pé o lè lọ fẹ́ ẹni tí ò sin Jèhófà. Má sì ronú pé tó o bá fẹ́ ẹni tí ò sin Jèhófà, ẹni náà lè pa dà wá kẹ́kọ̀ọ́.

6-7. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara ẹ tó o bá ti rí ẹnì kan tó wù ẹ́ láti fẹ́?

6 Má gbàgbé pé kì í ṣe gbogbo ẹni tó ti ṣèrìbọmi náà lo lè fẹ́. Torí náà, fara balẹ̀ wo ẹni tó o fẹ́ fẹ́ dáadáa.a Kó o wá bi ara ẹ pé: ‘Báwo ló ṣe ń ṣe sáwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀? Ṣé ó máa ń gba tàwọn èèyàn rò, ṣé ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn? Àwọn wo ló ń bá rìn? Báwo ló ṣe máa ń hùwà nígbà táwọn míì ò bá fara mọ́ ohun tó bá sọ? Ṣé ó máa ń rin kinkin mọ́ èrò ẹ̀, àbí ó máa ń fara mọ́ èrò àwọn míì tí ohun tí wọ́n sọ ò bá ta ko ìlànà Bíbélì? Báwo ló ṣe máa ń ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ owó?’

7 Bákan náà, o tún lè béèrè pé: ‘Ṣé àwọn ohun tẹ́ni yìí ń ṣe fi hàn pé gbogbo ọkàn ẹ̀ ló fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ṣé ó láwọn ìwà Kristẹni tó fi hàn pé ó ń gbé “ìwà tuntun” wọ̀? Ṣé á ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà? Ṣé àfojúsùn kan náà la ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé ọ̀rọ̀ àwa méjèèjì lè wọ̀ débi tá a fi máa di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn?’ (Kól. 3:9, 10) Tó bá jẹ́ pé arábìnrin ni ẹ́, ṣé arákùnrin tó ò ń fẹ́ lè di ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́, kó sì ṣe ojúṣe ẹ̀ bí olórí ìdílé? (1 Kọ́r. 11:3) Tó o bá jẹ́ arákùnrin, ṣé arábìnrin tó ò ń fẹ́ lè bọ̀wọ̀ fún ẹ bí olórí ìdílé láìka àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní sí? Ó lè gba àkókò díẹ̀ kó o tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Torí náà, àsìkò tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà ló yẹ kó o fara balẹ̀ wo ẹni tó ò ń fẹ́ dáadáa, kó o lè mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an.

8-9. Tó o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, kí làwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Tó o bá mọ ẹni tó ò ń fẹ́ dáadáa, wàá lè ṣe ìpinnu tó dáa lásìkò tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Torí náà, o lè béèrè nípa ẹni náà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ irú ẹni tí wọ́n mọ̀ ọ́n sí. Bí àpẹẹrẹ, ṣáwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí ẹni tó nírẹ̀lẹ̀, tó jẹ́ onínúure, tó sì máa ń gba tàwọn èèyàn rò? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah ní orílẹ̀-èdè French Guiana tó fẹ́ Arákùnrin Daniel sọ pé: “Mo béèrè nípa Daniel lọ́wọ́ onírúurú èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, mo bi arákùnrin tí wọ́n jọ gbélé tí wọ́n sì jọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo tún bi àwọn alàgbà ìjọ ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jọ wà níjọ.” O tún lè fọgbọ́n bi ẹni tó ò ń fẹ́ bóyá ohunkóhun wà tó ti ṣẹlẹ̀ sí i tó yẹ kó sọ fún ẹ. Ì báà jẹ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tàbí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Ó ṣe pàtàkì kó o mọ àwọn nǹkan yìí torí pé wọ́n lè fa ìṣòro tí ò ní yanjú bọ́rọ̀ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó.

9 Tí ohun kan bá ń kọ ẹ́ lóminú nípa ẹni náà, má ṣe gbójú fò ó. Táwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá sì sọ ohun tí wọ́n kíyè sí nípa ẹ̀, má ṣe kó ọ̀rọ̀ wọn dànù. Tó o bá fara balẹ̀ ronú lórí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, á jẹ́ kó o lè pinnu bóyá kó o fẹ́ ẹni náà tàbí kó o má fẹ́ ẹ.b Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn tọkọtaya lè ṣe kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé.

Àwọn méjì kan tó ń fẹ́ra sọ́nà jọ ń sọ̀rọ̀ níbi àpèjẹ kan, àwọn ọ̀rẹ́ wọn sì wà níbẹ̀.

Gbìyànjú láti mọ ẹni náà dáadáa lásìkò tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà (Wo ìpínrọ̀ 8-9)


Ẹ MÁA WAYÈ WÀ PA PỌ̀ KẸ́ Ẹ LÈ TÚBỌ̀ MỌWỌ́ ARA YÍN

10. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tọkọtaya máa wáyè fún ara wọn?

10 Àwọn tọkọtaya lè mú kí àárín wọn túbọ̀ gún régé tí wọ́n bá ń wáyè fún ara wọn láìka bí ọwọ́ wọn ṣe dí tó. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á lè fìfẹ́ hàn síra wọn, wọ́n á sì lè jọ gbádùn ara wọn.

11. Kí ló lè mú kí àárín tọkọtaya má gún régé mọ́?

11 Àwọn tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn dáadáa máa ń fẹ́ wà pa pọ̀ dípò kí kálukú máa dá tara ẹ̀ ṣe. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ni wọ́n á máa wà pa pọ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í wà pa pọ̀, ìyẹn lè ṣàkóbá fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti gbà láti lọ ṣiṣẹ́ lókè òkun, wọ́n sì ti fi ìdílé wọn sílẹ̀ fún àkókò tó gùn gan-an. Òótọ́ ni pé owó lè máa wọlé fún wọn, àmọ́ tí tọkọtaya bá jìnnà síra fún àkókò tó pọ̀, ó lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀.

12-13. (a) Kí làwọn tọkọtaya kan ṣe tó jẹ́ kí wọ́n lè máa wà pa pọ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Ipò wo ló yẹ kó o fi ọkọ tàbí aya ẹ sí? (Wo àpótí náà “Bó Ṣe Yẹ Kí Ẹnì Kejì Ẹ Ṣe Pàtàkì Sí Ẹ Tó.”)

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn tọkọtaya kan ṣe tó jẹ́ kí wọ́n lè máa wà pa pọ̀. Leah tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Guam sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan lèmi àti ọkọ mi jọ máa ń ṣe, tá a sì máa ń gbádùn ẹ̀. Kódà tá a bá fẹ́ lọ síbi àpèjẹ tàbí tá a fẹ́ gbafẹ́ jáde, a jọ sábà máa ń lọ ni torí bí ìgbín bá fà, ìkarawun á tẹ̀ lé e.” Roxanne tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Torí pé ọwọ́ wa túbọ̀ ń dí, a rí i pé ó yẹ ká dìídì ṣètò àwọn ìgbà tá a máa wà pa pọ̀, bá a ṣe máa ń ṣètò àwọn nǹkan pàtàkì míì tá a máa ń ṣe.” (Fi wé Émọ́sì 3:3.) Damien tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “A kọ́ bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ohun tẹ́nì kejì fẹ́ràn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í jọ gbádùn àwọn nǹkan yẹn.” (Mát. 7:12) Katie tóun náà ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà míì, ṣe la máa ń gbé fóònù wa sílẹ̀ ká lè ráyè fún ara wa.”

13 Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ ẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Myriam tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Tá a bá jí láàárọ̀, àá kọ́kọ́ ka Bíbélì, àá sì jọ sọ àwọn ohun tá a kọ́ àtàwọn nǹkan tá a lè fi sílò. Mo máa ń gbádùn àkókò yẹn gan-an.” Ó tún sọ pé: “Mo tún fẹ́ràn bá a ṣe jọ máa ń gbàdúrà torí ó máa ń jẹ́ kí n rí bí ọkọ mi ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó.” Katie tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àkókò tá a bá jọ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù làwa máa ń gbádùn jù. Bá a ṣe ń gbọ́ tẹ́nì kejì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ kọ́ àwọn nǹkan tuntun lára ẹnì kejì.”—Òwe 27:17.

Àwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà nínú àwòrán ẹ̀ẹ̀kan ti ṣègbéyàwó, wọ́n ń gbádùn ara wọn níbi tí wọ́n ti ń yáná níta.

Tẹ́ ẹ bá ń wáyè láti wà pa pọ̀ déédéé, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ mọwọ́ ara yín ẹ̀ẹ́ sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12-13)


Bó Ṣe Yẹ Kí Ẹnì Kejì Ẹ Ṣe Pàtàkì Sí Ẹ Tó

A láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó pọ̀ nígbèésí ayé wa. Àmọ́, ipò wo ló yẹ kó o fi ọkọ tàbí aya ẹ sí?—Fílí. 1:10.

  1. 1. Jèhófà. Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wa, torí náà òun ni ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ. (Mát. 6:33; Máàkù 12:30) A ò ní ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́ torí pé a fẹ́ tẹ́ ẹnì kejì wa lọ́rùn.—Ìṣe 5:29; fi wé Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:6.

  2. 2. Ẹnì kejì wa. Bíbélì sọ pé “ara kan” ni ìwọ àti ẹnì kejì ẹ. Torí náà, bó o ṣe ń ṣìkẹ́ ara ẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa ṣìkẹ́ ẹnì kejì ẹ.—Jẹ́n. 2:24; Éfé. 5:28, 29, 33.

  3. 3. Àwọn èèyàn míì àtàwọn ojúṣe wa. Ọ̀pọ̀ ojúṣe la ní nínú ètò Ọlọ́run, yàtọ̀ síyẹn à ń tọ́jú àwọn òbí wa, àwọn mọ̀lẹ́bí wa àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́, lẹ́yìn Jèhófà kò sí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sí wa ju ẹnì kejì wa. A gbọ́dọ̀ rí i pé à ń tọ́jú ọkọ tàbí aya wa dáadáa, a sì ń múnú ẹ̀ dùn.—1 Tím. 5:8.

Ẹ MÁ FI ARA YÍN SÍLẸ̀ TÍṢÒRO BÁ DÉ

14-15. Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè yanjú ìṣòro tí wọ́n bá ní nínú ìgbéyàwó wọn? Ṣàpèjúwe.

14 Àwọn tọkọtaya máa láwọn ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn torí aláìpé ni gbogbo wa. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé àwọn tó bá ṣègbéyàwó “máa ní ìpọ́njú nínú ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé “ìpọ́njú tí ibí yìí ń sọ làwọn ìṣòro táwọn tọkọtaya sábà máa ń ní.” Táwọn ìṣòro yìí bá dé, kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí wọ́n lè jọ yanjú ìṣòro náà?

15 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé àwọn nǹkan kan bà jẹ́ nínú ilé àwòṣífìlà kan, ó dájú pé ẹni tó ni ilé náà máa fẹ́ tún gbogbo nǹkan yẹn ṣe. Kò sí àní-àní pé àtúnṣe náà máa ná ẹni yẹn lówó gan-an, ó sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó parí ẹ̀. Kí nìdí tẹni náà fi máa ṣe gbogbo wàhálà yìí? Ìdí ni pé ilé náà ṣeyebíye lójú ẹ̀, kò sì fẹ́ kó wó. Lọ́nà kan náà, gbogbo ìgbéyàwó ló ṣeyebíye. Kò sì sí bí tọkọtaya kan ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó, tí wọn ò ní máa ní èdèkòyédè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ bó ṣe jẹ́ pé a lè tún ohun tó bà jẹ́ nínú ilé kan ṣe, bákan náà tọkọtaya lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá ní. Òótọ́ ni pé ó lè gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n tó lè yanjú ìṣòro náà, àmọ́ inú Jèhófà máa dùn gan-an tó bá rí i pé wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣe ara wọn lọ́kan, kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé. (Mál. 2:16) Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, á hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Kò tán síbẹ̀ o, ìgbéyàwó wọn á fògo fún Jèhófà Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀!

16. Bí 1 Kọ́ríńtì 13:4-8a ṣe sọ, kí làwọn tọkọtaya tó níṣòro tó le nínú ìgbéyàwó wọn lè ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí àti àpótí “Àwọn Nǹkan Táá Jẹ́ Kí Àárín Yín Túbọ̀ Gún Régé.”)

16 Tẹ́ ẹ bá níṣòro nínú ìgbéyàwó yín, ẹ má ṣe tètè pinnu pé kí kálukú máa lọ nílọ ẹ̀. (1 Kọ́r. 7:10, 11) Kàkà bẹ́ẹ̀, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe ká lè yanjú ọ̀rọ̀ yìí, kí àárín wa sì gún régé?’ O lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn, kó o sì wo bó o ṣe lè túbọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tí 1 Kọ́ríńtì 13:4-8a sọ. (Kà á.) Dípò kó o máa wá bí wàá ṣe fi ẹnì kejì ẹ sílẹ̀, ṣe ni kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kẹ́ ẹ lè túbọ̀ ṣe ara yín lọ́kan. Máa ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe kẹ́ ẹ lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà. Ṣèwádìí nínú àwọn ìwé àtàwọn fídíò ètò Ọlọ́run. Bákan náà, o lè ní káwọn alàgbà àtàwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì fi ìgbéyàwó wé “okùn onífọ́nrán mẹ́ta,” Jèhófà sì lẹni tó lágbára jù láàárín yín. Torí náà, tẹ́ ẹ bá ń ṣe nǹkan tí Jèhófà fẹ́, àárín yín á túbọ̀ gún régé.—Oníw. 4:12.

Tọkọtaya náà ní èdèkòyédè, wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ilé. Ìyàwó ń sunkún bó ṣe ń sọ̀rọ̀, ọkọ ẹ̀ ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ó sì gbé ọwọ́ lé èjìká ẹ̀. Bíbélì tí wọ́n ṣí sílẹ̀ àti ìwé “Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀” wà lórí tábìlì níwájú wọn.

Tẹ́ ẹ bá níṣòro nínú ìgbéyàwó yín, ẹ má ṣe fi ara yín sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 16)


Àwọn Nǹkan Táá Jẹ́ Kí Àárín Yín Túbọ̀ Gún Régé

Ètò Jèhófà ti ṣe àwọn ìwé àtàwọn fídíò tó lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé, kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ láwọn ìṣòro tó lè mú kí wọ́n fi ara wọn sílẹ̀. Ṣé o ti gbìyànjú ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà nínú àwọn nǹkan tá a tò sí ìsàlẹ̀ yìí?

  • Ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

  • Ọ̀wọ́ fídíò Tọkọtaya Aláyọ̀

  • Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé”

  • Abala tó sọ̀rọ̀ nípa “Ìgbéyàwó àti Ìdílé” lórí jw.org

17. Kí làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó àtàwọn tó ti ṣègbéyàwó lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ láyọ̀?

17 Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ máa láyọ̀, bóyá wọ́n ti ṣègbéyàwó tàbí wọn ò tíì ṣe. Torí náà, tó ò bá tíì ṣègbéyàwó tó sì wù ẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ dáadáa kó o tó yan ẹni tó o máa fẹ́. Tó o bá sì ti ṣègbéyàwó, máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àárín yín túbọ̀ gún régé. Tẹ́ ẹ bá níṣòro nínú ìgbéyàwó yín, ẹ ṣe gbogbo nǹkan tẹ́ ẹ lè ṣe láti yanjú ẹ̀, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí Jèhófà ràn yín lọ́wọ́. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, wàá “gbádùn ayé rẹ” pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ ọ̀wọ́n!—Oníw. 9:9.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni Kristẹni kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó lè ṣe tó bá fẹ́ yan ẹni tí wọ́n á jọ bára wọn kalẹ́?

  • Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe kí àárín wọn lè túbọ̀ gún régé?

  • Kí ló lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní fi ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn?

ORIN 132 A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo

a Àtọkùnrin àtobìnrin ló yẹ kó bi ara ẹ̀ ní ìbéèrè yìí.

b Kó o lè rí àwọn àbá míì nípa bẹ́ ẹ ṣe lè túbọ̀ mọ ara yín dáadáa, ka àpilẹ̀kọ “Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2024, lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ẹ Rí I Pé Ẹ Mọra Yín Dáadáa.”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́