ÀPILẸ̀KỌ 50
ORIN 48 Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Bíi Ti Jèhófà
“Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.”—ÉFÉ. 5:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí nǹkan mẹ́rin tó yẹ ká ṣe táá fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà.
1. Kí nìdí tó fi jọni lójú pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀?
TÁ A bá ń ronú nípa àwọn tó wà nípò àṣẹ lóde òní, ṣé a lè sọ pé wọ́n nírẹ̀lẹ̀? Kò dájú. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lágbára tó Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè, síbẹ̀ ó nírẹ̀lẹ̀. (Sm. 113:5-8) Jèhófà kì í gbéra ga rárá, kódà gbogbo ohun tó ń ṣe máa ń fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà, ká sì wo bí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe hàn nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Bàbá ẹ̀. Ohun tá a fẹ́ jíròrò yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì rí báwa náà ṣe lè nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Baba wa ọ̀run.
JÈHÓFÀ ṢEÉ SÚN MỌ́
2. Kí ni Sáàmù 62:8 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà? (Tún wo àwòrán.)
2 Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í rọrùn láti sún mọ́ àwọn agbéraga. Torí pé wọ́n máa ń ka ara wọn sí ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn máa ń mú kí wọ́n hùwà tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ yẹra fún wọn pátápátá. Àmọ́, Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Torí pé Baba wa ọ̀run nírẹ̀lẹ̀, ó fẹ́ ká sún mọ́ òun, ká sì sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa àti gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún òun. (Ka Sáàmù 62:8.) Bí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ ṣe máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn tí wọ́n bá ń sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń tẹ́tí sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Kódà, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni Jèhófà. (Jóṣ. 10:12-14; 1 Sám. 1:10-18) Àmọ́ tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò yẹ lẹ́ni tó lè sún mọ́ Jèhófà nítorí àṣìṣe wa ńkọ́?
Bíi ti Jèhófà, bàbá yìí nírẹ̀lẹ̀, ó ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọmọ ẹ̀ tó fọ́ àwo níbi tó ti ń ṣeré (Wo ìpínrọ̀ 2)
3. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà sóun déédéé?
3 A lè gbàdúrà sí Jèhófà tó bá tiẹ̀ ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ọmọ onínàákúnàá, ó fi Jèhófà wé bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀, tó sì ń ṣìkẹ́ wọn. Àmọ́, ọmọ ẹ̀ tó ṣàṣìṣe wò ó pé òun ò yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń gbà pa dà sínú ìdílé náà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ronú pìwà dà. Kí ni bàbá náà ṣe nígbà tí ọmọ yẹn pa dà sílé? Jésù sọ pé gbàrà tí bàbá náà rí ọmọ ẹ̀ tó ń bọ̀, ṣe ló “sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” (Lúùkù 15:17-20) Bí Jèhófà ṣe máa ń ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó bá gbọ́ àdúrà àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn àtàwọn tí ọkàn wọn ń dá wọn lẹ́bi tàbí tí wọ́n ń ṣàníyàn, ó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn torí pé ó nírẹ̀lẹ̀. (Ìdárò 3:19, 20) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àánú Jèhófà máa ń mú kó sáré pàdé wọn, kó lè tù wọ́n nínú, kó sì fi dá wọn lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, òun sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Àìsá. 57:15) Báwo ni Jèhófà ṣe ń “sáré pàdé” wa lónìí? Ó sábà máa ń lo àwọn alàgbà, àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ará láti ràn wá lọ́wọ́. (Jém. 5:14, 15) Jèhófà máa ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa torí pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun.
4. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ṣeé sún mọ́?
4 Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀. Bíi ti Jèhófà, Jésù náà nírẹ̀lẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tó wà láyé, ó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn. Ẹ̀rù kì í bà wọ́n láti bi í ní ìbéèrè. (Máàkù 4:10, 11) Tó bá béèrè èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ kan, wọn kì í bẹ̀rù láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Mát. 16:13-16) Tí wọ́n bá sì ṣàṣìṣe, wọn kì í gbọ̀n jìnnìjìnnì torí ọkàn wọn balẹ̀ pé Jésù kì í kanra, ó jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń ṣe sùúrù. (Mát. 17:24-27) Torí pé Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ láìkù síbì kan, ìyẹn jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. (Jòh. 14:9) Wọ́n rí i pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, ó sì ṣeé sún mọ́. Ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn tí wọ́n burú, tí wọ́n sì máa ń gbéra ga.
5. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, kí nìdí tó fi máa rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wa?
5 Bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, á rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wa. Àmọ́, tá ò bá nírẹ̀lẹ̀, ṣe làá máa jowú, àá máa gbéra ga, a ò sì ní máa dárí jini, irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń lé àwọn èèyàn sá. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa kanra, àá máa ṣe sùúrù, àá sì máa dárí jini, ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ wa. (Kól. 3:12-14) Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn ará. Bí àpẹẹrẹ, ní gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe, àwọn alàgbà máa ń sapá láti wá sípàdé lójúkojú, dípò kí wọ́n dara pọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bákan náà, wọ́n máa ń gbìyànjú láti bá àwọn ará lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Torí náà, báwọn ará bá ṣe ń sún mọ́ àwọn alàgbà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún wọn láti fọ̀rọ̀ lọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá níṣòro.
JÈHÓFÀ MÁA Ń FÒYE BÁNI LÒ
6-7. Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà kì í rin kinkin mọ́ èrò ẹ̀.
6 Àwọn agbéraga máa ń ronú pé àwọn làwọn gbọ́n jù, torí náà wọ́n máa ń rin kinkin mọ́ èrò wọn. Àmọ́ ní ti Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó gbọ́n tó o, tí òye ẹ̀ ò sì láfiwé, síbẹ̀ ó nírẹ̀lẹ̀, ó máa ń fòye báni lò, kì í sì í rin kinkin mọ́ èrò ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe fún Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Mósè ń ṣojú fún, Míríámù àti Áárónì sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa. Torí náà, a lè sọ pé Jèhófà ni Míríámù tàbùkù sí. Èyí mú kí Jèhófà bínú sí Míríámù, ó sì sọ ọ́ di adẹ́tẹ̀. Áárónì wá bẹ Mósè, Mósè sì bẹ Jèhófà pé kó wo Míríámù sàn. Kí ni Jèhófà ṣe? Jèhófà ò rin kinkin pé ohun tóun sọ labẹ́ gé. Àmọ́ torí pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Mósè, ó sì wo Míríámù sàn.—Nọ́ń. 12:1-15.
7 Jèhófà tún fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ bó ṣe gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Ọba Hẹsikáyà. Jèhófà rán wòlíì ẹ̀ sí ọba náà pé ikú ló máa gbẹ̀yìn àìsàn tó ń ṣe é. Hẹsikáyà wá sunkún sí Jèhófà lọ́rùn, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo òun sàn. Jèhófà gbọ́ àdúrà ẹ̀, ó ṣàánú ẹ̀, ó wá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé ẹ̀. (2 Ọba 20:1, 5, 6) Ẹ ò rí i pé aláàánú ni Jèhófà, ìrẹ̀lẹ̀ tó ní sì máa ń mú kó tẹ́tí gbọ́ wa.
8. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa ń fòye báni lò? (Máàkù 3:1-6)
8 Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tó bá rí i pé ó yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí ẹ̀sìn Júù tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn líle ta kò ó. (Ka Máàkù 3:1-6.) Títí dòní, Jésù ṣì máa ń fòye báni lò bó ṣe ń darí ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó máa ní sùúrù fún ẹni náà, ó sì máa fún onítọ̀hún láǹfààní láti ṣàtúnṣe.—Ìfi. 2:2-5.
9. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń fòye báni lò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà. Tá a bá fẹ́ máa fòye báni lò bíi ti Jèhófà, a gbọ́dọ̀ nírẹ̀lẹ̀, ká máa ronú bó ṣe ń ronú, ká sì máa hùwà bíi tiẹ̀. (Jém. 3:17) Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí tó bá ń fòye báni lò kì í gba ohun tí ò dáa láyè, síbẹ̀ wọn kì í retí pé káwọn ọmọ wọn ṣe ju agbára wọn lọ. Jékọ́bù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, bá a ṣe rí i nínú Jẹ́nẹ́sísì 33:12-14. Àwọn òbí tó bá nírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì ní òye kì í fi àwọn ọmọ wéra. Ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà náà máa fòye báni lò. Ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n má ṣe rin kinkin mọ́ èrò wọn tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn alàgbà bá ti fọwọ́ sí àbá kan, tí àbá náà ò sì ta ko ìlànà Bíbélì. (1 Tím. 3:2, 3) Bákan náà, ó yẹ kí gbogbo wa máa tẹ́tí sí èrò àwọn ẹlòmíì, ká sì gbìyànjú láti fi ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan wò ó, bí èrò wa ò bá tiẹ̀ bá tiwọn mu. (Róòmù 14:1) Ohun kan ni pé, gbogbo wa nínú ìjọ gbọ́dọ̀ sapá ‘kí gbogbo èèyàn lè rí i pé à ń fòye báni lò.’—Fílí. 4:5.
Ó yẹ káwọn òbí mọ ohun tágbára àwọn ọmọ wọn gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 9)
JÈHÓFÀ MÁA Ń NÍ SÙÚRÙ
10. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ní sùúrù?
10 Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àwọn tó bá ń gbéra ga kì í fẹ́ dúró de àwọn ẹlòmíì. Ìgbéraga kì í jẹ́ kéèyàn ní sùúrù. Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí pé òun ló ní sùúrù jù láyé àtọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Nóà, Jèhófà sọ pé òun máa ní sùúrù fún ọgọ́fà (120) ọdún kóun tó pa àwọn ẹni ibi run. (Jẹ́n. 6:3) Ìyẹn jẹ́ kí Nóà ráyè tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ yanjú, òun àti ìdílé ẹ̀ sì jọ kan ọkọ áàkì. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, áńgẹ́lì tí Jèhófà rán níṣẹ́ fi sùúrù tẹ́tí sí Ábúráhámù bó ṣe ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ nípa ìparun Sódómù àti Gòmórà. Ká ní áńgẹ́lì náà ń gbéra ga ni, ó ṣeé ṣe kó sọ pé, ‘Irú ìbéèrè wo lò ń bi mí yìí?’ Àmọ́ bíi ti Jèhófà, áńgẹ́lì náà ní sùúrù fún Ábúráhámù.—Jẹ́n. 18:20-33.
11. Bí 2 Pétérù 3:9 ṣe sọ, kí nìdí tí Jèhófà fi ń mú sùúrù lásìkò wa yìí?
11 Torí pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, ó máa ń mú sùúrù fáwa náà lónìí. Ó ń dúró de àkókò tó ti pinnu láti fòpin sí ayé burúkú yìí. Kí nìdí tó fi ń mú sùúrù? Bíbélì sọ pé: “Torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (Ka 2 Pétérù 3:9.) Ṣé sùúrù Jèhófà ṣe àwa èèyàn láǹfààní? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀pọ̀ èèyàn tó lọ́kàn tó dáa ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì wá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. A sì nírètí pé ọ̀pọ̀ àwọn míì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o, ó níbi tí sùúrù Jèhófà mọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kì í gbàgbàkugbà. Kò ní jẹ́ káwọn èèyàn burúkú máa wà títí lọ.—Háb. 2:3.
12. Kí ló fi hàn pé Jésù ní sùúrù bíi ti Jèhófà?
12 Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀. Bíi ti Jèhófà, ọjọ́ pẹ́ tí Jésù náà ti ń ní sùúrù. Ó rí gbogbo bí Sátánì ṣe ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́. (Jẹ́n. 3:4, 5; Jóòbù 1:11; Ìfi. 12:10) Jésù tún rí gbogbo bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn èèyàn. Ẹ wo bá ṣe máa wù ú tó láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú”! (1 Jòh. 3:8) Kí ló jẹ́ kí Jésù lè ní sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa sọ fún un pé kó fòpin sí gbogbo iṣẹ́ burúkú tí Èṣù ti ṣe pátápátá? Ìdí ni pé ó nírẹ̀lẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó fi ohun gbogbo lé Jèhófà lọ́wọ́, torí ó mọ̀ pé àsìkò Jèhófà ló dáa jù.—Ìṣe 1:7.
13. Kí ló fi hàn pé Jésù ní sùúrù fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
13 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ní sùúrù fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, àmọ́ Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú sùúrù fún wọn. (Lúùkù 9:46; 22:24-27) Ó gbà pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n á ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ṣé àṣìṣe kan wà tíwọ náà ti ṣe léraléra? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a mà dúpẹ́ o pé Ọba tó nírẹ̀lẹ̀, tó sì ń ṣe sùúrù la ní!
14. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ máa ní sùúrù?
14 Bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà. Tá a bá ní “èrò inú Kristi,” ìyẹn á jẹ́ ká lè túbọ̀ máa ronú bíi ti Jèhófà, ká sì fìwà jọ ọ́. (1 Kọ́r. 2:16) Kí la lè ṣe ká lè ní èrò inú Kristi? Kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ! Ohun kan tó ṣe pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ ṣe ni pé ká ka àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú lórí ohun tá a kà, ká lè mọ ohun tó mú kí Jésù ṣe àwọn ohun tó ṣe. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì máa ronú bí Jésù ṣe ń ronú. Tá a bá ní èrò inú Kristi, àá túbọ̀ fìwà jọ Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa fi sùúrù ṣe àwọn nǹkan tá a bá ń ṣe, ká sì máa ní sùúrù fáwọn ara wa.—Mát. 18:26-30, 35.
JÈHÓFÀ MÁA Ń BUYÌ KÚN ÀWỌN TÁWỌN ÈÈYÀN Ò KÀ SÍ
15. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 138:6, àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀?
15 Ka Sáàmù 138:6. Rò ó wò ná, Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run máa ń kíyè sí àwọn tó nírẹ̀lẹ̀! Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn èèyàn kan tí Jèhófà pọ́n lé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sí lára àwọn táwọn èèyàn kà sí pàtàkì. A lè má tètè rántí àwọn kan lára wọn, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí Mósè láti sọ nípa obìnrin kan tó ń jẹ́ Dèbórà, tó jẹ́ olùtọ́jú nínú ìdílé Ísákì àti Jékọ́bù. Odindi ọdún márùndínláàádóje (125) ló fi ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn fún ìdílé méjèèjì! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa obìnrin olóòótọ́ yìí, Jèhófà mú kí wọ́n kọ nípa ẹ̀ sínú Bíbélì ká lè mọ bí ìdílé Ísákì àti Jékọ́bù ṣe fẹ́ràn ẹ̀ tó. (Jẹ́n. 24:59; 35:8, àlàyé ìsàlẹ̀.) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí Dáfídì, ọmọ kékeré kan tó ń da àgùntàn di ọba Ísírẹ́lì. (2 Sam. 22:1, 36) Bákan náà lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mélòó kan, ó sì buyì kún wọn torí àwọn ló kọ́kọ́ sọ fún pé a ti bí ọmọ tó máa di Mèsáyà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:8-11) Nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà sì gbé Jésù wá sí tẹ́ńpìlì, Jèhófà pọ́n Síméónì àti Ánà lé torí ó jẹ́ kí wọ́n rí Jésù Ọmọ òun. (Lúùkù 2:25-30, 36-38) Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ inú Sáàmù tó sọ pé, “bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀”!
16. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó pọ́n àwọn èèyàn lé bíi ti Jèhófà?
16 Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀. Bíi ti Jèhófà, Jésù náà buyì kún àwọn táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ àwọn ‘tí ò kàwé àtàwọn gbáàtúù’ ní òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 4:13; Mát. 11:25) Jésù tún wo àwọn tára wọn ò yá sàn, ọ̀nà tó sì gbà wò wọ́n sàn fi hàn pé ó pọ́n wọn lé. (Lúùkù 5:13) Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ló sì máa ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. (Jòh. 13:5) Kó sì tó pa dà sí ọ̀run, ó buyì kún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ títí kan àwa náà. Ó fún wa ní iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí ẹnikẹ́ni lè ní, ìyẹn ni pé ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 28:19, 20.
17. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń buyì kún àwọn èèyàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà. À ń buyì kún àwọn èèyàn tá a bá ń sọ ìhìn rere fún wọn láìka ibi tí wọ́n ti wá, àwọ̀ wọn tàbí bí wọ́n ṣe kàwé tó. Bákan náà, à ń buyì kún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a bá gbà pé wọ́n sàn jù wá lọ bá a tiẹ̀ ní ẹ̀bùn abínibí tàbí àǹfààní tí wọn ò ní. (Fílí. 2:3) Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá nírẹ̀lẹ̀ tá a sì ń “mú ipò iwájú” tó bá di pé ká bọlá fáwọn èèyàn láwọn ọ̀nà yìí àti láwọn ọ̀nà míì.—Róòmù 12:10; Sef. 3:12.
Tá a bá ń wàásù fún onírúurú èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 17)a
18. Kí nìdí tó fi wù ẹ́ kó o nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà?
18 Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà, ó máa rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wa, àá túbọ̀ máa fòye báni lò, àá sì túbọ̀ máa ní sùúrù. Yàtọ̀ síyẹn, àá máa buyì kún àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé bá a ṣe ń sapá láti nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa níyì lójú ẹ̀.—Àìsá. 43:4.
ORIN 159 Jèhófà Ni Ìyìn àti Ògo Yẹ!
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Torí pé àwọn arábìnrin yìí nírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì fìwà jọ Jèhófà, wọ́n ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́.