ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 July ojú ìwé 32
  • Múra Ìdáhùn Ẹ Sílẹ̀ Kó O Lè Gbé Àwọn Ará Ró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Múra Ìdáhùn Ẹ Sílẹ̀ Kó O Lè Gbé Àwọn Ará Ró
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Nípàdé Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Máa Yin Jèhófà “ní Àárín Ìjọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹ Máa Gbé Ara Yín Ró Lẹ́nì Kìíní-Kejì Nípa Dídáhùn ní Àwọn Ìpàdé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 July ojú ìwé 32

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Múra Ìdáhùn Ẹ Sílẹ̀ Kó O Lè Gbé Àwọn Ará Ró

Láwọn ìpàdé wa, a lè gbé àwọn ará wa ró, ká sì fún wọn níṣìírí tá a bá ń dáhùn. (Héb. 10:24, 25) Báwo la ṣe lè fi ìdáhùn wa gbé àwọn ará ró?

  • Gbàdúrà sí Jèhófà. Bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí ìdáhùn ẹ lè yìn ín lógo, kó sì gbé àwọn míì ró.—Sm. 35:18.

  • Gbìyànjú láti dáhùn lọ́rọ̀ ara ẹ. Tó o bá ń sapá láti dáhùn lọ́rọ̀ ara ẹ, dípò kó o kà á jáde bó ṣe wà nínú ìwé gẹ́lẹ́, ìdáhùn ẹ máa gbé àwọn míì ró.

  • Jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. Ìdáhùn tí ò gùn tí ò sì lọ́jú pọ̀ ló sábà máa ń fún àwọn míì níṣìírí, á sì jẹ́ káwọn náà lè dáhùn nípàdé.—Òwe 10:19.

  • Má ṣe máa fi ìdáhùn ẹ gún àwọn èèyàn lára. Kò yẹ kó o máa fi ìdáhùn ẹ bá àwọn ará wí tàbí kó o máa fi ṣàríwísí wọn.

Tí wọn ò bá tiẹ̀ pè ẹ́ láti dáhùn, o ṣì lè fún àwọn ará níṣìírí tó o bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa, tó o sì ń gbóríyìn fáwọn tó dáhùn.—Òwe 10:21.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́