ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 July ojú ìwé 2-7
  • Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Àwọn Ará Gíbíónì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Àwọn Ará Gíbíónì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ NÍRẸ̀LẸ̀
  • GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ TÍ WỌ́N BÁ HÙWÀ TÍ Ò DÁA SÍ Ẹ
  • MÁA KỌ́WỌ́ TI ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ
  • Àwọn Ará Gíbéónì Ọlọgbọ́n
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Ìtàn Àwọn Ará Gíbíónì
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 July ojú ìwé 2-7

SEPTEMBER 7-13, 2026

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Àwọn Ará Gíbíónì

‘Àwọn tó ń gbé Gíbíónì bá Ísírẹ́lì ṣàdéhùn àlàáfíà, wọ́n sì wá ń gbé ní àárín wọn.’—JÓṢ. 10:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè kọ́ lára àwọn ará Gíbíónì, àá sì rí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn.

1-2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ará Gíbíónì?

LỌ́DÚN 1473 Ṣ.S.K., àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí. Lẹ́yìn tí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò àti ìlú Áì lọ́nà tó kàmàmà, ohun kan tí wọn ò retí ṣẹlẹ̀. Àwọn arìnrìn àjò kan wá bá wọn, wọ́n sì sọ pé ìlú kan tó jìnnà gan-an làwọn ti wá. Wọ́n wá sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bá àwọn ṣe àdéhùn àlàáfíà.

2 Àwọn ará Gíbíónì làwọn arìnrìn àjò yẹn. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Bíbélì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn. Lẹ́yìn ìgbà ìyẹn, Bíbélì tún sọ àwọn nǹkan míì nípa wọn. Kódà, àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ará Gíbíónì fi gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Onírúurú ẹ̀kọ́ pàtàkì la lè rí kọ́ nínú àwọn àkọsílẹ̀ yẹn, wọ́n sì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà Ọlọ́run wa.

NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ NÍRẸ̀LẸ̀

3. (a) Ta ni àwọn ará Gíbíónì? (b) Kí nìdí tí wọ́n fi fẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàdéhùn àlàáfíà?

3 Ìlú olódi Gíbíónì làwọn ará Gíbíónì ń gbé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Kénáánì. Àwọn ará Gíbíónì wà lára àwọn ọmọ Hífì, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè méje ní ilẹ̀ Kénáánì “tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára” ju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. (Diu. 7:1) Torí náà, àwọn ará Gíbíónì ò kẹ̀rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ogun jíjà. (Jóṣ. 10:2) Àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì tó kù pinnu láti gbógun ja àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ àwọn ará Gíbíónì ò ṣe bẹ́ẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò lè rọ́wọ́ mú. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ń jà fáwọn èèyàn ẹ̀, ó sì ti ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò nílẹ̀ náà. (Ẹ́kís. 34:11; Jóṣ. 9:24) Torí náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò àti ìlú Áì, àwọn ará Gíbíónì rán àwọn aṣojúa sí Jóṣúà ní Gílígálì kó lè bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà.

4. (a) Bó ṣe wà nínú Jóṣúà 9:8-13, báwo làwọn ará Gíbíónì ṣe tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àṣírí wọn tú?

4 Ka Jóṣúà 9:8-13. Àwọn ará Gíbíónì díbọ́n bíi pé ibi tó jìnnà gan-an làwọn ti wá. Wọ́n gbà pé Jèhófà ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Íjíbítì àtàwọn ọba Ámórì méjì náà, ìyẹn Síhónì àti Ógù. Àmọ́, àwọn ará Gíbíónì gbọ́n, wọn ò sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sílùú Jẹ́ríkò àti Áì. Ìdí ni pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè fura pé tòsí ni wọ́n ti wá torí pé kò tíì pẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ ò sì tíì lè dé “ọ̀nà tó jìn gan-an” tí wọ́n sọ pé àwọn ti wá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n gbà pé òótọ́ làwọn ará Gíbíónì sọ, wọ́n wá bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà, wọ́n sì bá wọn dá májẹ̀mú. (Jóṣ. 9:14, 15) Kò pẹ́ sígbà yẹn làṣírí tú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá rí i pé ṣe làwọn ará Gíbíónì tan àwọn. Síbẹ̀, wọn ò yẹ àdéhùn àlàáfíà tí wọ́n bá wọn ṣe torí pé wọ́n “ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn.” (Jóṣ. 9:16-19) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá fún àwọn ará Gíbíónì níṣẹ́ kan tó rẹlẹ̀. Wọ́n sọ pé wọ́n máa “di aṣẹ́gi àti àwọn tí á máa pọnmi fún àpéjọ náà àti pẹpẹ Jèhófà” títí lọ.—Jóṣ. 9:27.

Àwọn ará Gíbíónì kan kúnlẹ̀ síwájú Jóṣúà àtàwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń bẹ̀ wọ́n. Wọ́n fi aṣọ wọn tó ti gbó àti awọ tí wọ́n ń rọ wáìnì sí hàn wọ́n.

Àwọn ará Gíbíónì tan Jóṣúà kó lè bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Kí làwọn ará Gíbíónì ṣe tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú Jèhófà?

5 Nígbà táwọn ọba Ámórì márùn-ún gbọ́ pé àwọn ará Gíbíónì ti lọ bá Ísírẹ́lì ṣàdéhùn àlàáfíà, wọ́n kóra jọ láti gbógun ja Gíbíónì. Àwọn ará Gíbíónì wá lọ bẹ Jóṣúà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Jóṣ. 10:3-7) Jóṣúà ṣètò àwọn ọmọ ogun kí wọ́n lè gbèjà àwọn ará Gíbíónì, Jèhófà sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lójú ogun náà. Jèhófà rọ̀jò òkúta yìnyín ńláńlá sórí àwọn ọmọ Ámórì, ó sì mú kí oòrùn dúró sójú kan lọ́nà ìyanu títí wọ́n fi ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá. (Jóṣ. 10:9-14) Bí àwọn ará Gíbíónì ṣe lọ bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣàdéhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì bẹ Jóṣúà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ lákòókò ìṣòro fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, àti pé ó lágbára láti gbà wọ́n là.

6. Kí la kọ́ nínú ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ará Gíbíónì?

6 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà? Ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà láàánú, ó sì nírẹ̀lẹ̀. Ṣáájú àkókò yẹn, Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n “lé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò,” èyí ò sì yọ àwọn ará Gíbíónì sílẹ̀. (Nọ́ń. 33:51, 52) Àmọ́, torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà, Jèhófà ṣàánú àwọn ará Gíbíónì, ó sì dá ẹ̀mí wọn sí. Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fọ̀rọ̀ lọ̀ ọ́ kí wọ́n tó ṣàdéhùn náà. Kò tán síbẹ̀ o, Jèhófà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa àdéhùn wọn mọ́, ó sì gba àwọn ará Gíbíónì sílẹ̀ lọ́nà ìyanu.—Jóṣ. 9:26; 11:19.

7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nígbàgbọ́, a sì nírẹ̀lẹ̀ bíi tàwọn ará Gíbíónì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ará Gíbíónì? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ará Gíbíónì ò mọ̀ nípa Jèhófà làwa ti mọ̀ lónìí, torí náà ó yẹ káwọn nǹkan tá a mọ̀ yìí mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. (Sm. 40:4, 5) Yàtọ̀ síyẹn, a lè fara wé àwọn ará Gíbíónì tá a bá ṣe tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. (Jóṣ. 9:23, 27) Arákùnrin Luke tó jẹ́ ọ̀dọ́ rántí pé ohun tí arákùnrin kan tó ti dàgbà tó sì ti pẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì ni arákùnrin yìí ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì tíyẹn sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ará mọ̀ ọ́n. Síbẹ̀ ó yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ aṣọ́gbà lóru mọ́jú níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Ilé Ìpàdé kan. Luke sọ pé: “Ohun tí mo kọ́ ni pé, a lè rò pé a nírẹ̀lẹ̀, àmọ́ ohun tá a bá ṣe ló máa fi hàn bẹ́ẹ̀.” Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ bíi tàwọn ará Gíbíónì? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro, a tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí nínú ètò Ọlọ́run.

Fọ́tò: Àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ tinútinú. 1. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ará Gíbíónì gbé omi sí èjìká. 2. Arákùnrin kan tó ti dàgbà ń gbin òdòdó sí Ilé Ìpàdé.

A lè fìwà jọ àwọn ará Gíbíónì tá a bá ṣe tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 7)


GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ TÍ WỌ́N BÁ HÙWÀ TÍ Ò DÁA SÍ Ẹ

8. Ìwà burúkú wo ni Ọba Sọ́ọ̀lù hù sáwọn ará Gíbíónì?

8 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Gíbíónì. Ọba Sọ́ọ̀lù dájú sọ àwọn ará Gíbíónì tó ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Bíbélì sọ pé, “nítorí ìtara tó ní fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà,” Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa gbogbo àwọn ará Gíbíónì run pátápátá.b Torí náà, wọ́n pa àwọn kan lára wọn. (2 Sám. 21:2, 5, 6) Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà gbáà nìyẹn! Sọ́ọ̀lù yẹ àdéhùn àlàáfíà tó ti wà láàárín àwọn ará Gíbíónì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tipẹ́tipẹ́.

9. Ìgbà wo ni Jèhófà mú kí ìwà burúkú tí wọ́n hù sáwọn ará Gíbíónì wá sójú táyé?

9 Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà fìyà jẹ àwọn tó hùwà burúkú yìí. Kódà, ìgbà tí Ọba Dáfídì ń ṣàkóso ni Jèhófà tó mú kí ọ̀rọ̀ náà wá sójú táyé. Ṣe ni Jèhófà jẹ́ kí ìyàn mú lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta gbáko. Nígbà tí Dáfídì béèrè ohun tó fa ìyàn náà, Jèhófà sọ fún un pé Sọ́ọ̀lù àti ìdílé ẹ̀ ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí ìwà ìkà tí wọ́n hù sáwọn ará Gíbíónì lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.—2 Sám. 21:1.

10. Bó ṣe wà nínú 2 Sámúẹ́lì 21:3-6, kí làwọn ará Gíbíónì sọ fún Dáfídì tó fi hàn pé wọn ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú Òfin Ọlọ́run?

10 Ka 2 Sámúẹ́lì 21:3-6. Dáfídì lọ bá àwọn ará Gíbíónì, ó sì béèrè ohun tóun lè ṣe fún wọn nítorí ìwà ìkà tí Sọ́ọ̀lù hù. Ṣé àwọn ará Gíbíónì wá béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó kí wọ́n lè sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀? Rárá o, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ “kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà,” torí pé lábẹ́ òfin kò sí ìràpadà fún ẹni tó bá pààyàn. (Nọ́ń. 35:30, 31) Wọ́n tún mọ̀ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ pa ẹnikẹ́ni ní Ísírẹ́lì láìjẹ́ pé wọ́n fún àwọn láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ni Dáfídì bá fún wọn láṣẹ láti pa méje lára àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù tó ṣeé ṣe kí wọ́n lọ́wọ́ sí ìwà burúkú tí bàbá wọn hù. Nígbà tó yá, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, ìyàn náà sì dópin. Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà gbèjà àwọn ará Gíbíónì, kò sì bínú sí Ísírẹ́lì mọ́.—2 Sám. 21:9, 10, 14.

11. Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?

11 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà? Ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. (Sm. 37:28) Kì í fẹ́ kí wọ́n rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń hùwà ìkà sáwọn tó bá wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀. Tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, ó máa gba àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń rẹ́ wọn jẹ àtàwọn tó ń hùwà ìkà sí wọn. Bákan náà, ìtàn yìí tún kọ́ wa pé Jèhófà fẹ́ ká máa pa àdéhùn mọ́, bó ṣe retí pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àdéhùn tí wọ́n ṣe fáwọn ará Gíbíónì mọ́.—Fi wé Émọ́sì 1:9.

12. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ará Gíbíónì tí wọ́n bá hùwà tí ò dáa sí wa?

12 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ará Gíbíónì? Táwọn ará wa bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, á dáa ká ṣe sùúrù, ká sì dúró dìgbà tí Jèhófà máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà lásìkò tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Laura French. Lọ́dún 1926, wọ́n pè é kó wá máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà. Lẹ́yìn tó lo nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, wọ́n ṣe ohun kan tí ò dáa sí i. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó wà lára àwọn apẹ̀yìndà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ọ̀rọ̀ ò sì rí bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n ṣe ní kó kúrò ní Bẹ́tẹ́lì nìyẹn. Kí ló wá ṣe? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà dùn ún gan-an, kò bẹ̀rẹ̀ sí í fapá jánú, kó wá máa sọ ohun tí ò dáa nípa ètò Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e ló fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó dọdún 1940, ó yà á lẹ́nu pé wọ́n pè é pa dà sí Bẹ́tẹ́lì, inú ẹ̀ sì dùn gan-an. Ibẹ̀ ló wà fún àádọ́ta (50) ọdún títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé. Bíi ti Arábìnrin French, tí wọ́n bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù, ká sì máa ṣe ohun tó tọ́, ká fi sọ́kàn pé Jèhófà máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà lákòókò tó tọ́ lójú ẹ̀.—Àìsá. 26:3, 4.

MÁA KỌ́WỌ́ TI ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ

13. Ta ni àwọn “Nétínímù,” kí ni wọ́n sì ṣe lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn Bábílónì?

13 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún lẹ́yìn ìṣàkóso Ọba Dáfídì, Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Gíbíónì. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹrú fún àádọ́rin (70) ọdún nílùú Bábílónì, wọ́n dá wọn sílẹ̀. Gómìnà Serubábélì sì wà lára àwùjọ àwọn Júù tó kọ́kọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 Ṣ.S.K. (Ẹ́sírà 2:1, 2, 58) Nígbà tó dọdún 468 Ṣ.S.K., àwùjọ àwọn Júù míì pa dà sílùú wọn, Ẹ́sírà adàwékọ sì wà lára wọn. (Ẹ́sírà 7:1-7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ méjèèjì tó pa dà yìí ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ìdílé àwọn “Nétínímù” wà lára wọn. (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Ẹ́sírà 2:58 àti 7:7.) Ta ni àwọn Nétínímù yìí? Àwọn Nétínímù làwọn “tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ ẹrú tàbí ìránṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì,” ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbíónì.—Wo “Nétínímù” nínú Àlàyé Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì.

14. Kí làwọn ará Gíbíónì ṣe tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn tòótọ́? (1 Kíróníkà 9:2 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé)

14 Ka 1 Kíróníkà 9:2 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. “Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì” wà lára àwọn tó kọ́kọ́ pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìyẹn sì jọni lójú torí pé kì í ṣe gbogbo àwọn Júù tó wà nígbèkùn ló pa dà sílé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ti rọ́wọ́ mú nílùú Bábílónì, nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn. Torí náà, wọn ò fẹ́ fi gbogbo ohun tí wọ́n ní sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ tún ìlú ìbílẹ̀ wọn kọ́. Àmọ́, ó wu àwọn Júù tó nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn tòótọ́ àtàwọn kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbíónì láti pa dà. Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mímọ́ pa dà. Ká má gbàgbé pé àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbíónì ò jogún ilẹ̀ kankan ní Ísírẹ́lì bíi tàwọn Júù. Síbẹ̀, wọ́n pa dà kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n yàn fún wọn, kí wọ́n sì tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́.—Neh. 3:26.

15. Kí ni ìtàn àwọn ará Gíbíónì kọ́ wa nípa Jèhófà?

15 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà? Ìtàn yìí kọ́ wa pé Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́, ó sì máa ń tọ́jú wọn. Tá a bá wo àkókò táwọn ará Gíbíónì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà sí ìgbà tí àwọn Júù kúrò nígbèkùn Bábílónì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. Síbẹ̀, Jèhófà ṣì ń bù kún wọn. Nígbà táwọn ará Bábílónì pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣ.S.K, Jèhófà dáàbò bo àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbíónì. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dé láti ìgbèkùn, wọ́n ṣì ń bá àwọn ọmọ Léfì ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Kódà, àwọn kan lára àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbíónì ń gbé nítòsí tẹ́ńpìlì. (Ẹ́sírà 2:70; Neh. 11:21) Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í gba owó orí, ìṣákọ́lẹ̀ tàbí owó ibodè lọ́wọ́ wọn torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì.—Ẹ́sírà 7:24.

16. Kí la lè ṣe ká lè kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́ bíi tàwọn ará Gíbíónì?

16 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn ará Gíbíónì? Àwa náà fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn, tinútinú la máa ń yááfì àwọn nǹkan kan ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ohun tí Arákùnrin Alwin tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines ṣe nìyẹn. Iléeṣẹ́ kan tó ń rí sọ́rọ̀ epo ló ti ń ṣiṣẹ́, owó ńlá sì ń wọlé fún un. Síbẹ̀, ó wù ú láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, nígbàkigbà tí alábòójútó àyíká bá wá síjọ wọn, Alwin máa ń gbàyè lẹ́nu iṣẹ́ kó lè ráyè lọ sóde ìwàásù dáadáa lọ́sẹ̀ yẹn, ìyẹn sì máa ń múnú ẹ̀ dùn gan-an. Alwin wá fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, nígbà tó yá, ó pinnu pé òun máa fiṣẹ́ tóun ń ṣe sílẹ̀, òun á sì wáṣẹ́ míì tó máa jẹ́ kóun ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ìpinnu yẹn ò rọrùn rárá torí pé owó táá máa wọlé fún un ò ní pọ̀ mọ́. Síbẹ̀, ó ṣe ohun tó pinnu, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, ìyàwó ẹ̀ náà di aṣáájú-ọ̀nà, àwọn méjèèjì sì ti ran èèyàn mọ́kànlélógún (21) lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọyì ohun tí tọkọtaya yìí ṣe. Bákan náà, Jèhófà máa ń mọyì ẹ̀ tá a bá yááfì ohunkóhun ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, ó sì dájú pé gbogbo ìgbà lá máa pèsè ohun tá a nílò.—Mát. 6:33.

17. Àwọn nǹkan wo la ti kọ́ nínú ìtàn àwọn ará Gíbíónì?

17 Ìtàn àwọn ará Gíbíónì nínú Bíbélì jẹ́ ká túbọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ó jẹ́ ká rí i pé ó nírẹ̀lẹ̀, ó jẹ́ aláàánú, ó máa ń ṣèdájọ́ òdodo, kì í sì í gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo ìgbà ló máa ń bù kún wọn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la ti rí kọ́ nínú ìtàn àwọn ará Gíbíónì. Bíi tàwọn ará Gíbíónì, ó yẹ ká nígbàgbọ́ tó lágbára, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá ní ìṣòro tó kà wá láyà. Ìgbàgbọ́ yìí á tún jẹ́ ká fìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wa nínú ètò Ọlọ́run. Bákan náà, ó yẹ ká máa ní sùúrù tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa, ká sì gbà pé Jèhófà máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà tó bá tó àkókò lójú ẹ̀. Ó tún yẹ ká jẹ́ olóòótọ́, ká sì máa fìtara kọ́wọ́ ti ìjọsìn Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé àwa náà ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìtàn àwọn ará Gíbíónì.

KÍ LA RÍ KỌ́ LÁRA ÀWỌN ARÁ GÍBÍÓNÌ . . .

  • nípa ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀?

  • tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa?

  • nípa bá a ṣe lè kọ́wọ́ ti ìjọsìn Jèhófà?

ORIN 148 Jèhófà Ń Ṣe Ọ̀nà Àsálà

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n rán wá yìí wá láti ìlú Gíbíónì àtàwọn ìlú mẹ́ta míì nílẹ̀ Hífì, ìyẹn Kéfírà, Béérótì àti Kiriati-jéárímù.—Jóṣ. 9:17.

b Bíbélì ò sọ ìdí tí Sọ́ọ̀lù fi hùwà burúkú yìí. Àmọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́