JULY 13-19, 2026
ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
Bó O Ṣe Lè Fi Àwọn Ìlànà Bíbélì Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Ẹ
“Kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.”—GÁL. 6:5.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè fi ìlànà Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa ká lè máa ṣèpinnu tó tọ́.
1-2. (a) Ẹ̀bùn pàtàkì wo ni Jèhófà fún Ádámù àti Éfà? (b) Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè fi hàn pé wọ́n mọyì ẹ̀bùn náà?
BÍ Jèhófà ṣe dá àwa èèyàn yàtọ̀ pátápátá sáwọn nǹkan míì tó dá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹranko kì í ronú kí wọ́n tó ṣe nǹkan torí ọgbọ́n àdámọ́ni ni wọ́n ń lò. Bákan náà, tó bá kan onírúurú ẹ̀rọ táwọn èèyàn ṣe, ohun tí wọ́n bá ní kó ṣe nìkan lá máa ṣe. Àmọ́ tàwa èèyàn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nígbà tí Jèhófà dá wa, ó fún wa lẹ́bùn pàtàkì kan, ìyẹn òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá ká sì pinnu ohun tá a bá fẹ́. Àwa Kristẹni mọyì ẹ̀bùn yìí gan-an. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́n. 1:26, 27) Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ìyàwó ẹ̀ lọ́gbọ́n nígbà tó dá wọn, ó sì fún wọn lómìnira láti pinnu ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe.
2 Jèhófà ò fún Ádámù àti Éfà láwọn òfin jànràn-janran. Ṣe ló kàn ní kí wọ́n máa bójú tó ayé, kí wọ́n bímọ, káwọn ọmọ wọn sì kún ayé. Paríparí ẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n gbà pé òun lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́. (Jẹ́n. 1:28; 2:16, 17) Kí ló yẹ kí Ádámù àti Éfà ṣe kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn mọyì Ẹni tó fún wọn lómìnira láti pinnu ohun tí wọ́n bá fẹ́? Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn yìí, ó yẹ kí wọ́n ṣe tán láti pa àwọn òfin ẹ̀ mọ́, torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, wọ́n sì fẹ́ múnú ẹ̀ dún.—Òwe 23:15.
3. Báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe lo òmìnira tí Jèhófà fún wọn?
3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ádámù àti Éfà ṣi òmìnira wọn lò. Dípò kí wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ṣe ni wọ́n ṣàìgbọràn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà wọn ò sì mọyì gbogbo ohun tó ṣe fún wọn. (Jẹ́n. 3:1-7) A ṣì ń jìyà àbájáde ohun tí wọ́n ṣe yìí títí dòní.—Róòmù 5:12.
4. (a) Bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:5, kí ló yẹ kí kálukú wa ṣe? (b) Ẹ̀bùn míì wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Lónìí, ọ̀pọ̀ ìpinnu la máa ń ṣe lójoojúmọ́, ìyẹn ò sì rọrùn rárá. (Ka Gálátíà 6:5.) Àwọn ìpinnu kan máa ń rọrùn, àwọn míì sì máa ń ṣòro ṣe. Báwo la ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn? Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé àfi kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 16:3; Jer. 10:23) Kódà, Jésù tó jẹ́ ẹni pípé gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. (Héb. 5:7) Tí Jésù tó jẹ́ ẹni pípé bá nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, mélòómélòó àwa èèyàn tá a jẹ́ aláìpé. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ẹ̀bùn pàtàkì míì tí Jèhófà fún wa ká lè ṣèpinnu tó tọ́, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn wa.
KÍ NI Ẹ̀RÍ ỌKÀN?
5. (a) Kí ni ẹ̀rí ọkàn? (b) Iṣẹ́ wo ni ẹ̀rí ọkàn máa ń ṣe? (Róòmù 2:14, 15)
5 Ẹ̀rí ọkàn ni ohun tí Jèhófà dá mọ́ wa, tó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó dáa àtohun tí kò dáa. Kódà, ẹni tí ò mọ Ọlọ́run rárá náà ní ẹ̀rí ọkàn. (2 Kọ́r. 4:2) Ṣe ni ẹ̀rí ọkàn dà bí adájọ́ tó máa ń dá wa lẹ́jọ́ tàbí dá wa láre lórí àwọn nǹkan tá à ń rò, àtàwọn nǹkan tá à ń ṣe. (Ka Róòmù 2:14, 15.) Ó tún máa ń kìlọ̀ fún wa tá a bá fẹ́ ṣe ohun tá a mọ̀ pé ó kù díẹ̀ káàtó. (1 Sám. 26:8-11) Bákan náà, ó lè sún wa ṣe ohun tó tọ́. Ti pé a ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá kò fi hàn pé gbogbo ohun tá a bá ṣe lá máa múnú Jèhófà dùn. Torí náà, ó yẹ kí ẹ̀rí ọkàn wa lè jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín ìpinnu tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́.
6. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ẹ̀rí ọkàn wa má ṣiṣẹ́ dáadáa?
6 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ẹ̀rí ọkàn wa máa ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Ìdí ni pé aláìpé ni wá, torí náà kò sí bí ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ṣiṣẹ́ lọ́nà tó pé. Lára àwọn nǹkan tó lè mú kó má ṣiṣẹ́ dáadáa ni bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà, àṣà ìbílẹ̀ wa àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó máa ń wá sí wa lọ́kàn. Nígbà tí Bíbélì ń sọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn, ó sọ pé ó lè má “lágbára” mọ́, ó lè di “ẹlẹ́gbin,” ó sì lè dà bí èyí tí “irin ìsàmì ti dá àpá sí,” kódà, ó sọ pé èèyàn lè ní “ẹ̀rí ọkàn burúkú.” (1 Kọ́r. 8:12; Títù 1:15; 1 Tím. 4:2; Héb. 10:22) Ẹ̀rí ọ̀kan tó bá ti rí bẹ́ẹ̀ kò ní lè tọ́ wa sọ́nà mọ́. Ṣe ló máa dà bí aago kan tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, tó gba pé kí wọ́n tún ṣe, kí wọ́n sì yí ọwọ́ ẹ̀ síbi tó yẹ kó wà. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ kọ́ ọ kó lè tọ́ wa sọ́nà. (1 Pét. 3:16) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
OHUN TÁ A LÈ ṢE KÍ Ẹ̀RÍ ỌKÀN WA LÈ MÁA ṢIṢẸ́ DÁADÁA
7-8. (a) Kí la lè ṣe kí ẹ̀rí ọkàn wa lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa? (b) Báwo làwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Ṣàpèjúwe. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Kí la lè ṣe kí ẹ̀rí ọkàn wa lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa? A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì déédéé ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ àtohun tí ò fẹ́. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn òfin Ọlọ́run, á jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Àmọ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó lójú ibi téèyàn ti lè lo àwọn òfin tó ṣe pàtó. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa wá àwọn ìlànà Bíbélì, torí ìyẹn lá jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà àti bí ohun tá a fẹ́ ṣe ṣe máa rí lára ẹ̀.—Àìsá. 55:9.
8 Ìgbésí ayé dà bí ìgbà téèyàn ń rìn nínú aginjù tí kò sí ipa ọ̀nà tàbí àmì tó ń júwe ọ̀nà. Àmọ́ tá a bá rí àwòrán ilẹ̀ tó ń júwe ọ̀nà, tó sì ní àwọn àmì táá jẹ́ ká mọ ibi tá a dé, á mú kí ìrìn àjò náà rọrùn. Àwòrán ilẹ̀ yìí máa jẹ́ kó dá wa lójú pé ojú ọ̀nà la wà, á sì jẹ́ ká mọ̀ tá a bá ti ń ṣìnà. Bọ́rọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe rí níyẹn, bá a ṣe máa múnú Jèhófà dùn lohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa nígbèésí ayé. Bíbélì dà bí àwòrán ilẹ̀ tó ń jẹ́ ká mọ ibi tá à ń lọ gan-an. Àwọn ìlànà Bíbélì ló dà bí àwọn àmì tó wà nínú àwòrán ilẹ̀ náà. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn àmì tó wà nínú àwòrán ilẹ̀ náà, a máa débi tá à ń lọ láyọ̀ àti àlàáfíà. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àá múnú Jèhófà dùn.
Àwọn ìlànà Bíbélì dà bí àwọn àmì tó wà nínú àwòrán ilẹ̀ kan, àwọn àmì yìí ló sì máa jẹ́ ká mọ̀ pé a ṣì wà lójú ọ̀nà (Wo ìpínrọ̀ 8)
9. Bí Róòmù 9:1 ṣe sọ, kí ni nǹkan míì táá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
9 Tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, àfi kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. (Ka Róòmù 9:1.) Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè jẹ́ kó wù wá, kó sì fún wa lágbára láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Fílí. 2:13) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe?
10. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́? (Lúùkù 11:10, 13)
10 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́. (Ka Lúùkù 11:10, 13.) Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà ṣe tán láti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. (Jòh. 3:34) Torí pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà, inú ẹ̀ máa ń dùn láti fún àwọn tó bá ń ṣe ohun tó fẹ́ ní ẹ̀mí mímọ́. (Òwe 1:23; Jém. 1:5) Àmọ́ kí ni nǹkan míì táá jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
11. (a) Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ nígbèésí ayé? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká rí i dájú pé a kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
11 Máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn ní gbogbo ìgbà. (Òwe 8:34, 35) Ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ nígbèésí ayé nìyẹn. Tá a bá ń rántí pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, ìyẹn á lè jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, á jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà nípa ohun tá a bá fẹ́ ṣe, ká sì pinnu láti ṣe ohun tí ò ní bà á nínú jẹ́. Torí pé ọ̀pọ̀ ìpinnu la máa ń ṣe lónìí, ó ṣe pàtàkì ká kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń gba pé ká ṣèpinnu kan, tó sì jẹ́ pé Bíbélì ò sọ pàtó ohun tó yẹ ká ṣe. Àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ lè kan eré ìnàjú tá a fẹ́ ṣe, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, bá a ṣe máa kàwé tó àtàwọn tá a máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú pé ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí máa múnú Jèhófà dùn?—2 Kọ́r. 1:12.
12. Kí lá jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀rí ọkàn wa ń ṣiṣẹ́ dáadáa? (Éfésù 5:10)
12 Máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 49:3) Tó o bá ń ka Bíbélì, àwọn ìlànà tó máa jẹ́ kó o mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan ni kó o máa wá. (Ka Éfésù 5:10.) Àwọn ìlànà yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ẹ̀rí ọkàn ẹ ń ṣiṣẹ́ dáadáa àti bóyá ìpinnu tó dáa lò ń ṣe nígbà tó o bá níṣòro. (Òwe 2:4-9, 11-13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìlànà yìí máa jẹ́ kó o lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ dáadáa kó lè máa tọ́ ẹ sọ́nà láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.—Héb. 5:14.
13. Kí ni kò yẹ ká ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.
13 Má ṣe kọ́kọ́ ṣèpinnu, kó o wá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá ìlànà Bíbélì táá ti ìpinnu ẹ lẹ́yìn. Kò yẹ ká ṣe bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù ní Júdà lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 Ṣ.S.K. Wọ́n sọ fún Jeremáyà pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sọ ọ̀nà tó yẹ kí a rìn fún wa àti ohun tó yẹ ká ṣe.” (Jer. 42:3-6) Àmọ́ ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni wọ́n sọ torí wọ́n ti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀. Nígbà tí wọ́n rí i pé ohun tí Jèhófà sọ ò bá wọn lára mu, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti pinnu tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì kan ìdin nínú iyọ̀. (Jer. 42:19-22; 43:1, 2, 4) Torí náà, ká tó ṣèpinnu kan, ó yẹ ká kọ́kọ́ wá àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà lórí ohun tá a fẹ́ ṣe, ká sì ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣèpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu?
14 Máa ṣèpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu. (Mát. 7:24-29; Jém. 1:23-25) Tá a bá ń ṣe ìpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu, ṣe là ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa. Èyí á sì jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. (Ìṣe 5:32) Àmọ́, tá ò bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a lè “kó ẹ̀dùn ọkàn” bá ẹ̀mí mímọ́, tàbí ká máa ta kò ó. (Éfé. 4:30; Àìsá. 63:10; Ìṣe 7:51) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè gba ẹ̀mí ẹ̀ kúrò lára wa. (Sm. 51:11; 1 Tẹs. 5:19) Ìyẹn sì máa burú gan-an torí pé láìsí ẹ̀mí Ọlọ́run, a ò lè ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé.—Éfé. 3:16.
BÁ A ṢE LÈ RÍ ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TÁÁ RÀN WÁ LỌ́WỌ́
15-16. (a) Báwo la ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò wa mu? (b) Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú sìgá mímu?
15 Máa lo àwọn ohun èlò ìwádìí. A gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ká tó lè fi wọ́n sílò. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè má rí ohun tó burú nínú kéèyàn máa mu sìgá, kó sì máa rò ó pé: ‘Bíbélì ò sọ pé kéèyàn má mu sìgá, báwo la ṣe wá mọ̀ pé ìwà yẹn ò dáa?’ Báwo lo ṣe lè jẹ́ kó mọ àwọn ìlànà Bíbélì táá jẹ́ kó rí i pé ìwà náà ò dáa, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè fi àwọn ìlànà náà sílò? Ọ̀kan lára irinṣẹ́ tó gbéṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ṣe ni Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. O lè ní kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ wo abẹ́ ìsọ̀rí náà “Sìgá.” Ó máa rí àpilẹ̀kọ kan níbẹ̀ tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?” (Nínú Ilé Ìṣọ́, June 1, 2014.) Tó bá ka àpilẹ̀kọ náà, àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló máa rí níbẹ̀?
16 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì márùn-ún tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. (1) A ò gbọ́dọ̀ di ẹrú fún ìwà tàbí àṣà burúkú tó lè gbẹ̀mí wa. (Róòmù 6:16) (2) A gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè pa wá lára. (2 Kọ́r. 7:1) (3) Jèhófà fẹ́ ká fi gbogbo ara wa sin òun. (Mát. 22:37) (4) A ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó máa pa àwọn míì lára. (Mát. 22:39; 1 Kọ́r. 10:24) (5) Jèhófà lè fún wa lókun ká lè ṣe ohun tó tọ́. (Fílí. 4:13) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ní pàtó pé ká má ṣe mu sìgá, àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀ lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ náà.
17. Báwo làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó dáa tí wọ́n bá ń múra ìgbéyàwó wọn?
17 Báwo làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó dáa tí wọ́n bá ń múra ìgbéyàwó wọn? Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ran àwọn náà lọ́wọ́. Lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ìgbéyàwó àti Àpèjẹ Ìgbéyàwó” wọ́n máa rí àwọn ìlànà Bíbélì nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́fà tó lè ran àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́wọ́. (1) Gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà gbọ́dọ̀ bọlá fún Jèhófà. (1 Kọ́r. 10:31, 32) (2) Aṣọ tí wọ́n bá máa wọ̀ gbọ́dọ̀ bójú mu, kó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó má sì mú àwọn míì kọsẹ̀. (1 Tím. 2:9; 1 Pét. 3:3, 4) (3) Wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣekárími táyé Sátánì ń gbé lárugẹ. (Jòh. 17:14; Jém. 1:27; 1 Jòh. 2:15, 16) (4) Gbogbo nǹkan gbọ́dọ̀ lọ létòlétò. (1 Kọ́r. 14:40) (5) Tí wọ́n bá máa ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu, kò gbọ́dọ̀ di àríyá aláriwo táwọn èèyàn ti máa mutí yó kẹ́ri. (Gál. 5:21) (6) Ó yẹ kí wọ́n ní ẹni tó máa bojú tó bí gbogbo nǹkan ṣe máa lọ lọ́jọ́ náà.—Jòh. 2:8, 9.
18-19. (a) Ohun míì wo ni ètò Ọlọ́run ṣe tó lè ràn wá lọ́wọ́? (b) Àwọn ìlànà wo ló wà nínú ìwé yìí táá jẹ́ kó o lè pinnu irú ayẹyẹ tó yẹ kó o ṣe? (Wo àpótí náà “Ṣé O Mọ Ohun tí Jèhófà Fẹ́ Kó O Ṣe?”)
18 Ohun míì tí ètò Ọlọ́run ṣe tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ ni ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́. Wọ́n to àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sábẹ́ onírúurú àkòrí nínú ìwé yìí. Tó o bá mú àkòrí kan, wàá rí àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tò síbẹ̀ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ náà.
19 Bi àpẹẹrẹ, Kristẹni kan lè máa rò ó bóyá ó bójú mu kóun lọ síbi ayẹyẹ kan tàbí kò bójú mu. Tó bá lọ sábẹ́ àkòrí náà “Ayẹyẹ,” ó máa rí ìsọ̀rí náà “Àwọn ayẹyẹ táwa Kristẹni kì í ṣe.” Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n mẹ́nu kan lábẹ́ ìsọ̀rí yìí: “Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ táwọn ẹlẹ́sìn èké dá sílẹ̀? (1 Kọ́r. 10:21; 2 Kọ́r. 6:14-18; Éfé. 5:10, 11).” A máa rí àpẹẹrẹ irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ìsọ̀rí náà. Tá a bá ń ronú bóyá ó yẹ káwa Kristẹni máa bá wọn ṣe ayẹyẹ tí ìjọba fi ń rántí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe, a lè wo ìsọ̀rí náà “Ayẹyẹ orílẹ̀-èdè.” Níbẹ̀, a máa rí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń rántí àwọn ogun tí orílẹ̀-èdè ti jà, tàbí àwọn ayẹyẹ tí wọ́n fi ń júbà àwọn olókìkí èèyàn. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń lo ètò ẹ̀ láti pèsè àwọn irinṣẹ́ táá jẹ́ ká lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa!
RÍ I PÉ O KỌ́ Ẹ̀RÍ ỌKÀN Ẹ DÁADÁA
20. Báwo la ṣe máa mọ̀ pé a ti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
20 A mọyì ẹ̀bùn òmìnira tí Jèhófà fún wa. Àmọ́, a mọ̀ pé ká tó lè lo ẹ̀bùn òmìnira yìí dáadáa ó ṣe pàtàkì ká kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, àá lè ṣèpinnu tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu táá sì múnú ẹ̀ dùn. Ṣùgbọ́n ká tó lè ṣèyẹn, àfi kí ẹ̀mí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lẹ́mìí mímọ́, ká sì gbà kí ẹ̀mí yìí máa darí wa. Kò sí àní-àní pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa lo àwọn ẹ̀bùn yìí dáadáa, tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ agbára tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa mú káyé wa dáa sí i.—2 Tím. 3:16, 17; Héb. 4:12.
ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”