ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 May ojú ìwé 2-7
  • Kí Nìdí Táwọn Ìlànà Bíbélì Fi Ṣe Pàtàkì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Táwọn Ìlànà Bíbélì Fi Ṣe Pàtàkì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ?
  • KÍ NÌDÍ TÁWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ FI ṢE PÀTÀKÌ?
  • BÁ A ṢE LÈ MỌ ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ
  • PINNU PÉ WÀÁ MÁA FI ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ SÍLÒ LÁYÉ Ẹ
  • Bó O Ṣe Lè Fi Àwọn Ìlànà Bíbélì Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Máa Fi Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Tọ́ Ìṣísẹ̀ Ara Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Báwo Ni Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 May ojú ìwé 2-7

JULY 6-12, 2026

ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́

Kí Nìdí Táwọn Ìlànà Bíbélì Fi Ṣe Pàtàkì?

“Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run . . . kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín.”—RÓÒMÙ 12:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àá mọ ohun táwọn ìlànà Bíbélì túmọ̀ sí, àti bá a ṣè lè rí àwọn ìlànà yìí tá a bá ń ka Bíbélì.

1-2. (a) Ìgbà wo ni wọ́n ti kọ Bíbélì? (b) Kí nìdí tí Bíbélì ṣì fi wúlò títí dòní?

ỌJỌ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ọ́, wọ́n sì parí ẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. Síbẹ̀, àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ṣì wúlò títí dòní. (Héb. 4:12; 2 Tím. 3:16, 17) Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò lónìí ti jẹ́ káyé wọn dáa, kí wọ́n sì máa láyọ̀.

2 Àmọ́ báwo ni ìwé tí wọ́n ti kọ tipẹ́ yìí ṣe lè wúlò títí dòní? Ìdí pàtàkì méjì ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run alààyè,” tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa tó sì gbọ́n jù lọ ni Bíbélì ti wá. (1 Tím. 4:10; Róòmù 16:26, 27) Ìkejì, àwọn òótọ́ inú ẹ̀ kì í yí pa dà bó ti wù kó pẹ́ tó. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ ṣe àwọn èèyàn láǹfààní nígbà àtijọ́, ó sì ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní títí dòní láìka ipò yòówù kí wọ́n wà sí.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Kí ni ìlànà Bíbélì? Kí nìdí táwọn ìlànà yìí fi wúlò fún wa lónìí? Tá a bá ń ka Bíbélì, báwo la ṣe lè mọ àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀? A tún máa rí bí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ báwọn ìlànà Bíbélì ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn.

KÍ NI ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ?

4. Kí ni ìlànà Bíbélì?

4 Ìlànà Bíbélì ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tí òfin Ọlọ́run dá lé. Nígbà míì, ìlànà máa ń fara hàn kedere nínú òfin kan. (Mát. 22:37) Àmọ́, àwọn ìlànà Bíbélì wúlò ju àwọn òfin tó ṣe pàtó. Ó lójú ibi téèyàn ti lè lo àwọn òfin kan tó ṣe pàtó. Yàtọ̀ síyẹn, òfin lè wúlò láwọn àkókò kan kó má sì wúlò mọ́, ó sì lè jẹ́ pé torí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ni wọ́n ṣe gbé òfin kan kalẹ̀. Àmọ́, àwọn ìlànà Bíbélì máa ń jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Òótọ́ ni pé ó nídìí tí Jèhófà fi gbé àwọn òfin kan kalẹ̀, síbẹ̀ ìlànà ló jẹ́ ká mọ ìdí tí Jèhófà fi gbé àwọn òfin náà kalẹ̀. Onírúurú ipò tó yàtọ̀ síra la ti lè lo àwọn ìlànà tó wà nínú òfin Ọlọ́run, kò sì sígbà táwọn ìlànà yìí kì í ṣeni láǹfààní. (Sm. 119:111) Òfin lè yí pa dà, àmọ́ gbogbo ìgbà ni ìlànà máa ń wúlò.—Àìsá. 40:8.

5. Ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín òfin àti ìlànà. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Ká lè mọ ìyàtọ̀ tó wà nínú òfin àti ìlànà, ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ìyá kan lè sọ fún ọmọ ẹ̀ tó ṣì kéré pé, ‘Má fọwọ́ kan sítóòfù yẹn o.’ Òfin tàbí àṣẹ nìyẹn. Àmọ́ ìlànà tó wà nínú òfin yẹn ni pé, má fọwọ́ kan nǹkan tó gbóná kó má bàa jó ẹ. Kì í ṣe sítóòfù nìkan ni ìlànà yìí kàn, ó tún kan àwọn nǹkan míì tó máa ń gbóná bí áyọ́ọ̀nù ìlọṣọ, àtùpà, omi gbígbóná tàbí àwọn nǹkan míì tó lè jó ọmọ náà. Yàtọ̀ síyẹn kì í ṣe ìgbà tó bá wà nílé nìkan ni ìlànà yìí wúlò, ó tún máa wúlò fún un láwọn ibòmíì. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tí ọmọ náà bá dàgbà, ó ṣeé ṣe kó lo sítóòfù. Àmọ́ ó ṣì gbọ́dọ̀ kíyè sára kí sítóòfù náà má lọ jó o. Ẹ ò rí i pé òfin yẹn lè yí pa dà, àmọ́ ìlànà inú ẹ̀ ṣì dúró digbí.

Fọ́tò: Ìyá kan àtọmọ ẹ̀ jọ ń dáná. 1. Ó kìlọ̀ fún ọmọ náà pé kó má fọwọ́ kan sítóòfù tí wọ́n fi ń dáná. 2. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, òun àti ọmọ ẹ̀ jọ ń dáná, ọmọ náà sì ń lo sítóòfù náà.

Òfin lè yí pa dà, àmọ́ ìlànà inú ẹ̀ ṣì dúró digbí (Wo ìpínrọ̀ 5)


KÍ NÌDÍ TÁWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ FI ṢE PÀTÀKÌ?

6. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún wa nínú Bíbélì? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe buyì kún wa?

6 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó fún wa láwọn òfin pàtó kan ká má bàa kó sínú ewu. (Jém. 2:11) Yàtọ̀ síyẹn, ó ń jẹ́ ká mọ ìlànà tó wà nínú àwọn òfin náà. Bákan náà nínú Bíbélì, ó fún wa láwọn ìtọ́sọ́nà táá jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́ nígbà tí kò bá sí òfin pàtó kan tó dá lórí ohun tá a fẹ́ ṣe. Àwọn ìlànà inú Bíbélì máa ń jẹ́ ká lè máa ṣohun tó tọ́, ká sì lé máa ṣèpinnu tó dáa. Bí Jèhófà ò ṣe fún wa ní òfin lórí gbogbo nǹkan jẹ́ ká rí i pé ó buyì kún wa, ìyẹn ní pé ó fún wa lómìnira láti ṣe àwọn ìpinnu tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì mọyì àwọn ìlànà ẹ̀.—Gál. 5:13.

7. Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká mọ bí ìlànà Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Ká lè mọ bí ìlànà Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Oríṣiríṣi àmì ló máa ń wà lójú ọ̀nà táwọn awakọ̀ ń gbà. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé tí awakọ̀ bá rú òfin inú àmì yẹn, ìjọba máa fìyà jẹ ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tí awakọ̀ bá sáré níbi tí kò ti yẹ kó sáré tàbí tó gba ọ̀nà tí kò yẹ kó gbà. Àmọ́ àwọn àmì míì wà tó kàn ń jẹ́ kí awakọ̀ mọ ewu tó wà lójú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, àmì náà lè jẹ́ kí awakọ̀ mọ̀ pé kòtò ńlá wà lọ́nà. Tí awakọ̀ tó gbọ́n bá rí àmì tó fi hàn pé ewu wà lọ́nà, ṣe ló máa kíyè sára, kó má bàa kó sínú ewu. Bí àpẹẹrẹ tí òjò bá ń rọ̀, ṣe nirú awakọ̀ bẹ́ẹ̀ a rọra máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́. Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni máa ń yẹra fún ohunkóhun tí Bíbélì bá dìídì sọ pé kò dáa. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o, a tún máa ń ṣọ́ra fún àwọn èrò tàbí ìwà tó lè mú ká rú òfin Ọlọ́run. Ká sì tó lè ṣe gbogbo èyí àfi ká mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú.

Ọkọ̀ kan ń rìn lójú ọ̀nà tó léwu lálẹ́. Iná ẹ̀ sì tàn sáwọn àmì tó wà lójú ọ̀nà.

Ọ̀pọ̀ àwọn àmì ojú ọ̀nà máa ń jẹ́ káwọn awakọ̀ mọ ewu tó yẹ kí wọ́n ṣọ́ra fún. Ohun tí ìlànà Bíbélì máa ń ṣe fún wa náà nìyẹn (Wo ìpínrọ̀ 7)


8. Bí Róòmù 12:1, 2 ṣe sọ, tá a bá ń yẹ àwọn ìlànà Bíbélì wò, kí nìyẹn máa jẹ́ ká lè ṣe?

8 Àwọn àǹfààní míì wà tá a máa rí tá a bá ń yẹ àwọn ìlànà Bíbélì wò tá a sì ń fi wọ́n sílò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà yẹn máa ń jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan kan. Tá a bá ń ka Bíbélì, a máa ń ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú ẹ̀. A máa ń ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ náà wà nínú Bíbélì àti bá a ṣe lè fàwọn ẹ̀kọ́ náà sílò láyé wa. Ìyẹn sì ń jẹ́ ká lo “agbára ìrònú” wa láti máa ṣohun tí Jèhófà fẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ṣàwárí fúnra wa “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Ka Róòmù 12:1, 2.a

9. Àǹfààní wo la tún máa rí tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò? (Hébérù 5:13, 14)

9 Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, á jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wa. Tó bá jẹ́ àwọn ìlànà Bíbélì ló ń darí wa, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Ka Hébérù 5:13, 14.) Àwọn òbí máa ń fún àwọn ọmọ wọn kékeré ní òfin rẹpẹtẹ kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbà. Àwọn ọmọ náà sì sábà máa ń pa àwọn òfin yìí mọ́ torí wọ́n mọ̀ pé táwọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn á jìyà. Àmọ́ ṣé ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwa náà nìyẹn? Rárá o, kò fún wa lófin jànràn-janran bíi pé ọmọdé ni wá. Ó fọkàn tán wa, ó sì gbà pé a máa ṣe ìpinnu tó tọ́, tó sì bá ìfẹ́ ẹ̀ mu. Tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà máa ń dùn gan-an.—Sm. 147:11; Òwe 23:15, 26; 27:11.

BÁ A ṢE LÈ MỌ ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ

10. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tí òfin Ọlọ́run dá lé?

10 Tá a bá ń ka Bíbélì, ó yẹ ká máa wá àwọn ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ kan. Ó tún yẹ ká máa ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi fún wa láwọn òfin kan, ìyẹn á jẹ́ ká rí ìlànà tó wà nínú òfin náà. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń lóye ìdí tí Jèhófà fi fún wa láwọn òfin kan, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Àmọ́ ká tó lè lóye èrò Jèhófà, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká sì máa ronú jinlẹ̀ dáadáa. (Òwe 2:10-12) A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa lófin yìí? Tí Jèhófà bá kórìíra ìwà kan, ojú wo lá fi máa wo àwọn ìwà míì tó fara jọ ọ́? Ẹ̀kọ́ wo ni mo kọ́ nínú Bíbélì tí mo kà yìí, báwo sì ni mo ṣe lè fi sílò láyé mi?’ Tá a bá ti lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fún wa láwọn òfin kan nínú Bíbélì àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa, àá lè ṣèpinnu tó dáa, tó sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

11. Kí ni Jésù ṣe nínú Ìwàásù Orí Òkè tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò. Nínú àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan, Jésù kọ́kọ́ mẹ́nu kan ohun tí òfin sọ. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé èrò Ọlọ́run, ìyẹn ìlànà tí òfin náà dá lé. Bá a ṣe ń ronú nípa ohun tí Jésù sọ, àá rí bí àwọn ìlànà náà ṣe wúlò lónìí. Bákan náà, àá rí bá a ṣe lè fi wọ́n sílò àti àǹfààní tó máa ṣe wá.

Jésù jókòó sábẹ́ igi, ó sì ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀.

Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù ṣàlàyé bá a ṣe lè mọ ìlànà Bíbélì tó wà nínú òfin kan (Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Ìlànà wo ló wà nínú òfin tó wà ní Mátíù 5:21, 22? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Ka Mátíù 5:21, 22. “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.” Ìlànà wo ló wà nínú òfin yìí? Jèhófà ò fẹ́ ká kórìíra àwọn èèyàn. Kò fẹ́ ká ṣe ohun tí ò dáa tàbí sọ ohun tí ò dáa sí wọn, kódà kò fẹ́ ká máa ro èrò tí ò dáa nípa wọn. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé tí ẹnì kan ò bá tiẹ̀ pààyàn, ó ṣì lè jẹ̀bí níwájú Ọlọ́run tó bá kórìíra arákùnrin ẹ̀. Ó sọ pé “ẹni tí kò bá yéé bínú sí arákùnrin rẹ̀” tàbí tó sọ̀rọ̀ burúkú sí i máa “jíhìn.” Ìdí ni pé ìkórìíra ló máa ń sọni di apààyàn.—1 Jòh. 3:15.

13. Báwo la ṣe lè fi ìlànà inú Mátíù 5:21, 22 sílò láyé wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Mátíù 5:21, 22 sílò lónìí? Kò yẹ ká máa di àwọn èèyàn sínú kódà tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. (Léf. 19:18; Jóòbù 36:13) Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá di ẹnì kan sínú, àá bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra ẹ̀, ìyẹn sì lè mú ká sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tí ò dáa sí i. (Òwe 10:12) Bí àpẹẹrẹ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfófó tàbí ká máa fi ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́ bà á lórúkọ jẹ́ káwọn míì lè máa fojú burúkú wò ó. (Òwe 20:19; 25:23) Àbí ẹ ò rí nǹkan, kódà kí fóònù, Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ìkànnì àjọlò tó wà, Jésù ti fún wa ní ìlànà tó jẹ́ káwa Kristẹni mọ̀ pé kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa àwọn míì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ibi yòówù ká wà ì báà jẹ́ lójúkojú tàbí lórí ìkànnì, kò yẹ ká máa sọ ohun tí ò dáa nípa àwọn ẹlòmíì torí ìyẹn lè mú káwọn èèyàn kórìíra wọn.

Fọ́tò: 1. Ìlànà Bíbélì náà: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.” 2. Àwọn arábìnrin méjì ń ṣòfófó, ohun tí wọ́n sì ń sọ ò bá arábìnrin mí ì lára mu.

(Wo ìpínrọ̀ 12-13)


14. Ìlànà wo ló wà nínú òfin tó wà ní Mátíù 5:27, 28? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ka Mátíù 5:27, 28. “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.” Ìlànà wo ló wà nínú òfin yìí? Kì í ṣe ìṣekúṣe nìkan ni Jèhófà kórìíra, ó tún kórìíra èròkerò tó lè mú kéèyàn ṣèṣekúṣe. Jésù ṣàlàyé pé tí ọkùnrin kan tó ti níyàwó bá tẹjú mọ́ obìnrin tí kì í ṣe ìyàwó ẹ̀ lọ́nà táá fi wù ú pé kó bá a ṣe ìṣekúṣe, ó ti ṣẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti gbé èròkerò kúrò lọ́kàn bí ò tiẹ̀ rọrùn. (Mát. 5:29, 30) Ìlànà yìí náà kan àwọn Kristẹni tí ò tíì ṣègbéyàwó.

15. Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Mátíù 5:27, 28 sílò lónìí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Mátíù 5:27, 28 sílò lónìí? Kò yẹ ká máa ronú nípa ìṣekúṣe. (2 Sám. 11:2-4; Jóòbù 31:1-3) Torí náà, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo onírúurú àwòrán ìṣekúṣe. Kò yẹ kẹ́nì kan ronú pé ‘ṣebí mo kàn ń wò ó ni, mi ò kúkú ṣe é.’ Kò sì yẹ kó ronú pé irú àwòrán àti fídíò ìṣekúṣe tóun ń wò kò fi bẹ́ẹ̀ burú torí pé wọn ò ṣèṣekúṣe nínú ẹ̀ ní tààràtà. Ká má gbàgbé pé nígbà ayé Jésù kò sí ẹ̀rọ ìgbàlódé, fíìmù, tàbí àwòrán. Síbẹ̀, ìlànà tí Jésù ṣàlàyé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà ò ní dùn tẹ́nì kan bá ń wo àwòrán tàbí fídíò ìṣekúṣe lórí fóònù àtàwọn ẹ̀rọ míì. Bákan náà, ó tún jẹ́ ká rí i pé inú ẹ̀ kì í dùn sí ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù lónìí irú bíi kí wọ́n máa fi àwòrán àti fídíò ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kí wọ́n máa fọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàkùrọ̀sọ lórí fóònù. Ìlànà Bíbélì yìí máa ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. (Mál. 2:15) Á sì ran gbogbo àwa Kristẹni lọ́wọ́ Ká lè yẹra fún ohun tó lè mú kéèyàn ṣèṣekúṣe bóyá a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣe.—Òwe 5:3-14.

Fọ́tò: 1. Ìlànà Bíbélì náà: “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.” 2. Arákùnrin kan ń yọ ìkànnì àjọlò kan kúrò lórí fóònù ẹ̀.

(Wo ìpínrọ̀ 14-15)


16. Ìlànà wo ló wà nínú òfin tó wà ní Mátíù 5:43, 44? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ka Mátíù 5:43, 44. “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ.” Ìlànà wo ló wà nínú òfin yìí? Jèhófà fẹ́ ká ka gbogbo èèyàn sí ọmọnìkejì wa, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó dunni pé nígbà ayé Jésù, àwọn Júù ṣi òfin yẹn lóye. Wọ́n ronú pé àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn nìkan ló yẹ káwọn nífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì kórìíra àwọn èèyàn tó kù. Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ohun tí òfin yẹn dá lé kọ́ nìyẹn. Ó mọ̀ pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ó sì fẹ́ ká ka gbogbo èèyàn sí ọmọnìkejì wa láìka ìlú ìbílẹ̀ wọn, àṣà wọn tàbí àwọ̀ wọn sí.—Mát. 5:45-48.

17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá fi ìlànà inú Mátíù 5:43, 44 sílò láyé wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Mátíù 5:43, 44 sílò lónìí? Ìlànà yìí máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, kò sì ní jẹ́ ká lọ́wọ́ sí ogun àti rògbòdìyàn tó ń lọ nínú ayé. (Àìsá. 2:4; Míkà 4:3) Bákan náà, á jẹ́ ká máa hùwà dáadáa sáwọn tí ìlú àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa, títí kan àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì. (Ìṣe 10:34, 35) Kò tán síbẹ̀ o, á tún jẹ́ ká máa dárí ji àwọn tó bá hùwà burúkú sí àwa tàbí àwọn èèyàn wa.—Mát. 18:21, 22; Máàkù 11:25; Lúùkù 17:3, 4.

Fọ́tò: 1. Ìlànà Bíbélì náà: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ.” 2. Tọkọtaya kan ń wàásù nínú ọjà, wọ́n sì fún ọkùnrin kan tó wá láti ẹ̀yà mí ì ní ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!”

(Wo ìpínrọ̀ 16-17)


PINNU PÉ WÀÁ MÁA FI ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ SÍLÒ LÁYÉ Ẹ

18. (a) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà pọ́n wa lé, kò sì fún wa lófin jànràn-janran bíi pé ọmọdé ni wá! Ó fẹ́ ká máa ronú nípa àwọn ìlànà Bíbélì, ká sì jẹ́ kó máa darí wa bá a ṣe ń ṣèpinnu lójoojúmọ́. (1 Kọ́r. 14:20) Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá “máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfé. 5:17) Ìdí tá a fi ń ṣe ìpinnu tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu ni pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn, kì í ṣe torí kó má bàa fìyà jẹ wá. Yàtọ̀ sáwọn ìlànà Bíbélì, Jèhófà tún fún wa lẹ́bùn pàtàkì kan táá jẹ́ ká lè máa ṣe ìpinnu tó bá ìfẹ́ ẹ̀ mu, ìyẹn sì ni ẹ̀rí ọkàn wa. A máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni ìlànà Bíbélì?

  • Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú òfin àti ìlànà?

  • Àwọn ìlànà wo ni Jésù kọ́ àwọn èèyàn nínú Ìwàásù Orí Òkè?

ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

a Ọ̀pọ̀ ìgbà làwa Kristẹni máa ń ṣèpinnu lórí àwọn nǹkan tí Bíbélì ò fún wa ní òfin tó ṣe pàtó. Bọ́rọ̀ bá bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlànà Bíbélì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ká sì wo èyí tó bá ipò wa mu, ìyẹn á jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó dáa. Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè ronú fúnra wa. A lè lo agbára ìrònú yìí láti ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn, ká sì rí ìbùkún rẹ̀. Àyípadà yìí ò rọrùn fáwọn Júù tó di Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní torí pé ọ̀pọ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbé kalẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ lé ṣáájú àkókò yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́