ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 February ojú ìwé 14-19
  • Má Ṣe Fi Ìrìbọmi Falẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Fi Ìrìbọmi Falẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÍ KÌ Í JẸ́ KÁWỌN KAN FẸ́ ṢÈRÌBỌMI
  • MÁA RÁNTÍ PÉ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ
  • ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ TÓ O BÁ ṢÈRÌBỌMI LÁÌJÁFARA
  • Ohun Tí Ìrìbọmi Jẹ́ àti Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ya Ara Ẹ Sí Mímọ́ fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • “Máa Tẹ̀ Lé” Jésù, Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 February ojú ìwé 14-19

APRIL 20-26, 2026

ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Má Ṣe Fi Ìrìbọmi Falẹ̀

“Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà.”—2 KỌ́R. 6:2.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àkókò yìí gan-an ló yẹ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì ṣèrìbọmi.

1. (a) Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ṣèrìbọmi? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

ṢÉ O ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó o sì ti ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé o ti gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn rere lójú Ọlọ́run. (1 Pét. 3:21) Ohun tó o ṣe yìí máa ran àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ níjọ ẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi. Torí náà, ìpinnu tó dáa gan-an lo ṣe yẹn! Àmọ́, tó bá jẹ́ pé o ò tíì ṣèrìbọmi ńkọ́? Kò sí àní-àní pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ máa ṣe ohun tó fẹ́. O mọ̀ pé kí Jèhófà tó lè dárí jì ẹ́, kó sì tẹ́wọ́ gbà ẹ́, o gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:38-40) Síbẹ̀, o lè máa ṣiyèméjì bóyá kó o ṣèrìbọmi tàbí kó o má ṣe é. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa (1) ohun tí kì í jẹ́ káwọn kan fẹ́ ṣèrìbọmi, (2) ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa rántí pé òpin ti sún mọ́lé, àti (3) àǹfààní tó o máa rí tó o bá ṣèrìbọmi láìjáfara.

OHUN TÍ KÌ Í JẸ́ KÁWỌN KAN FẸ́ ṢÈRÌBỌMI

2. Kí ni kì í jẹ́ káwọn kan fẹ́ ṣèrìbọmi?

2 Ohun tí kì í jẹ́ káwọn kan fẹ́ ṣèrìbọmi ni pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wù wọ́n láti ṣèfẹ́ Jèhófà, ẹ̀rù ń bà wọ́n pé àwọn ò ní lè ṣe ohun táá múnú ẹ̀ dùn. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ nìyẹn, á dáa kó o gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan yẹ̀ wò táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò retí pé kó o máa ṣe nǹkan lọ́nà tó pé, inú ẹ̀ sì máa ń dùn tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tágbára ẹ gbé lò ń ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. (Sm. 103:13, 14; Kól. 3:23) Tẹ́rù bá sì ń bà ẹ́ pé àwọn èèyàn máa ta kò ẹ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà kó o lè ṣe bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”—Sm. 118:6.

3. Kí làwọn kan máa ń rò tí kì í jẹ́ kí wọ́n ṣèrìbọmi? (Tún wo àwòrán.)

3 Àwọn kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ wọn ò ṣèrìbọmi torí wọ́n rò pé àwọn ò ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa Jèhófà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ṣé ó dìgbà tí ìmọ̀ ẹ bá pọ̀ gan-an kó o tó lè ṣèrìbọmi? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan nínú Bíbélì. Lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé nínú ẹ̀wọ̀n tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà wà, àwọn méjèèjì wàásù fún ọkùnrin tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà àti ìdílé ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà àti ìdílé ẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run ló ṣiṣẹ́ ìyanu tó mú kí ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà ṣí. Bákan náà, wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà lóru ọjọ́ yẹn. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí wọ́n “ṣèrìbọmi láìjáfara.” (Ìṣe 16:25-33) Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tó o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ dénú, tó o mọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, tó o ti ronú pìwà dà, tó o sì ti ṣe tán láti máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run, á jẹ́ pé o lè ṣèrìbọmi.—Máàkù 12:30.

Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń wàásù fún ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan àti ìdílé ẹ̀. Gbogbo wọn sì tẹ́tí sílẹ̀.

Pọ́ọ̀lù àti Sílà wàásù fún ọkùnrin tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ìdílé ẹ̀, wọ́n sì “ṣèrìbọmi láìjáfara” (Wo ìpínrọ̀ 3)


4. Kí ni kì í jẹ́ káwọn kan ṣe ìyípadà tó yẹ kí wọ́n lè ṣèrìbọmi? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Ó wu àwọn kan láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àmọ́ wọ́n ń rò ó pé ó máa nira láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Ká sòótọ́, kéèyàn tó ṣe ìpinnu kan, ó yẹ kó rò ó dáadáa. (Lúùkù 14:27-30) Àwọn míì ní tiwọn máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tí wọ́n máa fi sílẹ̀ kí wọ́n lè sin Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Candace. Nígbà tó wà ní kékeré, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àmọ́ kò fi ohun tó kọ́ sílò. Nígbà tó dàgbà, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà ló yẹ kí n máa fayé mi sìn, àmọ́ àwọn nǹkan tí mò ń gbádùn nínú ayé ò jẹ́ kó rọrùn fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, mo mọ̀ pé ó máa nira láti fi àwọn nǹkan tí mò ń ṣe yẹn sílẹ̀.” Àwọn míì ò fẹ́ ṣèrìbọmi torí wọ́n rò pé kò ní rọrùn fáwọn láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Ẹ̀rù máa ń bà wọ́n pé táwọn bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn táwọn ṣèrìbọmi, wọ́n máa mú àwọn kúrò nínú ìjọ. Tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí ni ò jẹ́ kíwọ náà ṣèrìbọmi, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Arábìnrin kan ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí arábìnrin yẹn ṣe ń sọ̀rọ̀, obìnrin yẹn ń fojú inú wò ó pé òun ń mutí, òun sì ń jó pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ òun nílé ìgbafẹ́.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kò rọrùn fún wọn láti ṣe àwọn àyípadà kan kí wọ́n lè sin Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, kí ló yẹ kó o máa ronú nípa ẹ̀? (Mátíù 13:44-46)

5 Tá a bá fẹ́ ra nǹkan, kì í ṣe iye tí nǹkan náà máa ná wa nìkan la máa wò, a tún máa wo àǹfààní tó máa ṣe wá. Tá a bá rí i pé àǹfààní tó máa ṣe wá pọ̀ ju iye tó máa ná wa lọ, ó ṣeé ṣe ká rà á lójú ẹsẹ̀. Bákan náà, tá a bá ń ronú nípa ìrìbọmi, kì í ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ fi sílẹ̀ nìkan ló yẹ ká máa rò, ó tún yẹ ká máa ronú nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Jésù sọ àpèjúwe méjì tó jẹ́ kọ́rọ̀ yìí túbọ̀ yé wa. (Ka Mátíù 13:44-46.) Nínú àpèjúwe kọ̀ọ̀kan, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tí inú ẹ̀ dùn láti ta gbogbo nǹkan ìní ẹ̀ kó lè ra ohun iyebíye kan tó rí. Ìwọ náà ti rí ohun iyebíye kan, ìyẹn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Tó bá ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kó o lè ṣèrìbọmi, á dáa kó o ronú nípa àpèjúwe méjèèjì tí Jésù sọ. O lè bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ó dá mi lójú pé òtítọ́ tí mo mọ̀ yìí ṣeyebíye gan-an? Ṣé mo mọyì àǹfààní ńlá tí mo ní láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Ṣé mo sì mọyì ìrètí tí mo ní àti báwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe nífẹ̀ẹ́ mi?’ Bó o bá ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi àti ohun tó o lè ṣe.

6. Kí ló máa jẹ́ ká lè fi ohun tá à ń kọ́ sílò?

6 Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn lè mú kó ṣòro fún wọn láti tẹ̀ síwájú. Àmọ́, ó tún sọ pé àwọn kan máa fi “ọkàn tó tọ́, tó sì dáa” gba ìhìn rere Ìjọba náà. (Lúùkù 8:5-15) Tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ò sí nínú ohun tó ò ń kọ́, má jẹ́ kó sú ẹ. Jèhófà máa jẹ́ kó o “ní ọkàn tuntun,” táá jẹ́ kó o lè fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ò ń kọ́ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn kó o lè ṣe ohun tó yẹ.—Ìsík. 18:31; 36:26.

7-8. Kí nìdí táwọn ọ̀dọ́ kan ò fi tẹ̀ síwájú kí wọ́n lè ṣèrìbọmi? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Àwọn ọ̀dọ́ kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ wọn ò ṣèrìbọmi torí ohun táwọn míì fẹ́ kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùkọ́ kan máa ń sọ fáwọn ọmọléèwé pé kí wọ́n lọ́wọ́ sáwọn nǹkan kan. Nígbà míì sì rèé, àwọn nǹkan náà lè má múnú Ọlọ́run dùn. Irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè kó ẹ sí wàhálà. (Sm. 1:1, 2; Òwe 7:1-5) Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, á dáa kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onísáàmù tó sọ fún Jèhófà pé: “Mo ní òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi, nítorí pé mò ń ronú lórí àwọn ìránnilétí rẹ.”—Sm. 119:99.

8 Àwọn nǹkan tá à ń gbọ́ fi hàn pé àwọn òbí kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jẹ́ káwọn ọmọ wọn tètè ṣèrìbọmi. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ lè máa rọ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n kàwé dójú àmì kí wọ́n lè níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Ó sì lè jẹ́ pé wọn ò ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àfojúsùn táá jẹ́ kó wù wọ́n láti ṣèrìbọmi. Ṣé o rò pé àwọn nǹkan míì wà táwọn òbí ẹ lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o ò ṣe bá wọn sọ ọ́? Máa rántí pé bó o tiẹ̀ kéré lọ́jọ́ orí, o ṣì lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà.—Òwe 20:11.

Ọ̀dọ́kùnrin kan tọ́ka sí ẹ̀kọ́ 23 nínú ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” nígbà tó ń bá àwọn òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀.

Bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ tó bá wù ẹ́ láti ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Kí ni kì í jẹ́ káwọn kan fẹ́ tètè ṣèrìbọmi?

9 Àwọn kan tó kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi kì í fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ dúró káwọn àti ọ̀rẹ́ wọn tàbí ẹnì kan nínú ìdílé wọn lè jọ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà. Ká sòótọ́, kò sóhun tó burú níbẹ̀ tíwọ àtàwọn tá a sọ yìí bá jọ ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà. Àmọ́, ṣé ó yẹ kó o jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi? Má gbàgbé pé Jèhófà lo ya ara ẹ sí mímọ́ fún, àárín ẹ̀yin méjèèjì nìyẹn sì wà. Torí náà, kò yẹ kó o jẹ́ kí ohun tí ẹlòmíì ń ṣe pinnu ìgbà tó o máa ṣèrìbọmi.—Róòmù 14:12.

MÁA RÁNTÍ PÉ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ

10. Kí nìdí táwọn kan kì í fẹ́ tètè ṣe àtúnṣe tó yẹ kí wọ́n lè ṣèrìbọmi?

10 Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tá a ti sọ lókè yìí, àwọn kan kì í tètè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kí wọ́n lè ṣèrìbọmi torí wọ́n ronú pé ó ṣì máa pẹ́ kí òpin tó dé. Àmọ́ ṣé èrò tó dáa nìyẹn? Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.”—Lúùkù 12:40.

11. Bá a ṣe ń mọ Jèhófà sí i, kí ni Sáàmù 119:60 sọ pé àá máa ṣe sáwọn àṣẹ ẹ̀?

11 Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló yẹ kó mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún un. Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ìyẹn á sì jẹ́ kó máa yá wa lára láti pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́ láìjáfara. (Ka Sáàmù 119:60.) Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ láìfi falẹ̀. Ohun tó sọ jẹ́ ká mọ̀ pé òní la rí, kò sẹ́ni tó mọ̀la. Torí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ ká “ṣe ohun tó tọ́,” tó sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, torí kò sẹ́ni tó mọ ilẹ̀ tó máa mọ́ lọ́la.—Jém. 4:13-17.

12. Kí la kọ́ nínú àpèjúwe ọgbà àjàrà tí Jésù sọ?

12 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe ọgbà àjàrà tí Jésù sọ. Àwọn kan lè ronú pé ṣebí iye kan náà làwọn tó ṣiṣẹ́ wákátì kan àtàwọn tó ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ gbà bí Jésù ṣe sọ. Òótọ́ ni. Àmọ́, kí nìdí táwọn tó ṣiṣẹ́ wákàtí kan yẹn ò fi tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́? Wọ́n sọ pé: “Torí kò sẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ ni.” Torí náà, kì í ṣe pé wọ́n ya ọ̀lẹ, wọn ò kàn rẹ́ni gbà wọ́n síṣẹ́ ni. Ṣùgbọ́n, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n pè wọ́n síṣẹ́ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. (Mát. 20:1-16) Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn, Jésù ti pè wá pé ká wá di ọmọlẹ́yìn òun, ká sì máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ ká ṣe ohun tí Jésù sọ láìjáfara.

13. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aya Lọ́ọ̀tì?

13 Àwọn kan lè máa fi nǹkan falẹ̀ torí wọ́n gbà pé àwọn máa ṣe ìyípadà tó yẹ tó bá ku díẹ̀ kí òpin dé. Àmọ́, bí wọ́n bá ṣe ń fi nǹkan falẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa nira láti ṣe àwọn ìyípadà yẹn. Ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé ìjáfara léwu. Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:31-35) Aya Lọ́ọ̀tì mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó pa Sódómù àti Gòmórà run; àmọ́ ọkàn ẹ̀ ò kúrò nínú àwọn nǹkan ìní tó fi sílẹ̀. (Jẹ́n. 19:23-26) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí í rán wa létí pé Jèhófà ti ní àkókò pàtó tó fún àwọn èèyàn dà láti ṣe ìyípadà, kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Tí àkókò yìí bá sì pé, Jèhófà máa ti ilẹ̀kùn ìgbàlà náà, kò sì sẹ́ni tó máa lè ṣí i mọ́.—Lúùkù 13:24, 25.

14. Bó o ṣe ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ń ṣẹ, kí ló yẹ kó o ṣe?

14 Kárí ayé, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ jẹ́ ká rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ti ń ṣẹ. Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé àwọn kan nínú wọn ò tíì máa ṣẹlẹ̀ lágbègbè ẹ, bó o ṣe ń rí i tí wọ́n ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibòmíì yẹ kó sún ẹ láti tètè gbé ìgbésẹ̀ kó o lè ṣèrìbọmi. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “wà lójúfò,” tàbí “kí [wọ́n] má sùn,” torí “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” (1 Pét. 4:7; àlàyé ìsàlẹ̀.) “Òpin” tó ń sọ nínú ẹsẹ yìí ni ìgbà tí wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì ẹ̀ run. Ibi táwọn Kristẹni tí Pétérù kọ̀wé sí ń gbé jìnnà sílùú Jerúsálẹ́mù, torí náà ìparun ìlú yẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ kàn wọ́n. (1 Pét. 1:1) Àmọ́, bí wọ́n ṣe rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ míì tí Jèhófà sọ máa ṣẹ. Lọ́nà kan náà, ìwọ náà ń rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ṣe ń ṣẹ lónìí. Torí náà, jẹ́ káwọn nǹkan tó ò ń rí yìí mú kó o túbọ̀ wà lójúfò, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ṣèrìbọmi.

15. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà? (2 Pétérù 3:10-13)

15 Nínú lẹ́tà kejì tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pétérù láti kọ, ó sọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè múra sílẹ̀ de ìgbà tí Jèhófà máa pa ayé burúkú yìí run. Nígbà tí Pétérù kọ lẹ́tà yìí sáwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, òótọ́ ni pé ó ṣì máa pẹ́ kí òpin tó dé, síbẹ̀ ó sọ fún wọn pé kí wọ́n fi ọjọ́ náà “sọ́kàn dáadáa,” tàbí kí wọ́n jẹ́ kó máa “wù [wọ́n] gidigidi.” (Ka 2 Pétérù 3:10-13; àlàyé ìsàlẹ̀.) Àwa náà lè fi ọjọ́ náà sọ́kàn tá a bá ń múra sílẹ̀ tá a sì ń jẹ́ kó wù wá pé kí ọjọ́ náà dé. Tá a bá ń ‘hùwà mímọ́, tá a sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,’ ìyẹn á fi hàn pé lóòótọ́ ló ń wù wá pé kí ọjọ́ náà dé. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i tá à ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé à ń sin òun tọkàntọkàn! Torí náà, tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ TÓ O BÁ ṢÈRÌBỌMI LÁÌJÁFARA

16. Ìgbà wo ló dáa jù láti gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ kó o lè ṣèrìbọmi? (2 Kọ́ríńtì 6:1, 2) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ìgbà wo ló dáa jù láti gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ kó o lè ṣèrìbọmi? Ìsinsìnyí ni! (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:1, 2.) Ìwẹ̀fà ará Etiópíà tí Fílípì wàásù fún ò fọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá. Nígbà tó gbọ́ ìhìn rere, tó sì láǹfààní láti ṣèrìbọmi, kò sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ kí n ṣì kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ sí i, àá rí omi míì níwájú.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ fún Fílípì pé, “Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” (Ìṣe 8:26, 27, 35-39) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn! Lẹ́yìn tí ìwẹ̀fà náà ṣèrìbọmi, Bíbélì sọ pé, “ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn.”

Fọ́tò: 1. Ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà ń bọ̀ nínú omi nígbà tí Fílípì sọ pé kó wá ṣèrìbọmi. 2. Arábìnrin kan àti obìnrin tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tá a rí nínú àwòrán lẹ́ẹ̀kan ń bá àwọn alàgbà méjì sọ̀rọ̀ nípàdé, inú wọn sì ń dùn.

Á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ lára ìwẹ̀fà ará Etiópíà: Ìsinsìnyí ló dáa kó o gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 16)a


17. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?

17 Ṣé ohun kan wà tó ń dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Róòmù 2:4) Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ tàbí ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè, ó sì máa dúró tì ẹ́ táwọn míì ò bá tiẹ̀ jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti ṣèrìbọmi. Tó o bá ṣèrìbọmi, wàá ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wàá sì láyọ̀ bó o ṣe ń sin Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó o wá rí i pé ‘àwọn ohun tó o fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ ò já mọ́ nǹkan kan rárá. (Fílí. 3:8, 13) Wàá sì máa fojú sọ́nà fáwọn “ohun tó wà níwájú,” ìyẹn bí ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ tó sì ṣèrìbọmi ṣe máa ṣẹ.—Ìṣe 3:19.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni kì í jẹ́ káwọn kan fẹ́ ṣèrìbọmi?

  • Kí nìdí tí ò fi yẹ kó o fọ̀rọ̀ ìrìbọmi falẹ̀?

  • Ìgbà wo ló dáa jù láti gbé ìgbésẹ̀ táá jẹ́ kó o lè ṣèrìbọmi?

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Bíi ti ìwẹ̀fà ará Etiópíà tó sọ fún Fílípì pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi, ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ bá àwọn alàgbà pé ó wu òun láti ṣèrìbọmi.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́