ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 February ojú ìwé 8-13
  • Ohun Tí Ìrìbọmi Jẹ́ àti Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Ìrìbọmi Jẹ́ àti Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌRÌBỌMI?
  • ÀWỌN NǸKAN TÁ A MÁA Ń ṢE NÍGBÀ ÌRÌBỌMI
  • “NÍ ORÚKỌ BABA ÀTI TI ỌMỌ ÀTI TI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́”
  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kó o Ṣe Batisí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 February ojú ìwé 8-13

APRIL 13-19, 2026

ORIN 52 Ìyàsímímọ́ Kristẹni

Ohun Tí Ìrìbọmi Jẹ́ àti Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì

“Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”—MÁT. 28:19.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa mọ ohun tí ìrìbọmi jẹ́, ìdí tó fi ṣe pàtàkì àtàwọn nǹkan tá a máa ń ṣe nígbà ìrìbọmi.

1. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ni ìrìbọmi?

INÚ wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi! Ǹjẹ́ o mọ̀ pé bínú àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà ṣe dùn nìyẹn nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣèrìbọmi níbi ìpàdé àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K.? Níbi ìpàdé yẹn, wọ́n ṣàlàyé ohun tí ìrìbọmi jẹ́ àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì. (Ìṣe 2:38, 40, 41) Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi” wà lára “àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nípa Kristi.” (Héb. 6:1, 2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi wà lára ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ tá a kọ́kọ́ mọ̀, ó ṣe pàtàkì ká lóye ẹ̀ dáadáa. Kí nìdí?

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi?

2 Tí ìpìlẹ̀ ilé kan bá dáa, ilé náà máa dúró digbí. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì ká lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi, ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Gbogbo wa pátá ló yẹ ká mọ ìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì, bóyá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣèrìbọmi ni àbí ó ti pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni ìrìbọmi? Kí làwọn nǹkan tá a máa ń ṣe nígbà ìrìbọmi? Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká ṣèrìbọmi ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́?

KÍ NI ÌRÌBỌMI?

3. Kí ni ìrìbọmi tó o ṣe fi hàn?

3 Tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Jèhófà àti Jésù Kristi. Bákan náà, ó fi hàn pé o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ, o sì ti yí ìgbésí ayé ẹ pa dà kó o lè máa sin Jèhófà. Kò tán síbẹ̀ o, o gbà pé Jésù ni Jèhófà lò láti gbà wá là, o sì ti gbàdúrà pé wàá máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà nínú ètò ẹ̀. Ìlérí tó o ṣe yìí fi hàn pé o ti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ tó o sì ṣèrìbọmi, o ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ọ̀tun táá jẹ́ kó o ní ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn.

4. Tí wọ́n bá ri ẹnì kan bọmi pátápátá, kí nìyẹn fi hàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Tẹ́nì kan bá ṣèrìbọmi, wọ́n máa ri ẹni náà bọ inú omi pátápátá, wọ́n á sì gbé e jáde.a Ṣe ló dà bí ìgbà tẹ́ni náà kú, tá a sì jí i dìde. (Fi wé Kólósè 2:12.) Ìrìbọmi tó o ṣe fi hàn pé o ti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ? Ìdí ni pé tí wọ́n bá rì ẹ́ bọmi, ṣe ló fi hàn pé o ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Tí wọ́n bá gbé ẹ jáde nínú omi, ṣe ló fi hàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun kó o lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.

Fọ́tò: Ọkùnrin kan ṣèrìbọmi lẹ́yìn tó jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa tó ń hù tẹ́lẹ̀. 1. Inú ẹ̀ ń dùn bó ṣe ń wo àwọn tó ń ja ẹ̀ṣẹ́ nínú tẹlifíṣọ̀n. 2. Ó ń mu sìgá. 3. Ó ń mu ọtí lámujù. 4. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi.

Nígbà tó o ṣèrìbọmi, ṣe lo fi hàn pé o ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, o sì bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun kó o lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Báwo làwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe ká lè ṣèrìbọmi ṣe jọra pẹ̀lú iṣẹ́ tí Nóà ṣe nígbà tó kan ọkọ̀ áàkì? (1 Pétérù 3:18-21)

5 Ka 1 Pétérù 3:18-21. A lè fi àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kó o lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi wé iṣẹ́ tí Nóà ṣe nígbà tó kan ọkọ̀ áàkì. Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kà ẹ́ láyà, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé ìwọ náà fẹ́ kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò kan. Ṣé o rò pé ó pọn dandan kó o ṣe àwọn nǹkan yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, bọ́rọ̀ ṣe rí fún Nóà nìyẹn. Ọlọ́run ló sọ bí Nóà ṣe máa kan áàkì náà, ó sì pọn dandan kó ṣe é gẹ́lẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ kó lè gba ẹ̀mí là nígbà Àkúnya Omi. Nóà nígbàgbọ́, ó ṣègbọràn, Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ láti kan ọkọ̀ áàkì náà. Bíi ti Nóà, ìwọ náà lè ṣe “gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ” fún ẹ.—Jẹ́n. 6:22.

6. Báwo ni ìrìbọmi ṣe ń gbà wá là?

6 Ní ẹsẹ 21, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ìrìbọmi ń “gbà yín là.” Tí wọ́n bá ri ẹnì kan bọnú omi nígbà ìrìbọmi, ìyẹn ò sọ pé ẹni náà ti rí ìgbàlà tàbí pé wọ́n ti pa ẹ̀ṣẹ̀ ẹni náà rẹ́. Ó ṣe tán, ẹ̀jẹ̀ Jésù nìkan ló lè wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (1 Jòh. 1:7) Àmọ́, ìrìbọmi ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ máa ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ, òun náà la fi ń “bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ó dájú pé Jèhófà máa fún ẹ lóhun tó ò ń béèrè, á sì dárí jì ẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìrìbọmi ń “gbà [wá] là,” ìyẹn ni pé á jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun.

ÀWỌN NǸKAN TÁ A MÁA Ń ṢE NÍGBÀ ÌRÌBỌMI

7. Kí làwọn nǹkan tá a máa ń ṣe nígbà ìrìbọmi?

7 Yàtọ̀ sí pé ká ri ẹnì kan bọnú omi pátápátá, Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé àwọn nǹkan míì nípa bó ṣe yẹ ká ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó bójú mu tá a lè ṣe nírú àsìkò bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà Bíbélì kan wà tó jẹ́ káwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n múra, káwọn tó sì pé jọ mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe. (1 Kọ́r. 14:40; 1 Tím. 2:9) Lónìí, àwọn alàgbà ló sábà máa ń ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn, kò sì ní bójú mu ká máa gbé irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ gẹ̀gẹ̀. (1 Kọ́r. 1:14, 15) Inú Ọlọ́run máa dùn tí ẹnì kan bá ṣèrìbọmi, á sì tẹ́wọ́ gbà á, bóyá àwọn tó wà níbẹ̀ pọ̀ tàbí wọn ò pọ̀.—Ìṣe 8:36.

8. Àwọn ìbéèrè wo la máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi, kí sì nìdí? (Ìṣe 2:38-42) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká ‘kéde ìgbàgbọ́ wa ní gbangba kí a lè rí ìgbàlà.’ (Róòmù 10:9, 10; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “publicly declare” nínú nwtsty-E.) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì ká kéde ìgbàgbọ́ wa nígbà ìrìbọmi torí ó wà lára ohun tó máa jẹ́ ká rí ìgbàlà! Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ní ìbéèrè méjì kan. Ìbéèrè àkọ́kọ́ ni, “Ṣé o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ṣé o sì gbà pé Jésù Kristi ni Jèhófà lò láti gbà wá là?” Ìbéèrè yìí máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹni náà ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi, ó sì jọ ohun tí Pétérù sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní Pẹ́ńtíkọ́sì. Ìbéèrè kejì ni, “Ṣé o mọ̀ pé ìrìbọmi rẹ fi hàn pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ètò Ọlọ́run?” Ìbéèrè yìí máa ń rán wa létí pé tá a bá ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, tá a sì ń jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ńṣe là ń mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ. (Ka Ìṣe 2:38-42.) Àwọn tó bá dáhùn ìbéèrè méjèèjì yìí pé bẹ́ẹ̀ ni ló kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi.

Àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi tọ́jọ́ orí wọn yàtọ̀ síra dúró níbi àga tó wà níwájú nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan, wọ́n sì ń kéde ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba.

Nígbà ìrìbọmi, a máa ń ‘kéde ìgbàgbọ́ wa ní gbangba kí a lè rí ìgbàlà’ (Wo ìpínrọ̀ 8)d


9. Kí làwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí ojú rere Ọlọ́run?

9 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, o máa ń ṣe jẹ́jẹ́, o níwà ọmọlúàbí, o ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kankan. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí tó tọ́ ẹ dàgbà, wọ́n sì jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ṣé o rò pé ó ṣì yẹ kó o ronú pìwà dà, kó o sì ṣèrìbọmi kó o lè rí ojú rere Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni. Irú ẹni yòówù ká jẹ́ tẹ́lẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, ìyẹn ò sì jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 51:5) Àmọ́ nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó fẹ́ dípò ìfẹ́ ara wa. Lẹ́yìn ìyẹn, a ronú pìwà dà, a sì yí pa dà, ìyẹn ni pé a jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tí ò dáa tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ ká lè máa ṣe ohun tó ń múnú Baba wa ọ̀run dùn. Tá a bá ti ṣe àwọn nǹkan yìí, ìgbà yẹn la kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi.—Ìṣe 3:19.

10. Tó o bá ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

10 Tó o bá ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó ṣì yẹ kó o ṣèrìbọmi kó o lè di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà yẹn, o ò tíì mọ òtítọ́ nípa Jèhófà àti Jésù bó ṣe yẹ kó o mọ̀ ọ́n. Kódà tó o bá tiẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run tó o sì ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, ìlérí tó o ṣe nígbà yẹn lè má tọ̀nà torí pé o ò ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sí Éfésù, ó rí àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ti ṣèrìbọmi tẹ́lẹ̀ àmọ́ wọn ò ní ìmọ̀ tó péye nípa Jésù, torí náà ó ní kí wọ́n tún ìrìbọmi ṣe.b (Ìṣe 19:1-5) Bákan náà lónìí, kẹ́nì kan tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, kó sì máa ṣe ohun tó fẹ́.

“NÍ ORÚKỌ BABA ÀTI TI ỌMỌ ÀTI TI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́”

11. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká batisí ẹnì kan “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”? (Mátíù 28:18-20)

11 Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ batisí àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn òun “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Ka Mátíù 28:18-20.) Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “orúkọ,” ó sábà máa ń sọ nípa irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́. Ó tún lè túmọ̀ sí ipò tẹ́nì kan wà àti àṣẹ tó ní. Torí náà, tá a bá ṣe nǹkan kan “ní orúkọ” ẹnì kan tàbí ohun kan, a gbà pé ẹni náà ní àṣẹ, a sì fara mọ́ ipò tó wà. (Fi wé Mátíù 10:41; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “because he is a prophet” nínú nwtsty-E.) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ipò àti àṣẹ tí Baba àti Ọmọ ní, títí kan ipa tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń kó nígbèésí ayé wa.

12. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká batisí ní orúkọ Baba? (Ìfihàn 4:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Ní orúkọ Baba. A gbà pé Jèhófà ni Baba wa ọ̀run àtẹni tó jẹ́ ká wà láàyè. Òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, òun ló sì dá ohun gbogbo. (Ka Ìfihàn 4:11.) A gbà pé òun ló máa ń gbọ́ àdúrà, a máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ ẹ̀, a sì máa ń lo orúkọ náà tá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń sọ nípa ẹ̀ fáwọn èèyàn. (Sm. 65:2) Síbẹ̀, tẹ́nì kan bá fẹ́ batisí ní orúkọ Baba, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó yẹ kó ṣe. Pétérù sọ ohun tó yẹ ká ṣe nígbà tó ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ti mọ Jèhófà, ó sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà ni ẹni tó máa jẹ́ kí wọ́n rí ìyè nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Róòmù 5:8.

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tá a rí nínú àwòrán lẹ́ẹ̀kan ń gbàdúrà nínú ilé ẹ̀.

Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o fara mọ́ ipò àti àṣẹ Baba (Wo ìpínrọ̀ 12)


13. Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká batisí ní orúkọ Ọmọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Ní orúkọ Ọmọ. A gbà pé Jésù ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run. A tún gbà pé Jésù ni “ọ̀nà,” torí pé ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan la fi lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Jòh. 14:6) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù ló rà wá pa dà, ìyẹn ni pé ó kú nítorí wa ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun tá a mọ̀ nípa Jésù yìí máa ń jẹ́ kó wù wá láti fìwà jọ ọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kì í ṣe lọ́jọ́ tá a bá ṣèrìbọmi nìkan. (1 Jòh. 2:6) Torí náà, a máa ń fìtara wàásù bíi ti Jésù, a kì í sì í jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́. (Lúùkù 4:43) Kódà, a ṣe tán láti fara da inúnibíni torí pé à ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. (2 Tím. 3:12) Bákan náà, torí a gbà pé Jésù ni “orí ìjọ,” a máa ń ṣègbọràn sáwọn tó ń lò láti darí wa, tí wọ́n sì ń bójú tó wa.—Éfé. 4:8, 11, 12; 5:23.

Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tá a rí nínú àwòrán lẹ́ẹ̀kan ń ka Bíbélì fún ọkùnrin kan bó ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé.

Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o fara mọ́ ipò àti àṣẹ tí Ọmọ ní (Wo ìpínrọ̀ 13)


14. (a) Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Àwọn batisí míì wo làwọn ẹni àmì òróró máa ń ṣe? (Wo àpótí náà “Batisí Táwọn Ẹni Àmì Òróró Máa Ń Ṣe.”)

14 Ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́. A gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀mí mímọ́. Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan, kì í sì í ṣe ara Mẹ́talọ́kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. A gbà pé ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run lò láti darí àwọn wòlíì àtàwọn èèyàn tó kọ Bíbélì, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń kà á nígbà gbogbo, tá a sì máa ń fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò. (2 Pét. 1:20, 21) Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣọ́ra ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì torí pé ìyẹn lè mú kí ẹ̀mí Ọlọ́run fi wá sílẹ̀, kó má sì ṣiṣẹ́ nínú ìjọ mọ́.—Éfé. 4:30.

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tá a rí nínú àwòrán lẹ́ẹ̀kan ń ka Bíbélì nínú ilé.

Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o mọyì ipa tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń kó nígbèésí ayé wa (Wo ìpínrọ̀ 14)


Batisí Táwọn Ẹni Àmì Òróró Máa Ń Ṣe

Yàtọ̀ sí omi tá a fi batisí àwọn ẹni àmì òróró, àwọn batisí míì tún wà tí wọ́n máa ń ṣe.

  • A máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn nígbà tí Jèhófà bá yàn wọ́n pé wọ́n wà lára àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run. (Mát. 3:11)

  • Wọ́n “batisí sínú Kristi” ní ti pé wọ́n wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi débi tí Bíbélì fi pè wọ́n ní ara Kristi. (Gál. 3:27, 28; 1 Kọ́r. 12:27)

  • Wọ́n batisí sínú ikú Jésù ní ti pé wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù títí wọ́n fi máa parí iṣẹ́ ìsìn wọn láyé, tí Jèhófà sì máa jí wọn dìde sí ọ̀run. (Róòmù 6:3-5)

15. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?

15 Tó o bá ti ṣèrìbọmi, pinnu pé wàá túbọ̀ ṣèwádìí kó o lè lóye “ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi.”c Yàtọ̀ síyẹn, pinnu pé wàá mú ìlérí ẹ ṣẹ, ìyẹn ìlérí tó o ṣe nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó o sì ṣèrìbọmi. Àmọ́ tó ò bá tíì ṣèrìbọmi ńkọ́? Ṣé kì í ṣe pé ohun kan ló ń dí ẹ lọ́wọ́? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe kó o lè ṣèrìbọmi.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni ìrìbọmi táwa Kristẹni ṣe fi hàn?

  • Àwọn ìbéèrè wo la máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi, kí sì nìdí?

  • Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ká batisí ẹnì kan “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”?

ORIN 161 Inú Mi Ń Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ba’pti-sma, tá a tú sí “batisí,” túmọ̀ sí “ìrìbọmi.” Torí náà, tí wọ́n bá fẹ́ ṣèrìbọmi fẹ́nì kan, ṣe ni wọ́n máa ri ẹni náà bọnú omi pátápátá, kì í ṣe pé wọ́n máa wọ́n omi sẹ́ni náà lára báwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan ṣe máa ń ṣe.

b Àwọn ọkùnrin tó wà ní Éfésù sọ pé “ìrìbọmi Jòhánù” làwọn ṣe. (Ìṣe 19:3) Nígbà tí Jòhánù Onírìbọmi ń wàásù fáwọn Júù, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọn ò tẹ̀ lé Òfin Mósè, ó sì ṣèrìbọmi fáwọn tó ronú pìwà dà. (Máàkù 1:4, 5) Àmọ́ nígbà tí Òfin Mósè parí iṣẹ́, Jèhófà ò tẹ́wọ́ gba ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fáwọn èèyàn yẹn mọ́. Látìgbà yẹn, “ìbatisí kan” tó lè mú ká rí ìgbàlà ni Ọlọ́run fọwọ́ sí.—Éfé. 4:5.

c Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí?” tó wà ní abala “Ohun Tí Bíbélì Sọ” lórí jw.org àti JW Library®.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Níbi àpéjọ kan, àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi dìde dúró kí wọ́n lè kéde ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́