ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 February ojú ìwé 2-7
  • Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Mọ̀lẹ́bí Ẹ Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Mọ̀lẹ́bí Ẹ Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lọ́wọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁA FÀÁNÚ HÀN SÁWỌN MỌ̀LẸ́BÍ Ẹ
  • OHUN TÁ A LÈ ṢE TÍ WỌ́N BÁ SỌ TÀBÍ ṢE OHUN TÓ DÙN WÁ
  • NÍ SÙÚRÙ, KÓ O SÌ NÍRÈTÍ
  • JẸ́ KÍ WỌ́N MỌ̀ PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ WỌN
  • MÁ ṢE JẸ́ KỌ́RỌ̀ ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ Ẹ SÚ Ẹ
  • Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Wá Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2025-2026—Tí Alábòójútó Àyíká Máa Bá Wa Ṣe
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ṣé A Ṣì Lè Rí Nǹkan Kọ́ Nínú Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tá A Kọ́kọ́ Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 February ojú ìwé 2-7

APRIL 6-12, 2026

ORIN 82 “Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”

Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Mọ̀lẹ́bí Ẹ Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lọ́wọ́

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.”—GÁL. 6:9.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà lè máa wà láàárín àwa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Jèhófà.

1-2. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

JÉSÙ sọ fún ọkùnrin kan tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Máa lọ sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ.” (Máàkù 5:19) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti sọ ìròyìn ayọ̀ fáwọn mọ̀lẹ́bí wa.

2 Ṣé o rántí bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ó ṣeé ṣe kínú ẹ dùn débi pé o ò lè pa á mọ́ra! Ṣe ló ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ. Àmọ́, inú wọn lè má dùn pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé ọ̀nà tó o gbà ṣàlàyé ohun tó ò ń kọ́ fún wọn ló bí wọn nínú. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kí àlàáfíà sì tún wà láàárín ìwọ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ?

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa: (1) Bí àánú ṣe lè mú ká ran àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́, kódà tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìhìn rere; (2) ohun tá a lè ṣe tí wọ́n bá sọ tàbí ṣe ohun tó dùn wá; (3) bá a ṣe lè ní sùúrù, ká sì nírètí pé lọ́jọ́ kan wọ́n máa wá sin Jèhófà; àti (4) bá a ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

MÁA FÀÁNÚ HÀN SÁWỌN MỌ̀LẸ́BÍ Ẹ

4. Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ̀?

4 Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn tí ò gbọ́ ìhìn rere sú òun. Ó fi ara ẹ̀ wé òṣìṣẹ́ tó ń bójú tó igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí kò so èso nínú ọgbà àjàrà. Òṣìṣẹ́ náà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà lè so èso. (Lúùkù 13:6-9) Nígbà tí Jésù sọ àpèjúwe yìí, ó ti ju ọdún mẹ́ta lọ tó ti ń gbìyànjú láti ran àwọn Júù lọ́wọ́ kí wọ́n lè nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, kí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Kí nìdí tí Jésù ò fi jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú òun? Ìdí ni pé àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe é, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó mú sùúrù fún wọn.

5. Kí ló mú kí àánú àwọn Júù ṣe Jésù?

5 Àánú àwọn Júù máa ń ṣe Jésù torí pé àwọn olórí ẹ̀sìn wọn ò ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run. Jésù rí i pé àwọn èèyàn náà “dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Máàkù 6:34) Kí Jésù tó kú, ó sunkún nígbà tó ń wo ìlú Jerúsálẹ́mù torí ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbébẹ̀ máa kú torí pé wọn ò nígbàgbọ́. (Lúùkù 19:41-44) Bíi ti Jésù, ó yẹ kí àánú àwọn mọ̀lẹ́bí wa máa ṣe wá, ká má jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa, ìyẹn á jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (Gálátíà 6:9)

6 Ka Gálátíà 6:9. Táwọn mọ̀lẹ́bí wa ò bá tiẹ̀ ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó yẹ ká mú sùúrù fún wọn, ká má sì “jáwọ́ nínú ṣíṣe rere” sí wọn. Ká sòótọ́, ó máa ń gba àkókò kẹ́nì kan tó lè yí èrò ẹ̀ pa dà nípa àwọn nǹkan tó ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀, kó sì wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ṣé ìwọ náà rántí ìgbà kan tó o dà bí àwọn tí ò nírètí, tí wọn ò sì mọ Ọlọ́run? (Éfé. 2:12) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ẹnì kan ló fi sùúrù ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ Jèhófà. Ṣé kò wá yẹ kíwọ náà mú sùúrù fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà?

OHUN TÁ A LÈ ṢE TÍ WỌ́N BÁ SỌ TÀBÍ ṢE OHUN TÓ DÙN WÁ

7. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn àbúrò Jésù ò fi nígbàgbọ́ nínú ẹ̀?

7 Ó ṣeé ṣe káwọn àbúrò Jésù gbọ́ nípa iṣẹ́ ìyanu tó ṣe ní Gálílì. (Lúùkù 4:14, 22-24) Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. (Jòh. 7:5) Kí nìdí? Bíbélì ò sọ. Àmọ́ ó sọ nǹkan méjì tó ṣeé ṣe kó fà á táwọn Júù kan ò fi di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àwọn kan ń bẹ̀rù torí ohun táwọn aráàlú máa sọ. (Jòh. 9:18-22) Àwọn míì ti mọ Jésù láti kékeré, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló rán an wá. (Máàkù 6:1-4) Ó ṣeé ṣe káwọn àbúrò Jésù náà nírú èrò yìí. Ó sì lè jẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló ń ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí wa náà.

8. Kí ló lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà hùwà tàbí sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa?

8 Ronú nípa ohun tó fà á tí wọ́n fi sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí wọ́n hù. Ó ṣeé ṣe káwọn àbúrò Jésù wà lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tó sọ pé “orí rẹ̀ ti yí.” (Máàkù 3:21) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn fi hàn pé ọwọ́ Jésù dí gan-an débi pé kò tiẹ̀ ráyè jẹun. (Máàkù 3:20) Àwọn mọ̀lẹ́bí Jésù lè máa wò ó pé ó ti di agbawèrèmẹ́sìn. Bákan náà lónìí, ó ṣeé ṣe káwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wò ó pé a ti gbé ẹ̀sìn wa karí jù. Tí wọ́n bá nírú èrò yìí, ó máa dáa ká jẹ́ kí ìwà wa fi hàn pé a máa ń gba tàwọn èèyàn rò, a kì í sì í ṣàṣejù.

9. Kí ló lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí wa ní èrò tó dáa nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (1 Pétérù 3:1, 2) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Máa gba tiwọn rò nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ rere tá a bá ń sọ àti ìwà tó dáa tá a bá ń hù sáwọn mọ̀lẹ́bí wa lè mú kí wọ́n yí èrò wọn pa dà. (Ka 1 Pétérù 3:1, 2.) Tí arábìnrin kan tí ọkọ ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá lọ sípàdé tàbí òde ìwàásù, inú lè bí ọkọ ẹ̀ tàbí kó ronú pé ìyàwó òun ti pa òun tì. Kí ọkọ ẹ̀ má bàa nírú èrò yìí, arábìnrin náà lè ṣe àwọn àyípadà kan kó lè túbọ̀ ráyè fún ọkọ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè lọ wàásù lásìkò tí ọkọ ẹ̀ ò sí nílé tàbí tọ́wọ́ ọkọ ẹ̀ dí. Tí arábìnrin náà bá ń gba ti ọkọ ẹ̀ rò, tó sì ń ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ìyẹn lè mú kí ọkọ ẹ̀ ní èrò tó dáa nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Fọ́tò: 1. Arábìnrin kan ṣètò oúnjẹ ọ̀sán àti kọfí fún ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó tó lọ síbi iṣẹ́. 2. Nígbà tó yá, òun àti arábìnrin kan lọ wàásù, ó sì ń fi Bíbélì han obìnrin kan lórí fóònù ẹ̀.

Tó o bá ń sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tó dáa sí ọkọ tàbí aya ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn lè mú kó ní èrò tó dáa nípa wa (Wo ìpínrọ̀ 9)f


10. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù táwọn èèyàn bá sọ ohun tí ò dáa nípa wa?

10 Kì í ṣe gbogbo ìgbà tí wọ́n bá sọ ohun tí ò dáa nípa wa ló yẹ kó o fèsì. Nígbà táwọn kan fẹ̀sùn kan Jésù pé ó máa ń jẹ àjẹkì, ó sì máa ń mu àmujù, kò bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ara ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n lè mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. (Mát. 11:19) Bó sì ṣe gbé ìgbésí ayé ẹ̀ fi hàn pé kì í ṣàṣejù, síbẹ̀ ó máa ń gbádùn ara ẹ̀. (Fi wé Jòhánù 2:2, 6-10.) Bíi ti Jésù, kì í ṣe gbogbo ìgbà táwọn èèyàn bá sọ ohun tí ò dáa nípa wa ló yẹ kó o fún wọn lésì. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó hàn nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe pé o kì í ṣàṣejù, o sì ń gbádùn ayé ẹ. Báwọn mọ̀lẹ́bí ẹ ṣe ń wo bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ, ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa wa kì í ṣòótọ́.

NÍ SÙÚRÙ, KÓ O SÌ NÍRÈTÍ

11. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbúrò Jésù ò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, báwo ló ṣe hùwà sí wọn?

11 Àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká rí i pé Jésù ní sùúrù fáwọn àbúrò ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rí fi hàn pé ojú wọn ló ṣe nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ nílùú Kánà. (Jòh. 2:11, 12) Bá a sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn àbúrò ẹ̀ ò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀. Síbẹ̀, Jésù ò pa wọ́n tì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan bí ọdún mẹ́tà lẹ́yìn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nílùú Kánà, Jésù ṣì ń fi sùúrù bá àwọn àbúrò ẹ̀ sọ̀rọ̀.—Jòh. 7:5-8.

12. Kí ló jẹ́ ká nírètí pé àwọn mọ̀lẹ́bí wa kan lè wá sin Jèhófà?

12 Àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ ti jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, ìyẹn sì ń jẹ́ ká nírètí pé àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè wá sin Jèhófà. Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run, àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè rántí pé a ti máa ń sọ fún wọn pé èyí máa ṣẹlẹ̀.a (Ìfi. 17:16) Kódà, wọ́n lè wá sin Jèhófà lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀. Táwọn mọ̀lẹ́bí wa bá sì níṣòro kan tí wọ́n ń bá yí lásìkò yìí, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti dúró tì wọ́n. Tí wọ́n bá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú, a sì fi inúure hàn sí wọn, ìyẹn lè mú kó wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

JẸ́ KÍ WỌ́N MỌ̀ PÉ O NÍFẸ̀Ẹ́ WỌN

13. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wa máa ń dí bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?

13 Òótọ́ ni pé ọwọ́ wa máa ń dí torí ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa rò pé a ò ráyè tiwọn mọ́ tàbí pé a ò nífẹ̀ẹ́ wọn mọ́. (Mát. 7:12) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a lè ṣe.

14-15. Kí la lè ṣe táwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fi mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Máa kàn sí wọn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tá a bá ń kàn sí wọn déédéé, tá a sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àlàáfíà la wà. Bí àpẹẹrẹ, a lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn, tàbí ká fi àwọn fọ́tò tá a yà níbi tá a ti lọ gbafẹ́, nígbà tá a rìnrìn àjò tàbí èyí tá a yà níbi tá a ti ń gbádùn ara wa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa ránṣẹ́ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá fún wọn lẹ́bùn kékeré kan tàbí tó o kọ lẹ́tà sí wọn, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ mọwọ́ ara yín dáadáa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

15 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin Anna tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Àméníà. Kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òun àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ sábà máa ń wà pa pọ̀, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ọjọ́ ìbí àtàwọn ọdún míì tí wọ́n máa ń ṣe. Àmọ́ nígbà tí Anna kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé kò ní máa bá àwọn ṣe mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ẹ̀rù tún ń bà wọ́n pé tí Anna bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nǹkan máa nira fún un gan-an. Ọgbọ́n wo wá ni Anna dá sí i? Ó sọ pé: “Tí mo bá lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí mi, mo máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí mò ń ṣe àti bí nǹkan ṣe ń lọ fún mi. Mo tún máa ń sọ pé kí wọ́n wá kí mi nílé, mo sì máa ń fàwọn ọ̀rẹ́ mi hàn wọ́n. Ohun tí mo ṣe yìí jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí mi mọ àwọn ọ̀rẹ́ mi dáadáa, ó sì máa ń rọrùn fún wọn láti bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ lára wọn sọ pé àwọn rí i pé inú mi máa ń dùn gan-an, àwọn ò sì kọ́kàn sókè lórí ọ̀rọ̀ mi mọ́.”

16. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí Jémíìsì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ òun lógún? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

16 Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó dìídì fara han Jémíìsì àbúrò ẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí Jémíìsì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ òun jẹ ẹ́ lógún. (1 Kọ́r. 15:7) Ẹ ò rí i pé inú Jémíìsì máa dùn gan-an nígbà tó rí i pé Jésù ò pa òun tì! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Jésù ṣe yìí ló mú kí Jémíìsì gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Lẹ́yìn tí Jésù fara hàn án, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jémíìsì ló jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí tó kù mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà.b—Ìṣe 1:14.

17. Báwo lá ṣe lè ṣe ohun tí Róòmù 12:15 sọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Ka Róòmù 12:15. Tá a bá jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún nígbà dídùn àti nígbà kíkan, ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n yí èrò tí ò tọ́ tí wọ́n ní nípa wa pa dà.c Bí àpẹẹrẹ, a lè lọ kí wọn tí wọ́n bá bímọ, ká sì fún wọn lẹ́bùn kí wọ́n lè mọ̀ pé à ń bá wọn yọ̀. Tí èèyàn wọn bá kú, a lè lọ kí wọn, ká sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, ká sì fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bákan náà, á dáa ká máa béèrè àlàáfíà wọn látìgbàdégbà, pàápàá tí wọ́n bá láwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí. Ó ṣe tán, ìgbà ìpọ́njú là ń mọ̀rẹ́.

Arábìnrin tá a rí lẹ́ẹ̀kan ń ya fọ́tò pẹ̀lú ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìyá ọkọ ẹ̀ tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ arọ.

Tó o bá jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún, wọ́n lè yí èrò tí ò dáa tí wọ́n ní nípa wa pa dà (Wo ìpínrọ̀ 17)g


Ṣé Kí N Lọ Síbi Ìgbéyàwó Tàbí Ìsìnkú Mọ̀lẹ́bí Mi?

Lára nǹkan tó máa ń mú káwọn mọ̀lẹ́bí kóra jọ ni tẹ́nì kan bá fẹ́ ṣègbéyàwó tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìsìnkú. Kó o tó pinnu bóyá wàá lọ tàbí o ò ní lọ, á dáa kó o gbé àwọn ìlànà Bíbélì yìí yẹ̀ wò.

  • Ṣé wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìsìn èké níbi ìgbéyàwó tàbí ìsìnkú náà? (2 Kọ́r. 6:14, 15)

  • Tó o bá lọ, ṣé wàá lè kọ̀ tí wọ́n bá ní kó o dara pọ̀ tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìsìn èké tàbí tí kò bá ìlànà Bíbélì mu? (Òwe 22:3)

  • Ṣé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ pé o ò ní lọ́wọ́ sáwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu?

  • Tó o bá lọ síbi ìgbéyàwó tàbí ìsìnkú tí wọ́n ṣe nínú ilé ìjọsìn, ṣé ìpinnu tó o ṣe yìí ò ní mú àwọn míì kọsẹ̀? (Fílí. 1:10)

Ohun yòówù kó o ṣe, rí i dájú pé o fọgbọ́n ṣàlàyé ìpinnu ẹ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ lọ́nà tí ò ní bí wọn nínú. Àmọ́ má gbàgbé pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn ẹ mọ́, táá sì múnú Jèhófà dùn.e

18. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Áńdérù?

18 Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ará. Nígbà tí Áńdérù rí i pé Jésù ni Mèsáyà, kíá ló lọ sọ fún Pétérù arákùnrin ẹ̀. (Jòh. 1:40-42) Àwa náà lè ṣe bíi ti Áńdérù. Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè pe mọ̀lẹ́bí wa kan wá sí ìpàdé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí ká ní kó wá sí àpèjẹ kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa nínú ìjọ? Bá a ṣe ń fojú àwọn mọ̀lẹ́bí wa mọ àwọn ará, wọ́n á rí i pé èèyàn bíi tiwọn làwa náà, ọmọlúàbí sì ni wá.

19. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn mọ̀lẹ́bí wa, bí wọn ò tiẹ̀ mọ ìdí tá ò fi ṣe àwọn nǹkan kan? (1 Pétérù 3:15)

19 Ka 1 Pétérù 3:15. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè má mọ ìdí tá ò fi ṣe àwọn nǹkan kan, àmọ́ wọn ò ní gbàgbé bá a ṣe máa ń hùwà tó dáa sí wọn, tá a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Òótọ́ ni pé a lè má bá wọn ṣe àwọn nǹkan kan, síbẹ̀ wọ́n máa ń mọyì bá a ṣe máa ń wáyè fún wọn láwọn ìgbà míì. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kì í bá wọn ṣe àwọn ayẹyẹ tí ò bá Bíbélì mu, a lè wáyè lọ kí wọn, ká gbà wọ́n lálejò, ká sì fún wọn lẹ́bùn láwọn ìgbà míì.

MÁ ṢE JẸ́ KỌ́RỌ̀ ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ Ẹ SÚ Ẹ

20. Kí la kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jémíìsì?

20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jémíìsì ò tẹ̀ lé Jésù nígbà tí Jésù wà láyé, ó pa dà di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tó yá. (Gál. 1:18, 19; 2:9) Kò sí àní-àní pé Jémíìsì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tí Jésù sọ nígbà tó wà láyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ darí ẹ̀ láti kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ bá ohun tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè mu.d

21. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sú wa?

21 Láìka gbogbo ohun tá a ṣe sí, àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè má nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n sì lè má mọyì ìfẹ́ tá à ń fi hàn sí wọn. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo ìgbà tá a bá ń fi inúure hàn sí wọn là ń fìwà jọ Jèhófà Ọlọ́run aláàánú àti Jésù Ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 6:33, 36) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìwà tó dáa tá à ń hù sí wọn lè mú kí wọ́n yí èrò tí ò dáa tí wọ́n ní nípa wa pa dà. Wọ́n tiẹ̀ lè rántí àwọn nǹkan tá a ti sọ fún wọn nípa Jèhófà. Torí náà, tá ò bá jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú wa, àwọn kan nínú wọn lè wá sin Jèhófà. Ayọ̀ tá a sì máa ní á kọjá sísọ!

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Tí àánú àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń ṣe wá, kí nìyẹn máa mú ká ṣe?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù fáwọn mọ̀lẹ́bí wa, ká sì nírètí pé wọ́n lè wá sin Jèhófà?

  • Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn?

ORIN 60 Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́

a Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí La Mọ̀ Nípa Bí Jèhófà Ṣe Máa Ṣèdájọ́ Lọ́jọ́ Iwájú?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2024, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 11-13.

b Ó kéré tán méjì lára àwọn àbúrò Jésù, ìyẹn Jémíìsì àti Júùdù ló di Kristẹni lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde.

c Wo àpótí náà “Ṣé Kí N Lọ Síbi Ìgbéyàwó Tàbí Ìsìnkú Mọ̀lẹ́bí Mi?”

d Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra. Jémíìsì 1:2 àti Mátíù 5:11, 12; Jémíìsì 1:19 àti Mátíù 5:22; Jémíìsì 1:22; 2:24 àti Mátíù 7:21; Jémíìsì 2:13 àti Mátíù 5:7; 6:14, 15.

e Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ohun tó o lè ṣe tírú ẹ̀ bá wáyé, ka “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002, àti November 15, 2007.

f ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ṣètò oúnjẹ fún ọkọ ẹ̀ kó tó lọ sóde ìwàásù.

g ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin náà tún wáyè lọ kí ìyá ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́