APRIL 27–MAY 3, 2026
ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àwọn Ohun Tó Lè Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tó O Bá Ṣèrìbọmi?
“Má ṣe jẹ́ kí ìṣísẹ̀ mi kúrò ní ọ̀nà rẹ.”—SM. 17:5.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèrìbọmi.
1-2. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká má bàa fi Jèhófà sílẹ̀ lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi? Ṣàpèjúwe.
TORÍ pé inú ayé tí Sátánì ń darí là ń gbé, kò sí bá ò ṣe ní níṣòro. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ó di dandan kí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ wá.” (Mát. 18:7) Tá a bá fi ìkìlọ̀ tí Jésù fún wa yìí sọ́kàn, àá rí i pé ó yẹ ká múra sílẹ̀ de àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Lára ẹ̀ ni ìṣòro tó ṣeé ṣe kó wáyé láàárín àwa àtàwọn ará wa.
2 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ètò Ọlọ́run máa ń sọ fún wa látìgbàdégbà pé ká múra sílẹ̀ de àjálù. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká mọ irú àjálù tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa. Ìyẹn sì túbọ̀ ṣe pàtàkì tó bá jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí agbègbè náà. Tá a bá ti mọ àwọn àjálù tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, ohun tó kàn ni pé ká múra sílẹ̀ de ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. (Òwe 21:5) Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe ká ní lẹ́yìn tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lẹ́yìn náà, ká múra sílẹ̀ dè wọ́n. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìṣòro náà ò ní mu wá lómi, kò sì ní mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Sm. 17:5) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìṣòro mẹ́ta tó ṣeé ṣe ká ní lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi àti bá a ṣe lè múra sílẹ̀ de ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.a
TÍ ARÁKÙNRIN TÀBÍ ARÁBÌNRIN KAN BÁ ṢOHUN TÓ DÙN Ẹ́
3. Ìṣòro wo la lè ní lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi?
3 Ṣó o rántí bó ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kọ́kọ́ wá sípàdé, tó o sì rí i pé àwọn èèyàn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn? Ṣé ohun tó o rí yẹn jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ti rí ìsìn tòótọ́? (Jòh. 13:35; Kól. 3:12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Blancab nìyẹn. Àmọ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ohun tí kò retí ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Arábìnrin kan ṣe ohun tó dùn mí gan-an. Mo tún kíyè sí i pé ó máa ń sọ̀rọ̀ àwọn ará ìjọ láìdáa. Mi ò rò pé ó yẹ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, torí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń sapá kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà.” Ká sòótọ́, àwọn ará wa máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè túbọ̀ láwọn ànímọ́ Kristẹni, síbẹ̀ wọn kì í ṣe ẹni pípé. (Éfé. 4:23, 24; 1 Jòh. 1:8) Torí náà, láwọn ìgbà míì, ó ṣeé ṣe ká rí lára wọn tó máa sọ tàbí ṣe ohun kan táá dùn wá gan-an. (Jém. 3:8) Ó bani nínú jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti mú káwọn kan fi Jèhófà sílẹ̀.
4. Kí lo lè ṣe láti múra sílẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe ohun tó dùn ẹ́? (Éfésù 4:32)
4 Kí lo lè ṣe láti múra sílẹ̀ báyìí tó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe ohun tó dùn ẹ́? Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ṣe ohun tó wà nínú Éfésù 4:32. (Kà á.) Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti jẹ́ onínúure, tó o sì ń ṣàánú àwọn èèyàn, ìyẹn á jẹ́ kó o yẹra fáwọn ìṣòro tó lè ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn ará. Bákan náà, pinnu pé wàá máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́ fàlàlà. Kí ló máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí? Ronú nípa iye ìgbà tíwọ náà ti bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́ torí àwọn àṣìṣe tó o ṣe, tó sì dárí jì ẹ́ fàlàlà. (Mát. 6:12) Tó o bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń darí jì ẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà, á rọrùn fún ìwọ náà láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́.
5. Ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tẹ́nì kan bá ṣohun tó dùn wá? (Òwe 19:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ka Òwe 19:11. Bíbélì sọ pé tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye,c àá lè dẹwọ́ ìbínú wa. Ìlànà Bíbélì yìí ti ran Arábìnrin Rima lọ́wọ́ gan-an, ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tó ti ṣèrìbọmi. Ó sọ pé: “Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá múnú bí mi tàbí tó ṣohun tó dùn mí, ẹsẹ Bíbélì tí mo máa ń kọ́kọ́ rántí ni Òwe 19:11. Mo máa ń ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí àtohun tó lè fà á tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, mo máa ń rí i pé a jọ ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa.” Ẹ ò rí i pé á dáa táwa náà bá ṣe ohun tó sọ yìí. Ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ mọ àwọn ará wa dáadáa nísinsìnyí. Tá a bá mọ̀ wọ́n dáadáa, á rọrùn fún wa láti dárí jì wọ́n tí wọ́n bá ṣohun tó dùn wá.
Tí ìwọ àti arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ní èdèkòyédè, gbìyànjú kó o bá a ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 5)
6. Kí la lè ṣe ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará ìjọ?
6 Kí la lè ṣe ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará ìjọ? Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ará wa, á dáa ká máa kíyè sí àwọn ìwà tó dáa tí wọ́n ní. (Fi wé Òwe 10:12; Róòmù 12:10; Fílí. 2:2, 3) Wo bí ohun tá a sọ yìí ṣe ran Arákùnrin Mark tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́. Bó ṣe túbọ̀ ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìjọ ẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí wọ́n ní. Kí ló ṣe tóhun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò fi ba àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará jẹ́? Ó sọ pé: “Mo kíyè sí i pé kùdìẹ̀-kudiẹ táwọn ará ní ò tó nǹkan kan rárá tí mo bá fi wé ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù nínú ayé. Mo wá pinnu pé mi ò ní máa ronú ṣáá lórí àṣìṣe àwọn ará. Kàkà bẹ́ẹ̀ ibi tí wọ́n dáa sí ni màá máa wò.” Tíwọ náà bá ṣe bíi ti arákùnrin yìí, àárín ìwọ àtàwọn ará ìjọ ẹ á túbọ̀ gún régé.
TÁWỌN NǸKAN TÓ O FI SÍLẸ̀ BÁ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í WÙ Ẹ́
7. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kóhun tá a ti yááfì ká lè sin Jèhófà tún máa wù wá?
7 Nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò sí àní-àní pé inú ẹ dùn gan-an pé o kì í ṣe apá kan ayé yìí mọ́. O lè máa rò ó pé, ‘Kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ táá mú kí n pa dà sínú ayé.’ Àmọ́ tíṣòro bá dé, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn nǹkan tó o yááfì kó o lè wá sin Jèhófà, ó sì lè máa wù ẹ́ kó o pa dà sídìí àwọn nǹkan náà. (Fi wé Nọ́ńbà 11:4-6.) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará kan ti pinnu láti fi iṣẹ́ olówó ńlá tàbí àwọn nǹkan míì tó lè gba àkókò wọn sílẹ̀. Nígbà táwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ ò bá wọn ṣọ̀rẹ́ mọ́. Ní tàwọn míì, àwọn ìwà kan tí ò dáa ti mọ́ wọn lára, wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè jáwọ́ nínú ìwà náà. Ẹ ò rí i pé ó máa bani nínú jẹ́ gan-an tí Kristẹni kan bá jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ti yááfì tẹ́lẹ̀ mú kó fi Jèhófà sílẹ̀! Torí náà, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe báyìí tó ò fi ní pa dà sídìí àwọn ohun tó o ti yááfì kó o lè sin Jèhófà láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀?
8. Kí la kọ́ lára Ábúráhámù àti Sérà?
8 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n yááfì àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ràn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún Ábúráhámù àti Sérà pé kí wọ́n fi ìlú Úrì sílẹ̀ kí wọ́n lọ máa gbé nínú àgọ́, wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ. (Héb. 11:8, 9) Kò sí àní-àní pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tí wọ́n ń gbádùn nílùú Úrì lè máa wá sí wọn lọ́kàn. “Tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣì ń rántí” tàbí tí wọn ò gbọ́kàn kúrò lórí àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máa wù wọ́n láti pa dà. Àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn ni wọ́n gbájú mọ́.—Héb. 11:15, 16.
9. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn nǹkan tó yááfì? (Fílípì 3:7, 8, 13)
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà yááfì àwọn nǹkan kan kó lè sin Jèhófà. Kó tó di Kristẹni, ó kẹ́kọ̀ọ́ òfin àwọn Júù lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún dáadáa. (Ìṣe 22:3) Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù dé ipò ńlá nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. (Gál. 1:13, 14) Àmọ́ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, gbogbo nǹkan yẹn ló fi sílẹ̀. Ṣé nǹkan wá rọrùn fún un lẹ́yìn tó di Kristẹni? Rárá o! Wọ́n lù ú, wọ́n fi sẹ́wọ̀n, àwọn èèyàn sì kórìíra ẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23-26) Tó bá jẹ́ pé àwọn ìṣòro tó ní nìkan ló ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, tó sì ń fi bí nǹkan ṣe rí fún un báyìí wé ti tẹ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kó kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe láti di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń ronú nípa àǹfààní ńlá tó ní láti máa tẹ̀ lé Jésù àtàwọn nǹkan rere tó máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé àwọn ìbùkún tóun rí dáa fíìfíì ju àwọn nǹkan tóun yááfì lọ.—Ka Fílípì 3:7, 8, 13.
10. Kí ló yẹ kó o máa rántí ní gbogbo ìgbà? (Máàkù 10:29, 30) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Kí nìyẹn kọ́ wa? Tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tó o yááfì kó o lè di Kristẹni, á dáa kó o máa rántí ìdí tó o fi pa àwọn nǹkan náà tì. (Oníw. 7:10) Kó o sì tún máa rántí pé àwọn nǹkan rere tó ò ń gbádùn báyìí dáa ju ohun yòówù kó o yááfì kó o lè wá sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. (Òwe 3:32) O tún láwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ dénú. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Yàtọ̀ síyẹn, o nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa! (Àìsá. 65:21-23) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan rere tó ò ń gbádùn torí pé ò ń sin Jèhófà lò ń ronú nípa ẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ìyẹn ò ní jẹ́ káwọn nǹkan tó o yááfì láti wá sin Jèhófà tún máa wù ẹ́.
Dípò kó o máa ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tó o yááfì kó o lè sin Jèhófà, máa lo àkókò ẹ láti sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn, ìyẹn máa jẹ́ kó o láyọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10)e
11. Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí Arábìnrin Rosemary?
11 Arábìnrin Rosemary ti lé lẹ́ni àádọ́ta (50) ọdún nígbà tó ṣèrìbọmi. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣe táwọn nǹkan tó fi sílẹ̀ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ò fi bẹ̀rẹ̀ sí í wù ú pa dà. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú mi kì í dùn láwọn ọjọ́ Kérésìmesì torí pé lákòókò yẹn, èmi àtàwọn mọ̀lẹ́bí mi máa ń wà pa pọ̀, a sì jọ máa ń gbádùn ara wa. Mo tún fẹ́ràn bí mo ṣe máa ń fún àwọn tó sún mọ́ mi lẹ́bùn nígbà ayẹyẹ náà. Inú àwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ-ọmọ mi máa ń dùn tí wọ́n bá já ẹ̀bùn tí mo fún wọn, tí wọ́n sì ń ṣeré níbi igi Kérésì, gbogbo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn yẹn máa ń múnú mi dùn gan-an.” Kí ló wá ṣe? Ó sọ pé: “Mo ronú nǹkan míì tí mo lè máa ṣe dípò ọdún Kérésì. Mo máa ń wá ọjọ́ kan lọ́dún tó yàtọ̀ sí ọjọ́ Kérésì, màá kó àwọn mọ̀lẹ́bí mi jọ, màá fún wọn lẹ́bùn, màá sì sọ ohun tí mo mọyì nípa wọn.” Arábìnrin Rosemary tún sọ ìṣòro míì tó ní, ó sọ pé: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn ọ̀rẹ́ mi fi mí sílẹ̀. Nígbà míì, àárò wọn máa ń sọ mí, mi ò sì rẹ́ni fojú jọ.”d Kí ló wá ṣe? Ó máa ń rí i pé òun bá àwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá àwọn arábìnrin yìí ṣiṣẹ́ ti jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí mo nífẹ̀ẹ́, mo sì mọyì wọn gan-an.” Kí lo lè rí kọ́ lára arábìnrin yìí? Ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó ò ń ṣe tó sì ń múnú ẹ dùn kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wù ẹ́. Torí náà, á dáa kó o ronú àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe láti rọ́pò àwọn nǹkan náà, táá sì máa fún ẹ láyọ̀ tòótọ́. (Fílí. 4:8, 9) Má gbàgbé pé: Ẹni bá ti ní Jèhófà, ohun gbogbo ló ni, ó máa fún ẹ lóhun tó pọ̀ rẹpẹtẹ ju ohun yòówù kó o yááfì lọ.
TÁWỌN TÓ SÚN MỌ́ Ẹ BÁ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀
12. Kí ló lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nínú ìjọ?
12 Nígbà tó o di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe kára tù ẹ́ pé o ti fi àwọn tó ń hùwàkiwà sílẹ̀, o sì wá dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. (Àìsá. 65:14) Àmọ́ nígbà míì, o lè gbọ́ pé ẹnì kan dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ. Kódà wọ́n tiẹ̀ lè mú ẹlòmíì kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:13) Ẹ jẹ́ ká wo bọ́rọ̀ ṣe rí lára arábìnrin kan tó ń jẹ́ Samar. Ó sọ pé: “Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni wọ́n mú alàgbà kan kúrò nínú ìjọ torí pé ó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bá mi lójijì, díẹ̀ ló sì kù kí n fi Jèhófà sílẹ̀ torí ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ẹni tó jẹ́ alàgbà lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.” Òótọ́ ni pé ó yẹ ká fọkàn tán àwọn ará wa pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì wù wọ́n kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Síbẹ̀, ó dunni pé lọ́dọọdún, wọ́n ṣì máa ń mú àwọn kan kúrò nínú ìjọ. Tó bá wá jẹ́ pé ẹnì kan tó sún mọ́ wa tàbí ẹni tá a bọ̀wọ̀ fún ló dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí wọ́n sì mú un kúrò nínú ìjọ, ó máa dùn wá gan-an, ó sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa.
13. Kí lo lè máa ṣe báyìí kó o lè jẹ́ olóòótọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó sún mọ́ ẹ fi Jèhófà sílẹ̀?
13 Kí lo lè máa ṣe báyìí kó o lè jẹ́ olóòótọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó sún mọ́ ẹ fi Jèhófà sílẹ̀? Máa ṣe àwọn nǹkan tá a jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Máa rántí pé kálukú ló ní àjọṣe tiẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, torí náà má ṣe jẹ́ kí ohun tí ẹlòmíì ṣe pinnu bóyá wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, òótọ́ ni pé a máa ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ, síbẹ̀ ó yẹ kí kálukú máa wáyè gbàdúrà, kó sì máa ka Bíbélì.—Sm. 1:2; 62:8.
14. Kí la rí kọ́ lára àpọ́sítélì Pétérù? (Jòhánù 6:66-68)
14 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tí Pétérù ṣe nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn pa dà lẹ́yìn Jésù. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù náà má mọ ohun tó máa ṣe nígbà yẹn. Àmọ́ ẹ wo ohun tó sọ nínú Jòhánù 6:66-68. (Kà á.) Dípò kí Pétérù máa ronú lórí ohun táwọn èèyàn ṣe, ṣe ló ń ronú lórí òtítọ́ tí Jésù kọ́ ọ. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí Pétérù pa dà lẹ́yìn Jésù. Bákan náà lónìí, táwọn kan bá tiẹ̀ sọ pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́, máa rántí pé inú ètò yìí lo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Torí náà, pinnu pé o ò ní fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀! Samar tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé, “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń fi sọ́kàn pé torí ẹnì kan ṣohun tí kò dáa ò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ará ló ń hùwà burúkú tàbí pé ohun tí ètò Ọlọ́run fi kọ́ni ò dáa. Bákan náà, ìwà yòówù kí ẹnikẹ́ni hù, kò yí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ pa dà.”
15. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Emily?
15 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa arábìnrin kan tó ń jẹ́ Emily. Kò ju ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi ni wọ́n mú màmá ẹ̀ kúrò nínú ìjọ, tó sì fi ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ sílẹ̀. Emily sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ rò ó rí pé irú nǹkan báyìí lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kà mí láyà gan-an, gbogbo ìgbà ni àárò màmá mi máa ń sọ mí.” Kí ni Emily wá ṣe? Ó sọ pé: “Bàbá mi àtàwọn ará nínú ìjọ ò fi mí sílẹ̀. Ṣe ni wọ́n ń kẹ́mi lójú kẹ́mi nímú. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kálukú ló ní ohun tó ń bá yí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká sún mọ́ ara wa, ká sì máa fúnra wa níṣìírí.” (1 Pét. 5:9) Kò yẹ ká dúró dìgbà tíṣòro bá dé ká tó sún mọ́ àwọn ará wa. Á dáa ká jẹ́ kó mọ́ wa lára báyìí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, tíṣòro bá tiẹ̀ wá dé, kò ní ṣe wá bíi pé a dá wà.
16. Kí ló yẹ ká máa rántí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ohun míì tó yẹ kó o máa rántí ni pé àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí. (Héb. 12:6) Ó fẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ pa dà. (2 Pét. 3:9) Torí náà, tí wọ́n bá mú ẹni tó sún mọ́ ẹ kúrò nínú ìjọ, jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ pé àwọn alàgbà máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—2 Tím. 2:24, 25.
Tí wọ́n bá mú ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ kúrò nínú ìjọ, máa rántí pé àwọn alàgbà máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 16)f
17. Kí ló dá wa lójú?
17 A ti sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó o ní lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi. Òótọ́ ni pé àwọn ìṣòro kan lè kà ẹ́ láyà, àmọ́ má bẹ̀rù. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe báyìí láti múra sílẹ̀. Má sì gbàgbé pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́. Ó ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ báyìí, títí láé lá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀! (1 Pét. 5:10) Gbogbo ìgbà lá máa fún ẹ lókun tó o nílò láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní. Tó o bá ń jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó dájú pé kò sí ìṣòro èyíkéyìí tó máa mú kó o fi Jèhófà sílẹ̀!—Sm. 119:165; Róòmù 8:38, 39.
ORIN 154 Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀
a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi la dìídì ṣe àpilẹ̀kọ yìí fún, gbogbo wa pátá ló lè ṣe láǹfààní.
b A ti yí àwọn orúkọ pa dà.
c Tẹ́nì kan bá ní ìjìnlẹ̀ òye, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn bá sọ tàbí tí wọ́n ṣe nìkan lá máa rò. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa ronú nípa ìdí tí wọ́n fi sọ ọ̀rọ̀ kan tàbí ṣe ohun tí wọ́n ṣe.
d Gbogbo wa pátá nínú ìjọ ló yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, ká sì jẹ́ kára wọn mọlé. Ká má fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan. Ka ìpínrọ̀ 15 àti 16 nínú àpilẹ̀kọ náà “Bí Gbogbo Ìjọ Ṣe Lè Mú Kí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Tẹ̀ Síwájú Kó sì Ṣèrìbọmi” nínú Ilé Ìṣọ́ March 2021.
e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Nígbà tí arábìnrin kan wà lóde ìwàásù, ó rí àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù, ìyẹn mú kó rántí ìgbà tóun náà máa ń gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ kan. Nígbà tó yá, ó wàásù fún ọ̀kan lára àwọn tó ń gbá bọ́ọ̀lù náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n jọ máa ń gbá bọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀.
f ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn alàgbà méjì lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ, kí wọ́n lè gbà á níyànjú láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.