ÀPILẸ̀KỌ 46
ORIN 17 “ Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
Jésù Ni Àlùfáà Àgbà Tó Ń Bá Wa Kẹ́dùn
“Torí àlùfáà àgbà tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”—HÉB. 4:15.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí i pé Jésù ni Àlùfáà Àgbà tó dáa jù torí ó máa ń báni kẹ́dùn, ó sì láàánú. A tún máa rí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lóde òní.
1-2. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi rán Ọmọ ẹ̀ wá sáyé? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Hébérù 5:7-9)
NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, Jèhófà rán Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé. Kí nìdí? Ara ohun tó wá ṣe ni pé kó gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kó sì mú gbogbo ìṣòro tí Sátánì fà kúrò. (Jòh. 3:16; 1 Jòh. 3:8) Bákan náà, Jèhófà mọ̀ pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí Jésù láyé máa jẹ́ kó lè bá wa kẹ́dùn, kó sì láàánú tó bá di Àlùfáà Àgbà. Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi lọ́dún 29 S. K.,a ó di Àlùfáà Àgbà.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà láyé ṣe jẹ́ kó lè bá wa kẹ́dùn nígbà tó di Àlùfáà Àgbà. Tá a bá túbọ̀ mọ bí Jèhófà ṣe “sọ ọ́ di pípé” kó lè di Àlùfáà Àgbà, á rọrùn fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà kódà tínú wa ò bá dùn torí pé a dẹ́ṣẹ̀ tàbí tá a ṣàṣìṣe.—Ka Hébérù 5:7-9.
ỌMỌ ỌLỌ́RUN WÁ SÁYÉ
3-4. Àwọn ìyípadà wo ni Jésù ṣe nígbà tó wá sáyé?
3 Ọ̀pọ̀ lára wa ló ti ṣe àwọn àyípadà kan, irú bíi ká kúrò nílé, ká sì fi àwọn èèyàn wa àtàwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀. Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ kì í tètè bá wa lára mu. Àmọ́, kò sẹ́ni tó ṣe àyípadà bíi Jésù. Òun ni áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá, ipò tó ṣe pàtàkì ló sì wà nígbà tó wà lọ́run. Jèhófà fẹ́ràn ẹ̀ gan-an, inú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń ṣiṣẹ́ ní “ọwọ́ ọ̀tún” Ọlọ́run. (Sm. 16:11; Òwe 8:30) Síbẹ̀, Fílípì 2:7 sọ pé “ó fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀,” ó fi ipò gíga tó wà lọ́run sílẹ̀, ó sì wá gbé láyé láàárín àwa èèyàn aláìpé.
4 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bí Jésù àtìgbà tó ń dàgbà. Ohun táwọn òbí ẹ̀ fi rúbọ nígbà tí wọ́n bí i fi hàn pé tálákà ni wọ́n. (Léf. 12:8; Lúùkù 2:24) Nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé wọ́n bí Mèsáyà, ó gbìyànjú láti pa á. Kí ọwọ́ Hẹ́rọ́dù má bàa tẹ Jésù, ìdílé náà fẹsẹ̀ fẹ, wọ́n sì lọ forí pa mọ́ sí Íjíbítì. (Mát. 2:13, 15) Ẹ ò rí i pé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù yàtọ̀ pátápátá sí bí nǹkan ṣe rí nígbà tó wà lọ́run!
5. Kí ni Jésù rí nígbà tó wà láyé, báwo lóhun tó ṣẹlẹ̀ sí i ṣe jẹ́ kó bá wa kẹ́dùn nígbà tó di Àlùfáà Àgbà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó rí bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn èèyàn. Jésù mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Ó dájú pé ó mọ àwọn kan tó kú, ẹ̀rí sì fi hàn pé Jósẹ́fù bàbá tó tọ́ ọ dàgbà wà lára wọn. Nígbà tó wà láyé, ó rí àwọn adẹ́tẹ̀, àwọn tí ò ríran, àwọn tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀ àtàwọn òbí tí ọmọ wọn kú, àánú wọn sì ṣe é. (Mát. 9:2, 6; 15:30; 20:34; Máàkù 1:40, 41; Lúùkù 7:13) Òótọ́ ni pé nígbà tó wà nípò gíga lọ́run ó rí bí ìyà ṣe ń jẹ́ àwọn èèyàn. Àmọ́, nígbà tó wá sáyé, ó mọ bó ṣe máa ń rí lára èèyàn tí ìyà bá ń jẹ wọ́n. (Àìsá. 53:4) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù láyé jẹ́ kó mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí wọ́n bá níṣòro tí ara sì ń ni wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń rẹ àwa èèyàn, ìdààmú máa ń bá wa, inú wa sì máa ń bà jẹ́. Gbogbo nǹkan yìí náà ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù.
Jésù bá àwọn tó ń jìyà kẹ́dùn, ó sì ṣàánú wọn (Wo ìpínrọ̀ 5)
JÉSÙ BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN KẸ́DÙN
6. Kí la kọ́ nínú àwọn àpèjúwe tí wòlíì Àìsáyà lò láti ṣàlàyé bí Jésù ṣe ń bá àwọn èèyàn kẹ́dùn tó sì ń ṣàánú wọn? (Àìsáyà 42:3)
6 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó bá àwọn aláìlera kẹ́dùn, ó sì ṣàánú àwọn tí ìyà ń jẹ. Ohun tó ṣe yìí mú kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ sí i lára. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sábà máa ń fi àwọn tó lágbára àtàwọn ọlọ́rọ̀ wé igi ńlá tàbí ọgbà tó lọ́ràá. (Sm. 92:12; Àìsá. 61:3; Jer. 31:12) Àmọ́, ó fi àwọn aláìní àtàwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ wé esùsú tó ti fọ́ àti òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú tí kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún ẹnikẹ́ni. (Ka Àìsáyà 42:3) Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí wòlíì Àìsáyà láti fi àwọn àpèjúwe yìí ṣàlàyé bí Jésù ṣe máa fìfẹ́ àti àánú hàn sáwọn èèyàn tí wọ́n ń fojú pa rẹ́.
7-8. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣe ṣẹ sí Jésù lára?
7 Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kò ní ṣẹ́ esùsú kankan tó ti fọ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.” Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere sọ pé Jésù ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí lára. (Mát. 12:20) Àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ tí wọ́n dà bí esùsú tó ti fọ́ àtàwọn tí kò nírètí, tí wọ́n dà bí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú tó máa tó kú, wà lára àwọn tó jàǹfààní iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Ọ̀kan lára wọn ni ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò látòkè délẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó ti ro ara ẹ̀ pin pé bóyá lara òun máa yá, tóun á sì láǹfààní láti bá àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé òun ṣeré. (Lúùkù 5:12, 13) Yàtọ̀ síyẹn, ọkùnrin kan wà tó jẹ́ adití, tí kò tún lè sọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára ẹ̀ nígbà tó rí báwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n tí ò gbọ́ nǹkan tí wọ́n ń sọ. (Máàkù 7:32, 33) Àmọ́, àwọn nǹkan míì wà tí Jésù ṣe.
8 Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù gbà pé ṣe làwọn aláìsàn àtàwọn aláàbọ̀ ara ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tàbí tàwọn òbí wọn. (Jòh. 9:2) Èrò tí kò tọ́ tí wọ́n ní yìí máa ń mú kí wọ́n fojú burúkú wo àwọn tó ń jìyà. Àmọ́ Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣẹ sí i lára, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì mú kí wọ́n nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Kí lohun tí Jésù ṣe yìí kọ́ wa?
9. Kí ni Hébérù 4:15, 16 sọ tó jẹ́ ká gbà pé Àlùfáà Àgbà wa máa ń bá wa kẹ́dùn lóòótọ́?
9 Ka Hébérù 4:15, 16. Ó dá wa lójú pé kò sígbà tí Jésù ò ní bá wa kẹ́dùn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe ẹni tó bá ń báni kẹ́dùn, ó sì máa ń dùn ún tó bá ráwọn tíyà ń jẹ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “kẹ́dùn” túmọ̀ sí kéèyàn máa fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara ẹ̀ wò, kó sì máa gba tiwọn rò. (Tún wo Hébérù 10:34, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà.) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń jìyà ṣe jẹ ẹ́ lógún tó. Kò wo àwọn èèyàn sàn torí ó kàn rò pé ó yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tó fi wò wọ́n sàn ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó wo adẹ́tẹ̀ yẹn sàn, ó lè pinnu pé àtòkèèrè lòun ti máa wò ó sàn. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló sún mọ́ ọkùnrin náà, ó sì fọwọ́ kàn án. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tọ́kùnrin yẹn ti rẹ́ni fọwọ́ kan òun. Bákan náà, nígbà tí Jésù wo adití yẹn sàn, ó mú un kúrò láàárín èrò, ó sì lọ wò ó sàn níbi tí ò sáwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà fi omijé ẹ̀ fọ ẹsẹ̀ Jésù, tó sì fi irun ẹ̀ nù ún, Farisí kan fojú àbùkù wò ó, àmọ́ Jésù gbèjà obìnrin náà. (Mát. 8:3; Máàkù 7:33; Lúùkù 7:44) Jésù ò sá fáwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun, ó ṣàánú wọn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ó dá wa lójú pé bó ṣe ń báwa náà kẹ́dùn nìyẹn.
À Ń FARA WÉ ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ WA LÓNÌÍ
10. Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti ṣe láti ran àwọn adití àtàwọn tí ò ríran lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Torí pé Jésù là ń fara wé, a máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, a máa ń ṣàánú wọn, a sì máa ń bá wọn kẹ́dùn. (1 Pét. 2:21; 3:8) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè la etí adití, a ò sì lè la ojú afọ́jú, a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn fídíò tá a fi ń kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti wà ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún (100) èdè yẹn lọ. Bákan náà, ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìwé táwọn tí kò ríran lè kà, ó sì ti wà ní èdè tó ju ọgọ́ta (60) lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn fídíò tó ní àlàyé fáwọn tí ò ríran ti wà ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ. Àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run ṣe yìí máa ń jẹ́ káwọn adití àtàwọn tí ò ríran di ọ̀rẹ́ Jèhófà àti Jésù Ọmọ ẹ̀.
A ti ṣe àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ
Apá Òsì: A ti ṣe fídíò àwọn adití ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100)
Apá Ọ̀tún: A ti ṣe ìwé àwọn tí ò ríran ní èdè tó ju ọgọ́ta (60) lọ
(Wo ìpínrọ̀ 10)
11. Bíi ti Jésù, báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ onírúurú èèyàn? (Ìṣe 2:5-7, 33) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Onírúurú èèyàn ni ètò Ọlọ́run máa ń ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Ẹ má gbàgbé pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kí gbogbo àwọn tó wá sí àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lè gbọ́ ìhìn rere ‘ní èdè wọn.’ (Ka Ìṣe 2:5-7, 33.) Torí pé Jésù ló ń darí ètò Ọlọ́run, ìyẹn ti jẹ́ ká ṣe àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ làwọn tó ń sọ àwọn kan lára èdè náà. Bí àpẹẹrẹ, North àti South America ni wọ́n ti ń sọ àwọn èdè Amerindian kan, àwọn tó ń sọ àwọn èdè náà ò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Síbẹ̀, ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìwé àti fídíò ní èdè tó lé ní ọgọ́jọ (160) lára àwọn èdè náà kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere. Bákan náà, ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìwé àti fídíò ní èdè tó lé ní ogún (20) lára èdè àwọn ará Roma. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ àwọn èdè yìí ló sì ti wá ń sin Jèhófà.
Apá Òsì: A ti tú àwọn ìwé wa sí èdè àwọn Amerindian tó lé ní ọgọ́jọ (160)
Apá Ọ̀tún: A ti tú àwọn ìwé wa sí èdè tó lé ní ogún (20) lára èdè àwọn ará Roma
(Wo ìpínrọ̀ 11)
12. Àwọn ìrànwọ́ míì wo ni ètò Ọlọ́run máa ń ṣe?
12 Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run ń ṣe ká lè wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn, wọ́n tún ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù. Torí náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ló máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́ nírú àsìkò bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ètò Ọlọ́run tún máa ń kọ́ àwọn ilé ìjọsìn tó mọ níwọ̀n káwọn èèyàn lè kóra jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run níbẹ̀.
ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ WA Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́
13. Kí ni díẹ̀ lára nǹkan tí Jésù máa ń ṣe fún wa?
13 Torí pé Jésù ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, ó máa ń rí i pé a lóhun táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jòh. 10:14; Éfé. 4:7) Nígbà míì, nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa máa ń jẹ́ ká dà bí òwú àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú tàbí esùsú tó ti fọ́. Gbogbo nǹkan lè sú wa tá a bá ń ṣàìsàn tó le, tá a bá láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tàbí tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín àwa àtẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà. Ó lè má rọrùn fún wa láti gbọ́kàn kúrò lórí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa báyìí, ká sì máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ máa rántí pé Jésù mọ ohun tó ò ń bá yí, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Ó máa ṣàánú ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ fún ẹ lágbára lásìkò tí nǹkan tojú sú ẹ. (Jòh. 16:7; Títù 3:6) Bákan náà, Jésù lè lo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà láti fún ẹ níṣìírí, kí wọ́n sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Éfé. 4:8.
14. Kí ló yẹ ká ṣe tí nǹkan bá tojú sú wa?
14 Tí iná ìtara ẹ bá ti ń jó rẹ́yìn tàbí tí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ, máa ronú nípa nǹkan tí Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa ń ṣe. Máa rántí pé kì í ṣe torí kí Jésù lè fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà nìkan ni Jèhófà ṣe rán an wá sáyé, àmọ́ ó fẹ́ kó túbọ̀ mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn aláìpé. Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì torí ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá tàbí torí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, Jésù ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tó tọ́.”—Héb. 4:15, 16.
15. Sọ ohun tó ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
15 Nǹkan míì tí Jésù ń ṣe ni pé ó ń tọ́ àwa èèyàn ẹ̀ sọ́nà ká lè wá àwọn tó ti kúrò nínú ètò Ọlọ́run, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Mát. 18:12, 13) Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Stefano.b Lẹ́yìn ọdún méjìlá (12) tí wọ́n ti mú un kúrò nínú ìjọ, ó pinnu pé òun máa lọ sípàdé. Ó sọ pé: “Nígbà àkọ́kọ́ tí mo lọ sípàdé kò rọrùn fún mi, àmọ́ ó wù mí kí n pa dà sínú ìdílé Jèhófà. Àwọn alàgbà tó bá mi sọ̀rọ̀ jẹ́ kára tù mí. Nígbà míì, ó máa ń dùn mí pé mo fi Jèhófà sílẹ̀, ó sì máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè pa dà wá mọ́. Àwọn alàgbà yẹn máa ń rán mi létí pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì fẹ́ kí n ṣàtúnṣe. Nígbà tí wọ́n gbà mí pa dà, gbogbo ìjọ ló kí èmi àti ìdílé mi káàbọ̀. Nígbà tó yá, ìyàwó mi náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo wa sì jọ ń sin Jèhófà báyìí.” Ẹ wo bí inú Àlùfáà Àgbà wa ṣe ń dùn bó ṣe ń rí bí gbogbo ìjọ ṣe ń ran àwọn tó ti ronú pìwà dà lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà!
16. Kí nìdí tó o fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa ní Àlùfáà Àgbà tó ń bá wa kẹ́dùn?
16 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ lákòókò tí wọ́n nílò ẹ̀ gan-an. Lónìí, ó dá wa lójú pé ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ lásìkò tá a nílò ẹ̀. Tó bá sì di inú ayé tuntun tó máa dé láìpẹ́, ó máa ran àwọn onígbọràn lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run aláàánú, tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì fi Ọmọ rẹ̀ ṣe Àlùfáà Àgbà tó ń bá wa kẹ́dùn!
ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa
a Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa bí Jésù Àlùfáà Àgbà ṣe rọ́pò àlùfáà àgbà àwọn Júù, wo àpilẹ̀kọ náà “Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Jọ́sìn Jèhófà Nínú Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2023 ojú ìwé 26, ìpínrọ̀ 7-9.
b A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.