ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 November ojú ìwé 8-9
  • Ṣé Ó Yẹ Kí N Ṣì Máa Wakọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ó Yẹ Kí N Ṣì Máa Wakọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÓ O ṢE LÈ MỌ̀ BÓYÁ KÓ O ṢÌ MÁA WAKỌ̀
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TÓ MÁA RAN ÀWỌN ARÚGBÓ LỌ́WỌ́
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
  • Bó O Ṣe Lè Dènà Ìjàǹbá Ọkọ̀
    Jí!—2011
  • Aláàbọ̀ Ara—Tí Ó Sì Tún Lè Wakọ̀
    Jí!—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 November ojú ìwé 8-9
Arákùnrin kan tó ti darúgbó jókòó sínú ilé, ó ń wo mọ́tò ẹ̀ látojú wíńdò. Ó mú kọ́kọ́rọ́ mọ́tò náà dání, ó sì ń ro ohun tó máa ṣe.

Ṣé Ó Yẹ Kí N Ṣì Máa Wakọ̀?

ỌJỌ́ pẹ́ tó o ti ń wakọ̀. Ìwọ lo ni mọ́tò náà, ibi tó bá sì wù ẹ́ lo máa ń wà á lọ. Àmọ́, ọkàn àwọn ará ilé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò balẹ̀ mọ́, wọ́n sì fẹ́ kó o ronú sí i bóyá kó o ṣì máa wa mọ́tò tàbí kó o má wà á mọ́. Ọ̀rọ̀ wọn ò yé ẹ rárá, o ò sì mọ ìdí tí ọkàn wọn ò fi balẹ̀.

Ṣé ọ̀rọ̀ ẹ jọ tẹni tá a sọ̀rọ̀ ẹ tán yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o ṣì máa wa mọ́tò tàbí kó o má wà á mọ́?

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, táwọn awakọ̀ bá ti kọjá ọjọ́ orí kan, dókítà gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ṣì kúnjú ìwọ̀n láti máa wakọ̀, kí ìjọba tó lè fún wọn ní ìwé ìwakọ̀ míì. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè yẹn máa ń ṣe ohun tí ìjọba bá sọ. (Róòmù 13:1) Àmọ́, tí kò bá tiẹ̀ sí irú òfin yẹn lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, àwọn nǹkan míì wà tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o ṣì máa wa mọ́tò tàbí kó o má wà á mọ́.

BÓ O ṢE LÈ MỌ̀ BÓYÁ KÓ O ṢÌ MÁA WAKỌ̀

Ìkànnì àjọ National Institute on Aging (NIA) tó ń bójú tó àwọn àgbàlagbà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, tó o bá jẹ́ arúgbó tó ṣì ń wakọ̀, á dáa kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé ó máa ń ṣòro fún mi láti rí àwọn atọ́ka ojú ọ̀nà tàbí ríran dáadáa lálẹ́?

  • Ṣé kì í ṣe pé ara tó ti ń dara àgbà ti mú kó ṣòro fún mi láti yí ọrùn tí mo bá fẹ́ fi dígí ọkọ̀ wo àwọn ibi tí mi ò lè rí?

  • Tí ohun kan bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, ṣé ó máa ń rọrùn fún mi láti tètè tẹ bíréèkì?

  • Ṣé mi ò kì í dá sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ torí pé mi ò lè yára wakọ̀?

  • Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni jàǹbá ọkọ̀ fẹ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí mò ń wakọ̀ tàbí ṣé ọkọ̀ mi ti tẹ̀, tí mo sì ti fi ara ẹ̀ ha torí pé mo fi ń gbá nǹkan?

  • Ṣé ọlọ́pàá ti dá mi dúró rí torí pé mò ń wàwàkuwà?

  • Ṣé mo ti tòògbé rí nígbà tí mò ń wakọ̀?

  • Ṣé kì í ṣe pé mò ń lo àwọn oògùn kan tí ò ní lè jẹ́ kí n wakọ̀ dáadáa?

  • Ṣé àwọn ará ilé mi tàbí àwọn ọ̀rẹ́ mi ti ń sọ fún mí pé mi ò wakọ̀ dáadáa mọ́?

Tí ìdáhùn ẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn ìbéèrè yìí, o lè ṣe àwọn àtúnṣe kan. Bí àpẹẹrẹ, o lè pinnu pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wàá máa wakọ̀, pàápàá lọ́wọ́ alẹ́. Máa ṣàyẹ̀wò ara ẹ déédéé kó o lè mọ̀ bóyá o ṣì ń wakọ̀ dáadáa. O lè bi ará ilé ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan bóyá o ṣì mọ ọkọ̀ wà dáadáa. O tún lè lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe lè wakọ̀ láìséwu. Àmọ́, tí ìdáhùn ẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìbéèrè yìí, á dáa kó o má wakọ̀ mọ́.a

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TÓ MÁA RAN ÀWỌN ARÚGBÓ LỌ́WỌ́

Ẹ lè má mọ̀ pé ẹ ò lè wakọ̀ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Inú yín sì lè má dùn táwọn èèyàn bá sọ fún un yín pé kẹ́ ẹ má wakọ̀ mọ́. Torí náà, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn yín lọ́wọ́ táá jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ bóyá kẹ́ ẹ ṣì máa wakọ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára wọn.

Mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. (Òwe 11:2) Bá a ṣe ń darúgbó, ojú wa, etí wa, iṣan ara wa àtàwọn nǹkan míì lára wa kì í ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan kì í ṣe eré ìdárayá kan mọ́ tí wọ́n bá rí i pé àwọn ti ń dàgbà, ìdí ni pé téèyàn bá ti dàgbà ó lè tètè fara pa. Àwọn tó ń wakọ̀ lè ṣe ohun kan náà. Tẹ́nì kan bá mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó lè pinnu pé òun ò ní wakọ̀ mọ́, kó lè dáàbò bo ara ẹ̀. (Òwe 22:3) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn ará ilé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ bá sọ fún un pé kò yẹ kó wakọ̀ mọ́, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa gbọ́ ohun tí wọ́n bá sọ.—Fi wé 2 Sámúẹ́lì 21:15-17.

Má ṣe ohun táá jẹ́ kó o gbẹ̀mí èèyàn. (Diu. 22:8) Tẹ́nì kan ò bá mọ ọkọ̀ wà dáadáa, ó lè ṣèèyàn léṣe tàbí kó pààyàn. Torí náà, tẹ́nì kan bá mọ̀ pé òun ò lè wakọ̀ dáadáa mọ́ torí àwọn ìdí kan àmọ́ tónítọ̀hún ṣì ń wakọ̀, ó lè pa ara ẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì. Yàtọ̀ síyẹn, tó bá jẹ́ pé òun ló fa jàǹbá ọkọ̀ náà, ó lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.

Tó o bá pinnu pé o ò ní wakọ̀ mọ́, má rò pé àwọn èèyàn á máa fojú yẹpẹrẹ wò ẹ́. Mọ̀ dájú pé Jèhófà máa nífẹ̀ẹ́ ẹ torí pé o mọ̀wọ̀n ara ẹ, o nírẹ̀lẹ̀, o sì ń wá ire àwọn ẹlòmíì. Ó sì ti ṣèlérí pé òun máa bójú tó ẹ, òun á sì tù ẹ́ nínú. (Àìsá. 46:4) Kò ní pa ẹ́ tì láé. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀, kó o lè mọ̀ bóyá kó o má wakọ̀ mọ́.

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Arúgbó Lọ́wọ́

Àwọn ará ilé ẹni tó ti darúgbó tó ṣì ń wakọ̀ ló dáa jù láti gbà á nímọ̀ràn. Tó o bá sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹni náà, tó o sì ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ pé bó ṣe ń wakọ̀ ò dáa, á dáa kó o má kóyán ọ̀rọ̀ wọn kéré. Tó bá ṣeé ṣe, o lè ní kẹ́ni náà gbé ẹ jáde kó o lè rí bó ṣe ń wakọ̀. Tó o bá rí i pé bó ṣe ń wakọ̀ léwu, ó yẹ kó o gbà á nímọ̀ràn. Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, fi ọ̀rọ̀ ro ara ẹ wò. Bákan náà, má kàn án lábùkù, àmọ́ má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Má sọ pé torí àgbàlagbà ni, o ò ní lè sojú abẹ níkòó. Rántí pé ohun tó máa ṣe é láǹfààní lo fẹ́ bá a sọ. Tó o bá fẹ́ gbà á nímọ̀ràn, o lè sọ pé “Kẹ́ ẹ má bàa fara pa, ṣé ẹ rò pé á dáa kẹ́ ẹ ṣì máa wakọ̀?” dípò kó o sọ pé “Bẹ́ ẹ ṣe ń wakọ̀ ò dáa rárá.” Jẹ́ kó rí i pé tó bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó máa ṣe é láǹfààní.

Gbogbo wa la lè ran àwọn arúgbó lọ́wọ́ tí wọ́n bá pinnu pé àwọn ò ní wakọ̀ mọ́. Wọ́n lè máa rò pé àwọn ò lè dá ṣe nǹkan mọ́. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Máa ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. (Òwe 17:17) Má dúró dìgbà tó máa sọ fún ẹ pé kó o gbé òun lọ síbi tóun fẹ́ lọ, torí ó lè máa rò pé òun yọ ẹ́ lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣètò ìgbà tí ìwọ tàbí àwọn míì á fi mọ́tò gbé e lọ síbi tó bá fẹ́ lọ, bóyá tó bá fẹ́ lọ sípàdé, tó fẹ́ lọ wàásù, tó fẹ́ lọ ra nǹkan lọ́jà tàbí tó fẹ́ lọ rí dókítà nílé ìwòsàn. Jẹ́ kó mọ̀ pé òótọ́ lo fẹ́ ràn án lọ́wọ́, ó sì wù ẹ́ kẹ́ ẹ jọ wà pa pọ̀.—Róòmù 1:11, 12.

a Kó o lè mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?” nínú Jí! September 8, 2002.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́