Báwo Làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Máa Ń Ṣe Sáwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Wa Mọ́?
Gbogbo èèyàn la máa ń fi ìfẹ́ àti inúure hàn sí, a kì í sì í fojú pa ẹnikẹ́ni rẹ́. Tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ò bá fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn ẹ̀ mọ́, tàbí tí kò ṣe ẹ̀sìn wa mọ́, a máa ń kàn sí ẹni náà, àá jẹ́ kó mọ̀ pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, àá sì gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run.—Lúùkù 15:4-7.
Láwọn ìgbà míì, tẹ́nì kan bá ṣohun tí kò dáa, wọ́n lè mú un kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:13) Àmọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ ń sin Ọlọ́run dénú, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tètè ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ tó le débi pé wọ́n á mú un kúrò nínú ìjọ. Tí wọ́n bá sì wá pa dà mú un kúrò, àá ṣì máa ṣohun táá jẹ́ kó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kódà àá máa bọ̀wọ̀ fún un bó ṣe yẹ, torí ohun tí Bíbélì sọ pé ká máa ṣe nìyẹn.—Máàkù 12:31; 1 Pétérù 2:17.
Kí ló lè jẹ́ kí wọ́n mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ?
Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé tí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tó sì kọ̀ láti yí pa dà, kí a mú un kúrò nínú ìjọ.a (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Bíbélì jẹ́ ká mọ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a lè kà sí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tó lè jẹ́ kí wọ́n mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ. Àpẹẹrẹ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àgbèrè, ìmutíyó, ìpànìyàn, híhu ìwà ìkà sáwọn mọ̀lẹ́bi tó ń báni gbélé àti olè.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Gálátíà 5:19-21; 1 Tímótì 1:9, 10.
Àmọ́, kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tẹ́nì kan bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì la máa ń mú un kúrò nínú ìjọ. Àwọn alàgbà ìjọb máa kọ́kọ́ gbìyànjú láti pe orí rẹ̀ wálé. (Róòmù 2:4) Wọ́n á sapá láti fi ìwà tútù, sùúrù àti inúure ràn án lọ́wọ́ kó lè rí ibi tó ti ṣàṣìṣe. (Gálátíà 6:1) Èyí máa jẹ́ kí ẹni náà rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, ó sì yẹ kóun ṣàtúnṣe. (2 Tímótì 2:24-26) Táwọn alàgbà bá ṣe gbogbo nǹkan yìí àmọ́ tẹ́ni náà ò yéé hùwà tí Bíbélì sọ pé kò dáa, tí kò sì ronú pìwà dà, wọ́n gbọ́dọ̀ mú onítọ̀hún kúrò nínú ìjọ. Lẹ́yìn náà, àwọn alàgbà máa ṣèfilọ̀ fáwọn ará ìjọ ní ṣókí pé ẹni náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.
Àwọn alàgbà máa ń fi sùúrù àti ìfẹ́ ran ẹni tó hùwà àìdáa lọ́wọ́, kó lè rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, kó sì lè ṣàtúnṣe
Tá a bá mú ẹnì kan tí kò jáwọ́ nínú ìwà burúkú kúrò nínú ìjọ, àǹfààní wo ló wà níbẹ̀? Àkọ́kọ́ ni pé ó máa fi hàn pé ìjọ fara mọ́ ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ìwà mímọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí ìwàkiwà ran àwọn míì tó wà nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:6; 15:33; 1 Pétérù 1:16) Yàtọ̀ síyẹn, irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí ẹni náà jáwọ́ nínú ìwà tó ń hù, kó sì sapá láti yíwà pa dà.—Hébérù 12:11.
Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwọn tá a ti mú kúrò nínú ìjọ?
Bíbélì sọ pé káwa Kristẹni “jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́” pẹ̀lú ẹni tá a ti mú kúrò nínú ìjọ, ó ní ká “má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́ríńtì 5:11) Torí náà, a kì í bá ẹni tí wọ́n ti mú kúrò nínú ìjọ ṣe wọléwọ̀de. Àmọ́ kì í ṣe pé a máa ń pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ tì pátápátá. Àá máa bọ̀wọ̀ fún un bó ṣe yẹ, a ò sì ní sọ pé kó má wá sáwọn ìpàdé wa tó bá fẹ́. Tó bá wá sípàdé, àwọn ará ìjọ lè kì í.c Kódà ó lè sọ fáwọn alágbà pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́ kóun lè pa dà sínú ìjọ.
Àwọn tá a ti mú kúrò nínú ìjọ lè wá sáwọn ìpàdé wa, inú wa sì máa dùn láti rí wọn
Tí ẹnì kan tá a mú kúrò nínú ìjọ bá ní ìyàwó tàbí ọkọ tàbí tó láwọn ọmọ tí kò tíì dàgbà tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Lóòótọ́, ẹni tá a mú kúrò nínú ìjọ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, àmọ́ ìdílé kan náà ṣì ni wọ́n. Torí náà, bó ṣe jẹ́ pé inú ilé kan náà ni wọ́n ṣì jọ ń gbé, wọ́n á máa ṣe bó ṣe yẹ kí tọkọtaya máa ṣe, wọ́n á sì máa bójú tó àwọn ọmọ wọn bó ṣe yẹ.
Ẹni tá a mú kúrò nínú ìjọ lè ní káwọn alàgbà wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ òun, wọ́n á sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n á fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà á nímọ̀ràn tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n á sì fìfẹ́ rọ̀ ọ́ pé kó ronú pìwà dà, kó sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run. (Sekaráyà 1:3) Tó bá yíwà pa dà, tó sì jẹ́ kó hàn pé òun fẹ́ máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì lóòótọ́, a máa gbà á pa dà sínú ìjọ. Ìjọ máa ‘dárí jì í tinútinú, wọ́n á sì tù ú nínú.’ Ohun táwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ṣe nìyẹn nígbà tí ẹnì kan tá a mú kúrò nínú ìjọ ronú pìwà dà.—2 Kọ́ríńtì 2:6-8.
Ohun táwọn tá a mú kúrò nínú ìjọ nígbà kan sọ
Wo ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ lẹ́yìn tá a mú wọn kúrò nínú ìjọ, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run pa dà.
“Nígbà tí mo sọ fáwọn alàgbà pé mo fẹ́ pa dà sínú ìjọ, mo rò pé ṣe ni wọ́n á máa béèrè gbogbo ohun tí mo ti ṣe ní ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi mú mi kúrò nínú ìjọ ni. Àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ o, ṣe ni wọ́n kàn sọ fún mi pé, ‘Bí wàá ṣe máa ṣohun tí Jèhófà fẹ́ báyìí ló ṣe pàtàkì jù.’ Ohun tí wọ́n sọ yẹn jẹ́ kára tù mí gan-an.”—Maria, United States.
“Inú àwọn ará ìjọ dùn gan-an nígbà tí mo pa dà. Ó jẹ́ kí n rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi lóòótọ́. Àwọn ará mi lọ́kùnrin àti lóbìnirin ò fojú àtijọ́ wò mí, wọn ò jẹ́ kí n máa ro àròdùn torí ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn alàgbà náà dúró tì mí, wọ́n tù mí nínú, wọ́n sì jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi.”—Malcom, Sierra Leone.
“Inú mi dùn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn ẹ̀, ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tó ní sí wa ló jẹ́ kó ṣètò pé ká mú ẹni tó bá lè kó ìwà burúkú ran àwọn ará kúrò nínú ìjọ. Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè rò pé ìgbésẹ̀ yẹn ti le jù, àmọ́ ohun tó yẹ ká ṣe ni, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló sì máa ń tibẹ̀ yọ. Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì múra tán láti dárí ji ẹlẹ́sẹ̀ tó bá ronú pìwà dà.”—Sandi, United States.
a Tẹ́lẹ̀, ohun tá a máa ń sọ nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà ni pé a yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Àmọ́ ní báyìí, ṣe la máa ń sọ pé a mú wọn kúrò nínú ìjọ, torí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò nìyẹn.
b Àwọn alàgbà ni àwọn Kristẹni ọkùnrin tó nírìírí, tó máa ń fi Ìwé Mímọ́ kọ́ni. Wọ́n máa ń bójú tó àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì máa ń fún wọn níṣìírí láti ṣe ohun tó dáa. Wọn kì í gba owó fáwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe yìí.—1 Pétérù 5:1-3.
c Láwọn ìgbà míì, ẹnì kan lè kúrò nínú ìjọ, kó sì máa mọ̀ọ́mọ̀ ba ìjọ lórúkọ jẹ́ tàbí kó máa mọ̀ọ́mọ̀ fi ìwà ìbàjẹ́ tó ń hù lọ àwọn míì nínú ìjọ káwọn náà lè máa ṣe ohun tí ò dáa. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ la máa ń tẹ̀ lé, ó ní kí a má “kí” ẹni náà.—2 Jòhánù 9-11.