Àpéjọ tá a ṣe nílùú Indianapolis, ìpínlẹ̀ Indiana,
lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1925
1925—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
ILÉ ÌṢỌ́ January 1, 1925 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwa Kristẹni ń retí ohun pàtàkì kan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún yìí.” Ilé Ìṣọ́ yẹn tún sọ pé: “Kò yẹ káwa Kristẹni máa dara wa láàmú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́dún yìí, torí ìyẹn lè má jẹ́ ká ṣiṣẹ́ tí Jèhófà ní ká máa ṣe.” Kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń retí kó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1925? Báwo sì ni wọ́n ṣe gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń retí ò ṣẹlẹ̀?
OHUN TÍ WỌ́N Ń RETÍ Ò ṢẸLẸ̀
Ọ̀pọ̀ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rò pé ayé máa di Párádísè lọ́dún 1925. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀? Arákùnrin Albert Schroeder, tó di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí nígbà tó yá sọ pé: “Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rò pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró máa lọ sọ́run kí wọ́n lè bá Kristi jọba. Wọ́n tún rò pé Jèhófà máa jí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bí Ábúráhámù, Dáfídì àtàwọn míì dìde kí wọ́n lè di olórí, kí wọ́n sì máa ṣàkóso ayé nínú Ìjọba Ọlọ́run.” Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ohun tí wọ́n ń retí ò ṣẹlẹ̀, torí náà inú wọn ò dùn rárá.—Òwe 13:12.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dun àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí ohun tí wọ́n ń retí ò ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù torí wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe lo ilé iṣẹ́ rédíò láti wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn.
A DÁ ÀWỌN ILÉ IṢẸ́ RÉDÍÒ MÍÌ SÍLẸ̀
Lọ́dún 1924, ètò Ọlọ́run dá ilé iṣẹ́ rédíò WBBR sílẹ̀, ó sì ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò míì sítòsí ìlú Chicago, ìpínlẹ̀ Illinois lọ́dún 1925. Orúkọ tí wọ́n pe ilé iṣẹ́ rédíò náà ni WORD. Ralph Leffler, ìyẹn ẹnjiníà tó to irinṣẹ́ ilé iṣẹ́ rédíò náà pa pọ̀ sọ pé: “Nígbà òtútù táwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ jáde, wọ́n máa ń gbọ́ rédíò WORD lọ́wọ́ alẹ́ láti ibi tó jìnnà réré.” Bí àpẹẹrẹ, ìdílé kan tó ń gbé ìlú Pilot Station, ní ìpínlẹ̀ Alaska tan rédíò wọn, wọ́n sì gbọ́ rédíò náà ketekete nígbà tí ilé iṣẹ́ náà kọ́kọ́ gbóhùn sáfẹ́fẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ibi tí wọ́n ń gbé jìnnà ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) kìlómítà síbi tí ilé iṣẹ́ rédíò náà wà. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ètò orí rédíò náà tán, wọ́n kọ̀wé sáwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn pé ètò náà jẹ́ káwọn túbọ̀ mọ Bíbélì àti Ọlọ́run.
Apá òsì: Òpó tí wọ́n fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò WORD, nílùú Batavia, ìpínlẹ̀ Illinois
Apá ọ̀tún: Arákùnrin Ralph Leffler rèé níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò
Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ December 1, 1925 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi lè gbọ́ rédíò náà láti ibi tó jìnnà gan-an, ó sọ pé: “Ilé iṣẹ́ rédíò WORD wà lára ilé iṣẹ́ rédíò tó ní irinṣẹ́ tó lágbára jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn èèyàn ń gbọ́ ètò orí rédíò náà káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, títí dé orílẹ̀-èdè Cuba àtàwọn ibi tó jìnnà gan-an ní àríwá ìpínlẹ̀ Alaska. Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ò tíì mọ òtítọ́ fẹ́ túbọ̀ mọ Ọlọ́run torí pé wọ́n ń gbọ́ ètò orí rédíò náà.”
Arákùnrin George Naish
Àsìkò yẹn náà làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tún gbìyànjú láti wàásù fáwọn èèyàn lórí rédíò lórílẹ̀-èdè Kánádà. Lọ́dún 1924, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ ilé iṣẹ́ rédíò kan tó ń jẹ́ CHUC sílùú Saskatoon, ní ìpínlẹ̀ Saskatchewan lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ilé iṣẹ́ rédíò yìí wà lára àwọn ilé iṣẹ́ rédíò àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ń gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sáfẹ́fẹ́ ní Kánádà. Nígbà tó di 1925, wọ́n fẹ́ kó ilé iṣẹ́ rédíò náà lọ síbòmíì. Torí náà, Watch Tower Society wá bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó ilé iṣẹ́ rédíò náà, wọ́n sì kó lọ sílé ńlá kan tí wọ́n rà tó ń jẹ́ Regent Building tí wọ́n tún ṣe, ìyẹn gbọ̀ngàn ìṣeré kan nílùú Saskatoon.
Ilé iṣẹ́ rédíò yìí ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere káàkiri ìpínlẹ̀ Saskatchewan. Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú kan tó jìnnà síbi tí ilé iṣẹ́ rédíò yẹn wà, Mrs. Graham gbọ́ ìwàásù orí rédíò náà. Lẹ́yìn náà, ó kọ lẹ́tà pé kí wọ́n fi àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sóun. Arákùnrin George Naish sọ pé, “Bí obìnrin náà ṣe fìtara sọ̀rọ̀ nínú lẹ́tà náà pé ‘Ẹ wá kọ́ wa!’ jẹ́ ká fi ìdìpọ̀ ìwé Studies in the Scriptures ránṣẹ́ sí i.” Kò pẹ́ rárá tí Mrs. Graham fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, kódà títí dé agbègbè tó jìnnà gan-an.
A NÍ ÒYE TUNTUN
Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925 gbé àpilẹ̀kọ pàtàkì kan jáde, àkòrí ẹ̀ ni “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà.” Kí nìdí tí àpilẹ̀kọ yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ó pẹ́ díẹ̀ táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mọ̀ pé Sátánì ní ètò kan. Àwọn áńgẹ́lì burúkú ní ọ̀run, àwọn ẹlẹ́sìn, àwọn oníṣòwò àtàwọn olóṣèlú ayé ló sì para pọ̀ di ètò náà. Àmọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lo àpilẹ̀kọ yìí láti jẹ́ káwọn ará kárí ayé mọ̀ pé Jèhófà náà ní ètò kan tó yàtọ̀ pátápátá sí ètò Sátánì, àwọn tó wà nínú ètò náà ò sì fara mọ́ ètò Sátánì. (Mát. 24:45) Bákan náà, ẹrú olóòótọ́ ṣàlàyé pé Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914 nígbà tí ‘ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run.’ Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ló bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ jagun yìí, wọ́n lé wọn sáyé, wọn ò sì lè pa dà sọ́run mọ́.—Ìfi. 12:7-9.
Àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò fara mọ́ òye tuntun yìí. Torí náà, àpilẹ̀kọ náà gbà wọ́n níyànjú pé: “Tí àwọn kan lára àwọn tó ń ka Ilé Ìṣọ́ ò bá fara mọ́ òye tuntun yìí, á dáa kí wọ́n fi sùúrù dúró de Olúwa, kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì máa fòótọ́ inú sìn ín nìṣó.”
Arákùnrin Tom Eyre tó ń gbé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó jẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri (aṣáájú-ọ̀nà là ń pè wọ́n báyìí), sọ bó ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí wọ́n ka àpilẹ̀kọ náà, ó ní: “Inú àwọn ará dùn gan-an bí ètò Ọlọ́run ṣe ṣàlàyé Ìfihàn orí 12. Torí a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run, inú wa dùn gan-an láti sọ ìròyìn ayọ̀ yìí fáwọn èèyàn. Ó jẹ́ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ṣe nǹkan ńlá fáwọn èèyàn ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”
WỌ́N Ń WÀÁSÙ NÍPA JÈHÓFÀ
Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa Àìsáyà 43:10 tó sọ pé: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni Jèhófà wí, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’” Ṣáájú ọdún 1925, a kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí nínú àwọn ìwé wa. Àmọ́ lọ́dún 1925, nǹkan yí pa dà, kódà ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ mọ́kànlá (11) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ló sọ̀rọ̀ nípa Àìsáyà 43:10 àti 12!
Níparí oṣù August 1925, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ kan nílùú Indianapolis, ìpínlẹ̀ Indiana, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Joseph F. Rutherford kọ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó fi kí àwọn èèyàn káàbọ̀ sọ pé: “A wá sí àpéjọ yìí láti gba okun látọ̀dọ̀ Olúwa ká lè pa dà máa fìtara wàásù, ká sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀.” Jálẹ̀ àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́jọ náà, wọ́n fún àwọn tó wá síbẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n máa wàásù nípa Jèhófà ní gbogbo ìgbà.
Lọ́jọ́ Sátidé, August 29, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ẹ Jára Mọ́ṣẹ́.” Nínú àsọyé náà, ó tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì, ó ní: “Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé . . . : ‘Ẹ̀yin ni í ṣe ẹlẹ́rìí mi . . . Èmi ni Ọlọ́run.’ Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ lóhùn tó lágbára pé: ‘Ẹ gbé ọ̀págun ró fún àwọn ènìyàn.’ Kò sí ẹlòmíì láyé tó lè gbé ọ̀págun tàbí àmì ró fún àwọn èèyàn, àfi àwọn [èèyàn rẹ̀] tí wọ́n ní ẹ̀mí Olúwa tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀.”—Àìsá. 43:12; 62:10, Bíbélì Mímọ́.
Ìwé ìléwọ́ Iṣẹ́ Ìrètí Tí À Ń Jẹ́
Lẹ́yìn tí Arákùnrin Rutherford parí àsọyé náà, àwọn tó wà ní àpéjọ náà tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Iṣẹ́ Ìrètí Tí À Ń Jẹ́.” Wọ́n sọ nínú ìpinnu náà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú “àlàáfíà, oúnjẹ rẹpẹtẹ, ìlera pípé, ìyè àìnípẹ̀kun, òmìnira àti ayọ̀ ayérayé wá.” Wọ́n túmọ̀ ìpinnu yìí sí oríṣiríṣi èdè, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé ìléwọ́. Nǹkan bí ogójì (40) mílíọ̀nù ìwé náà ni wọ́n fáwọn èèyàn.
Ó ṣì máa pẹ́ díẹ̀ káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó yí orúkọ wọn pa dà sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, torí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ káwọn túbọ̀ máa wàásù.
A PA DÀ LỌ SỌ́DỌ̀ ÀWỌN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ ÌHÌN RERE
Bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń pọ̀ sí i kárí ayé, wọ́n gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Lẹ́yìn tí wọ́n fáwọn èèyàn ní ìwé ìléwọ́ náà, Iṣẹ́ Ìrètí Tí À Ń Jẹ́, ìwé Bulletina sọ pé: “Ẹ ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n gba ìwé ìléwọ́ náà, Iṣẹ́ Ìrètí Tí À Ń Jẹ́, àmọ́ tá ò fún ní ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Ìwé Bulletin tó jáde ní January 1925 sọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí nípa Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nílùú Plano, ní ìpínlẹ̀ Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Ó yà wá lẹ́nu gan-an pé àwọn èèyàn fetí sílẹ̀ dáadáa láwọn ìpínlẹ̀ tá a ti máa ń wàásù lọ́pọ̀ ìgbà ju àwọn ìpínlẹ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ìlú kékeré kan wà tá a ti wàásù nígbà márùn-ún lọ́dún mẹ́wàá tó kọjá. . . . Àmọ́ láìpẹ́ yìí, Arábìnrin Hendrix àti ìyá mi pa dà lọ síbẹ̀, wọ́n sì fáwọn èèyàn ní ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”
Lórílẹ̀-èdè Panama, arákùnrin kan tó ń pín ìwé wa kiri sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò fetí sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n lé mi kúrò nílé wọn ló fara balẹ̀ gbọ́ mi nígbà tí mo pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kejì tàbí lẹ́ẹ̀kẹta. Nǹkan tí mo ṣe jù lọ́dún yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ni pé mo pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí mo ti bá sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, inú mi sì dùn pé àwọn kan lára wọn fetí sílẹ̀ dáadáa.”
ÀWỌN NǸKAN TÁ A MÁA ṢE LỌ́DÚN TÓ TẸ̀ LÉ E
Nínú lẹ́tà tí wọ́n máa ń kọ lọ́dọọdún sí àwọn tó ń pín ìwé wa kiri, Arákùnrin Rutherford sọ àwọn ohun tí wọ́n ṣe lọ́dún yẹn, ó sì tún sọ ohun tí wọ́n máa ṣe lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Ó sọ pé: “Lọ́dún 1925 yìí, ẹ ti sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tí ìbànújẹ́ sorí wọn kodò. Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe yìí sì ti fún yín láyọ̀ gan-an . . . Àmọ́ lọ́dún tó ń bọ̀, ẹ máa láǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, ẹ̀ẹ́ sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. . . . Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa yin Ọlọ́run wa àti Ọba wa.”
Bí ọdún 1925 ṣe ń parí lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí wọ́n ṣe máa mú kí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn tóbi sí i. Torí náà, lọ́dún 1926, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọn ò ṣerú ẹ̀ rí nínú ètò Ọlọ́run.
Ìgbà tí wọ́n ń kọ́lé ètò Ọlọ́run lọ́wọ́ ní òpópónà Adams, nílùú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lọ́dún 1926
a Ìwé Ìpàdé—Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni là ń pè é báyìí.