Ìtọ́ni fún Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
1. Àwọn ìtọ́ni tó wà nínú ìwé yìí á ran gbogbo àwọn tó níṣẹ́ ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́wọ́. Ẹ ka àwọn ìtọ́ni tó wà fún iṣẹ́ yín, èyí tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àti èyí tó wà nínú ìwé yìí kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í múra iṣẹ́ yín. Ó yẹ káwọn alàgbà fún gbogbo àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n ṣe tán láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Àwọn míì tó bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé náà lè ṣiṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, tí wọ́n bá fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wọn. Tí ẹnì kan tí kì í ṣe akéde bá fẹ́ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́, kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ẹni náà jíròrò àwọn ohun tó máa ṣe kó lè kúnjú ìwọ̀n, kó sì jẹ́ kó mọ̀ tó bá kúnjú ìwọ̀n. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ẹni náà jíròrò níṣojú ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (tàbí níṣojú òbí rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà). Àwọn ohun kan náà tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi náà là ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́.—od orí 8 ìpínrọ̀ 8.
Ọ̀RỌ̀ ÌBẸ̀RẸ̀
2. Ìṣẹ́jú kan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn orin àti àdúrà, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sọ ohun táá mú kí àwùjọ fojú sọ́nà láti gbádùn ìpàdé náà. Àwọn kókó tó ṣe pàtàkì tó máa ṣe ìjọ láǹfààní jù ni kó mẹ́nu bà.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
3. Àsọyé: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Àkòrí àsọyé yìí àtàwọn kókó pàtàkì méjì sí mẹ́ta máa ń wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ní ọ̀sẹ̀ tá a bá bẹ̀rẹ̀ ìwé Bíbélì tuntun, a máa wo fídíò tó sọ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì náà. Olùbánisọ̀rọ̀ lè sọ bí ohun tó wà nínú fídíò náà ṣe tan mọ́ àkòrí àsọyé náà. Àmọ́ ṣá o, kó rí i pé òun bójú tó àwọn kókó tó wà nínú ìwé ìpàdé náà. Ó tún yẹ kó fi àwòrán tó wà níbẹ̀ ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì náà. Ó tún lè tọ́ka sí àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde míì, tó bá ṣáà ti bá àwọn kókó tó wà nínú ìwé ìpàdé náà mu.
4. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Apá yìí jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn tí kò ní ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ìparí. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó o. Kó bi àwùjọ láwọn ìbéèrè méjèèjì tó wà nínú ìwé ìpàdé. Bákan náà, òun ló máa pinnu bóyá a máa ka ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ tàbí a ò ní kà á. Kí àwọn tó máa dáhùn ní apá yìí ṣe bẹ́ẹ̀ láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀.
5. Bíbélì Kíkà: Ìṣẹ́jú mẹ́rin. Ọkùnrin ni kó ṣiṣẹ́ yìí. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ka ibi tá a yàn fún un láìsí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìparí. Kí alága ìpàdé máa ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ láti kàwé bó ṣe yẹ, lọ́nà tó yéni yékéyéké, tó já geere, kí wọ́n sì tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó yẹ. Kó jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa yí ohùn pa dà bó ṣe tọ́, bí wọ́n á ṣe máa dánu dúró níbi tó yẹ, tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn. Nítorí pé àwọn ẹsẹ tá a yàn fún Bíbélì kíkà máa ń gùn jura lọ, kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ronú nípa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe mọ̀wé kà tó kó tó yan iṣẹ́ fún un.
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
6. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. A dìídì ṣe apá yìí kó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù, kí ọ̀nà tá à ń gbà fọ̀rọ̀ wérọ̀, bá a ṣe ń wàásù àti bá a ṣe ń kọ́ni lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà lè ṣiṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ṣiṣẹ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ tá a mú látinú ìwé Kíkọ́ni tàbí nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, èyí tá a kọ sínú àkámọ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ tá a yàn fún un nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Nígbà míì, apá tó jẹ́ ìjíròrò lè wà nínú ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó bójú tó iṣẹ́ yẹn.—Wo ìpínrọ̀ 15 nípa bá a ṣe máa bójú tó apá tó bá jẹ́ ìjíròrò.
7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. Àmọ́ tí ọkùnrin bá fẹ́ lo obìnrin tàbí tí obìnrin bá fẹ́ lo ọkùnrin, kó jẹ́ ara ìdílé ẹni náà. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró.—Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ohun tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa sọ àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, wo ìpínrọ̀ 12 àti 13.
8. Pa Dà Lọ: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. (km 5/97 ojú ìwé 2) Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ ohun tá a lè sọ tá a bá pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tá a ti bá sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀.—Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ohun tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa sọ àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, wo ìpínrọ̀ 12 àti 13.
9. Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn: Ẹ lè yan iṣẹ́ yìí fún ọkùnrin tàbí obìnrin. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. (km 5/97 ojú ìwé 2) Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ wọn lórí ìjókòó tàbí lórí ìdúró. Tó bá jẹ́ àṣefihàn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ lọ́wọ́ ni iṣẹ́ tí wọ́n fún ẹ, kò ní sí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ ìparí àyàfi tó bá jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn kókó ẹ̀kọ́ yẹn ni wọ́n ní kó o ṣiṣẹ́ lé. Kò pọn dandan kí á ka gbogbo ìpínrọ̀ náà jáde nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò burú láti ṣe bẹ́ẹ̀.
10. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́: Tí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ àsọyé, ọkùnrin ni kó ṣe é. Tó bá jẹ́ àṣefihàn, ọkùnrin tàbí obìnrin lè ṣe é. Kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ọkùnrin jẹ́ ọkùnrin, kí olùrànlọ́wọ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ obìnrin sì jẹ́ obìnrin. Àmọ́ tí ọkùnrin bá fẹ́ lo obìnrin tàbí tí obìnrin bá fẹ́ lo ọkùnrin, kó jẹ́ ara ìdílé ẹni náà. Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ fọgbọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà fún apá yìí lọ́nà tó ṣe kedere, kó sì lo àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a tọ́ka sí. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ló máa pinnu bóyá òun máa mẹ́nu ba ìtẹ̀jáde tá a ti mú àwọn ìsọfúnni tá a tọ́ka sí nígbà tó bá ń ṣe iṣẹ́ yìí.
11. Àsọyé: Àsọyé fún ìjọ ni kí apá yìí jẹ́, ọkùnrin sì ni kó ṣe é. Tá a bá gbé àsọyé náà ka kókó kan nínú àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sọ bí a ṣe lè lo àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣàlàyé ìgbà tá a lè lo ẹsẹ Bíbélì kan, ìtumọ̀ ẹ àti bá a ṣe lè mú kí ẹnì kan ronú lórí ẹ̀. Tá a bá gbé àsọyé náà ka orí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sọ bá a ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ náà nígbà tá a bá ń wàásù. Ó lè lo àpẹẹrẹ tó wà ní kókó kìíní ẹ̀kọ́ náà tàbí ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà.
12. Ohun Tí Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Sọ: Ìsọfúnni tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e wà fún iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tá a pè ní “Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa” àti “Pa Dà Lọ.” Àfojúsùn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ni láti sọ òtítọ́ Bíbélì kan tó rọrùn lóye fún ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀, kó sì sọ ohun tó máa bá ẹni náà jíròrò nígbà tó bá pa dà lọ, àyàfi tí ìtọ́ni tó wà fún ìpàdé bá ní kó ṣe nǹkan míì. Kí ọ̀rọ̀ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bágbàmu, kó sì jẹ́ èyí tó máa wúlò ní àdúgbò yín. Ó lè pinnu bóyá kóun lo ìtẹ̀jáde tàbí fídíò èyíkéyìí tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Dípò kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kàn há iṣẹ́ wọn sórí lásán, ńṣe ni kó jẹ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀, kí wọ́n fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wọ́n lógún, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gangan.
13. Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀: Kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un lọ́nà tó bá bí nǹkan ṣe máa ń rí ládùúgbò yín mu. Bí àpẹẹrẹ:
(1) Ilé-dé-Ilé: Èyí ni wíwàásù láti ilé dé ilé. Yálà lójúkojú, lórí fóònù, ká kọ lẹ́tà àti ká pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
(2) Ìwàásù Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà: Èyí dá lórí bá a ṣe lè lo àǹfààní ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ láti jẹ́rìí fún àwọn tá à ń bá pàdé. Ẹ lè jíròrò kókó kan látinú Bíbélì pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ pàdé níbi iṣẹ́, ní ilé ìwé, ládùúgbò, nínú ọkọ̀ èrò àti níbòmíì.
(3) Wíwàásù Níbi Térò Pọ̀ Sí: Èyí ni iṣẹ́ ìwàásù níbi àtẹ ìwé, níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, ní òpópónà, láwọn ibi ìgbafẹ́, ibi ìgbọ́kọ̀sí àti láwọn ibòmíì táwọn èèyàn máa ń wà.
14. Bá A Ṣe Máa Lo Àwọn Fídíò àti Àwọn Ìwé Wa: Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lè yàn láti lo fídíò tàbí ìtẹ̀jáde kan, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Tí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ní fídíò tàbí tó yàn láti lò ó, kó nasẹ̀ fídíò náà, kó sì ṣàlàyé ẹ̀, ṣùgbọ́n kí wọ́n má ṣe wò ó.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
15. A máa fi orin bẹ̀rẹ̀ apá yìí. Lẹ́yìn náà, a máa ṣe iṣẹ́ kan tàbí méjì, ó sì máa gba ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15). Apá yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó ń fẹ́ àbójútó lẹ fẹ́ jíròrò, alàgbà ni kó ṣe é. Tó bá jẹ́ pé ìjíròrò ni apá yìí, olùbánisọ̀rọ̀ lè béèrè àwọn ìbéèrè míì láfikún sí àwọn ìbéèrè tó wà fún iṣẹ́ náà. Kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ má gùn, kí àkókò lè tó láti mú kókó ọ̀rọ̀ jáde, kí àwùjọ sì lóhùn sí i. Tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò bá wà nínú iṣẹ́ náà, á dáa kí ẹni tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ̀rọ̀ látorí pèpéle, tó bá ṣeé ṣe.
16. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: Ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú. Alàgbà tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. (Tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó nínú ìjọ yín, ẹ lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.) Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n láti darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Àwọn tá a bá yàn gbọ́dọ̀ lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́nà tó nítumọ̀, kí wọ́n má kọjá àkókò, kí wọ́n mú kí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ẹ̀kọ́ náà ṣe kedere, kí wọ́n sì jẹ́ káwọn ará mọ bí wọ́n á ṣe fi àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì náà sílò. Àwọn tá a bá yàn láti darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ á rí àwọn ìlànà tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó dára láti gbà darí apá tó ní ìbéèrè àti ìdáhùn. (w23.04 ojú ìwé 24, àpótí) Kò pọn dandan kẹ́ ẹ fa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò gbogbo kókó tó wà ní apá tá a yàn fún ọ̀sẹ̀ náà. Tó bá ṣeé ṣe, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ náà sì ni kó máa kàwé. Tí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ní kí ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ dín àkókò tó yẹ kó fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀ kù, ọwọ́ ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ló kù sí láti mọ bó ṣe máa dín àkókò kù. Ó lè pinnu pé a ò ní ka àwọn ìpínrọ̀ kan.
Ọ̀RỌ̀ ÌPARÍ
17. Ìṣẹ́jú mẹ́ta. Alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì táá ran ìjọ lọ́wọ́. Bí àkókò bá ṣe wà sí, ó lè ní kí àwọn ará sọ ohun tí wọ́n kọ́. Á sì tún sọ ohun tá a máa kọ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Tí àkókò bá sì wà, ó lè ka orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó máa níṣẹ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Nínú ọ̀rọ̀ ìparí ni alága ìpàdé ti máa ṣe ìfilọ̀ tàbí ka lẹ́tà tó pọn dandan, àyàfi tẹ́ ẹ bá gba ìtọ́ni míì. Ẹ má ṣèfilọ̀ àwọn ohun tá a máa ń ṣe látìgbàdégbà, bí ètò fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé lórí pèpéle. Pátákó ìsọfúnni ni kẹ́ ẹ lẹ̀ wọ́n mọ́. Tí àkókò tó wà fún ọ̀rọ̀ ìparí kò bá ní tó láti ṣe ìfilọ̀ tàbí ka lẹ́tà, kí alága sọ fún àwọn arákùnrin tó níṣẹ́ ní apá Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni pé kí wọ́n dín àkókò tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ wọn kù. (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 19.) Kẹ́ ẹ fi orin àti àdúrà parí ìpàdé náà.
ÌṢÍRÍ ÀTI ÌMỌ̀RÀN
18. Tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan bá ṣiṣẹ́ rẹ̀ tán, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lo ìṣẹ́jú kan péré láti gbóríyìn fún un, kó sì fún un nímọ̀ràn tó dá lórí kókó ẹ̀kọ́ tá a ní kó ṣiṣẹ́ lé. Nígbà tí alága bá ń pe ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan láti wá ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò ní sọ kókó ẹ̀kọ́ tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà bá parí iṣẹ́ rẹ̀, tí alága sì ti gbóríyìn fún un, ó lè sọ kókó ẹ̀kọ́ tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣiṣẹ́ lé lórí. Kó sọ ìdí tó fi sọ pé ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe dáadáa lórí kókó yẹn tàbí kó sọ ìdí tó fi yẹ kó fún kókó náà láfiyèsí àti bó ṣe lè ṣe é. Kí alága ìpàdé ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Alága ìpàdé tún lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó míì nínú àṣefihàn náà tó mọ̀ pé á ṣe ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà tàbí àwùjọ láǹfààní. Nígbà míì, ó lè pọn dandan pé kí alága tún bá ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tàbí lásìkò míì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí alága lo ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, ìwé Kíkọ́ni tàbí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láti jẹ́ kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà mọ bó ṣe lè sunwọ̀n sí i lórí kókó ẹ̀kọ́ tí wọ́n yàn fún un tàbí láwọn apá ibòmíì.—Wo àlàyé tó wà ní ìpínrọ̀ 19, 24, àti 25 fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ojúṣe alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti ti olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn.
ÀKÓKÒ
19. Ẹ má ṣe kọjá àkókò tá a yàn fún apá kọ̀ọ̀kan, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ náà má ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò tá a yàn fún apá kọ̀ọ̀kan ti wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, tó o bá ti parí gbogbo kókó tó o fẹ́ jíròrò kí àkókò ẹ tó pé, kò pọn dandan kó o fa iṣẹ́ ẹ gùn kó o lè lo gbogbo àkókò ẹ tán. Tí apá èyíkéyìí nínú ìpàdé náà bá kọjá àkókò tá a yàn fún un, kí alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn fún ẹni tó ṣiṣẹ́ náà ní ìmọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. (Wo ìpínrọ̀ 24 àti 25.) Kí ìpàdé náà, látì ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, títí kan orin àti àdúrà, má ṣe kọjá wákàtí kan àti ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta (45).
ÌBẸ̀WÒ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ
20. Nígbà tẹ́ ẹ bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ni kẹ́ ẹ tẹ̀ lé. Àmọ́, ẹ fi ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn ọlọ́gbọ̀n (30) ìṣẹ́jú tí alábòójútó àyíká máa sọ rọ́pò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ ní apá Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni. Kẹ́ ẹ tó gbọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn, alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ṣe àtúnyẹ̀wò ìpàdé ọjọ́ yẹn, á sì fojú àwùjọ sọ́nà fún ohun tẹ́ ẹ máa gbádùn lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, á ṣe àwọn ìfilọ̀ tó bá pọn dandan, á sì ka àwọn lẹ́tà tó bá yẹ. Lẹ́yìn náà, á pe alábòójútó àyíká sórí pèpéle. Tí alábòójútó àyíká bá parí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, òun ló máa yan orin tẹ́ ẹ máa fi parí ìpàdé. Tó bá fẹ́, ó lè ní kí arákùnrin míì wá gbàdúrà ìparí. Kò ní sí kíláàsì kejì ní ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Àwùjọ tó bá ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí èdè tí ìjọ yín fi ń ṣe ìpàdé lè ṣe ìpàdé tiwọn lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò yín. Àmọ́, kí àwùjọ náà dara pọ̀ mọ́ yín kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn alábòójútó àyíká.
Ọ̀SẸ̀ ÀPÉJỌ ÀYÍKÁ TÀBÍ TI AGBÈGBÈ
21. Ẹ ò ní ṣe ìpàdé ìjọ ní ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè. Ẹ rán àwọn ará létí pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ àwọn apá ìpàdé ọ̀sẹ̀ yẹn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí káwọn ìdílé jíròrò ẹ̀ pa pọ̀.
Ọ̀SẸ̀ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
22. Tí Ìrántí Ikú Kristi bá bọ́ sí àárín ọ̀sẹ̀, kò ní sí Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lọ́sẹ̀ yẹn.
ALÁBÒÓJÚTÓ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́
23. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló máa yan alàgbà kan tó máa jẹ́ alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ojúṣe rẹ̀ ni láti rí i pé ìpàdé yìí lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó sì rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú ìwé yìí. Kí òun àti olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn máa kàn sí ara wọn látìgbàdégbà. Tí Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ bá ti dé, kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tètè yan gbogbo iṣẹ́ tó wà ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ fún oṣù méjì tó wà nínú ìwé ìpàdé. Òun ló máa yan àwọn iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àwọn iṣẹ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àti ẹni tó máa jẹ́ alága ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ lára àwọn tí ìgbìmọ̀ alàgbà fọwọ́ sí. (Wo ìpínrọ̀ 3-16 àti 24.) Kó tó yan iṣẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, kó ronú nípa ọjọ́ orí, ìrírí àti bí wọ́n ṣe ní òmìnira ọ̀rọ̀ tó nípa ohun tí ọ̀rọ̀ wọn dá lé. Kó ṣe bẹ́ẹ̀ náà tó bá ń pín àwọn iṣẹ́ yòókù. Ó yẹ kí àwọn tó máa níṣẹ́ nípàdé ti mọ̀ pé àwọn níṣẹ́ ó kéré tán ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ wọn. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lo Ìwé Iṣẹ́ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni (S-89) láti fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ níṣẹ́. Kí alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ wà lójú pátákó ìsọfúnni. Ìgbìmọ̀ alàgbà lè yan alàgbà míì tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti máa ràn án lọ́wọ́. Àmọ́ o, alàgbà nìkan ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó máa yan àwọn iṣẹ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́.
ALÁGA ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́
24. Alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lá máa ṣe alága Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó nínú ìjọ yín, ẹ lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.) Kó múra ọ̀rọ̀ tó máa fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àtèyí tó máa fi parí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, òun ló máa pe àwọn tí iṣẹ́ kàn láti ṣe iṣẹ́ wọn. Òun náà lè ṣe àwọn iṣẹ́ kan lọ́jọ́ tó ṣe alága, tí àwọn alàgbà kò bá pọ̀ tó, pàápàá àwọn apá tó bá jẹ́ pé fídíò nìkan la fẹ́ wò, tí kò sì ní ìjíròrò. Kí ọ̀rọ̀ tó máa sọ lẹ́yìn tí ẹnì kan bá parí iṣẹ́ ṣe ṣókí. Ìgbìmọ̀ alàgbà ló máa yan àwọn alàgbà tó kúnjú ìwọ̀n láti máa ṣe alága ìpàdé. Látìgbàdégbà làwọn alàgbà tá a yàn yìí á máa ṣe alága ìpàdé Ìgbésí Ayé. Tó bá gbà bẹ́ẹ̀, alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lè ṣe alága ìpàdé ju àwọn alàgbà míì tí wọ́n ti yàn lọ. Tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá gbà pé alàgbà kan mọ̀ọ̀yàn kọ́ débi táá fi máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, á jẹ́ pé alàgbà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alága ìpàdé náà. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi sọ́kàn pé alàgbà tó máa ṣe alága ìpàdé ní láti mọ bí a ṣe ń fìfẹ́ gbóríyìn fún àwọn tó ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kó sì fìfẹ́ gbà wọ́n nímọ̀ràn nípa àwọn ibi tó yẹ kí wọ́n ti sunwọ̀n sí i, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ojúṣe rẹ̀ ni láti rí i pé ìpàdé parí lásìkò. (Wo ìpínrọ̀ 17 àti 19.) Bí alága bá fẹ́, tí àyè rẹ̀ sì wà, ẹ lè ṣètò makirofóònù kan tó dá dúró sí apá kan pèpéle, látibẹ̀ á máa pe àwọn tó níṣẹ́, tí àwọn yẹn á sì ti wà níbi tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ tá a ṣètò fún wọn. Tí alága ìpàdé bá fẹ́, ó lè jókòó sídìí tábìlì kan lórí pèpéle nígbà Bíbélì kíkà àti ní apá Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù. Ìyẹn ò ní jẹ́ ká fàkókò ṣòfò.
OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN
25. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí nímọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Èyí kan apá tí wọ́n bá bójú tó nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àsọyé fún gbogbo èèyàn, dídarí tàbí kíkàwé nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ.—Wo ìpínrọ̀ 19.
KÍLÁÀSÌ KEJÌ
26. Bí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu bóyá kẹ́ ẹ ní kíláàsì kejì. Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan ẹni tó tóótun fún kíláàsì kejì yìí; ó máa dáa kó jẹ́ alàgbà. Àmọ́ níbòmíì, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun lè ṣe iṣẹ́ náà. Kí ìgbìmọ̀ alàgbà yan ẹni táá máa bójú tó iṣẹ́ yìí, kí wọ́n sì pinnu bóyá ẹnì kan lá máa ṣe é tàbí ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lá máa ṣe é. Àlàyé tá a ṣe ní ìpínrọ̀ 18 ni kí ẹni náà tẹ̀ lé. Tẹ́ ẹ bá ní kíláàsì kejì, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti parí apá tá a pè ní Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì ní abala Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní káwọn tó máa ṣe iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kọjá síbi tí wọ́n á ti ṣe é. Kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ pa dà lẹ́yìn iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó gbẹ̀yìn.
FÍDÍÒ
27. A ti ṣètò àwọn fídíò kan tí àá máa lò nínú ìpàdé yìí. Ẹ máa rí àwọn fídíò náà lórí JW Library®, ẹ lè fi oríṣiríṣi ẹ̀rọ wo àwọn fídíò náà.
© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
S-38-YR 10/25