Sísin Ọlọ́run ní Bèbè Ikú
BÍ JOÃO MANCOCA ṢE SỌ Ọ́
Ní June 25, 1961, àwọn sójà já wọ ibi tí a ti ń ṣèpàdé Kristẹni ní Luanda, Àǹgólà. Wọ́n kó ọgbọ̀n lára wa lọ dà sẹ́wọ̀n, wọ́n sì lù wá lálùbami débi pé ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kan ò kọjá kí àwọn sójà náà máà wá yọjú wò wá bóyá ẹnikẹ́ni lára wa ti kú. A gbọ́ tí àwọn kan lára wọ́n ń sọ pé ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run tòótọ́ ni Ọlọ́run wa, nítorí pé kò sẹ́ni tó kú nínú wa.
LẸ́YÌN lílù tí wọ́n lù wá yẹn, oṣù márùn-ún ni mo fi wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n São Paulo. Lẹ́yìn náà, ọdún mẹ́sàn-án gbáko ni wọ́n fi ń gbé mi láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan lọ sí òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń lù mí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan dù mí, wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní ọdún 1970, wọ́n tún wá mú mi, lọ́tẹ̀ yìí, àgọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń kú sí ní São Nicolau, tó ń jẹ́ Bentiaba nísinsìnyí, ni wọ́n lọ tì mí mọ́. Ọdún méjì ààbọ̀ ni mo lò níbẹ̀.
Ẹ lè máa ṣe kàyéfì pé kí ló dé tí wọ́n ṣe fi èmi tó jẹ́ aráàlú tó ń pòfin mọ́ sẹ́wọ̀n nítorí pé mo ń sọ àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ nínú Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn tí èyí sì tún jẹ́ níbi tí èmi fúnra mi ti kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
Mo Láǹfààní Ẹ̀kọ́ Tó Gbámúṣé
October 1925 ni wọ́n bí mi nítòsí ìlú Maquela do Zombo, ní àríwá Àǹgólà. Nígbà tí bàbá mi kú ní ọdún 1932, màmá mi mú mi lọ gbé lọ́dọ̀ àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ní Belgian Congo (tó ń jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Kóńgò nísinsìnyí). Kì í ṣe ohun tó tọkàn rẹ̀ wá láti ṣe gan-an nìyẹn, ṣùgbọ́n kò lówó tó fi lè gbọ́ bùkátà mi.
Ìjọ Onítẹ̀bọmi ni arákùnrin ìyá mi ń lọ, ó sì ń fún mi níṣìírí láti máa ka Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo di mẹ́ńbà ìjọ rẹ̀, ohun tí mo ń kọ́ níbẹ̀ kò pa òùngbẹ tó ń gbẹ mí nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni kò wú mi lórí láti sin Ọlọ́run. Àmọ́, arákùnrin ìyá mi rán mi lọ sílé ìwé, ó sì rí sí i pé mo kàwé débi téèyàn ń kàwé dé. Ọ̀kan lára ohun tí mo kọ́ ni èdè Faransé. Bí àkókò ti ń lọ, mo tún kọ́ èdè Potogí. Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ìwé, mo rí iṣẹ́ bí amojú ẹ̀rọ ìtẹwáyà-ránṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò ìjọba ní Léopoldville (tó ń jẹ́ Kinshasa nísinsìnyí). Nígbà tí mo pé ọmọ ogún ọdún, mo gbé Maria Pova níyàwó.
Àjọ Ìsìn Tuntun Kan
Lọ́dún 1946 yẹn kan náà, aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin Ìjọ Onítẹ̀bọmi kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà, tó sì kàwé dáadáa bẹ̀rẹ̀ sí darí ayé mi. Ó hára gàgà láti rí i pé àwọn èèyàn tí ń sọ èdè Kikongo tí wọ́n ń gbé àríwá Àǹgólà kàwé, kí ayé wọ́n sì gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ó ra ìwé kékeré The Kingdom, the Hope of the World, tí a tú sí èdè Potogí, èyí tí Watch Tower Bible and Tract Society ṣe, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń pín kiri.
Aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin yẹn túmọ̀ ìwé kékeré yìí sí èdè Kikongo, ó sì ń fi darí ìjíròrò Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ àwa ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà tí ń ṣiṣẹ́ ní Belgian Congo. Bí àkókò ti ń lọ, aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin náà kọ̀wé sí orílé iṣẹ́ Watch Tower Society ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó sì rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i gbà. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tó ń kọ́ wa dà pọ̀ mọ́ ohun tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Nítorí náà, mi ò mọ ìyàtọ̀ yékéyéké láàárín ìsìn Kristẹni tòótọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.
Àmọ́, mo ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti Watch Tower Society yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ ní Ìjọ Onítẹ̀bọmi. Fún àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Bíbélì fi ọwọ́ pàtàkì mú orúkọ Ọlọ́run náà, Jèhófà, àti pé lọ́nà tó bá a mu, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Sáàmù 83:18; Aísáyà 43:10-12) Síwájú sí i, ọkàn mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nípa ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Bíbélì ṣe fún àwọn tó bá fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3-5.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì tí mo ní kò tó nǹkan, ńṣe nìmọ̀lára mi dà bíi ti wòlíì Jeremáyà, tí kò lè pa sísọ nípa Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀ mọ́ra. (Jeremáyà 20:9) Àwọn tí a jọ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dara pọ̀ mọ́ mi nínú wíwàásù láti ilé dé ilé. Mo tilẹ̀ ṣètò ìpàdé nínú ọgbà ilé arákùnrin màmá mi, mo sì ń fi ìwé ìkésíni tí a tẹ̀ pe àwọn èèyàn. Nígbà kan, àwọn tó wá tilẹ̀ pọ̀ tó méjìdínlọ́gọ́rin. Nípa bẹ́ẹ̀, a dá àjọ ìsìn tuntun kan sílẹ̀ lábẹ́ ìdarí aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà náà.
Ìgbà Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Jù Mí Sẹ́wọ̀n
Mi ò mọ̀ pé wọ́n ti ka ẹgbẹ́ èyíkéyìí tó bá ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Watch Tower Society léèwọ̀ ní Belgian Congo. Nípa bẹ́ẹ̀, ní October 22, 1949, wọ́n kó díẹ̀ lára wa. Kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wa, adájọ́ bá èmi nìkan sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ó sì gbìyànjú láti dá mi sílẹ̀, nítorí ó mọ̀ pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni mí. Ṣùgbọ́n kó lè dá mi sílẹ̀ lómìnira, mo ní láti yọwọ́ nínú ẹgbẹ́ oníwàásù tí a ti dá sílẹ̀, mo sì kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìn tí mo ti lo oṣù méjì ààbọ̀ lẹ́wọ̀n, ìjọba pinnu láti dá àwa tí a jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà padà sí orílẹ̀-èdè wa. Àmọ́, nígbà tí a padà sí Àǹgólà, àwọn aláṣẹ Potogí tí ń ṣàkóso ilẹ̀ wa pẹ̀lú fura sí àwọn ìgbòkègbodò wa ni wọ́n bá pààlà sí òmìnira wa. Àwọn púpọ̀ sí i lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ wa padà dé láti Belgian Congo, iye àwa tí a wà ní gbogbo Àǹgólà wá lé ní ẹgbẹ̀rún kan.
Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ọmọlẹ́yìn Simon Kimbangu tó jẹ́ gbajúmọ̀ aṣáájú ìsìn wà lára ọmọ ẹgbẹ́ àjọ wa. Àwọn èèyàn wọ̀nyí kò nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí Watch Tower Society ṣe, nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé abẹ́mìílò nìkan ló lè ṣàlàyé Bíbélì. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ wa ló ti èrò yẹn lẹ́yìn, títí kan aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin náà, tí a ṣì kà sí aṣáájú wa. Mo gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Jèhófà jẹ́ kí a rí ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú tòótọ́ fún Watch Tower Society. Mo nírètí pé èyí yóò jẹ́ kí àwa ọmọ ẹgbẹ́ àjọ yìí lápapọ̀ lè gbà láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, kí a sì kọ àwọn àṣà tí kò sí níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.
Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà fìbínú hàn sí ìwàásù tí àwa díẹ̀ ń ṣe. Nítorí náà, wọ́n táṣìírí wa fún àwọn aláṣẹ, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé a jẹ́ aṣáájú àjọ òṣèlú. Ní àbájáde èyí, ní February 1952 wọ́n kó àwọn mélòó kan lára wa, títí kan Carlos Agostinho Cadi àti Sala Ramos Filemon. Wọ́n tì wá mọ́ túbú tí kò ní fèrèsé. Bó ti wù kó rí, ẹ̀ṣọ́ kan tó jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ gba oúnjẹ àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wá fún wa lọ́wọ́ àwọn ìyàwó wa kí a lè túbọ̀ máa tẹ àwọn ìwé kékeré ti Watch Tower Society.
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, wọ́n kó wa kúrò nílùú lọ sí Baia dos Tigres, àgbègbè aṣálẹ̀ kan ní gúúsù Àǹgólà. Àwọn ìyàwó wa tẹ̀ lé wa lọ síbẹ̀. Wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára, a sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ẹja kan. Baia dos Tigres kò ní èbúté tí àwọn ọkọ̀ ẹja máa ń gúnlẹ̀ sí, nítorí náà, ńṣe làwọn ìyàwó wa máa ń wọnú ọkọ̀ tí wọ́n a tún máa jáde bí wọ́n ti ń ru ẹrù ẹja tó wúwo jáde láti inú ọkọ̀ láti àárọ̀ títí di alẹ́.
Ní àgọ́ ẹ̀wọ̀n yìí, a bá àwọn mìíràn lára ọmọ ẹgbẹ́ àjọ wa pàdé, a sì gbìyànjú láti rọ̀ wọ́n kí wọ́n máa bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ. Ṣùgbọ́n wọ́n yàn láti tẹ̀ lé Toco, aṣáájú ẹgbẹ́ akọrin yẹn. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí pè wọ́n ní ọmọlẹ́yìn Toco.
Ìpàdé Tí A Ti Ń Fojú Sọ́nà fún Tipẹ́tipẹ́
Nígbà tí a wà ní Baia dos Tigres, a rí àdírẹ́sì ẹ̀ka Watch Tower Society ti Àríwá Rhodesia (tó ń jẹ́ Zambia nísinsìnyí), a sì kọ̀wé pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n fi lẹ́tà wa ṣọwọ́ sí ẹ̀ka ti Gúúsù Áfíríkà, tó kọ̀wé sí wa, tí wọ́n béèrè nípa bí a ṣe di olùfìfẹ́hàn sí òtítọ́ Bíbélì. Wọ́n sọ nípa wa fún orílé iṣẹ́ Watch Tower Society, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì ṣètò láti rán aṣojú pàtàkì kan wá sọ́dọ̀ wa. Ẹni náà ni John Cooke, míṣọ́nnárì tó ti nírìírí ní ilẹ̀ àjèjì fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Lẹ́yìn tí Arákùnrin Cooke dé Àǹgólà, ó gbà á ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kí ìjọba ilẹ̀ Potogí tó jẹ́ kó wá bẹ̀ wá wò. Ó dé Baia dos Tigres ní March 21, 1955, wọ́n sì jẹ́ kó wà lọ́dọ̀ wa fún ọjọ́ márùn-ún. Àwọn àlàyé Bíbélì tó ṣe tẹ́ni lọ́rùn gan-an, ó sì dá mi lójú pé ó ń ṣojú fún ètò àjọ tòótọ́ kan ṣoṣo tó jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn ìbẹ̀wò Arákùnrin Cooke, ó sọ àsọyé lórí kókó ọ̀rọ̀ náà, “Ìhìn Rere Ìjọba Náà.” Èèyàn méjìlélọ́gọ́rin ló wá gbọ́ ọ, olórí alákòóso Baia dos Tigres pẹ̀lú wá. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wá ló gba ẹ̀dà àsọyé náà tí a tẹ̀.
Láàárín oṣù márùn-ún tí Arákùnrin Cooke lò ní Àǹgólà, ó kàn sí àwọn ọmọlẹ́yìn Toco bíi mélòó kan àti aṣáájú wọn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, èmi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ronú pé a gbọ́dọ̀ mú ìdúró wa ṣe kedere sí àwọn aláṣẹ. A sì ṣe èyí nínú lẹ́tà kan tí a kọ ní June 6, 1956, sí “Ọlọ́lá Gómìnà Àgbègbè Moçâmedes.” A kọ ọ́ síbẹ̀ pé a kò ní nǹkan kan láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn Toco àti pé kí wọ́n kà wá sí “ọmọ ẹgbẹ́ Society ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” A tún béèrè pé kí wọ́n fún wa lómìnira ìjọsìn. Àmọ́, dípò kí wọ́n dín àkókò tí a ó fi ṣẹ̀wọ̀n kù, ńṣe ni wọ́n fi ọdún méjì kún un.
Àwọn Ohun Tó Ṣamọ̀nà sí Ìrìbọmi
Níkẹyìn, wọ́n tú wa sílẹ̀ ní August 1958, nígbà tí a sì padà dé Luanda, a bá àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kékeré kan. Ọdún tó ṣáájú ìyẹn ni Mervyn Passlow, míṣọ́nnárì tí wọ́n gbé wá sí Àǹgólà láti rọ́pò John Cooke, ṣètò wọn jọ ṣùgbọ́n ká tó padà dé wọ́n ti lé e jáde nílùú. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ní ọdún 1959, Harry Arnott, míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mìíràn wá bẹ̀ wá wò. Ṣùgbọ́n wọ́n mú òun àti àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a wá pàdé rẹ̀ nígbà tó gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfuurufú.
Àwọn méjì yòókù, Manuel Gonçalves àti Berta Teixeira, àwọn Ẹlẹ́rìí, ọmọ ilẹ̀ Potogí, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, ni wọ́n tú sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe ìpàdé kankan mọ́. Wọ́n lé Arákùnrin Arnott jáde nílùú, wọ́n sì kìlọ̀ fún èmi pé bí mi ò bá fọwọ́ sí ìwé kan tó sọ pé n kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́, wọ́n á dá mi padà sí Baia dos Tigres. Lẹ́yìn wákàtí méje tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìjẹ́ pé mo fọwọ́ sí ìwé kankan. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, mo ṣèrìbọmi, bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ mi Carlos Cadi àti Sala Filemon. A gba iyàrá kan ní Muceque Sambizanga, níkangun ìlú Luanda, tó wá di ibi tí a ti kọ́kọ́ dá ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ ní Àǹgólà.
Inúnibíni Bẹ̀rẹ̀ Lákọ̀tun
Ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé. Àwọn kan wá ṣamí wa ni, ṣùgbọ́n wọ́n gbádùn àwọn ìpàdé náà, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá! Ipò ìṣèlú ń yí padà, nǹkan sì túbọ̀ ń ṣòro sí i fún wa lẹ́yìn rògbòdìyàn kan tó dá lórí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó bẹ́ sílẹ̀ ní February 4, 1961. Láìka irọ́ tí wọ́n ń pa káàkiri nípa wa sí, a ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní March 30, àádóje èèyàn ló sì wá.
Ní oṣù June, nígbà tí mo ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́wọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ ológun wá da ìpàdé wa rú. Wọ́n fi àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n kó àwa ọgbọ̀n ọkùnrin tó wà níbẹ̀ lọ, bí mo ṣe sọ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n fi kóńdó lù wá fún wákàtí méjì gbáko. Ńṣe ni mo ń pọ ẹ̀jẹ̀ fún oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà. Mo ti ní in lọ́kàn pé màá kú; lóòótọ́, ẹni tó lù mí ti mú un dá mi lójú pé màá kú. Àwọn ẹni tuntun ló pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n lù náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí kò tíì ṣèrìbọmi, nítorí náà mo gbàdúrà tọkàntọkàn nípa wọn pé: “Jèhófà, tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ.”
Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé kò sí èyí tó kú nínú wọn, èyí sì ya àwọn ológun náà lẹ́nu. Èyí sún àwọn kan lára àwọn sójà náà láti yin Ọlọ́run wa, wọ́n sọ pé òun ló jẹ́ ká là á já! Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wá di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi, àwọn kan lára wọ́n sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà Kristẹni nísinsìnyí. Ọ̀kan lára wọn, Silvestre Simão, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àǹgólà.
A Fi Ọdún Mẹ́sàn-án Jìyà
Bí mo ṣe sọ níṣàájú, mo jìyà ní oríṣiríṣi ọ̀nà fún ọdún mẹ́sàn-án, wọ́n sì ń gbé mi láti ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan lọ sí òmíràn. Ní gbogbo ibẹ̀, mo ń wàásù fún àwọn tí ìjọba jù sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú, ọ̀pọ̀ lára wọn ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi báyìí. Wọ́n jẹ́ kí Maria tó jẹ́ ìyàwó mi, àti àwọn ọmọ wa tẹ̀ lé mi.
Nígbà tí a wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Serpa Pinto, wọ́n mú mẹ́rin lára àwọn tí ìjọba jù sẹ́wọ̀n tí wọ́n fẹ́ sá lọ. Wọ́n dá wọn lóró títí wọ́n fi kú lójú gbogbo àwa ẹlẹ́wọ̀n kí ẹ̀rù lè bà wá láti má ronú àtisálọ rárá. Ẹ̀yìn ìyẹn ni apàṣẹ-wàá ní àgọ́ náà wá halẹ̀ mọ́ mi lójú Maria àti àwọn ọmọ pé: “Bí mo bá tún gbá ẹ mú tí o ń wàásù, irú ikú táwọn tó fẹ́ sá lọ yẹn kú lo máa kú.”
Níkẹyìn, ní November 1966, a bá ara wa ní São Nicolau, tó ti wá di àgọ́ ikú ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀. Nígbà tí a débẹ̀, ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí mo rí i pé Ọ̀gbẹ́ni Cid, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ lù mí pa ní ọgbà ẹ̀wọ̀n São Paulo, ni alákòóso àgọ́ náà! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ni wọ́n ń dọ́gbọ́n pa lóṣooṣù, wọ́n sì ń fipá mú ìdílé mi láti máa wo bí wọ́n ṣe ń pa àwọn èèyàn nípakúpa. Ní àbájáde rẹ̀, ojora kọ́lé sí Maria lára, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀ síbẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo gba àyè láti kó òun àti àwọn ọmọ lọ sí Luanda, níbi tí àwọn ọmọ mi obìnrin àgbà méjèèjì, Teresa àti Joana, ti tọ́jú wọn.
Wọ́n Tú Mi Sílẹ̀, àmọ́ Wọ́n Tún Jù Mí Sẹ́wọ̀n
Ọdún tó tẹ̀ lé e ni wọ́n tú mi sílẹ̀, ní September 1970, mo sì tún dara pọ̀ mọ́ ìdílé mi àti gbogbo àwọn ará ní Luanda. Omijé bọ́ lójú mi nígbà tí mo rí bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe tẹ̀ síwájú tó láàárín ọdún mẹ́sàn-án tí mi ò fi sí níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n lọ fi mí sẹ́wọ̀n ní ọdún 1961, àwùjọ kéékèèké mẹ́rin ló para pọ̀ jẹ́ ìjọ tó wà ní Luanda nígbà náà. Nísinsìnyí, ìjọ ńláńlá mẹ́rin ló wà níbẹ̀, wọ́n wà létòlétò, arìnrìn-àjò kan tó jẹ́ aṣojú ètò Jèhófà sì ń lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ lóṣù mẹ́fà-mẹ́fà. Inú mi dùn gan-an pé wọ́n tú mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n òmìnira mi kò tọ́jọ́.
Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá Inú àti Aláàbò Ìlú (PIDE) tó ti kógbá sílé nísinsìnyí ké sí mi. Lẹ́yìn tó yìn mí níyìn èké tán níwájú Joana, ọmọ mi, ó mú ìwé kan fún mi pé kí n buwọ́ lù ú. Ó fẹ́ fi mí ṣe ẹni tí yóò máa ta àjọ PIDE lólobó, ó sì ṣèlérí pé òun á sọ mí di ọlọ́rọ̀ tabua bí mo bá gbà láti ṣe iṣẹ́ yẹn. Nígbà tí mo kọ̀ láti buwọ́ lù ú, ó halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn á dá mi padà sí São Nicolau, ó sì sọ pé mi ò ní kúrò níbẹ̀ mọ́ láé.
Ní January 1971, lẹ́yìn oṣù mẹ́rin péré tí wọ́n fi tú mi sílẹ̀, wọ́n mú àwọn ọ̀rọ̀ ìhalẹ̀mọ́ni náà ṣẹ. Lápapọ̀, àwọn Kristẹni alàgbà mẹ́tàdínlógójì láti Luanda ni wọ́n kó lọ sí São Nicolau. Wọ́n dà wá sẹ́wọ̀n títí di oṣù August 1973.
Wọ́n Tú Wa Sílẹ̀, àmọ́ Wọ́n Ṣì Ń Ṣenúnibíni sí Wa
Ní ọdún 1974, wọ́n kéde òmìnira ìsìn ní ilẹ̀ Potogí, lẹ́yìn náà, wọ́n nawọ́ òmìnira yìí dé àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀ Potogí lókè òkun. Àǹgólà gbòmìnira lọ́wọ́ ilẹ̀ Potogí ní November 11, 1975. Ìdùnnú gbáà ló jẹ́ fún wa ní oṣù March ọdún yẹn kan náà nígbà tí a ṣe àpéjọ àyíká wa àkọ́kọ́ fàlàlà! Mo ní àǹfààní láti sọ àsọyé ní àwọn àpéjọ aláyọ̀ wọ̀nyí ní Pápá Ìṣiré ní Luanda.
Bó ti wù kó rí, ìjọba tuntun tó wà lórí àléfà lòdì sí ìdúró aláìdásí-tọ̀tún-tòsì wa, ogún abẹ́lé sì bẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Àǹgólà. Ọ̀ràn náà le débi pé nígbà tó di kàráǹgídá, ńṣe láwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ òyìnbó sá kúrò ní orílẹ̀-èdè yìí. Wọ́n fi ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù ní Àǹgólà síkàáwọ́ àwa arákùnrin mẹ́ta tí a jẹ́ ọmọ ilẹ̀ náà, lábẹ́ ìdarí ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Potogí.
Láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rí orúkọ mi nínú àwọn ìwé ìròyìn, wọ́n sì ń sọ ọ́ lórí rédíò. Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mo ń ṣojú fún àjọ agbókèèrè-jẹgàba kan àti pé èmi ni kò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà máa gbébọn. Nítorí náà, wọ́n pè mí lọ síwájú gómìnà àkọ́kọ́ fún ẹkùn ìpínlẹ̀ Luanda. Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún un nípa ìdúró aláìdásí-tọ̀tún-tòsì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú jákèjádò ayé, bíi ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. (Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52) Nígbà tí mo sọ fún un pé mo ti lò ju ọdún mẹ́tàdínlógún lọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà táwọn òyìnbó ń ṣàkóso, ó pinnu láti má mú mi.
Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, ó gba ìgboyà láti sìn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà. Níwọ̀n bí wọ́n ti ń ṣọ́ ilé mi lójú méjèèjì, a ò ṣe ìpàdé níbẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, “a há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra.” (2 Kọ́ríńtì 4:8) A ò dáwọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dúró. Mo ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ, mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, mo ń mú àwọn ìjọ tó wà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Benguela, Huíla, àti Huambo lọ́kàn le. Orúkọ mìíràn ni mo lò nígbà yẹn, orúkọ náà ni Arákùnrin Filemon.
Ní March 1978, wọ́n tún fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn tó ṣeé gbíyè lé sì sọ fún mi pé àwọn agbawèrèmẹ́sìn tí ń ṣe onígbọ̀wọ́ ìyípadà tegbòtigaga ń gbèrò láti pa mí. Nítorí náà, mo sá pa mọ́ sílé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìgbàwé àṣẹ ìwọ̀lú ti Nàìjíríà ní Àǹgólà. Lẹ́yìn oṣù kan, nígbà tí wàhálà náà ti rọlẹ̀, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí bá iṣẹ́ sísin àwọn ará gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká lọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, tí ogun abẹ́lé sì ń jà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Àǹgólà ló gbọ́ ìwàásù wa. Nítorí pé iye àwọn tí ń di Ẹlẹ́rìí ń pọ̀ sí i, a yan ìgbìmọ̀ orílẹ̀-èdè láti máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Àǹgólà, lábẹ́ ìdarí ẹ̀ka ilẹ̀ Potogí. Láàárín àkókò yìí, mo lọ sí ilẹ̀ Potogí nígbà bíi mélòó kan, ibẹ̀ ni mo ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó pójú owó láti ọ̀dọ̀ àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n tóótun, mo sì tún gba ìtọ́jú ara tó yẹ.
Òmìnira Láti Wàásù Dé Wàyí!
Nígbà tí mo wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àwọn tí ìjọba jù sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ pé wọn ò ní tú mi sílẹ̀ láé bí mi ò bá yé wàásù. Ṣùgbọ́n mo máa ń dá wọn lóhùn pé: “Àkókò ò tíì tó tí Jèhófà máa ṣílẹ̀kùn ni, ṣùgbọ́n nígbà tó bá ṣí i, kò sí ẹ̀dá tó lè tì í.” (1 Kọ́ríńtì 16:9; Ìṣípayá 3:8) Ilẹ̀kùn àǹfààní yẹn láti wàásù láìsí ìkálọ́wọ́kò ṣí lọ́nà gbígbòòrò sí i lẹ́yìn tí Soviet Union tú ká ní ọdún 1991. Nígbà yẹn, òmìnira ìjọsìn tí a ní túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Àǹgólà. Ní ọdún 1992, wọ́n fàṣẹ sí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin. Níkẹyìn, ní ọdún 1996, a kọ́ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àǹgólà, wọ́n sì yàn mí láti jẹ́ ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.
Láàárín ọ̀pọ̀ ọdún tí mo fi ṣẹ̀wọ̀n, ìdílé mi ń rí ìtọ́jú lọ́nà kan ṣáá. Ọmọ mẹ́fà la bí, márùn-ún lára wọn ṣì wà láyé. Àrùn jẹjẹrẹ pa Joana olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n lọ́dún tó kọjá. Mẹ́rin lára àwọn ọmọ wa tó kù ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi, ṣùgbọ́n ọmọ wa kan tó kù kò tíì gbégbèésẹ̀ àtiṣèrìbọmi.
Nígbà tí Arákùnrin Cooke bẹ̀ wá wò ní ọdún 1955, àròpọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Àǹgólà tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ mẹ́rin. Lónìí, ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì olùpòkìkí Ìjọba tó wà lórílẹ̀-èdè yìí, wọ́n sì ń darí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́rin ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀ rí wà lára àwọn tó ń wàásù ìhìn rere náà. Èrè ẹ̀san gbáà lèyí jẹ́, mo sì dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà fún dídá mi sí àti fún jíjẹ́ kí n mú ìfẹ́-ọkàn mi tí ń jó fòfò láti kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ!—Aísáyà 43:12; Mátíù 24:14.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Kóńgò
Kinshasa
Àǹgólà
Maquela do Zombo
Luanda
São Nicolau (tó ń jẹ́ Bentiaba nísinsìnyí)
Moçâmedes (tó ń jẹ́ Namibe nísinsìnyí)
Baia dos Tigres
Serpa Pinto (tó ń jẹ́ Menongue nísinsìnyí)
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Nísàlẹ̀: Èmi àti John Cooke ní ọdún 1955. Sala Filemon ló wà lápá òsì
Lápá ọ̀tún: Mo ṣalábàápàdé John Cooke lẹ́yìn ọdún méjìlélógójì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Èmi àti ìyàwó mi, Maria