ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 7/8 ojú ìwé 16-17
  • Àwọn Obìnrin Ṣe Bẹbẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Obìnrin Ṣe Bẹbẹ
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Lè Lo Àkókò àti Okun Rẹ?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Túbọ̀ Wàásù
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 7/8 ojú ìwé 16-17

Àwọn Obìnrin Ṣe Bẹbẹ

IPA pàtàkì tí àwọn obìnrin Kristẹni kó nínú iṣẹ́ kíkọ́ ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Zimbabwe gbàfiyèsí nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ ilé náà ní December 12, 1998. Láàárín ọdún mẹ́rin tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà, àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè—àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn láti Zimbabwe—lo àkókò, agbára, òye iṣẹ́, àti ohun ìní wọn láti kọ́ àwọn ilé tó jojúnígbèsè tí ẹ ń wò nínú fọ́tò tó wà nínú ìwé yìí.

Ẹ wo ilé gbígbé mẹ́fà tí wọ́n rí bákan náà lẹ́yìn lọ́hùn-ún. Inú ilé ńlá tó sún mọ́ wọn yẹn ni ilé ìjẹun, ilé ìgbọ́únjẹ, àti ilé ìfọṣọ wà. Iyàrá mọ́kànlélọ́gọ́ta ló wà nínú àwọn ilé gbígbé náà, ilé ìjẹun náà sì lè gba nǹkan bí igba ènìyàn. Àwọn ọ́fíìsì ló wà nínú ilé ti iwájú, lápá òsì. Ibi tí àlejò ń jókòó sí ló wà láàárín, ilé ìkẹ́rùsí ló sì wà lápá ọ̀tún, níbi tí a ti ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà.

Ilé ẹ̀ka jíjojúnígbèsè yìí tó wà ní Zimbabwe, ní ìhà gúúsù Áfíríkà, jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ tí a ti kọ́ parí láti ìgbà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ ètò iṣẹ́ ilé kíkọ́ kárí ayé ní November 1985. Jí! ti August 22, 1991, ṣàpèjúwe ètò yìí nínú àpilẹ̀kọ kan tó ní àkọlé náà, “Ohun kan tí ó Jẹ Titun Ninu Iṣẹ Ikọle Jakejado Awọn Orilẹ-ede.”

Jí! ròyìn ipa tí àwọn obìnrin kó nínú iṣẹ́ náà pé: “Ọ̀pọ̀ lára wọn ni a kọ́ bí a ṣe ń fi wáyà de irin tí a óò fi ṣe òpó ilé, bí a ṣe ń to bíríkì dídán àfiṣelẹ̀lọ́ṣọ̀ọ́, bí a ṣe ń fi bébà dán nǹkan àti bí a ṣe ń kun nǹkan. Àwọn mìíràn ń bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó yẹ ní ṣíṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn ń lọ́wọ́ sí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tí a ń ṣe jákèjádò ayé lọ́nà tó dára.”

Nígbà ìyàsímímọ́ tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Zimbabwe, George Evans àti James Paulson, tí wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé náà, fi ipa tí àwọn obìnrin kó nínú iṣẹ́ kíkọ́ ẹ̀ka ti Zimbabwe náà wé ipa tí àwọn obìnrin kó nínú kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn ti Ísírẹ́lì ìgbàanì. Bíbélì sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wọ́n wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́, . . . wọ́n sì ń wá ṣáá, àwọn ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin.”—Ẹ́kísódù 35:21, 22.

Pẹ̀lú ẹsẹ Bíbélì yìí, Arákùnrin Evans àti Paulson tẹnu mọ́ bí ipa tí àwọn obìnrin kó ti ṣeyebíye tó. Wọ́n ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó sọ pé: “Gbogbo àwọn obìnrin tí wọ́n gbọ́n ní ọkàn-àyà sì fi ọwọ́ wọn rànwú, . . . gbogbo obìnrin tí ọkàn-àyà wọn sún wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n.” Ní gidi, àwọn obìnrin wà lára àwọn tó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ náà. “Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí ọkàn-àyà wọn ru wọ́n sókè láti mú ohun kan wá fún gbogbo iṣẹ́ tí Jèhófà ti pa láṣẹ láti ṣe nípasẹ̀ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀.”—Ẹ́kísódù 35:25, 26, 29.

Alábòójútó ilé kíkọ́ sọ nípa iṣẹ́ ilé ẹ̀ka ti Zimbabwe pé: ‘Gbogbo iṣẹ́ tí àwọn ọkùnrin ṣe ni àwọn obìnrin náà ṣe.’ Títí kan díde irin àti wíwa katakata. Arákùnrin Paulson sọ pé, àwọn kẹ̀kẹ́ ìkókọnkéré àti àwọn katakata mìíràn tí àwọn lò làwọn obìnrin ń fọ̀ mọ́ tónítóní, tó ń dán gbinrin, ó sì sọ pé, àwọn ọkùnrin kì í sábàá fẹ́ láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.

Dájúdájú, a ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin tí wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀ka ti Zimbabwe

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́