ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 7/8 ojú ìwé 15
  • Ìjẹ́mímọ́ Kristẹni—Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Tí A Gbọ́dọ̀ Rọ̀ Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjẹ́mímọ́ Kristẹni—Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Tí A Gbọ́dọ̀ Rọ̀ Mọ́
  • Jí!—1999
Jí!—1999
g99 7/8 ojú ìwé 15

Ìjẹ́mímọ́ Kristẹni—Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Tí A Gbọ́dọ̀ Rọ̀ Mọ́

ÀWỌN Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin àti àwọn nǹkan tó là kalẹ̀ nípa ìwẹ̀nùmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ṣì ń ṣàmúlò irú àwọn Òfin bẹ́ẹ̀ àti àṣà rẹ̀ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 11:55) Òfin ní “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀”; “ohun gidi náà jẹ́ ti Kristi.” (Hébérù 10:1; Kólósè 2:17) Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ọ̀ràn ìwẹ̀nùmọ́ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin [Mósè fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ìwé, àwọn ènìyàn, àgọ́, àti àwọn ohun èlò], bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé. Nítorí náà, ó pọndandan pé kí a wẹ àwọn àwòrán ìṣàpẹẹrẹ àwọn ohun ti ọ̀run mọ́ nípasẹ̀ ohun àmúlò wọ̀nyí.” “Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí ó di ẹlẹ́gbin bá ń sọni di mímọ́ dé àyè ìmọ́tónítóní ara, mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni tí ó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè?”—Hébérù 9:19-23, 13, 14.

Nítorí náà, ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi Olúwa ló ń wẹ àwọn Kristẹni mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣòdodo. (1 Jòhánù 1:7, 9) Kristi “nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un, kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, ní wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,” kí ó lè wà láìlábùkù, kí ó lè jẹ́ mímọ́, láìní àbààwọ́n, kí wọ́n lè jẹ́ “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe, . . . àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Éfésù 5:25-27; Títù 2:14) Fún ìdí yìí, kò yẹ kí olúkúlùkù mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni yìí “gbàgbé ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,” ṣùgbọ́n ṣe ló yẹ kó máa bá a lọ ní fífi èso tẹ̀mí Ọlọ́run hàn (2 Pétérù 1:5-9), kó máa rántí pé “gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó [Ọlọ́run] ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.”—Jòhánù 15:2, 3.

Nítorí náà, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìjẹ́mímọ́ gíga nípa tara, ní ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì yàgò fún “gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Lójú ìwòye ohun tí Jésù sọ, pé, ‘kì í ṣe ohun tí ó kọjá sínú ènìyàn bí kò ṣe ohun tí ń jáde wá láti inú rẹ̀ ní ń sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin,’ àwọn wọ̀nyí tó ti jàǹfààní látinú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí ń wẹni mọ́ ń fojú ribiribi wo ìjẹ́mímọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n ní “ọkàn-àyà tí ó mọ́” àti “ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́” lójú Ọlọ́run. (Máàkù 7:15; 1 Tímótì 1:5; 3:9; 2 Tímótì 1:3) Lójú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó ní ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́, “ohun gbogbo ni ó mọ́,” yàtọ̀ sáwọn aláìnígbàgbọ́, tí ẹ̀rí-ọkàn wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin, àwọn tó jẹ́ pé lójú tiwọn, “kò sí ohun tí ó mọ́.” (Títù 1:15) Àwọn tó bá fẹ́ wà ní mímọ́ tónítóní ní ọkàn-àyà máa ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tí ń bẹ nínú Aísáyà 52:11, tó kà pé: “Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; . . . ẹ wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà.” (Sáàmù 24:4; Mátíù 5:8) Bí wọ́n bá ń ṣe èyí, “ọwọ́” wọn, lọ́nà àpèjúwe, yóò mọ́ (Jákọ́bù 4:8), Ọlọ́run yóò sì kà wọ́n sí ẹni tó mọ́.—2 Sámúẹ́lì 22:27; Sáàmù 18:26; tún wo Dáníẹ́lì 11:35; 12:10.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́