Calcutta—Ìlú Ńlá Ọlọ́pọ̀ Èrò Tí Àwọn Nǹkan Ti Yàtọ̀ Síra
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Íńdíà
NÍ TI òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Britain náà, Rudyard Kipling, ó jẹ́ “ìlú ńlá tí àyà ti ń foni lálaalẹ́,” “ìlú kíkúnfọ́fọ́, tó kún fún ìwà ibi.” Àmọ́ ní ti olókìkí akéwì lédè Urdu náà, Mīrzā Ghālib, ó jẹ́ “ìlú ńlá amáratuni gan-an,” “ìlú ńlá amúniláyọ̀.” Òǹkọ̀wé Dominique Lapierre rí ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan sí ìlú ńlá náà bí “ìrírí tuntun tí a nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi,” àmọ́ nígbà tí Peter T. White ń kọ nínú ìwé ìròyìn National Geographic, ó fa ọ̀rọ̀ àwọn mìíràn yọ tí wọ́n ń pè é ní “amúniwárìrì, ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, adáyàfoni. Ibi tí ènìyàn lọ́rí lù sí jù lọ lágbàáyé.” Láìsí àní-àní, Calcutta (Kalikata, lédè Bengali), jẹ́ ìlú ńlá tí àwọn nǹkan ti yàtọ̀ síra.
Ìwáṣẹ̀ Ìlú Ńlá Náà
Calcutta, ní etíkun àríwá ìlà oòrùn Íńdíà, ní ìpínlẹ̀ West Bengal, kò sí lára Íńdíà àtijọ́. Tí a bá fi wé àwọn ìlú ńlá bí Delhi àti Thanjavur, kò tíì pẹ́ rárá. Bó ti sábà máa ń jẹ́ nínú ọ̀ràn àwọn ìlú ńlá, ìwáṣẹ̀ Calcutta jẹ́ nítorí odò kan, Ganges ńlá. Nítòsí Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Bengal, odò Ganges kọ́kọ́ pín sí méjì, ó tún wá pín sọ́nà púpọ̀ sí i, ó sì di ẹ̀ya ẹnu odò títóbi jù lọ lágbàáyé. Èyí tó wà ní ìkángun ẹ̀ya ẹnu odò náà, lápá ìwọ̀ oòrùn, lódò tí a kọ́kọ́ mọ̀ sí Bhagirathi-Ganga, lẹ́yìn náà sí Hooghly, tí ń ṣàn gba ìhà gúúsù lọ sínú òkun.
Ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún àti ìkẹrìndínlógún, àwọn oníṣòwò ará Potogí, Dutch, àti Britain wakọ̀ dé Hooghly, wọ́n sì ṣí àwọn ibùdó ìṣòwò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda àwọn alákòóso àdúgbò náà. Job Charnock, ọ̀gá kan ní Ilé Iṣẹ́ British East India, fìdí òwò sọlẹ̀ sábúlé Sutanuti. Lẹ́yìn àwọn ìdíwọ́ díẹ̀, ó wakọ̀ wọ Sutanuti, ó fa ojú àwọn ará abúlé Govindpur àti Kalikata mọ́ra, ó fi ìpìlẹ̀ fún títẹ abúlé kan dó fún àwọn ará Britain dípò ibùdó ìṣòwò lásán. Ní August 24, 1690, ni. Ìgbà ìwáṣẹ̀ Calcutta!
Wọ́n gbàwé àṣẹ àyálò ilẹ̀ lábẹ́ òfin ní 1698, Britain ń sanwó ilẹ̀ fún àwọn alákòóso Mogul títí di 1757. Àwọn ará Britain mọ Odi William láti pèsè ààbò ológun fún ìlú ńlá tí ń tóbi sí i náà. Àwọn oníṣòwò, tí wọ́n ń nímọ̀lára àìléwu tí Odi William pèsè, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ilé ńlá-ńlá. Nígbà náà, iye àwọn tí ń gbé ìlú náà àti àwọn abúlé tó yí i ká ti di 400,000, nǹkan bí 50 ọkọ̀ òkun sì ń wá sí Hooghly lọ́dọọdún nítorí àtiṣòwò.
Ihò Dúdú ti Calcutta
Ní 1756, ọ̀dọ́ alákòóso kan tó jẹ́ oníwàǹwára, Sirāj-ud-Dawlah ti Bengal, gbógun ti Calcutta. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olùgbé ibẹ̀ sá lọ, àmọ́ àwọn ará Yúróòpù kan, tí wọ́n ti sá di Odi William tẹ́lẹ̀, juwọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣẹ̀wọ̀n nínú túbú kékeré kan nígbà tí ooru ń mú gan-an ní June. Lọ́jọ́ kejì, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ooru ti pa. Wọ́n wá mọ túbú náà sí Ihò Dúdú Calcutta.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí rùbínú Ilé Iṣẹ́ East India sókè, nígbà tó sì di 1757, Robert Clive ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Britain kan láti tún lọ gba ìlú ńlá náà. A gbọ́ pé Ogun Plassey tó bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn náà ló sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Britain ní Íńdíà. Kí lèyí wá yọrí sí fún Calcutta? Ní 1773, ó di olú ìlú British India, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di 1911.
Wọ́n Ṣàtúnṣe Calcutta
Bí búrùjí ìlú ńlá náà ti ń jí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ilé ńlá, tó mú ká pe Calcutta ní Ìlú Ńlá Tí Ààfin Pọ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀nà fífẹ̀, wọ́n sì kọ́ àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí àti ibi ìkówèésí. Púpọ̀ lára àwọn ilé ńlá-ńlá tí wọ́n ṣì wà níbẹ̀ lónìí jẹ́ ẹ̀rí èyí.
Lẹ́yìn 190 ọdún tí Britain fi ṣàkóso níbẹ̀, Íńdíà gba òmìnira ní 1947 lábẹ́ ìṣàkóso Mohandas Gandhi àti Jawaharlal Nehru, ìpínyà sì ṣẹlẹ̀. Lábẹ́ Mohammed Ali Jinnah, wọ́n dá ilẹ̀ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ti Pakistan (Ìlà Oòrùn Pakistan àti Ìwọ̀ Oòrùn Pakistan), sílẹ̀. Nígbà tó yá, ní 1971, Ìlà Oòrùn Pakistan di Bangladesh. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mú kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi rọ́ wọ Calcutta; lónìí, a fojú díwọ̀n pé àwọn olùgbé ìlú ńlá náà lé ní 12,000,000.
Rírọ́ tọ́pọ̀ ènìyàn rọ́ wọbẹ̀ láìsí ọ̀nà àtigbọ́bùkátà yọrí sí ìṣòro bíburú jáì. Àìsílé túmọ̀ sí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn ń gbé ibi tọ́pọ̀ ènìyàn lọ́rí lù sí tí kò dára páàpáà, láwọn ilé tí wọ́n fi páálí àti igi jute kọ́, níbi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìmọ́tótó, iná mànàmáná, tàbí omi. Ojú pópó ni àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún mìíràn ń gbé. Ní 1967, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlú jákèjádò ayé ń ròyìn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní Calcutta, wọ́n wí pé, ó ti “ń yára lọ dé ipò tí ètò ọrọ̀ ajé, ètò ilé gbígbé, ọ̀ràn ìmọ́tótó, ètò ìrìnnà àti àwọn ohun amáyédẹrùn fún ìgbésí ayé ẹ̀dá níbẹ̀ yóò ti dẹnu kọlẹ̀.” Ó jọ pé ọjọ́ iwájú rẹ̀ kò ní sunwọ̀n.
Nínú ìsapá láti mú kílé pọ̀ sí i, ní pàtàkì fún àwùjọ àwọn tí owó kéréje ń wọlé fún, wọ́n fún àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ níbi àbàtà olómi iyọ̀ kan tó gbòòrò. Bákan náà, kíkó òkúta látinú odò láti fi dí ilẹ̀ náà mú kí títukọ̀ rọrùn sí i.
Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dókòwò sílẹ̀ Íńdíà gan-an, Calcutta kò sì fẹ́ gbẹ́yìn. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ ètò ìfọ̀mọ́ gígadabú kan. Wọ́n kó àwọn tí wọ́n lọ́rí lù lọ sí àwọn àgbègbè mìíràn lóde ìlú ńlá náà, wọ́n ń fi pàǹtírí ṣèpèsè iná mànàmáná àti ajílẹ̀, wọ́n sì fòfin de àwọn ọkọ̀ ìrìnnà tí ń fi èéfín ba àyíká jẹ́ àti lílo àwọn ààrò ìyanǹkan tí ń ṣèéfín. Wọ́n fẹ àwọn ọ̀nà sí i, wọn kọ́ àwọn ilé ìtajà ńlá-ńlá. Àwọn ẹgbẹ́ àwọn ará ìlú palẹ̀ mọ́, wọ́n fọ ilẹ̀, wọ́n sì kun àwọn nǹkan. Wọ́n fa Calcutta padà kúrò ní bèbè ìjábá, wọ́n sì fún un láǹfààní mìíràn láti tún gbérí—tí ìlú ńlá ‘tó ti ń kú lọ,’ ‘tó wà nínú ìjábá’ tẹ́lẹ̀ rí náà fi wá lárinrin lẹ́ẹ̀kan sí i. Nínú ìròyìn kan lórí àǹfààní àti àwọn ohun amáyédẹrùn fún ará ìlú tó jáde ní 1997, ipò tí wọ́n fi í sí ga ju ti àwọn ìlú ńlá pàtàkì mìíràn ní Íńdíà lọ fíìfíì.
Ìlú Ńlá Ìṣòwò
Nítorí àwọn olùwá-ibi-ìsádi láti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká, àwọn aṣíwọ̀lú láti àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn ní Íńdíà, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Bengal, àti àwọn ará China àti Armenia tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tipẹ́, ìlú ńlá náà ti di ibi tí ọ̀pọ̀ èdè, àṣà ìbílẹ̀, ìsìn, àti oúnjẹ kóra jọ sí. Kí ló gbé gbogbo àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn wọ̀nyí wá sí Calcutta? Òwò ni! Àwọn ọkọ̀ òkun látibi gbogbo jákèjádò ayé ń wá sí èbúté yìí, níbi tí Ìlà Oòrùn ti pàdé Ìwọ̀ Oòrùn. Iyọ̀, igi jute, tíì, ṣúgà, aró, òwú, àti ṣẹ́dà wà lára àwọn ohun tí wọ́n ń kó ránṣẹ́ sílẹ̀ òkèèrè. Ọ̀pọ̀ ẹrù ni wọ́n ń fi mọ́tò, ọkọ̀ ojú irin, àti ọkọ̀ òkun kó wọ Calcutta tí wọ́n sì ń kó jáde níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n gba òmìnira, wọ́n dá ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti ń rọ irin àti irin lílẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń wa àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ṣíṣeyebíye nínú ilẹ̀ fún lílò nínú ilé àti láti kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.
Èbúté tó wà níbẹ̀ ni lájorí ohun tí ń mú kówò búrẹ́kẹ́ níbẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ará Britain máa ń dá ọkọ̀ wọn ró sí apá ibi tó jindò jù nínú odò Hooghly, wọn á wá fi àwọn ọkọ̀ kéékèèké kó ẹrù lọ síbi tódò kò ti jìn. Ní 1758, wọ́n gbé lájorí ohun tí yóò wá jẹ́ èbúté pàtàkì ní Íńdíà kalẹ̀ ní Calcutta. Iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé àti ìṣàn omi tí a mú pọ̀ sí i nípasẹ̀ adágún kan tí wọ́n fi sé odò Ganges ti mú kí omi Calcutta di ọ̀nà ojú omi, ti etíkun, àti èyí tó wọ ilẹ̀ fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
Ètò Ìrìnnà—Ní Àtijọ́ àti Ní Òde Òní
Ètò ìrìnnà jẹ́ lájorí ìṣòro ní ìlú ńlá kan tí ènìyàn ibẹ̀ lé ní mílíọ̀nù 12. Calcutta ní gbogbo oríṣi ohun ìrìnnà tí a sábà máa ń rí ní àwọn ìlú ńlá lóde òní—àti jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ọkọ̀ ricksha àfọwọ́fà jẹ́ ohun ìyanu fún àwọn àlejò bí wọ́n ti ń rí tí àwọn abarapá ọkùnrin ń gba àárín sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀—tí wọ́n sábà máa ń yára gbé àwọn èrò débi tí wọ́n ń lọ ju àwọn ọkọ̀ èrò tàbí takisí tí a ti há mọ́ lọ. Ẹrù kíkó ni wọ́n ṣe ricksha fún ní 1900, kò sì pẹ́ tó fi di èyí tí wọ́n fi ń gbé ènìyàn; a rò pé nǹkan bí 25,000 ricksha ló ń rìnnà ní ìlú ńlá náà! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń dí àwọn ọkọ̀ lọ́wọ́ níbẹ̀, nǹkan bí 50,000 ọkùnrin ló jẹ́ òun ni iṣẹ́ wọn, ó sì jẹ́ ohun ìrìnnà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Lójoojúmọ́, àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké ń kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ará ìlú láti àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin pàtàkì-pàtàkì ní Calcutta lọ sí àárín gbùngbùn àgbègbè ìṣòwò rẹ̀. Wọ́n ti mú kí fífi ọkọ̀ ojú omi kó èrò pọ̀ sí i láti dín ìṣòro ohun ìrìnnà kù, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkọ̀ akẹ́rù tí iye wọ́n lé ní 50,000 ní ń du ọ̀nà lórí afárá tí a ń lò jù lọ lágbàáyé náà, Afárá Howrah, lójoojúmọ́.
Ó lè jẹ́ àwọn ọkọ̀ ojú irin elérò tí mànàmáná ń gbé ṣiṣẹ́ ni àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ ní ìlú ńlá náà. Ó jẹ́ ètò fífi àwọn ọkọ̀ tí kì í ba àyíká jẹ́, tó lè kó èrò púpọ̀, tí ń ṣiṣẹ́ dáradára, kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn káàkiri ìlú ńlá náà lójoojúmọ́, èyí dára gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ìdẹ̀ra. Rírọ̀ lẹ́nu ọkọ̀ nítorí àpọ̀jù èrò ń béèrè ìjáfáfá lọ́nà àrà ọ̀tọ̀! Ìmúsunwọ̀n ńlá wáyé nígbà tí wọ́n parí Ètò Ọkọ̀ Ojú Irin Metro, tí ń fi ìdẹ̀ra kó ènìyàn tí iye wọ́n lé ní 60,000 la àárín gbùngbùn ìlú ńlá náà kọjá láàárín wákàtí kan, láìpẹ́ yìí.
Àṣà Ìbílẹ̀ Yíyàtọ̀síra ní Calcutta
Àǹfààní ẹ̀kọ́ ti mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn yà sí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti òfin ní Calcutta, ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọnà di irú, ó sì di igba, ní ilẹ̀ tó wá di ibi àfihàn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé apá kékeré ti kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí iye wọ́n lé ní ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù ni wọ́n ti kàwé ní Yunifásítì Calcutta tó ti pé 140 ọdún, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó tóbi jù lọ lágbàáyé.
Bí Mumbai bá jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣe sinimá àṣedánilárayá ní Íńdíà, ó dájú pé Calcutta ni wọ́n ti ń ṣe sinimá eléré ìtàn. A mọ àwọn orúkọ bí Satyajit Ray àti Mrinal Sen jákèjádò ayé fún ipa tí wọ́n kó nínú iṣẹ́ ọnà. Calcutta ní àwọn akéwì tí iye wọ́n pọ̀ ju ti Róòmù àti Paris lápapọ̀ lọ, ó ní àwọn ìwé ìròyìn tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ju New York àti London lọ, ó sì ní ọ̀kan lára àwọn ọjà àlòkù ìwé tó tóbi jù lọ lágbàáyé ní Òpópónà College.
Àwọn Ohun Ṣíṣàjèjì Tí A Óò Rí
Ibi Ìrántí Victoria wà lára àwọn ohun gbígbàfiyèsí tí wọ́n fi mábìlì kọ́ bí ti Ìgbà Ìmúsọjí Ilẹ̀ Ítálì. Wọ́n ṣí i ní 1921, ó jẹ́ arabaríbí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, tí a fi ń rántí ìṣàkóso àwọn ará Britain ní Íńdíà. Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí Íńdíà ńlá náà àti àwọn mìíràn tí iye wọn lé ní 30 wà lára àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ní Calcutta. Ó yẹ kí ènìyàn ṣèbẹ̀wò sí Àwọn Ọgbà Irúgbìn ti Íńdíà tí wọ́n ní igi banyan tó ti pé 240 ọdún, tí títóbi rẹ̀ jẹ́ 400 mítà, àti àwọn Ọgbà Ẹranko ibẹ̀. Maidan—tó jẹ́ ilẹ̀ gbalasa oníhẹ́kítà 520—ni a mọ̀ sí ẹ̀dọ̀fóró Calcutta, àti gbàgede abúlé tó tóbi jù lọ ní gbogbo Íńdíà. Calcutta tún ní ibi tí wọ́n ti ń fi ẹ̀rọ wo àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tí ń jẹ́ Birla Planetarium, ọ̀kan lára àwọn tó tóbi jù lọ lágbàáyé. Fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí eré ìdárayá cricket, pápá Eden Gardens tí wọ́n ti ń ṣe eré cricket, máa ń gba àwọn òǹwòran onítara, tí wọ́n ń pariwo, tí iye wọn tó 100,000 tí orílẹ̀-èdè méjì bá fẹ́ figa gbága.
Ilé tó jojú ní gbèsè gan-an ni Ìbùdó Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì ibẹ̀ jẹ́, òun ni ibùdó ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì títóbi jù lọ ní Éṣíà, tí ń fi bí ilẹ̀ ṣe ń sẹ̀, bí omi ṣe ń bo erékùṣù mọ́lẹ̀, bí ẹ̀fúùfù ṣe ń gbára jọ han àwọn ènìyàn, tí wọ́n sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun tí ń fani lọ́kàn mọ́ra nípa àyíká àti bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dá ṣe ń hùwà. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn onísìn Híńdù, ohun tí ń fa àfiyèsí jù lọ ní Calcutta ni àjọ̀dún Durga Puja, ìgbà tí ìlú ńlá náà máa ń bẹ̀rẹ̀ àwẹ̀jẹwẹ̀mu amẹ́mìígbóná ọlọ́jọ́ márùn-ún, tó máa ń dá ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìgbòkègbodò tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ dúró.
Kí ni o lè rí rà bí o bá lọ nájà ní Calcutta? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí kò sí níbẹ̀! Àmọ́ ṣáá, múra láti kó sáàárín èrò tí ń pariwo, kí o sì ṣàkíyèsí àwọn obìnrin tí wọ́n wọ aṣọ sari aláwọ̀mèremère jíjojúnígbèsè. O lè ra àwọn ohun tí wọ́n fawọ ṣe ní iye tí kò wọ́n jù, títí kan bàtà aláwọ tó lálòpẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù àwọn ará China. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí ẹni tí ń nájà kan, tó fara balẹ̀ lè rí ní àwọn ọjà ńlá-ńlá “párádísè olùnájà” yìí ni àwọn ohun tí wọ́n fi irin lílẹ̀ ṣe, aṣọ, àwọn ohun mèremère tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọn ṣe dáradára.
Oúnjẹ Àjẹpọ́nnulá
Wọ́n tún ṣàpèjúwe Calcutta bí párádísè olóúnjẹ àjẹpọ́nnulá, nítorí náà a kò lè kúrò níbẹ̀ láìtọ́ díẹ̀ lára àwọn oúnjẹ aládùn rẹ̀ wò. A gbọ́ pé àwọn ará Bengal kúndùn oúnjẹ, wọ́n sì máa ń kan sárá sí àwọn ènìyàn látàrí bí wọ́n bá ṣe mọ oúnjẹ sè tó! Ẹja ò lè ṣàìsí nínú oúnjẹ ní Calcutta, wọ́n sì máa ń ta onírúurú ẹja, ẹran, àti ewébẹ̀ ní àwọn ọjà ńlá-ńlá. Àwọn ògidì èròjà amóúnjẹ-tasánsán, tí wọ́n fìṣọ́ra pò pọ̀, máa ń fi kún adùn ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ tó wọ́pọ̀ jù lọ. Oúnjẹ ìbílẹ̀ China pọ̀ níbẹ̀. Àwọn mindin-mín-ìndìn tó wọ́pọ̀ ní Calcutta ló tún máa ń fi kún adùn oúnjẹ jù níbẹ̀. Rasagollas, ìṣù wàràkàṣì tí wọ́n ro omi rẹ̀, tí wọ́n fèròjà amóúnjẹ-tasánsán sí, tí wọ́n sì kì sínú ṣúgà tí wọ́n yọ́, ni àmì ìṣàpẹẹrẹ Bengal. Má sì ṣàìtọ́ mishti doi, yúgọ́ọ̀tì dídùn tí àwọn ènìyàn sábà máa ń mu lẹ́yìn oúnjẹ, wò. Ṣé ẹnu rẹ ti ń ṣe mú un-wá mú un-wá? Ṣé o ń gbọ́ ohun tí ń ta sánsán wá láti àwọn ilé àrójẹ wọ̀nyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ ni pé Calcutta jẹ́ ìlú ńlá ọlọ́pọ̀ èrò, fífani-lọ́kàn-mọ́ra, tí àwọn nǹkan ti yàtọ̀ síra!
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SRI LANKA
ÍŃDÍÀ
Calcutta
BANGLADESH
[Àwòrán ilẹ̀]
CALCUTTA
Ọgbà Ohun Ọ̀gbìn ti Íńdíà
Maidan
Ọgbà Ẹranko
Birla Planetarium
Ibi Ìrántí Victoria
Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Íńdíà
Hooghly Odò
Adágún Omi Oníyọ̀
Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá Dum Dum
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ibùdó Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ibi Ìrántí Victoria
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọjà kan tí wọ́n ń ná lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ṣọ́ọ̀bù onígbàjámọ̀ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà