Ẹranko Puma—Bí A Ṣe Ń Rí Wọn Ni Wọ́n Ń Pòórá
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Brazil
OJÚ òfuurufú lókè igbó kìjikìji Gúúsù Amẹ́ríkà ti ń pàwọ̀ dà sí àwọ̀ tí kò ṣeé júwe tó máa ń ní kété kí ilẹ̀ tó ṣú. Nígbà náà, lójijì àti láìsí àmì kankan, a rí ẹranko puma kan níbẹ̀! Ó ti yọ́ bọ́ síbì kan tí wọ́n ti gé igi lulẹ̀ nínú igbó náà, ó sì dúró lójijì.
Fún ìwọ̀n àkókò díẹ̀, ẹranko ẹ̀yà ológbò ńlá yìí dúró láìmira, àfi ìrù rẹ̀, tí ń jù lọ jù bọ̀ bí ọ̀pá ìnugíláàsì ọkọ̀ tí ń ṣiṣẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ẹranko puma náà fura pé a ń wo òun, ó fò la ibi gbalasa náà kọjá, ó sì yára bẹ́ lugbó. Ní ọ̀sán yẹn, ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, mo rí ìdí tí àwọn bàtà àwọ̀sáré, àwọn ọkọ̀ ayára-bí-àṣá, àti àwọn ọkọ̀ òfuurufú ológun, fi ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Ní kedere, a ṣẹ̀dá ẹranko puma, tàbí ẹranko cougar, ẹranko ẹ̀yà ológbò tó tóbi ṣìkejì ní Amẹ́ríkà, fún eré sísá.a
Ìṣùpọ̀ Ẹran Ara
Nítorí àwọ̀ ilẹ̀ títàn, tí kò lábùlà, tí ẹranko puma ni, ó lè rán ọ létí abo kìnnìún kan. Bí ó ti wù kí ó rí, apá iwájú orí rẹ̀ kò ní igun mẹ́rin bí ti ìbátan rẹ̀ ti ilẹ̀ Áfíríkà náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí ẹranko puma ṣe róbótó, ó sì kéré, ó sì ní àwọn etí kéékèèké tó rí róbótó bákan náà lókè rẹ̀. Bí a bá ti ẹ̀gbẹ́ wò ó, orí rẹ̀ dà bí ọta ìbọn—tí a ṣù dáradára, tó sì gùn. Àwọn ojú rẹ̀ tóbi, wọ́n ní àwọ̀ ewé. Irun funfun tó ní yí ẹnu rẹ̀ ká mú kó dà bí pé ó tẹnu bọ àwo wàrà, kò sì rántí nu ẹnu náà. Ara rẹ̀ rírọ̀, tó sì ṣe pẹ́lẹ́ńgẹ́, lè gùn tó mítà 1.5 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, láìfi ìrù rẹ̀ nínípọn, tó dúdú nípẹ̀kun, kún un.
Àwọn ẹsẹ̀ ẹ̀yìn rẹ̀ tó gùn, tó sì lágbára, mú kí ìbàdí rẹ̀ ga ju èjìká rẹ̀ lọ. Àwọn ẹsẹ̀ lílágbára wọ̀nyẹn ń fún ẹran tó tẹ̀wọ̀n 60 kìlógíráàmù, tó sì ki yìí, lágbára tó nílò láti gbéra kúrò lórí ilẹ̀ bí rọ́kẹ́ẹ̀tì. A ti rí àwọn ẹranko puma tó fò sókè lógìdo dé ibi tó ga tó mítà márùn-ún lọ́wọ́ kan. Ìyẹn dà bí fífò láìṣèyọnu lílo ọ̀pá níbi tó yẹ ká fi ọ̀pá fò!
Nígbà tí ẹranko puma bá ń fò wálẹ̀, ó ń kàmàmà bákan náà. A ti mọ̀ pé ó máa ń fò wálẹ̀ láti ibi tó ga tó mítà 18. Èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì àwọn pèpéle tí àwọn tí ń bẹ́ láti orí pèpéle nínú ìdíje Olympic ti ń bẹ́, ṣùgbọ́n, kò sí àǹfààní ìkùdu ìlúwẹ̀ẹ́ tí omi kún inú rẹ̀ fún ẹranko puma láti bẹ́ sí. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹranko ẹ̀yà ológbò náà ń balẹ̀ pẹ̀lú ìmúratán láti ta síbòmíràn bí pé orí tìmùtìmù onírin-kíká tí ń ta bọ̀n-ùnbọ̀n-ùn ló balẹ̀ sí.
Onímọ̀ nípa ohun alààyè inú ìgbẹ́, Kenneth Logan, sọ pé: “Ẹranko alágbára, tó kọyọyọ, kan nìyí. Ní gbàrà tí o bá ti mọ bí àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò wọ̀nyí ṣe ń wá jíjẹ-mímu, ó yẹ kí o gbóríyìn fún wọn gan-an.” Lọ́nà gbígbàfiyèsí, ó jọ pé wọ́n wà níbi gbogbo—ṣùgbọ́n bí a ṣe ń rí wọn ni wọ́n ń pòórá.
Wọ́n Fẹ́rẹ̀ẹ́ Wà Níbi Gbogbo, Ṣùgbọ́n A Kì Í Rí Wọn
Nígbà tí àwọn agbókèèrè-ṣàkóso kọ́kọ́ gúnlẹ̀ sí Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé, gbogbo àgbáálá ilẹ̀ náà ni ẹranko puma ti ń jẹ̀, láti Àtìláńtíìkì dé Pàsífíìkì. Ó ń gbé inú àwọn òkè ńlá, inú irà, inú ilẹ̀ pápá, àti inú igbó bákan náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọdẹ àti àwọn àgbẹ̀ ti pa ẹranko puma run ní apá púpọ̀ ní Àríwá Amẹ́ríkà, ó ṣì jẹ́ ẹranko ẹ̀yà ológbò tó kárí ilẹ̀ Amẹ́ríkà síbẹ̀, ó ṣì ń rìn kiri láti Kánádà dé góńgó Gúúsù Amẹ́ríkà. Bí o bá fi bí àgbègbè tí a ti ń rí ẹranko kan ṣe gbòòrò tó, àti bí ibi tó ń gbé ṣe jẹ́ onírúurú tó díwọ̀n ìkẹ́sẹjárí rẹ̀, nígbà náà, ẹranko puma ní láti jẹ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà, tó kẹ́sẹ járí jù lọ ní báyìí. Kí ni kókó pàtàkì fún ìkẹ́sẹjárí rẹ̀?
A mú ẹranko puma gbára dì dáradára láti máa wà nìṣó. Ó ní ikùn lílágbára, ó sì ń lo ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọ̀nà ìṣọdẹ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé oríṣi oúnjẹ èyíkéyìí tó bá wà ládùúgbò ló lè jẹ. Olùtọ́jú ẹranko kan tó ti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nínú ikùn ọ̀pọ̀ ẹranko puma tí wọ́n pa ní Brazil, sọ pé: “Ó lè pa ẹranko tó tóbi tó òun fúnra rẹ̀ ní ìlọ́po márùn-ún, kí ó sì wọ́ ọ lọ, ṣùgbọ́n ó tún ń jẹ tata, bí kò bá sí ohunkóhun mìíràn nítòsí mọ́. Bó bá di ọ̀ràn oúnjẹ, ẹranko puma mọwọ́ yí padà ju irú ọ̀wọ́ ẹranko ẹ̀yà ológbò èyíkéyìí mìíràn lọ.”
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan oúnjẹ tún gba ọ̀kan-ò-jọ̀kan ọgbọ́n ìṣọdẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọgbọ́n tó gbà láti fi mú ẹyẹ yàtọ̀ sí èyí tó gbà láti fi ki ìgalà. Báwo ni ẹranko puma ṣe ń ṣe é? Nínú igbó Àtìláńtíìkì ti Brazil, ó ń fa ẹyẹ tinamou mọ́ra nípa dídún bí ẹyẹ náà. Alákìíyèsí kan sọ pé: “Àfarawé pípé ni. Ẹyẹ tinamou máa ń ké nígbà mélòó kan péré, ṣùgbọ́n ẹranko puma ń dún lọ—ìgbà 10 tàbí 20.” Síbẹ̀síbẹ̀, ó gbéṣẹ́. Ẹyẹ tinamou náà ń rò pé akọ ẹyẹ kan tó jẹ́ aláriwo ti wọ àgbègbè ìpínlẹ̀ òun, ó sì ń pinnu láti jáde, kí ó sì ko abánidíje náà lójú—ó jẹ́ ìgbésẹ̀ aṣekúpani kan.
Yálà o wá ẹranko puma ní Àríwá, Àáríngbùngbùn tàbí Gúúsù Amẹ́ríkà, nígbà púpọ̀ jù, ó ń fara pa mọ́—bí afẹ́fẹ́, ó ń wà níbi gbogbo, ṣùgbọ́n kì í ṣeé rí. Àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe tí àwọn olùwádìí tí ń wádìí nípa ẹranko puma sábà máa ń lò ni “afarasin, afarapamọ́ àti oníṣọ̀ọ́ra.” Lẹ́yìn tí ọdẹ kan ti pa nǹkan bí 70 ẹranko puma, ó jẹ́wọ́ pé, “kò sí èyí tí òun ń rí ṣáájú kí àwọn ajá tó lé e gungi lára àwọn tí òun pa náà.” Abájọ tí àwọn olùwádìí tí ó ti tán ní sùúrù fi pe ẹranko ẹ̀yà ológbò náà ní “afarapamọ́ lọ́nà tí ń múni bínú”!
Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Tó Ní Ọ̀pọ̀ Orúkọ
Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe pé ẹranko ẹ̀yà ológbò tó kárí ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà ṣòro rí nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún ṣòro sọ lórúkọ pẹ̀lú. Ìwé The Guinness Book of Animal Records sọ pé, ẹranko puma “ni orúkọ tó ń jẹ́ pọ̀ ju ti ẹranko èyíkéyìí mìíràn lọ lágbàáyé.” Yàtọ̀ sí 40 orúkọ pàtó tí a fi mọ̀ ọ́n lédè Gẹ̀ẹ́sì, “ó kéré tán, ó tún ní orúkọ 18 lédè ìbílẹ̀ àwọn ará Gúúsù Amẹ́ríkà àti orúkọ 25 mìíràn lédè ìbílẹ̀ àwọn ará Àríwá Amẹ́ríkà.”
Puma, orúkọ tí àwọn onímọ̀ nípa ẹranko fi ń pè é jù, wá láti inú èdè Quechua ti Peru. Díẹ̀ lára àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n sọ ẹranko ẹ̀yà ológbò yìí ni kìnnìún orí òkè, catamount, àmọ̀tẹ́kùn, painter, ẹkùn pupa, àti ẹkùn ìgalà.
Dókítà Faiçal Simon, alábòójútó Ọgbà Ẹranko São Paulo tó tún jẹ́ ògbógi nípa àwọn ẹranko puma wí pé: “Ìhùwàsí ẹranko puma àti àwọn agbára ìlèṣeǹkan rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ jọ ti àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò ńlá mìíràn.” Ní tòótọ́, oríṣi ẹranko ẹ̀yà ológbò kan tó yàtọ̀ ni èyí, ó sì ń yàtọ̀ síra ní ti títóbi àti àwọ̀. Àwọn ẹ̀yà irú ọ̀wọ́ ẹranko puma tí a mọ̀ jákèjádò Amẹ́ríkà tó 30, 6 lára wọn wà ní Brazil.
Ṣó Yẹ Ká Pa Á Run?
Lójú ọ̀pọ̀ alágbo-ẹran ní Brazil àti níbòmíràn, ewu ńlá ni ẹranko puma, ó sì yẹ kí a máa yìnbọn pa á lójú ẹsẹ̀ tí a bá ti rí i ni. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ orúkọ burúkú tí a ń sọ ẹranko puma bí èyí tí ń pa ẹran ọ̀sìn nípakúpa tọ́ sí i ní gidi? Dókítà Simon sọ pé: “Bí àwọn ẹranko ìgbẹ́ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ó ṣọ̀wọ́n kí ẹranko puma tó pa ẹran ọ̀sìn. Ìgbà mélòó kan tó ṣẹlẹ̀ kò dá pípa ẹranko yìí run díẹ̀díẹ̀ láre. Ní gidi, àwọn alágbo-ẹran tí ń yìnbọn pa àwọn ẹranko puma wulẹ̀ ń pa ara wọn lára ni.” Lọ́nà wo?
Bí àpẹẹrẹ, ní Pantanal ti Brazil, ilẹ̀ àbàtà kan tó tóbi ju Gúúsù Korea lọ, níbi tí àìlóǹkà màlúù ti ń wọ́gbó kiri fàlàlà, àwọn alágbo-ẹran ń pa ẹranko puma. Dókítà Simon sọ pé, ní ìyọrísí rẹ̀, iye àwọn ẹranko armadillo—oúnjẹ tí ẹranko puma yàn láàyò ní àgbègbè náà—ń yára pọ̀ sí i. Àwọn ẹranko armadillo jẹ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú tó ní nǹkan líle tó bo ara wọn, wọ́n tóbi bí ehoro, wọ́n sì ń gbẹ́ ihò. Láìsí àwọn ẹranko puma nítòsí, àwọn ẹranko armadillo ń sọ pápá ìjẹko Pantanal di pápá ìpẹran. Lọ́nà wo?
Ó dára, àwọn màlúù ń já sí àwọn kòtò náà, wọ́n ń ṣẹ́ lẹ́sẹ̀, wọ́n sì ń kú. Dókítà Simon wí pé: “Àwọn alágbo-ẹran wọ̀nyẹn ń pàdánù ẹran nísinsìnyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nítorí pé wọ́n ti pa àwọn ẹranko puma. Ó wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan péré sí i nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ènìyàn bá ń tọwọ́ bọ ìṣẹ̀dá lójú.”
Àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i ní Amẹ́ríkà ń fẹ́ kí a dáàbò bo ẹranko puma. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ ní àwọn apá kan Àríwá Amẹ́ríkà ti ṣe àwọn òfin ìdáàbòbo-ẹranko puma láti pààlà sí ṣíṣọdẹ ẹranko ẹ̀yà ológbò náà, kí a sì dáàbò bo ibùgbé àdánidá rẹ̀.
Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ní ìhà ìwọ̀ oòrùn United States, ẹranko puma ti ń padà di púpọ̀, ó ti tún ń wà ní àwọn ibi tó ti wà tẹ́lẹ̀ rí. Lóòótọ́, gbogbo ènìyàn kọ́ ló dunnú sí èyí, ṣùgbọ́n àwọn tó dunnú sí i pọ̀. Ìwé ìròyìn Smithsonian sọ pé ẹranko puma “ti ṣe . . . ìyípadà jíjọjú láàárín ìwọ̀n àkókò kúkúrú gan-an, láti ipò jíjẹ́ ewu ńlá sí ipò jíjẹ́ ẹranko tí a fọkàn fẹ́ gidigidi.”
Àwọn olùfẹ́ ìṣẹ̀dá àti àwọn ọdẹ fọkàn fẹ́ ẹranko puma. Ní ti àwọn tàkọ́kọ́, ẹranko ẹ̀yà ológbò náà jẹ́ àmì ọlọ́lá ńlá ti aginjù, ṣùgbọ́n, ní ti àwọn tìgbẹ̀yìn, ó jẹ́ àmì ẹ̀yẹ kan. Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni ẹranko puma yóò ṣe jẹ́ méjèèjì pẹ́ tó?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹranko ẹ̀yà ológbò tó tóbi jù lọ ní Amẹ́ríkà ni ẹranko jaguar; wo Jí!, February 22, 1991, ojú ìwé 25 sí 27.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ṣé “Ó Fẹ́ Láti Máa Ṣe Àjọgbé”?
Kì í ṣe pé àwọn òfin tí ń dáàbò bo ẹranko puma, tàbí ẹranko cougar níhà ìwọ̀ oòrùn United States ti mú kí ó pọ̀ sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún yọrí sí àfikún ìkọlura láàárín àwọn ẹranko puma àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Ohun tó fà á ṣe kedere: Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń gbé ẹ̀bá ijù—ẹkùn ilẹ̀ ẹranko puma—tí ń fa ìṣòro ààbò aráàlú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbéjàkoni láti ọ̀dọ̀ ẹranko puma ṣì ṣọ̀wọ́n.
Àwọn olùwádìí ti ṣàkọsílẹ̀ ìgbéjàkò 65 tí ẹranko puma ti gbéjà ko ènìyàn ní United States àti Kánádà láti 1890—tó túmọ̀ sí nǹkan bí ìgbéjàkò 3 láàárín ọdún márùn-ún. Lára àwọn ìgbéjàkò 65 wọ̀nyẹn, bóyá 10 yọrí sí ikú. Ní ìfiwéra, ní United States nìkan, nǹkan bí 40 ènìyàn ni oyin ń ta pa lọ́dún.
Onímọ̀ nípa ẹ̀dá abẹ̀mí inú ìgbẹ́, Kevin Hansen, sọ pé: “Lójú àwọn ẹ̀rí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, gbígbéjàko-ènìyàn ṣọ̀wọ́n lọ́nà tó yani lẹ́nu gan-an, tó fi hàn pé ẹranko cougar múra tán gidigidi láti máa ṣe àjọgbé, ó kéré tán, níbi tí ọ̀ràn bá ti kan àwọn ẹ̀dá ènìyàn.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn àwòrán: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure São Paulo Zoo