Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn lè “yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́,” kí ni a gba Tímótì nímọ̀ràn láti máa ṣe? (2 Tímótì 4:4, 5)
2. Àwọn òṣìṣẹ́ ààfin méjì wo ni wọ́n di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí Ọba Ahasuwérúsì? (Ẹ́sítérì 2:21)
3. Kí ni Nímírọ́dù fi hàn pé òun jẹ́? (Jẹ́nẹ́sísì 10:9)
4. Ta ni ìyàwó Ábúráhámù kejì? (Jẹ́nẹ́sísì 25:1)
5. Báwo ni Jésù ṣe mú obìnrin tí “ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá” lára dá? (Máàkù 5:27-29)
6. Ní ṣíṣàpèjúwe bí yóò ṣe ṣòro tó “fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run,” kí ni Jésù sọ pé ó rọrùn jù? (Lúùkù 18:25)
7. Ẹ̀rí ìdánilójú bíbófinmu wo ni Ọlọ́run lò láti pèsè àfikún ìdánilójú nípa ìlérí rẹ̀? (Hébérù 6:17)
8. Ẹ̀yà wo ní ara ère tí Nebukadinésárì rí lójú àlá ló jẹ́ irin àti amọ̀? (Dáníẹ́lì 2:41, 42)
9. Irúgbìn wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wọ́n ẹ̀jẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn kí áńgẹ́lì Ọlọ́run lè dá àkọ́bí wọn sí? (Ẹ́kísódù 12:22)
10. Ẹranko wo ni wọ́n ń sábà lò jù fún ogun jíjà láyé ìgbàanì? (Ẹ́kísódù 15:21)
11. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà kò lè ṣe? (Hébérù 6:18)
12. Ibo ni Jèhófà fún Èlíjà nítọ̀ọ́ni láti fi ara pamọ́ sí, kí ẹyẹ ìwò sì máa bọ́ ọ? (1 Àwọn Ọba 17:3)
13. Ta ni Jèhófà yanṣẹ́ fún láti máa ru àpótí májẹ̀mú? (Diutarónómì 10:8)
14. Ta ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ “ẹni àyànfẹ́ nínú Olúwa”? (Róòmù 16:13)
15. Ta ni bàbá Ṣékémù, tí a tún pa lẹ́yìn tí Ṣékémù fipá bá Dínà lò pọ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 34:26)
16. Ta ni bàbá Ábúráhámù (Jóṣúà 24:2)
17. Kí ni Ọlọ́run béèrè pé kí a san bí ìràpadà fún àwọn àkọ́bí 273 tí àwọn ẹ̀yà mìíràn fi lé sí àwọn ọmọ Léfì? (Númérì 3:46, 47)
18. Bí olówó ẹrú kan ní Ísírẹ́lì bá ba ibo nínú ara ẹrù náà jẹ́ ní yóò mú kí a dá a sílẹ̀ lómìnira? (Ẹ́kísódù 21:26, 27)
19. Kí ni Jésù sọ pé yóò dáni sílẹ̀ lómìnira? (Jòhánù 8:32)
20. Nítorí ìdàníyàn tọ̀túntòsì àti wíwà ní ẹgbẹ́ òun ipò kan náà, kí ni Ọba Hírámù pe Sólómọ́nì? (1 Àwọn Ọba 9:13)
21. Igi wo, tí a mọyì nítorí òórùn ìtasánsán rẹ̀ àti bí ohun ìṣaralóge, ni a mẹ́nu kàn nínú Orin Sólómọ́nì nìkan? (Orin Sólómọ́nì 1:14)
22. Ní ìmúṣẹ ègún tí Jóṣúà gún, àwọn wo ni wọ́n kú nígbà tí bàbá wọn tún Jẹ́ríkò kọ́? (1 Àwọn Ọba 16:34)
23. Èròjà wo ni kò jẹ́ kí omi wọnú áàkì Nóà? (Jẹ́nẹ́sísì 6:14)
Àwọn Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. ‘Kí ó máa pa agbára ìmòye rẹ̀ mọ́, kí ó j ìyà ibi, kí ó ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, kí ó ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní kíkún’
2. Bígítánì àti Téréṣì
3. “Ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà”
4. Kétúrà
5. Ó fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù
6. “Fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá”
7. Ìbúra kan
8. Ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka
9. Hísópù
10. Ẹṣin
11. Purọ́
12. Àfonífoj ì olójú ọ̀gbàrá ti Kẹ́rítì
13. Ẹ̀yà Léfì
14. Rúfọ́ọ̀sì
15. Hámórì
16. Térà
17. Iye owó ìràpadà ṣékélì márùn-ún fún ẹnì kọ̀ọ̀kan
18. Ojú tàbí eyín
19. Mímọ òtítọ́
20. Arákùnrin
21. Làálì
22. Ábírámù àti Ségúbù
23. Ọ̀dà bítúmẹ́nì