ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/22 ojú ìwé 3
  • Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́pani”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́pani”
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìfararọ Tó Láǹfààní, Àìfararọ Tó Lewu
    Jí!—1998
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
  • Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/22 ojú ìwé 3

Àìfararọ—“Ayọ́kẹ́lẹ́pani”

“Àmì tí mo kọ́kọ́ rí ni pákáǹleke rírékọjá ààlà. Ó bẹ̀rẹ̀ nítòsí egungun àyà mi; ó ti yára dé èjìká, ọrùn, àti páárì mi; ó sì gba apá mi méjèèjì padà. Ńṣe ló dà bí pé erin kan rọ́ lù mí láyà. Agbára káká ni mo fi ń mí. Òógùn bò mí. Ìfun mi bẹ̀rẹ̀ sí ta wọ̀n-ìnwọ̀n-ìn, lẹ́yìn náà, ẹ̀dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rìn mí gan-an. . . . Nígbà tó yá, bí àwọn nọ́ọ̀sì ṣe gbé mi sórí bẹ́ẹ̀dì ilé ìwòsàn kan, mo rántí pé mo sọ tìyanutìyanu pé, ‘ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ló ń ṣe mí.’ Ẹni ogójì ọdún ni mí nígbà náà.”

BÍ DÓKÍTÀ Robert S. Eliot ṣe ṣàpèjúwe sísún tí ó sún mọ́ bèbè ikú ní ohun tí ó lé ní 20 ọdún sẹ́yìn nìyẹn nínú ìwé rẹ̀, From Stress to Strength. Lówùúrọ̀ ọjọ́ yẹn, ó lọ sí ìpàdé àpérò kan, ó sì sọ̀rọ̀ níbẹ̀—lọ́nà títakora, lórí ìkìmọ́lẹ̀ àrùn ọkàn-àyà. Lójijì, Dókítà Eliot, tí ó jẹ́ onímọ̀ ìṣe àti àrùn ọkàn-àyà, rí ara rẹ̀ nínú ipò tí ó pè ní “ẹni ì bá máa ṣètọ́jú tó jẹ́ òun la ń tọ́jú ní ẹ̀ka ìtọ́jú àrùn ọkàn-àyà.” Kí ni ó sọ pé ó fa ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ tí ó dé bá òun? Dókítà Eliot sọ pé: “Nínú lọ́hùn-ún, bí mo ṣe ń hùwà padà sí àìfararọ ló ń pa mí.”a

Bí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Dókítà Eliot ṣe fi hàn, àìfararọ lè yọrí sí ipò tí ń wu ìwàláàyè léwu. Ní gidi, ní United States, a ti so ó mọ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí ń ṣokùnfà ikú jù lọ. Àwọn àbáyọrí àìfararọ lè kóra jọ, lọ́nà tí a kò fura sí, láàárín àkókò kan, kí ó sì yọjú láìṣèkìlọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní ìdí rere fún pípe àìfararọ ní “ayọ́kẹ́lẹ́pani.”

Lọ́nà tí ó yani lẹ́nu, kì í ṣe àwọn tí wọ́n ní ìṣarasíhùwà onípò kìíní—tí ó jẹ́ ọ̀nà ìhùwà oníwàdùwàdù, oníjàgídíjàgan, àti ìbáradíje—nìkan ni pákáǹleke tí ó tan mọ́ àìfararọ lè ṣẹlẹ̀ sí. Àwọn tí ó jọ pé wọ́n ní àkópọ̀ ìwà tí ó fara rọ pẹ̀lú lè wà nínú ewu, ní pàtàkì, bí ìparọ́rọ́ wọn bá jẹ́ kìkì ṣíṣe ojú ayé lọ́nà ẹlẹgẹ́, bí ìdérí ìdáná onígáàsì tí a kò dè le. Dókítà Eliot nímọ̀lára pé èyí jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn òun. Ó wá kìlọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn pé: “O lè kú lójijì lónìí—láìmọ̀ pé a ti wé bọ́ǹbù kan tí a kẹ́ sílẹ̀ mọ́ ọkàn-àyà rẹ fún ọ̀pọ̀ ọdún.”

Ṣùgbọ́n ìkìmọ́lẹ̀ àrùn ọkàn-àyà àti ikú òjijì nìkan kọ́ ni ìṣòro tí ó so pọ̀ mọ́ àìfararọ, bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí yóò ṣe fi hàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìfararọ lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń fa ọ̀pọ̀ jù lọ ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, ìbàjẹ́ tí ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan tí ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ọkàn-àyà ń ṣe fún òpójẹ̀-àlọ pọ̀ jọjọ. Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu kí ẹnì kan fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn àmì ìkọlù àrùn ọkàn-àyà, bóyá kí ó gbà gbọ́ pé wíwulẹ̀ dín àìfararọ kù yóò wo òun sàn. Wo Jí!, December 8, 1996, ojú ìwé 3 sí 13.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́