Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Abẹ
LÁKỌ̀Ọ́KỌ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀fọ́rí tí ń ṣe Christine le gan-an, a rò pé kì í ṣe ìṣòro ńlá kan ni; ó ṣe tán, láàárín ọjọ́ kan ló ti lọ. Àmọ́ ńṣe ni ọrùn Christine gan pa. Lẹ́yìn náà, ẹ̀fọ́rí rẹ̀ padà wá, kò sì mọ nǹkan kan mọ́—àwọn àmì àrùn tí kì í sábà ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, áńbọ̀sì-bọ́sí ọmọ ọdún mẹ́jọ.
Ní ilé ìwòsàn, àyẹ̀wò ìlànà ìwádìí àrùn tí ń lo fọ́tò afẹ̀yà ara pàtó hàn tí a gbé jáde lórí kọ̀ǹpútà (CT) fi hàn pé Christine ní ìṣòro ìṣiṣẹ́gbòdì òpójẹ̀ (AVM) nínú ọpọlọ rẹ̀—ipò kan nínú èyí tí òpójẹ̀ àlọ ti lọ́ mọ́ òpójẹ̀ àbọ̀.a Bí Christine kò bá rí ìtọ́jú gbà, ó lè ní àrùn ẹ̀gbà aṣekúpani lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Títi di àìpẹ́ yìí, kìkì iṣẹ́ abẹ́ ọpọlọ tí ó kan líla ara ni a lè fi tọ́jú irú àwọn ìṣòro AVM bẹ́ẹ̀. Nínú ìlànà yìí, oníṣẹ́ abẹ́ náà yóò fa awọ orí sẹ́yìn, yóò sì la agbárí. Lẹ́yìn náà, ó ní láti ti ìsokọ́ra dídíjú ti àwọn iṣan àti ẹran ọpọlọ ṣíṣẹlẹgẹ́ síhìn-ín àti sọ́hùn-ún láti dé ibi tí ìpalára náà wà. Àwọn àyẹ̀wò àìsàn fi hàn pé láàárín 1995, àwọn ìṣòro ṣẹlẹ̀ nínú nǹkan bí ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn iṣẹ́ abẹ ìṣòro AVM tí a ṣe.
Àwọn òbí Christine yan lílo Abẹ Onítànṣán Gamma dípò abẹ tí a fi ń ṣiṣẹ́ abẹ́. Orúkọ rẹ̀ ń tanni jẹ bákan, nítorí pé Abẹ Onítànṣán Gamma náà kì í ṣe abẹ gidi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìhùmọ̀ kan tí ń fagbára fún 201 ìgbì ìtànṣán, tí a dorí rẹ̀ kọ ibi pàtó kan, tí ń kọjá lára agbárí tí wọn kò là. Agbára ìgbì kọ̀ọ̀kan kò tó láti ba ẹran ara tí ó ń lọ bá jẹ́. Ṣùgbọ́n a fìṣọ́ra dorí gbogbo 201 ìgbì náà kọ ibi tí ìpalára náà wà, kí ó sì gbé ìwọ̀n ìtànṣán púpọ̀ lọ síbẹ̀.
Nínú àwọn ìwádìí kan, Abẹ Onítànṣán Gamma náà kì í náni lówó púpọ̀, ọ̀ràn kí agbàtọ́jú ní ìṣòro àkóràn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ sì mọ níwọ̀n gan-an ju bó ti máa ń rí nínú iṣẹ́ abẹ inú ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ tí ó wọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni wọn ṣe ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà?
Ìgbésẹ̀ Mẹ́rin Nínú Iṣẹ́ Abẹ Lílo Agbára Ìtànṣán
Ìgbésẹ̀ mẹ́rin pàtó ni iṣẹ́ abẹ lílo Abẹ Onítànṣán Gamma ń gbà. Àkọ́kọ́, wọn óò fi férémù fífúyẹ́ kan gbá orí aláìsàn náà mú, èyí kò ní jẹ́ kí aláìsàn náà máa yí kiri nígbà ìtọ́jú náà. Ìkejì, wọn óò ya “àwòrán” ọpọlọ aláìsàn náà, yálà nípasẹ̀ àyẹ̀wò CT, èrọ ayàwòrán ìmújáde ìró onímágínẹ́ẹ̀tì (MRI), tàbí ẹ̀rọ ayàwòrán iṣan ọpọlọ. Lẹ́yìn náà, àwọn àwòrán ọpọlọ ni a gbé lọ sínú ìgbékalẹ̀ ìṣètò ìtọ́jú lórí kọ̀ǹpútà, tí ń ya ohun tí a ń wá gangan sọ́tọ̀, tí yóò sì pinnu apá ibi tó wà.
Níkẹyìn, ó tó àkókò fún ìpele ìṣètọ́jú náà, nígbà tí wọn óò gbé orí aláìsàn náà sínú akoto kan tí ó ní 201 ihò tí àwọn ìtànṣán gamma náà ń gbà. Báwo ni ìtọ́jú náà ṣe ń pẹ́ tó? Ìṣẹ́jú 15 sí 45 péré ni, àkókò yìí ni wọn óò kun aláìsàn náà lóorun níwọ̀nba, kò sì ní jẹ̀rora rárá.
Tí ìtọ́jú bá ti parí, aláìsàn náà yóò ṣì wà ní ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò, òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ni wọ́n sì sábà máa ń fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Christine tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ nìyí. Wọ́n ṣètọ́jú rẹ̀ ní ọjọ́ Thursday, wọ́n fi í sílẹ̀ kí ó máa lọ ní ọjọ́ Friday, ó sì padà sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ Monday tó tẹ̀ lé e.
Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Ìṣòro AVM Náà?
Iṣẹ́ abẹ lílo agbára ìtànṣán kì í mú ìṣòro ìṣiṣẹ́gbòdì òpójẹ̀ kúrò ní ti gidi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì ara àwọn òpójẹ̀ náà di púpọ̀, tí ó wá ń tipa bẹ́ẹ̀ dènà kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn lọ sí ìhà ibi tí ìṣòro náà wà. Ní àbáyọrí rẹ̀, ní nǹkan bí ọdún kan tàbí méjì, àwọn òpójẹ̀ tí ó lábùkù náà yóò ti dí pa pátápátá. Nígbà náà òpójẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ gbòdì náà yóò sún kì, yóò sì wá yòrò nínú ara lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
A tún ti lo Abẹ Onítànṣán Gamma láti ṣètọ́jú àwọn eéwo aṣèpalára kéékèèké tí a rí ààlà ibi tí wọ́n dé dáadáa àti láti ṣètọ́jú àwọn eéwo tí ń pẹ́ ju bó ti yẹ lọ, tí wọ́n máa ń ràn dé inú ọpọlọ láti inú egbò tó wà ní apá mìíràn nínú ara. Ní àfikún, àwọn àbáyọrí rẹ̀ nínú ìtọ́jú ìrora òjijì nínú iṣan iwájú orí (ipò ìrora kan tí ń kan iṣan iwájú orí), wárápá, àrùn Parkinson, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìrora kan tí a kò mọ ìdí rẹ̀, ń fi hàn pé nǹkan yóò ṣì dára.
Dájúdájú, àwọn eéwo àti àwọn ipò kan nínú ọpọlọ ṣì wà tí Abẹ Onítànṣán Gamma náà kò kápá wọn. A ṣì ń wọ̀nà bóyá àwọn ìlọsíwájú nínú iṣẹ́ abẹ inú ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ yóò ṣamọ̀nà sí àwọn ìtọ́jú tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. Ní báyìí ná, iṣẹ́ abẹ lílo Abẹ Onítànṣán Gamma ń fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn tí eéwo sọ ní ìrètí pé nǹkan yóò ṣì dára.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àyẹ̀wò CT jẹ́ àwòrán X ray tí ń fi apá kan ara hàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Bí Iṣẹ́ Abẹ Lílo Agbára Ìtànṣán Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Oníṣẹ́ abẹ iṣan ọpọlọ náà, Lars Leksell àti onímọ̀ biophysics Börje Larsson ṣàgbékalẹ̀ Abẹ Onítànṣán Gamma ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn. Leksell ṣàwárí pé ìwọ̀n tí ìtànṣán lílágbára kan fi ń rani lè wó àwọn ìpalára wíwọnilára inú ọpọlọ palẹ̀ láìlà á—kí ó má sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀jẹ̀ tàbí kí ó máà sí ewu àkóràn àrùn.
Leksell pe ìlànà rẹ̀ tuntun náà ní ìlànà iṣẹ́ abẹ lílo agbára ìtànṣán láti mú orí ohun èlò ẹlẹgẹ́ kan dé ibi pàtó nínú ọpọlọ. Níkẹyìn, àwọn dókítà wá ní ọ̀nà tí wọn óò fi máa ṣètọ́jú àwọn apá ibi tí kò ṣeé dé nínú ọpọlọ, láìsí pé wọ́n ń lo abẹ láti máa ti ìsokọ́ra dídíjú ti àwọn iṣan àti ẹran ọpọlọ ṣíṣẹlẹgẹ́ síhìn-ín àti sọ́hùn-ún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lílo ìlànà tuntun yìí ní láti dúró fún ọ̀pọ̀ ọdún kí a lè ṣe àwọn ìlànà ìyàwòrán ìgbàlódé, bí àyẹ̀wò CT àti MRI, fún rírí ẹ̀yà ara, tí ó lè tọ́ka ibi pàtó tí àwọn oníṣẹ́ abẹ ní láti dorí ìtànṣán náà kọ. Stockholm ni wọ́n gbé irin iṣẹ́ Abẹ Onítànṣán Gamma àkọ́kọ́ kalẹ̀ sí ní 1968.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin iṣẹ́ abẹ lílo abẹ onítànṣán gamma
1. Gbígbé férémù sípò
2. Yíyàwòrán ọpọlọ
3. Àwọn àwòrán orí kọ̀ǹpútà ń ṣèrànwọ́ nínú ìṣètò ìtọ́jú
4. Ìpele ìṣètọ́jú
[Credit Line]
Àwọn àwòrán nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Elekta Instruments, Inc., tó ṣàmújáde Abẹ Onítànṣán Gamma®