Igi Òpòpó—Igi Kan Dá Igbó Ṣe
LÁTI ỌWỌ́ AṢÒJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ INDIA
IGI púpọ̀ ló sábà máa ń di igbó. Àmọ́ igi kan dá igbó ṣe níbì kan. Òpòpó jẹ́ àràmàǹdà igi tí ó lè máa gbilẹ̀ títí tí yóò fi bo agbègbè tí ó ju hẹ́kítà méjì lọ! Báwo ni ó ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í hù? Báwo ni ó ṣe máa ń gbilẹ̀ títí ti a óò fi lè pè é ní igbó?
Igi òpòpó jẹ́ ọ̀kan láwùjọ àwọn irúgbìn tí ń yọ òdòdó tí a ń pè ní Urticale láti ìdílé Moraceae, tàbí ìdílé mulberry, tí ó ní nǹkan bí 800 irú ẹ̀yà irúgbìn ọ̀pọ̀tọ́ nínú. Igi òpòpó, tàbí ọ̀pọ̀tọ́ Bengal, máa ń bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ gígùn láti inú èso tí ó wà nínú imí àwọn ọ̀bọ, ẹyẹ, tàbí àdán, tí wọ́n jẹ èso òpòpó.
Àwọn hóró èso náà máa ń hù lára igi tí wọ́n bá wà, gbòǹgbò wọn sì máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó jẹrà tí ó gbára jọ sínú ẹ̀là igi. Ipò ọ̀rinrin máa ń ran àwọn gbòǹgbò igi tuntun náà lọ́wọ́ láti yára dàgbà; wọ́n yóò fẹ̀ lára ẹ̀là igi tí wọ́n wà, wọn óò sì hù wọnú ilẹ̀ lọ. Bí wọ́n ti ń lágbára, tí wọ́n sì ń tóbi sí i, wọn óò wá fún igi tí wọ́n wà lára rẹ̀ pa, tí ó jẹ́ ìdí tí a fi fún irú igi yìí ní orúkọ náà, ọ̀pọ̀tọ́ afúnǹkanpa.
Wàyí o, igi òpòpó ti ṣe tán láti gbilẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn gbòǹgbò rẹ̀ ń gbilẹ̀ láti ìdí ìyá igi náà nìkan ni àmọ́ bí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣe ń gùn sókè sí i, àwọn gbòǹgbò tí ó yọ síta máa ń ṣàn wálẹ̀ láti ara wọn, wọn óò sì fìdí ara wọn múlẹ̀ nínú yẹ̀pẹ̀. Dídi igbó ti bẹ̀rẹ̀.
Igi òpòpó tí ó ní ewé ńlá, fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, tí a máa ń rí ní agbègbè olóoru Áfíríkà àti India, ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìbòrí fún àwọn ènìyàn àti ẹranko. Ọ̀kan tí ó wà ní India gbòòrò gan-an débi tí wọ́n fi sọ pé àwọn ènìyàn tí ó lé ní 20,000 lè wà lábẹ́ rẹ̀! Èso rẹ̀ kò dára fún ènìyàn láti jẹ, igi òpòpó rọ̀, ó sì ní ihò fótófótó; bí ó ti wù kí ó rí, ohun funfun kan, tí ń lẹ̀ mọ́wọ́, tí wọ́n ń pè ní birdlime, tí ó wá láti inú igi náà, ni a máa ń lò láti mú ẹyẹ.
Báwo ni igi òpòpó ṣe máa ń pẹ́ tó? Ọ̀kan tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Andhra Pradesh ni a fojú díwọ̀n pé ó ti lé ní 600 ọdún; àwọn igi mìíràn tí a mọ̀, tí a ń dáàbò bò ti fi púpọ̀púpọ̀ lé ní ọdún 250. Bí igi òpòpó sì ṣe ń dàgbà tí ó sì ń gbilẹ̀ sí i kò lópin.
Igi òpòpó tí a tí ì mọ̀ sí èyí tí ó tóbi jù lọ wà ní Sri Lanka. Ó ní 350 ìdí igi ńláńlá àti ohun tí ó lé ní 3,000 ìdí igi kéékèèké tí gbogbo wọ́n so mọ́ ìyá igi kan. Láìpẹ́ yìí ni wọ́n wọn igi kan tí ó ní ohun tí ó lé ní 1,100 gbòǹgbò aṣètìlẹ́yìn àti ọwọ́ ìbòrí tí ó ju hẹ́kítà méjì lọ ní India, wọ́n sì rí i pé òun ni ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Àwọn ọkùnrin adìhámọ́ra mẹ́rin kan ló máa ń ṣọ́ ọ nígbà gbogbo kí àwọn ènìyàn má baà bà á jẹ́. Àwọn igi òpòpó mìíràn tí wọ́n lókìkí ní India ní nínú, ọ̀kan tí ó wà nítòsí Bangalore tí ó gba ilẹ̀ hẹ́kítà kan àti ẹ̀sún méjì, ó sì jẹ́ ibi ìjáde fàájì tí àwọn olùgbé ìlú ńlá náà yàn láàyò. Lẹ́yìn náà, òmíràn tí ó jẹ́ àgbàyanu wà ní ọgbà ẹranko Ranthambhore. Igi tí àkọsílẹ̀ olú ọba kan ní Mogul sọ nípa rẹ̀ ní 500 ọdún sẹ́yìn yìí máa ń pèsè ibòòji fún àwọn ẹyẹ, àdán, ejò, ọ̀kẹ́rẹ́, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹranko kéékèèké àti àwọn kòkòrò, ní àfikún sí pé ó jẹ́ ibi ìṣiré àti ibi ìṣọdẹ fún àwọn ẹkùn àti àwọn adọdẹpẹran mìíràn nínú ọgbà ẹranko náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, bóyá igi òpòpó tí àwọn ènìyàn mọ̀ jù lọ ní India ni èyí tí ó ti wà fún 240 ọdún ní Ọgbà Ọ̀gbìn Orílẹ̀-Èdè ní Calcutta. Ó ga ju mítà 24.5 lọ, ó gba ilẹ̀ hẹ́kítà 1.2, ó sì ní àwọn gbòǹgbò tí ó yọ síta tí iye wọn lé ní 1,800 tí orí rẹ̀ sì fẹ̀ ní mítà 420. Igbó ni lóòótọ́!
Ìsìn àti Igi Òpòpó
Látayébáyé ni àwọn ènìyàn ti ń jọ́sìn àwọn igi. Òpòpó pẹ̀lú kò sì gbẹ́yìn; wọ́n kà á sí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ ní India títí di òní olónìí. Àwọn igi mímọ́ ọlọ́wọ̀ ni a ronú pé wọ́n dúró fún àwọn ọlọrun àjúbàfún pàtàkì kan—ní ti igi òpòpó, ọlọrun Vishnu ni. Wọ́n kà á sí jíjọ́sìn ọlọrun àjúbàfún igi náà nígbà tí wọ́n bá ń gbin igi kan, tí wọ́n bá ń bomi rin ín, àti tí wọ́n bá ń ṣìkẹ́ rẹ̀.
Ní àwùjọ àwọn ẹ̀yà Polynesia ìgbàanì pẹ̀lú, wọ́n ka igi òpòpó sí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀. Wọ́n máa ń ṣe àwọn ayẹyẹ ìsìn ní gbàgede onígun mẹ́rin kan, tàbí tohua, èyí tí àwọn ènìyàn ti kọ́lé yí ká. Ní igun kan gbàgede náà ni a ti sábà máa ń rí tẹ́ḿpìlì kan tí igi òpòpó mímọ́ ọlọ́wọ̀ kan wà, tí wọ́n máa ń so ìdì egungun àwọn tí wọ́n ti kú lára àwọn mẹ́ḿbà ẹ̀yà náà tí wọ́n yọrí ọlá, rọ̀ sára ẹ̀ka rẹ̀.
Àwọn ará Europe ni wọ́n kọ́kọ́ fún igi ràbàtà yìí ní orúkọ náà. Ní Persian Gulf àti India, àwọn tí ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Europe ní ìgbà ìjímìjí rí i pé ọwọ́ títẹ́ rẹrẹ igi náà tí ó jọ ìbòrí pèsè ibòòji tí àwọn oníṣòwò máa ń da àwọn ọjà wọn sábẹ́ rẹ̀ láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ooru jíjó fòfò nítorí oòrùn. Nínú ètò ẹgbẹ́ àjẹbí àwọn onísìn Hindu, àwọn oníṣòwò náà wá láti inú ìpín lájorí ẹgbẹ́ náà tí wọ́n ń pè ní Vaisya, tí a sì mọ àwọn òpòpó, tí wọ́n jẹ́ ìsọ̀ǹgbè ẹgbẹ́ àjẹbí, gẹ́gẹ́ bí olùta ọkà àti àwọn wóróbo mìíràn. Nígbà tí wọ́n ṣàkíyèsí pé àwọn òpòpó yóò ta ọjà wọn lábẹ́ igi tí ó ní ibòòji yìí ni ó jẹ́ kí àwọn àjèjì wọ̀nyẹ́n máa pe igi náà ní òpòpó.
Ní ìgbà yẹn, àwọn òpòpó wọ̀nyẹn sábà máa ń wọ ẹ̀wù alápá péńpé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí ó ní àpò inú fún owó wọn. Nítorí pé aṣọ náà dára, ó sì rọrùn láti fọ̀, ó wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn òpòpó oníṣòwò débi tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í pe aṣọ náà ní òpòpó, nígbà tí ó yá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo orúkọ náà fún ẹ̀wù ọkùnrin tàbí ṣẹ́ẹ̀tì àwọ̀tẹ́lẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá lápá péńpé. Wọ́n ṣì ń lo orúkọ náà fún ṣẹ́ẹ̀tì àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọkùnrin ní India, àṣà wíwọ irú aṣọ yìí nígbà tí àwọn òpòpó bá ń ṣiṣẹ́ ṣì wà di òní olónìí.
Jẹ́ Kí Á Pọ́n Igi Òpòpó Kan
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti pọ́nkè dé àárín igi òpòpó bí? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí o bá ti ṣèbẹ̀wò sí Hyderabad ní gúúsù India rí. Machan, ilé àrójẹ òkè igi kan tí wọ́n kọ́ wọnú àwọn ẹ̀ka ràbàtà-ràbàtà igi òpòpó kan àti igi pipal alámùúlégbè rẹ̀, tí òun pẹ̀lú jẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, wà nítòsí Ibùdókọ̀ Òfuurufú Begumpet, tí ó sì sún mọ́ àárín gbùngbùn ìlú ńlá náà. Pọ́n àtẹ̀gùn nínípọn tí wọ́n fokùn ṣe náà kọjá àwọn pèpéle tí a fi là á láàárín. Ọparun, ewé àgbọn, àti okùn ni wọ́n fi ṣe ibi tí ó dúró sí. Òrùlé ṣóńṣó tí wọ́n fi ọparun ṣe náà yóò dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ oòrùn àti òjò bí o bá ṣe ń wọnú èyí tí ó ga jù lára àwọn yàrá ìjẹun méjì tí ibi tí wọ́n kọ́ ọ̀kan sí ga ju èkejì lọ. O ti wà ní mítà mẹ́sàn-án sí ilẹ̀. Àga dáradára tí wọ́n fi ikàn ṣe àti àwọn ohun ìṣọ̀ṣọ́ ìbílẹ̀ tí wọ́n gbé kọ́ ara ògiri pa kún ìmọ̀lára wíwà nínú igbó.
Gbàrà tí o bá ti jókòó, wọn óò fún ọ ní káàdì kan tí wọ́n ń pè ní Mowgli, orúkọ kan tí kò ṣàjèjì sí àwọn tí ń ka àwọn ìtàn Rudyard Kipling tí ó wà nínú ìwé The Jungle Book. Èyí pẹ̀lú pa kún ìmọ̀lára wíwà ní àyíká igbó. Wàyí o, rọra sinmẹ̀dọ̀ láti ní ìrírí àrà ọ̀tọ̀ ti jíjẹun láàárín igi òpòpó. Gbádùn àwọn èròjà díẹ̀ láti ilẹ̀ India, irú bíi biriyani tí èèlò dùn, èyí tí ó mú kí Hyderabad lókìkí, kebab, àti oríṣiríṣi àwọn oúnjẹ mìíràn.
Oúnjẹ rẹ ti tán, fi tìṣọ́ratìṣọ́ra sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn olókùn náà, wo ìtàkìtì omi kékeré àti ìkùdu àwọn lílì, sì jáde kúrò ní ilé àrójẹ orí igi tí ó wà lábẹ́ ìbòrí igi òpòpó yìí—igi tí ó lé máa gba ilẹ̀ lọ rẹrẹẹrẹ títí igi kan yóò fi dá igbó ṣe.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Igi òpòpó kan dá igbó ṣe
Lókè: Àyẹ̀wò fínnífínní igi òpòpó kan nínú Ọgbà Ọ̀gbìn Orílẹ̀-Èdè, Calcutta
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Igi òpòpó nínú Ọgbà Ọ̀gbìn Orílẹ̀-Èdè, Calcutta
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Machan, ilé àrójẹ tí ó wà nínú igi òpòpó kan, Hyderabad