ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 March ojú ìwé 32
  • Jẹ́ Onígboyà àti Olóòótọ́ Bíi Ti Bẹnáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Onígboyà àti Olóòótọ́ Bíi Ti Bẹnáyà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ní Ìgboyà Bíi Sádókù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • “Ìwọ Yóò Hùwà Lọ́nà Ìdúróṣinṣin”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 March ojú ìwé 32

ÀWỌN TÍ BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ WỌN

Jẹ́ Onígboyà àti Olóòótọ́ Bíi Ti Bẹnáyà

Jagunjagun tó nígboyà ni Bẹnáyà, ó sì bá Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì ṣiṣẹ́. Àlùfáà ni bàbá Bẹnáyà, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì kì í lo ohun ìjà ogun tàbí kí wọ́n jagun. Síbẹ̀ Bẹnáyà náà kópa nínú àwọn ogun tí wọ́n jà fún Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé ó nígboyà gan an. Bí àpẹẹrẹ, ó wọnú kòtò omi ó sì pa kìnnìún kan síbẹ̀, yàtọ̀ síyẹn ó pa ọmọ ogun kan tó tóbi fàkìàfakia. Torí pé Dáfídì fọkàn tán Bẹnáyà, ó fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.—2 Sám. 23:20-23.

Bẹnáyà dúró ti Dáfídì nígbà tí Ábúsálómù àti Ádóníjà dìtẹ̀ mọ́ ọn. (2 Sám. 8:18; 15:18; 1 Ọba 1:8) Nígbà tí Dáfídì sì darúgbó, Bẹnáyà ràn án lọ́wọ́ kó lè fi Sólómọ́nì jọba. (1 Ọba 1:32-40) Bẹnáyà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àtàwọn tó yàn sípò báwọn míì ò tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

Ó yẹ káwa náà nígboyà ká lè kojú Sátánì ọ̀tá wa àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn. Ó tún yẹ ká pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ làá máa ṣe láyé wa. (Éfé. 6:11; 1 Pét. 5:8, 9) Kódà táwọn kan bá tiẹ̀ sọ pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́, àwa ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ torí ó dá wa lójú pé ó máa san wá lérè.—2 Sám. 22:26.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́