ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 December ojú ìwé 26-30
  • Ẹ̀yin Àgbàlagbà, Ẹ Wúlò Gan-an Nínú Ìjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Àgbàlagbà, Ẹ Wúlò Gan-an Nínú Ìjọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́ KÓ O ṢE
  • O LÈ FÚN ÀWỌN MÍÌ NÍṢÌÍRÍ
  • JÈHÓFÀ MỌYÌ GBOGBO OHUN TÓ Ò Ń ṢE
  • MÁA RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́
  • Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jẹ́ Kí Inú Ẹ Máa Dùn Bó O Ṣe Ń Ṣe Gbogbo Ohun Tó O Lè Ṣe fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ǹjẹ́ O Mọyì Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 December ojú ìwé 26-30
Fọ́tò: Àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà. 1. Arákùnrin kan gbójú sókè, ó ń rẹ́rìn-ín músẹ́. 2. Arábìnrin kan tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláìlera ń fún ọ̀kan lára àwọn tó ń tọ́jú wọn ní ìwé kékeré kan. 3. Arábìnrin kan ń dáhùn nípàdé. 4. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ di arábìnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́ mú nígbà tí wọ́n ń wàásù. 5. Arákùnrin kan ń bá àwọn ọmọ kékeré méjì àti ìyá wọn sọ̀rọ̀ ní ilé ìpàdé.

Ẹ̀yin Àgbàlagbà, Ẹ Wúlò Gan-an Nínú Ìjọ

“Tí mo bá ronú nípa àwọn nǹkan tí mo lè ṣe nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń yà mí lẹ́nu gan-an pé mi ò lè ṣe é mọ́ torí àgbà ti dé báyìí.”—Arábìnrin Connie tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83).

Ó ṣeé ṣe kíwọ náà má lè ṣe àwọn nǹkan tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́ torí ara tó ti ń dara àgbà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún lo ti ń sin Jèhófà bọ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí ò tọ́ torí pé o ò lè ṣe tó bó o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó o máa rántí àwọn nǹkan tó o ti ṣe sẹ́yìn, kó o wá máa fi wé àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́ KÓ O ṢE

O lè bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà fẹ́ kí n ṣe?’ Ohun tó wà ní Diutarónómì 6:5 lè tù ẹ́ nínú, ó sọ pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”

Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jèhófà fẹ́ kó o fi gbogbo ọkàn, ara àti okun rẹ sin òun. Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o máa fi ara ẹ wé àwọn míì tàbí kó o máa fi àwọn nǹkan tó o ti ṣe sẹ́yìn wé àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí.

Rò ó wò ná: Nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ṣé gbogbo ohun tágbára ẹ gbé lo ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Ó sì dájú pé ìwọ náà ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nígbà yẹn. Ṣé gbogbo ohun tágbára ẹ gbé lò ń fún Jèhófà báyìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tó o máa lè ṣe torí pé ara ti dara àgbà. Gbogbo ohun tágbára ẹ gbé báyìí nìyẹn. Tó o bá gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, wàá rí i pé ohun tó ò ń ṣe fún Jèhófà nígbà yẹn náà lò ń ṣe báyìí. Gbogbo ohun tágbára ẹ gbé lo ṣe nígbà yẹn, gbogbo ohun tágbára ẹ gbé náà lo sì ń ṣe báyìí.

Fọ́tò: Arábìnrin kan tó ti ń fi òótọ́ inú sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. 1. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, arábìnrin náà ń wàásù fún obìnrin kan. 2. Ní báyìí tí arábìnrin náà ti dàgbà, òun àti arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ jọ ń wàásù lórí fóònù.

Bó o ṣe ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nígbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ náà lò ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé báyìí tó o ti dàgbà

O LÈ FÚN ÀWỌN MÍÌ NÍṢÌÍRÍ

Ohun míì tó yẹ kó o ronú lé lórí nìyí: Dípò kó o máa ronú lórí àwọn nǹkan tí o ò lè ṣe mọ́ torí pé o ti dàgbà, ṣe ló yẹ kó o máa ro ohun tó o lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn nǹkan kan wà tí o ò lè ṣe nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ àmọ́ tó o lè ṣe báyìí torí pé o ti dàgbà. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí:

Sọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ fáwọn míì. Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn kan sọ nínú Bíbélì:

Ọba Dáfídì: “Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó, síbẹ̀ mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”—Sm. 37:25.

Jóṣúà: “Ẹ wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú, ẹ sì mọ̀ dáadáa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara yín pé kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.”—Jóṣ. 23:14.

Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fáwọn èèyàn kó o lè fún wọn níṣìírí. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì àti Jóṣúà sọ yìí kì í ṣe àsọdùn rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn àtohun tójú wọn ti rí fún ọ̀pọ̀ ọdún ló mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn ló jẹ́ kọ́rọ̀ náà dùn lẹ́nu wọn.

Tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ tó o ti ń sin Jèhófà, o lè sọ àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún ẹ fáwọn èèyàn. Ṣé o rántí ìgbà kan tí Jèhófà ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè sọ ìrírí yẹn fáwọn míì. Bí ìrírí yẹn ṣe wọ̀ ẹ́ lọ́kàn nígbà yẹn, ó lè rí bẹ́ẹ̀ fáwọn náà. Torí náà, tó o bá sọ àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ fáwọn ará, ó dájú pé wàá fún wọn níṣìírí.—Róòmù 1:11, 12.

Ọ̀nà míì tó o lè gbà fún àwọn ará níṣìírí ni pé kó o máa lọ sípàdé lójúkojú bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè fún àwọn ará níṣìírí, àwọn náà á sì fún ẹ níṣìírí. Arábìnrin Connie tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bí mo ṣe ń lọ sípàdé lójúkojú ni ò jẹ́ kí n rẹ̀wẹ̀sì. Báwo ni inú mi ò ṣe ní dùn pẹ̀lú gbogbo báwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń fìfẹ́ hàn sí mi tí mo bá lọ sípàdé? Èmi náà máa ń fún wọn láwọn ẹ̀bùn kéékèèké kí n lè fi hàn pé mo mọyì wọn. Mo sì ti pinnu pé mi ò ní yéé jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.”

JÈHÓFÀ MỌYÌ GBOGBO OHUN TÓ Ò Ń ṢE

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tí ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ àmọ́ tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn ló wà nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ti dàgbà. Síméónì lórúkọ ẹ̀, ó ṣì wà láyé nígbà tí wọ́n bí Jésù. Tí Síméónì bá lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó ṣeé ṣe kó rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì níbẹ̀. Àmọ́ Síméónì ńkọ́? Tá a bá ní ká fojú èèyàn wò ó, Síméónì lè máa rò ó pé torí pé òun ti darúgbó, òun ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò lójú Jèhófà mọ́ bíi tàwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn. Àmọ́ ohun tí Jèhófà rí kọ́ nìyẹn. Ó rí i pé “olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn” ni Síméónì. Torí náà, Jèhófà fún un láǹfààní láti rí Jésù nígbà tí wọ́n bí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún jẹ́ kí Síméónì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù ló máa di Mèsáyà. (Lúùkù 2:25-35) Ó hàn gbangba pé kì í ṣe ara Síméónì tó ti hun jọ ni Jèhófà rí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó rí i pé Síméónì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, “ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀.”

Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ kékeré, inú Jósẹ́fù àti Màríà dùn bí wọ́n ṣe gbé e wá sọ́dọ̀ Síméónì.

Jèhófà fún Síméónì láǹfààní láti rí Jésù nígbà tí wọ́n bí i, ó sì tún jẹ́ kó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù ló máa di Mèsáyà

Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń fòótọ́ inú sìn ín bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Lójú Jèhófà, iṣẹ́ ìsìn ẹ máa ‘túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tó o ní lo fi ṣe é, kì í ṣe ohun tó ò ní.’—2 Kọ́r. 8:12.

Torí náà, ohun tó o lè ṣe ni kó o gbájú mọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú nípa onírúurú ọ̀nà tó o lè gbà wàásù, bó tiẹ̀ jẹ́ fún àkókò díẹ̀. O tún lè ronú nípa arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó o lè pè lórí fóònù tàbí kọ lẹ́tà sí kó o lè fún un níṣìírí. Tó o bá ṣe àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan yìí fáwọn ará, á múnú wọn dùn gan-an, á sì gbé wọn ró. Pàápàá tó bá jẹ́ pé ìwọ tó o ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún lo ṣe é fún wọn.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn àtàwọn nǹkan míì lè má jẹ́ kẹ́yin àgbàlagbà ṣe tó bẹ́ ẹ ṣe fẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ ṣì lè ṣe fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wo ìrírí arábìnrin kan ní East Africa nínú àpótí náà “Ó Gbẹ̀mí Ẹ̀ Là.”

Máa rántí pé bó o ṣe ń sin Jèhófà tọkàntọkàn fún ọ̀pọ̀ ọdún láìbọ́hùn lè fún àwọn ará níṣìírí. Yàtọ̀ síyẹn, àpẹẹrẹ rere lo jẹ́ fáwọn ará bó o ṣe ń fara dà á. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ ẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀ bí o ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí o sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.’—Héb. 6:10.

MÁA RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́

Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ máa ń ní ìlera tó dáa, wọ́n máa ń ronú bó ṣe tọ́, wọ́n sì máa ń pẹ́ láyé.

Ká sòótọ́, ti pé à ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn ò sọ pé a máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa mú ohun tó ń fa ọjọ́ ogbó àti ikú kúrò pátápátá, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù.—Róòmù 5:12.

Àmọ́ bó o ṣe ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tó o sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ ọ́n máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kí ìlera ẹ dáa sí i. Torí náà, ẹ̀yin àgbàlagbà wa ọ̀wọ́n, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé Jèhófà mọyì ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Bákan náà, àpẹẹrẹ àtàtà lẹ jẹ́ fáwọn ará bẹ́ ẹ ṣe nígbàgbọ́ tó lágbára.

Arábìnrin àgbàlagbà kan ń wàásù níbi ìpàtẹ ìwé. Nígbà tí arábìnrin náà ka ẹsẹ Bíbélì kan fún ọ̀dọ́bìnrin kan, omijé bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú ọ̀dọ́bìnrin náà.

Ó Gbẹ̀mí Ẹ̀ Là

Lọ́jọ́ kan, ọ̀dọ́bìnrin kan ń kọjá níbi tá a pàtẹ ìwé wa sí. Lẹ́yìn tí arábìnrin àgbàlagbà tó wà nídìí ìpàtẹ ìwé náà kí ọ̀dọ́bìnrin yẹn, ó bi í bóyá òun lè ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un. Ó ka Jeremáyà 29:11 níbi tí Jèhófà ti sọ pé èrò àlàáfíà lòun ń rò nípa wa, kì í ṣe ti àjálù. Arábìnrin náà wá bi í pé, “Ṣé o kíyè sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ẹ lọ́jọ́ iwájú?”

Inú ọ̀dọ́bìnrin náà dùn gan-an débi pé omijé bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú ẹ̀. Ó dá arábìnrin náà lóhùn, ó ní: “Ọlọ́run fẹ́ kí n nírètí, kí n sì mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ẹ ṣeun gan-an tẹ́ ẹ ka ẹsẹ Bíbélì yìí fún mi. Ṣe lohun tẹ́ ẹ ṣe yìí jẹ́ kí n rí i pé Ọlọ́run gbọ́ àdúrà mi. Ìdí ni pé ṣe ni mo kàn ń ti orí ìṣòro kan bọ́ sórí òmíì lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. Ó le débi pé mo ti ń ronú láti pa ara mi. Kódà láàárọ̀ yìí, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ táá jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Ó wá yà mí lẹ́nu pé ẹ̀yin tẹ́ ò mọ̀ mí rí dá mi dúró, ẹ sì ka ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ kí n mọ ohun tí Ọlọ́run ń rò nípa mi fún mi. Mi ò gbà pé ṣe ló kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀.”

Arábìnrin náà fi oríṣiríṣi àpilẹ̀kọ han ọ̀dọ́bìnrin náà lórí jw.org. Àwọn àpilẹ̀kọ náà sọ bí Bíbélì ṣe lè ran ẹni tó bá ń ronú láti gbẹ̀mí ara ẹ̀ lọ́wọ́. Arábìnrin náà tún sọ bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún un, ó sì ní kó wá sáwọn ìpàdé wa. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ọ̀dọ́bìnrin náà wá sípàdé tá a ṣe lópin ọ̀sẹ̀, ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé báyìí.

Bóyá ọmọdé ni wá tàbí a ti dàgbà, gbogbo wa la lè wàásù níbi ìpàtẹ ìwé.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́