ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 April ojú ìwé 14-19
  • Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Tọ́ Nígbà Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Tọ́ Nígbà Ìṣòro
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÈRÒ TÓ YẸ KÁ NÍ NÍPA ÀWỌN ÌṢÒRO WA
  • BÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́ ṢE LÈ PA WÁ LÁRA
  • ÀWỌN NŃKAN TÁ A LÈ ṢE TÍṢÒRO BÁ DÉ
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fàwọn Ìṣòro Rẹ Jẹ Ẹ́ Níyà?
    Jí!—2009
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 April ojú ìwé 14-19

JUNE 15-21, 2026

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin

Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Tọ́ Nígbà Ìṣòro

“Bí wàhálà àti ìṣòro tilẹ̀ bá mi, síbẹ̀, mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ.”—SM. 119:143.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Tá a bá ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìṣòro wa, á rọrùn fún wa láti fara dà á, ká sì máa láyọ̀.

1-2. Kí la lè ṣe ká lè fara da àwọn ìṣòro wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

ÀWỌN ìṣòro wo lò ń bá yí? Ṣé àwọn èèyàn ló ń hùwà ìkà sí ẹ, àbí àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ ló ń ta kò ẹ́ torí ohun tó o gbà gbọ́? Ṣé àìsàn kan ló ń bá ẹ fínra àbí ara ti ń dara àgbà? Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan burúkú kan ló ṣẹlẹ̀ sí ẹ, bóyá èèyàn ẹ kan ló kú? Bíi ti ọ̀pọ̀ àwa èèyàn Jèhófà, ó lè jẹ́ pé “wàhálà àti ìbànújẹ́” lò ń bá yí lọ́pọ̀ ìgbà.—Sm. 90:10.

2 Ká tó lè fara da àwọn ìṣòro wa, ká sì máa láyọ̀, a gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìṣòro náà. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ká tó lè fara da àwọn ìṣòro wa, ká sì borí ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa fojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣòro wa wò ó. Ṣe lọ̀rọ̀ yẹn dà bíi ti ẹnì kan tó ń wa mọ́tò lójú ọ̀nà. Tí wíńdò ọkọ̀ ẹ̀ bá dọ̀tí, kò ní lè rí àwọn kòtò tó wà lọ́nà. Àmọ́ tí wíńdò ẹ̀ bá mọ́, á rí ọ̀nà dáadáa, kò sì ní kó sí kòtò náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa (1) èrò tó yẹ ká ní nípa àwọn ìṣòro wa, (2) bí èrò tí kò tọ́ ṣe lè pa wá lára, àti (3) àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé.

Ẹnu ya ọkùnrin kan tó ń wa mọ́tò tí wíńdò ẹ̀ dọ̀tí nígbà tó rí i pé wọ́n ti dí ọ̀nà tó wà níwájú ẹ̀.

Tó bá jẹ́ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ìṣòro wa làwa náà fi ń wò ó, ìyẹn á jẹ́ ká lè fara dà á (Wo ìpínrọ̀ 2)


ÈRÒ TÓ YẸ KÁ NÍ NÍPA ÀWỌN ÌṢÒRO WA

3. Kí la gbọ́dọ̀ máa rántí nípa ayé burúkú yìí?

3 Kò sí ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní níṣòro nínú ayé burúkú yìí. Gbogbo wa la máa níṣòro torí pé aláìpé ni wá àti pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí. Bákan náà, bí ayé yìí ṣe ń kógbá sílé, ìṣòro á máa pọ̀ sí i. Àwọn àjálù bí omíyalé àti ìmìtìtì ilẹ̀ á máa ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn á máa hùwà burúkú. (Mát. 24:8; 2 Tím. 3:13) Tí Jèhófà bá yanjú àwọn ìṣòro yẹn lákòókò yìí, ṣe ló máa dà bí ìgbà tó ń ran Sátánì lọ́wọ́ láti ṣàkóso ayé. Torí náà, kò sí bá a ṣe fẹ́ ṣe é tá ò ní níṣòro.—Oníw. 9:12.

4. Àwọn ìṣòro míì wo làwa Kristẹni máa ń ní?

4 Àwọn ìṣòro míì wà táwa Kristẹni máa ń ní. Jésù sábà máa ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wọn torí ìgbàgbọ́ wọn. (Mát. 24:9; Jòh. 16:2) Ohun tá a mọ̀ yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ṣenúnibíni sí wa. (1 Tẹs. 3:3, 4) Torí náà tá a bá fara dà á, tá a sì jẹ́ olóòótọ́, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa, àá sì rí ìyè àìnípẹ̀kun. Yàtọ̀ síyẹn, à ń fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ìdí ni pé Sátánì ti sọ pé nǹkan tá à ń rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà ló ń mú ká sìn ín, kì í ṣe torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Torí náà, Sátánì máa ń jẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà fojú winá ìṣòro tó le gan-an ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 1:9-11) Tá a bá fara dà á torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó dájú pé inú ẹ̀ á dùn sí wa.—Òwe 27:11.

5. Kí la kọ́ látinú ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ nínú Oníwàásù 7:13, 14? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Jèhófà máa ń fàyè gbà á kí nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ nígbà míì. Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í ṣe ìkà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í fi ibi dán wa wò. (Jém. 1:13) Àmọ́, Ọba Sólómọ́nì pe “ọjọ́ àjálù” ní “iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.” (Ka Oníwàásù 7:13, 14.) Lọ́pọ̀ ìgbà, tí Bíbélì bá sọ pé Jèhófà ṣe ohun kan, ohun tó máa ń túmọ̀ sí ni pé Jèhófà fàyè gba nǹkan náà. Bọ́rọ̀ ṣe rí nínú ẹsẹ yìí náà nìyẹn. Báwo ni ohun tí Sólómọ́nì sọ yìí ṣe lè jẹ́ ká ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìṣòro wa? Lákọ̀ọ́kọ́, nínú ayé Sátánì yìí, ó yẹ ká máa rántí pé ìgbà gbogbo kọ́ ni nǹkan á máa lọ dáadáa. Torí náà, láwọn ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ọ̀dọ̀ ẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti ń wá. Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì sọ pé a ò lè sọ “pàtó ohun tó máa ṣẹlẹ̀” sí wa lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, bóyá rere lọ́jọ́ yẹn máa mú wá tàbí búburú. Òótọ́ kan ni pé àjálù lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nígbàkigbà, bóyá olódodo ni tàbí ẹni burúkú.

Fọ́tò: Ìgbà tí nǹkan ń lọ dáadáa fún ọkùnrin kan tó ní ọgbà àtìgbà tí nǹkan ò lọ dáadáa. 1. Inú ẹ̀ dùn nígbà tó ká tòmátì tó pọ́n dáadáa torí pé ọgbà ẹ̀ méso jáde. 2. Lọ́jọ́ mí ì, inú ẹ̀ ò dùn bó ṣe ń wo tòmátì tó bà jẹ́ torí pé ọgbà ẹ̀ kò méso jáde.

Torí pé inú ayé Sátánì la wà, ó yẹ ká máa rántí pé ìgbà gbogbo kọ́ ni nǹkan á máa lọ dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 5)


6. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń fàyè gbà á ká níṣòro? (Hébérù 12:7, 11)

6 Tá a bá fara balẹ̀ ronú lọ́nà tó tọ́ nígbà tá a bá níṣòro, àá rí i pé Jèhófà ń kọ́ wa ká lè gbẹ́kẹ̀ lé òun, dípò ká gbára lé ara wa. Jèhófà kì í fojú kéré ìṣòro wa, kì í sì í dá wa dá a. Tó bá tiẹ̀ fàyè gbà á pé ká rìn nínú “àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,” kò ní fi wá sílẹ̀, á máa tọ́ wa sọ́nà, á sì fún wa lókun ká lè fara dà á. (Sm. 23:4) Ìṣòro wa tún lè jẹ́ ká mọ àwọn ibi tá a kù sí. Tá a bá mọ ibi tá a kù sí, á wù wá láti ṣàtúnṣe, Jèhófà sì máa ràn wá lọ́wọ́. (Ka Hébérù 12:7, 11.) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà rí i pé ó yẹ kí Jóòbù túbọ̀ nírẹ̀lẹ̀. Òótọ́ ni pé Jèhófà kọ́ ló fa ìṣòro Jóòbù, síbẹ̀ ó fáyé gbà á kí Jóòbù lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀. (Jóòbù 42:1-6) Ìṣòro yòówù ká ní, a mọ̀ pé bópẹ́ bóyá Jèhófà máa fòpin sí i. Tá a bá fara dà á, tá ò sì bọ́hùn, ó dájú pé a máa “ja àjàṣẹ́gun.”—Róòmù 8:35-39.

7. Kí ló máa jẹ́ ká láyọ̀ tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́?

7 A lè láyọ̀ tí wọ́n bá tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí ẹ torí ohun tó o gbà gbọ́, má ṣe rò pé inú Jèhófà ò dùn sí ẹ. Kódà, ṣe ni àtakò tí wọ́n ń ṣe sí ẹ fi hàn pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ. (Mát. 5:10-12) Tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí la ní tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, ìyẹn á jẹ́ ká máa láyọ̀ bíi tàwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 5:40-42) Bákan náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò, ìyẹn lè mú káwọn míì wá mọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ‘yìn ín lógo.’ (1 Pét. 2:12) Bíi ti Jósẹ́fù, kì í ṣe ìgbà tí ìṣòro wa bá lọ nìkan lọ́kàn wa máa balẹ̀, a tún lè láyọ̀ kódà lásìkò tá à ń kojú ìṣòro.—Jẹ́n. 39:3, 23.

8. Kí ló tún máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa?

8 Àwọn ìṣòro wa máa dópin lọ́jọ́ kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù jẹ́ ká mọ̀ pé, bópẹ́ bóyá àwọn ìṣòro wa máa dópin lọ́jọ́ kan. Kódà Bíbélì sọ pé: “Jèhófà wá bù kún ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:12) Lọ́nà kan náà, Jèhófà máa bù kún wa gan-an nínú ayé tuntun, ìyẹn sì ju ìtura èyíkéyìí tá a lè rí nínú ayé tó ti ń kógbá sílé yìí. Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí ohun tá a mọ̀ yìí mú ká fara dà á dópin!—Mát. 24:13.

BÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́ ṢE LÈ PA WÁ LÁRA

9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìṣòro wa?

9 Ìṣòro yòówù ká ní, ó ṣe pàtàkì ká ní èrò tó tọ́ torí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè dá kún ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ, a lè rò pé Jèhófà ló fa ìṣòro wa. Ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Ìgbà kan wà tó rò pé Jèhófà ló fa ìṣòro òun, èrò tó ní yìí ló mú kó máa sọ pé “òun jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ.” (Job 32:2) Bákan náà, Náómì kọ́kọ́ sọ pé Jèhófà ló fa àwọn àjálù tó bá òun. (Rúùtù 1:13, 20, 21) Ká sọ pé Jóòbù àti Náómì ò yí èrò wọn pa dà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n bínú, kí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní sin Jèhófà mọ́. (Òwe 19:3) Àmọ́, Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́, ó sì bù kún wọn torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

10. Kí ló ṣeé ṣe ká máa rò tá a bá níṣòro?

10 Tá ò bá tiẹ̀ sọ pé Jèhófà ló fa àwọn ìṣòro wa, ó ṣì lè máa ṣe wá bíi pé kò rí tiwa rò. Irú èrò yìí lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ká sì sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́. (Òwe 24:10) Àwọn ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Hábákúkù níṣòro, wọ́n sì ronú pé Jèhófà ò gbọ́ àdúrà àwọn. (Sm. 10:1; Háb. 1:2) Síbẹ̀, wọn ò dákẹ́ àdúrà. Jèhófà jẹ́ kó dá àwọn olóòótọ́ yìí lójú pé òun ò fi wọ́n sílẹ̀, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà.—Sm. 10:17.

11. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ní èrò tí ò tọ́ nípa àwọn ìṣòro wa?

11 Tá ò bá ní èrò tó tọ́, a lè máa ronú pé kò yẹ ká láwọn ìṣòro kan. Tírú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ bá wá dé, ó lè bá wa lójijì. (1 Pét. 4:12) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò gbà pé ó yẹ kí Jésù jìyà kó sì kú. (Lúùkù 18:33, 34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun, àpọ́sítélì Pétérù gbà pé kò yẹ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí i. Jésù mọ̀ pé irú èrò yìí lè mú kó ṣòro fún òun láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, torí náà ó bá Pétérù wí. (Máàkù 8:31-33) Kódà lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ò lóye ìdí tó fi jìyà tó sì kú. Síbẹ̀, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú òun. Nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó jíǹde, ó “ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún [wọn] ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,” ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó tọ́ nípa ìdí tó fi jìyà tó sì kú. (Lúùkù 24:25-27, 32, 44-48) Tí wọ́n bá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jésù ń kọ́ wọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tí wọ́n máa ní lọ́jọ́ iwájú torí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Táwa náà bá ń ronú nípa àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, á jẹ́ ká lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe ká ní lọ́jọ́ iwájú.

12. Tá a bá ní èrò tí ò tọ́ nípa ìṣòro wa, kí nìyẹn lè mú ká máa rò?

12 Tá a bá ní èrò tí ò tọ́, ó lè mú ká máa rò pé ìṣòro wa burú ju bó ṣe yẹ lọ. Jésù sọ ọ̀nà kan tíyẹn lè gbà ṣẹlẹ̀ nígbà tó sọ àpèjúwe kan nípa àwọn òṣìṣẹ́ inú ọgbà àjàrà. Àwọn òṣìṣẹ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé torí wọ́n ronú pé owó tí wọ́n san fáwọn ò tó, àmọ́ ọ̀gá iṣẹ́ náà sọ fún ọ̀kan lára wọn pé: “Ọ̀gbẹ́ni, mi ò hùwà àìtọ́ sí ọ.” (Mát. 20:10-13) Kì í ṣe torí pé ọ̀gá náà rẹ́ wọn jẹ ni wọ́n ṣe ń ṣàròyé, àmọ́ wọ́n ronú pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ sí owó tó ju iye tí ọ̀gá náà fún wọn lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iye tó yẹ kí wọ́n gbà ni ọ̀gá náà fún wọn. Lónìí, àwọn ará wa kan lè nírú èrò yìí. Wọ́n lè ronú pé àwọn ló yẹ kí wọ́n fún ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tí wọ́n fún ẹlòmíì tàbí pé kò yẹ kí wọ́n gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan táwọn ní. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè ní èrò tó tọ́ tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?

ÀWỌN NŃKAN TÁ A LÈ ṢE TÍṢÒRO BÁ DÉ

13. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tíṣòro bá dé?

13 O ṣeé ṣe kó o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìṣòro tá à ń ní. Kódà o lè ti lo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí láti tu àwọn míì nínú nígbà ìṣòro. Síbẹ̀, tí ìṣòro bá dé bá ẹ, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ronú lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè rò pé Jèhófà ló ń fìyà jẹ ẹ́, tàbí pé ṣe ni kò gbọ́ àdúrà ẹ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan wo lo lè ṣe?

14. Kí làwọn nǹkan tó o lè gbàdúrà nípa ẹ̀ tó o bá níṣòro? (Fílípì 4:13)

14 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Sọ àwọn ìṣòro tó o ní fún Jèhófà kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe rí lára ẹ. Tó o bá ń gbàdúrà, sọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ ní pàtó. Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kó sì fún ẹ ní okun àti ọgbọ́n tó o nílò láti fara dà á. Má gbàgbé pé Jèhófà lè dáhùn àdúrà ẹ lọ́nà tó ò lérò. (Éfé. 3:20) Ó tún lè lo àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 34:7) Torí náà, máa fiyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣe tán láti fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè fara da ìṣòro yòówù kó o ní.—Ka Fílípì 4:13.

15. Kí ló máa jẹ́ kó o lè fara da ìṣòro? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé o ò tiẹ̀ lè ṣe tó àwọn nǹkan tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, rí i pé ò ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nínú ìjọsìn Jèhófà. Ó yẹ kó o máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o máa ronú nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́, pàápàá lásìkò “wàhálà àti ìṣòro.” (Sm. 119:143) Bí àpẹẹrẹ, máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ṣèwádìí nípa ohun tó o kà, kó o sì máa ronú jinlẹ̀ nípa ẹ̀. Rí i pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, máa lọ sípàdé kó o sì máa dáhùn. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá wà, gbìyànjú láti máa wà pẹ̀lú àwọn ará, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ wọn.—Òwe 18:1.

Arákùnrin kan tó wà nílé ìwòsàn ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́” pẹ̀lú àwọn ará lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Òun náà gbé Bíbélì àti “Ilé Ìṣọ́” ẹ̀ dání.

Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Àwọn èrò tí ò tọ́ wo ló lè wá sí wa lọ́kàn tá a bá níṣòro, kí la sì lè ṣe sí i? (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5)

16 Mú èrò tí ò tọ́ kúrò lọ́kàn. Tí ìṣòro bá dé bá wa, ó lè mú ká ṣinú rò, ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara wa tàbí Jèhófà lẹ́bi. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí ló máa jẹ́ ká lè ronú lọ́nà tó tọ́? (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5.) Tá a bá ka Bíbélì, tá a sì ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run, àá ní “ìmọ̀ Ọlọ́run” èyí á sì jẹ́ ká lérò tó tọ́ nípa Jèhófà àti ara wa. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù, ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, àmọ́ dípò kó rẹ̀wẹ̀sì, ṣe làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i mú kó túbọ̀ dá a lójú pé inú Jèhófà àti Jésù ń dùn sí òun. (2 Kọ́r. 11:23-27) Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò tíì dárí jì ẹ́ torí àwọn nǹkan tí kò dáa tó o ti ṣe sẹ́yìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń dárí jì wá. (Àìsá. 43:25) Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, kó o sì ronú lórí wọn. (Sm. 119:97) Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan burúkú kan ló ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ṣèwádìí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ wá àti bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn bá a tiẹ̀ níṣòro. (Sm. 91:9-12) Bákan náà, ka ìrírí àwọn ará tó níṣòro tó le gan-an àtohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n lè fara dà á.a

17. Kí ló yẹ ká ṣe tíṣòro bá dé?

17 Ó ṣeé ṣe kí nǹkan máa lọ geerege fún ẹ báyìí, kó o má sì níṣòro tó ń mu ẹ́ lómi. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà kó o sì máa yìn ín torí àwọn nǹkan rere tó ń ṣe fún ẹ. (Oníw. 7:14) Àmọ́, tíṣòro bá dé, Jèhófà ni kó o gbẹ́kẹ̀ lé, má ṣe jẹ́ kí ìṣòro náà mú kó o ṣinú rò. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ‘ṣe ọ̀nà àbáyọ kó o lè fara dà á.’ (1 Kọ́r. 10:13) Àmọ́, báwo la ṣe lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro? Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Èrò wo ló yẹ ká ní nípa àwọn ìṣòro wa?

  • Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìṣòro wa?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tíṣòro bá dé?

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

a Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin David Maza tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ìṣẹ̀lẹ̀ Burúkú Kan Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Wa, àmọ́ A Pa Dà Láyọ̀” tó wà lórí jw.org, wàá rí ohun tó ran òun àti ìdílé ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tọ́mọ wọn kú.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́