OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Ohun Táá Jẹ́ Kó O Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́
Ọ̀pọ̀ wa lọwọ́ wa máa ń dí gan-an, ìyẹn sì lè jẹ́ kó nira fún wa nígbà míì láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? (Jóṣ. 1:8) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbìyànjú ọ̀kan lára àwọn àbá yìí:
Ṣe ohun tó máa rán ẹ létí. Lo àláàmù orí fóònù ẹ kó lè rán ẹ létí pé kó o ka Bíbélì.
Gbé Bíbélì ẹ síbi tí wàá ti máa rí i. Tó bá jẹ́ Bíbélì tá a tẹ̀ sínú ìwé lò ń kà, gbé e síbi tí wàá ti máa rí i lójoojúmọ́.—Diu. 11:18.
Máa gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Máa gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ bó o ṣe ń ṣe àwọn nǹkan tó ò ń ṣe lójoojúmọ́. Aṣáájú-ọ̀nà ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Tara, ó ti bímọ, iṣẹ́ alẹ́ ló sì ń ṣe. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ kí n ka Bíbélì lójoojúmọ́.”
Má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìka Bíbélì. Tí nǹkan tó ò retí bá ṣẹlẹ̀, tó ò sì lè ka Bíbélì lásìkò tó yẹ kó o kà á, rí i pé o ka ẹsẹ díẹ̀ kó o tó lọ sùn. Kódà tó bá jẹ́ ẹsẹ díẹ̀ lò ń kà lójúmọ́, wàá jàǹfààní ẹ̀.—1 Pét. 2:2.