ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 5
  • Ètò Kíka Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ètò Kíka Bíbélì
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Gbádùn Bíbélì Kíkà Sí I?
    Jí!—2001
  • Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 1
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Nípìn-ín Kíkún—Nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2002
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 5
Obìnrin kan ń wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka lórí jw.org

Ètò Kíka Bíbélì

Inú Bíbélì la ti lè rí ọgbọ́n tó dáa jù lọ téèyàn lè fi gbé ayé. Tó a bá ń kà á, tó ò ń ronú lé e lórí, tó o sì ń fi ohun tó o kọ́ sílò, “ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere.” (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3) Wàá tún mọ Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀, ìmọ̀ tó o ní yìí á sì jẹ́ kó o rí ìgbàlà.​—Jòhánù 17:3.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka

Ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé inú Bíbélì? Ohun kan wà tó o lè ṣe. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka yìí á jẹ́ kó o lè máa ka àwọn ìwé Bíbélì bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra wọn tàbí ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ka àwọn apá kan tó o yàn kó o lè mọ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lò. O sì tún lè ka apá míì láti mọ bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tó sì ń pọ̀ sí i. Tó o bá ń ka àwọn orí tá a yàn síbẹ̀ lójoojúmọ́, wàá parí Bíbélì lódindi láàárín ọdún kan.

Ìbáà jẹ́ ètò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ lò ń wá tàbí ti ọdọọdún tàbí èyí tó wà fẹ́ni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa ka Bíbélì, ètò Bíbélì kíkà yìí máa wúlò fún ẹ. Wa ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka tó ṣeé tẹ̀ yìí jáde, kó o sì bẹ̀rẹ̀ lónìí.

Wà á

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́