ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 32
  • Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Owó Ọkùnrin náà Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Owó Ọkùnrin náà Lọ
  • Jí!—1999
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 32

Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Gbé Owó Ọkùnrin náà Lọ

Nígbà tí ọkùnrin kan ń wọkọ̀ láti ìlú kan lọ sí òmíràn láàárín Nàìjíríà, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ó bá ọkùnrin kan tí wọ́n jọ wọkọ̀ sọ̀rọ̀ nípa “Àwọn Àṣà Tí Ọlọ́run Kórìíra,” ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Nígbà tí ọkọ̀ náà dúró nílé àrójẹ kan, ọkùnrin tí ìwé pẹlẹbẹ náà ti wọ̀ lọ́kàn yìí gbé àpò kan tó gbé dání síta, ó sì ṣàlàyé pé: “Owó ló wà nínú rẹ̀. . . . Inú àpò ọ̀kan lára àwọn èrò ọkọ̀, tó wà níbi ìkẹ́rùsí, ni mo ti jí i gbé.”

Àmọ́, ọkùnrin tó jí owó náà ti wá kábàámọ̀ ohun tó ṣe, ó sì fẹ́ dá owó náà padà fún ẹni tó ni í. Ọ̀dọ́mọkùnrin oníṣòwò kan, tí òun náà wà nínú ọkọ̀ kan náà sọ pé tòun ni àpò náà. Ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] náírà (nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán dọ́là) ló wà níbẹ̀. Olè tó ti ń tẹ̀ lé ẹni tó lowó náà fún nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà, wí fún oníṣòwò náà pé kí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó bá òun jíròrò ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Ó ṣàlàyé pé, ohun tí òun gbọ́ yẹn ló mú kí òun dá owó náà padà.

Nígbà tí awakọ̀ àti àwọn èrò ọkọ̀ yòókù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, gbogbo wọn sì béèrè fún ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà. Oníṣòwò náà kì í jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí bá òun sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó wá fẹ́ kí wọ́n máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nísinsìnyí.

O lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé méjìlélọ́gbọ̀n tó ṣeyebíye yìí gbà nípa kíkọ̀wé kún fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ sínú fọ́ọ̀mù náà tàbí sí àdírẹ́sì tó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé karùn-ún ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, gbà.

Kọ èdè tí o fẹ́

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́