ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 1/8 ojú ìwé 32
  • Ìwọ Ha Fẹ́ Mú Inú Ọlọ́run Dùn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Fẹ́ Mú Inú Ọlọ́run Dùn Bí?
  • Jí!—1999
Jí!—1999
g99 1/8 ojú ìwé 32

Ìwọ Ha Fẹ́ Mú Inú Ọlọ́run Dùn Bí?

Àìní kan nípa tẹ̀mí ha jẹ ọ́ lọ́kàn nínú ìgbésí ayé rẹ bí? Ó ha ń ṣe ọ́ bí ẹni pé ohun kan wà tó jọ pé ayé kan tí ó gbé àwọn ohun ìní ti ara lékè kò ní bí? Ìwọ ha fẹ́ mọ Ọlọ́run kí o sì ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ bí?

O lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ báwo ni mo ṣe fẹ́ ṣe é? Ṣé kò ṣòro láti ka Bíbélì kí n sì lóye rẹ̀ ni?’ Àwọn ènìyàn kan wà tó jẹ́ pé ìwé díẹ̀ ni wọ́n kà bóyá nítorí ipò ìṣúná owó tí kò rọrùn fún wọn, wọ́n sì lè ní ìṣòro ìwé kíkà. Báwo ni a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run àti ohun tí ó ń fẹ́ kí a ṣe kí a lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?

Ní ọdún 1996, Watch Tower Society ṣe ìwé kan jáde, tí ó ti wà ní èdè igba ó lé mọ́kànlá báyìí, tí a ń pè ní Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ó jẹ́ ìwé pẹlẹbẹ aláwọ̀ mèremère, olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n, tí a pín sí apá mẹ́rìndínlógún tí ó ní àwọn ìdáhùn tí ó rọrùn láti inú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè bíi: Ta ni Ọlọrun? Ta ni Jésù Kristi? Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé? Báwo ni o ṣe lè rí ìsìn tòótọ́? Ìwé pẹlẹbẹ náà tún jíròrò bí a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà àti bí a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé ìdílé tí inú Ọlọ́run dùn sí.

Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ yìí gbà, jọ̀wọ́ kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì gé e ránṣẹ́.

□ Ẹ fi ìsọfúnni síwájú sí i ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? gbà.

Sọ èdè tí o fẹ́

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́