ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/22 ojú ìwé 32
  • Kí Ló Dé Tí Kò Gba Ọlọ́run Gbọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí Kò Gba Ọlọ́run Gbọ́?
  • Jí!—1998
Jí!—1998
g98 6/22 ojú ìwé 32

Kí Ló Dé Tí Kò Gba Ọlọ́run Gbọ́?

OLESYA, ọ̀dọ́bìnrin kan ní Rustavi, Georgia, orílẹ̀-èdè olómìnira kan ní Soviet Union àtijọ́, fi fọ́tò àwọn òbí rẹ̀ han àwọn àlejò méjì kan, ó sì kígbe pé: “Ká ní Ọlọ́run wà ni, kò ní jẹ́ kí àwọn òbí mi kú nígbà tí wọ́n kéré gan-an bẹ́ẹ̀!” Lẹ́yìn tí ọkọ́ Olesya, Tamazi, dé, àwọn àlejò náà fún wọn ní àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”

Nígbà tí wọ́n padà lọ bẹ àwọn tọkọtaya náà wò, Olesya ti ka ìwé pẹlẹbẹ “Sawo o!” náà, ó sì ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó kà. Nígbà tí wọ́n ń jíròrò lẹ́yìn náà, ó yára ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà, ó sì ka àwọn ibi tí ó ti falà sí. Àlàyé bíbọ́gbọ́nmu tí ó wà níbẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn.

Fún àpẹẹrẹ, ìwé pẹlẹbẹ náà sọ pé: “Awọn ohun kayefi ológo tí ó yí wa ká naa—awọn òdòdó, awọn ẹyẹ, awọn ẹranko, iṣẹda tí ó kún fun iyanu tí a ńpè ní eniyan, iṣẹ-iyanu iwalaaye ati ti ọmọ bíbí—gbogbo iwọnyi nkede-jẹrii si Ọ̀gá Onírònúmòye kan tí a kò lè fojuri tí ó mú wọn jade wá. (Rome 1:20) Nibi tí ìrònúmòye bá wà, ero-inu wà nibẹ. Nibi tí ero-inu bá sì wà, ẹnikan wà nibẹ. Ìrònúmòye gigajulọ naa ni ti Ẹni Gigajulọ naa, Ẹlẹdaa ohun gbogbo tí nbẹ laaye, Ojúsun ìyè gan-an funraarẹ̀. (Psalm 36:9) Ẹlẹdaa naa dajudaju yẹ fun gbogbo ìyìn ati ọ̀wọ̀ jijinlẹ.—Psalm 104:24; Iṣipaya 4:11.”

Olesya sọ láṣìírí lẹ́yìn náà pé, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò jí àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n ti kú dìde ló mú kí òun fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A lérò pé ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní nínú àwọn ìsọfúnni tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun tí ó wà nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun” gbà tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nílé rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ ní ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́