ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/8 ojú ìwé 31
  • Ìrísí Ni O Ń Wò Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrísí Ni O Ń Wò Bí?
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ó Fara Da Ìjákulẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Máa Gbára Lé Èrò Tó Bá Kọ́kọ́ Wá sí Ọ Lọ́kàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/8 ojú ìwé 31

Ìrísí Ni O Ń Wò Bí?

O HA ń fi èèpo ẹ̀yìn ìwé kan pinnu bí ó ṣe dára sí bí? A lè tàn ọ́ jẹ. Láti yẹra fún ìyẹn, kọ́kọ́ yẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tó wà nínú rẹ̀ wò. A ṣàpèjúwe èyí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí olókìkí ẹ̀dá inú ìtàn ilẹ̀ Turkey kan, Nasreddin Hoja. (Ọ̀rọ̀ èdè Turkey náà, hoja, túmọ̀ sí “olùkọ́.”) Ó “jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ àti aláìmọ̀kan, ọlọgbọ́n àti òmùgọ̀ . . . Ó jẹ́ olùfọkànsìn, àmọ́ ó ní àwọn àìpé ẹ̀dá ènìyàn.” Òun ni “àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ àti èyí tí kò báradé” kì í rí gbé ṣe.—Tales of the Hoja, láti ọwọ́ John Noonan, Aramco World, September-October 1997.

Wọ́n sọ ìtàn kan nípa àjò kan tí ó lọ láti bẹ òṣìṣẹ́ kan wò ní Ottoman, kí ó sì jẹun alẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. “Láìfarabalẹ̀, [Nasreddin] sọ̀ kalẹ̀, ó sì kan ilẹ̀kùn gìrìwò tí ó wà ní iwájú ilé. Nígbà tí wọ́n ṣí i, ó rí i pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ àsè. Ṣùgbọ́n kí ó tó sọ ẹni tí òun jẹ́, bí ẹni tí ó pè é ti ń wo aṣọ rẹ̀ tí ìrìn àjò ti mú kí ó dọ̀tí, ó fi àìlọ́wọ̀ wí fún un pé òun kò pe àwọn alágbe.”

Nasreddin fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sídìí àpò ẹrù rẹ̀, ó sì “pààrọ̀ aṣọ, ó wọ aṣọ rẹ̀ tí ó dára jù lọ: ẹ̀wù gẹ̀rẹ̀jẹ̀ olówó-ńlá onísílíkì, tí wọ́n fi irun ẹran ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, àti láwàní onísílíkì gbígbòòrò kan. Bí ó ti ró dẹ́dẹ́ yìí, ó padà lọ sídìí ilẹ̀kùn ìta náà, ó sì tún kanlẹ̀kùn.

“Lọ́tẹ̀ yìí, ẹni tí ó pè é kí i káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà . . . Àwọn ìránṣẹ́ gbé oúnjẹ aládùn síwájú rẹ̀. Nasreddin Hoja da ọbẹ̀ abọ́ kan sínú àpò aṣọ rẹ̀ kan. Sí ìyàlẹ́nu àwọn àlejò yòókù, ó ki àwọn ekìrí ẹran dídín sínú ìṣẹ́tí láwàní rẹ̀. Lẹ́yìn náà, lójú ẹni tí ó pè é, tí inú ń bí, ó ti irun ẹran tí wọ́n fi ṣe iwájú aṣọ rẹ̀ bọ àwo àdàlú ìrẹsì àti ẹran eléròjà, ó ń kùn pé, ‘Jẹun, irun ẹran, jẹun!’

Ẹni tí ó pè é náà béèrè pé: “‘Kí ni èyí jẹ́?’

Hoja dáhùn pé: “‘Alàgbà mi ọ̀wọ́n, mo ń fún aṣọ mi lóúnjẹ ni. Bí o ṣe ṣe sí mi ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sẹ́yìn, ó hàn kedere pé kì í ṣe èmi fúnra mi lò ń ṣe lálejò, bí kò ṣe aṣọ mi!’”

Ẹ wo bí a ṣe máa ń fi ìrísí nìkan pinnu nǹkan lọ́nà òdì tàbí lọ́nà títọ́ nígbà púpọ̀ tó! Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì rò pé Élíábù, ẹ̀gbọ́n Dáfídì, gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba tí oyè kàn ní Ísírẹ́lì, Jèhófà wí fún un pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bẹ́ẹ̀ ni, ipò ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wò, kì í ṣe ìrísí. Kí ni ìwọ ń wò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Jèhófà kìlọ̀ fún Sámúẹ́lì láti má ṣe jẹ́ kí ìrísí tàn án jẹ

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́