‘Ó Dà Bí Lílá Oyin’
NÍ AGBEDEMÉJÌ ọdún 1993, ní Altus, Oklahoma, U.S.A., baba kan tí ń ṣàníyàn, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ àgbà fún olórí ẹ̀ka Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Òfuurufú United States, gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà láti ṣèrànwọ́ fún ọmọbìnrin rẹ̀ tó ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó, tó sì ń fẹ́ ṣe ìkọ̀sílẹ̀. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sẹ́nu ọ̀nà rẹ̀, ó sì fún un ní ìtẹ̀jáde Jí!, July 8, 1993, tó gbé kókó ẹ̀kọ́ náà, “Ìkọ̀sílẹ̀—Ọ̀nà si Igbesi-Ayé ti o Tubọ Munilayọ sii Ha Ni Bi?” jáde lákànṣe.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà kò fẹ́ràn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà kankan tẹ́lẹ̀, tí kò sì tẹ́tí sí wọn rí, ó gba ìwé ìròyìn Jí! yẹn láìjanpata, ó sì kà á. Lẹ́yìn náà, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ṣàjọpín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àwọn kókó tó wà nínú rẹ̀. Ó tún ka ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tó gbà pẹ̀lú Jí! náà. Ó ní àpilẹ̀kọ kan nínú, tó mú un ronú jinlẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ tó ti ní láti kékeré nípa Mẹ́talọ́kan. Ó mọ̀ pé a ń dáhùn àdúrà òun fún ìrànlọ́wọ́ nípa ọmọbìnrin òun, síbẹ̀, ó ṣe kàyééfì lórí ìdí tí Ọlọ́run yóò fi lo àwọn ènìyàn tí kò gba Mẹ́talọ́kan gbọ́ láti dáhùn àwọn àdúrà rẹ̀. Ó ronú pé, dájúdájú, Ọlọ́run kì í lo àwọn ènìyàn láti dáhùn àdúrà bí wọn kì í bá fi òtítọ́ kọ́ni.
Ìyẹn ló mú kí ó tẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láago, láti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ tí ń ṣàlàyé ní kíkún sí i nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa Mẹ́talọ́kan. Ìpàdé àwọn Kristẹni alàgbà ni ọkùnrin tó gbé tẹlifóònù náà wà. Olùrànlọ́wọ́ àgbà fún olórí ẹ̀ka ológun òfuurufú náà lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì fún un ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye àti ìwé pẹlẹbẹ Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ọkùnrin náà ka ìwé pẹlẹbẹ náà tán. Bí ó ti ń kà á, ó dùn mọ́ ọn gan-an, tí ó fi sọ lẹ́yìn náà pé, ńṣe ni òun ń dúró díẹ̀, tí òun sì ń sọ fún ara òun pé, ‘Fara balẹ̀. Èyí kò lè rí bẹ́ẹ̀. Èyí ti dùn ju kó jẹ́ òótọ́ lọ.’ Ó ṣàlàyé pé, ìwé pẹlẹbẹ náà pèsè ẹ̀rí láti inú Bíbélì lòdì sí Mẹ́talọ́kan lọ́nà tó ṣe kedere tó bẹ́ẹ̀ tí kíkà “á wulẹ̀ dà bí lílá oyin.” Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìpàdé àkọ́kọ́ tí yóò bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ohun tí ó gbọ́ sì dùn mọ́ ọn.
Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìgbà àkọ́kọ́ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì jíròrò kúnnákúnná lórí èrò Bíbélì nípa sìgá mímu, ó rún àwọn sìgá rẹ̀, kò sì tún fẹnu kan sìgá mọ láé. Wọ́n bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́pọ̀ ìgbà láàárín ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí ó ka ìwé pẹlẹbẹ Mẹ́talọ́kan, tí ó sì fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ológun, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá Àwọn Ẹlẹ́rìí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ní gbangba. Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run hàn, ó sì ṣe ìrìbọmi. Ó ń ṣiṣẹ́ sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nísinsìnyí.